Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìmúwàdéédéé Lẹ́yìn tí mo ka àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ̀bùn Ìmúwàdéédéé Tí Ọlọrun Fún Wa” (March 22, 1996), mo nímọ̀lára pé ó yẹ kí n dúpẹ́ lọ́wọ́ yín. Mo ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìgbọ́ròó lọ́wọ́lọ́wọ́, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ìwé kíkà mi tí ó ní ìsọfúnni pípé pérépéré, tí ó sì rọrùn láti lóye, bí àpilẹ̀kọ inú Jí! náà ti ṣe. Àwòrán etí náà fakọ yọ pẹ̀lú.
J. P. A., Brazil
Táì Ọrùn Ẹ ṣeun púpọ̀ fún àpilẹ̀kọ náà, “Ta Ló Hùmọ̀ Táì Ọrùn?” (May 8, 1996) Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ kan ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo ti ń di táì mọ́rùn níbi tí ojú ọjọ́ ti móoru ju ìwọ̀n 30 lọ lórí òṣùwọ̀n Celsius, nígbà tí mo bá ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà. Mo ti sábà ń ní àbá èrò orí náà pé, ó ní láti jẹ́ pé olùṣèwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ kan ní ọ̀rúndún kẹtàlá, tí ń fi ìkọ́ àkàbà, ìdè onírin, ìgbálóròóró, tàbí dídi táì mọ́rùn lọ́sàn-án gangan, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn kan, halẹ̀ mọ́ aládàámọ̀ kan láti jẹ́wọ́, ni ó hùmọ̀ táì ọrùn.
W. B., United States
Àwọn kan lè rò pé dídi táì mọ́rùn ní ipò ojú ọjọ́ èyíkéyìí jẹ́ ìdálóró. Bí ó ti wù kí ó rí, ó gboríyìn pé, ní àwọn ibi tí a ti ka táì ọrùn sí ìwọṣọ yíyẹ, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gbogbogbòò ń fara da àìbáradé tí dídi táì mọ́rùn ń mú wá nígbà tí wọ́n bá ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà àti nígbà tí wọ́n bá ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Tábà Tí Kò Ní Èéfín Ní kíláàsì ẹ̀kọ́ nípa ìlera ní ilé ẹ̀kọ́ wa, a ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa oògùn líle. Mo fi ẹ̀dà kan ìtẹ̀jáde Jí!, April 22, 1996, tí ó ní àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Tábà Tí Kò Ní Èéfín—Ó Ha Léwu Bí?,” han olùkọ́ mi. Ó jẹ́ kí n ṣe 30 ẹ̀dà àpilẹ̀kọ náà, kí ó lè fi wọ́n fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn kíláàsì rẹ̀, kí wọ́n sì jọ kà á. Àwọn ọmọ kíláàsì mi gbádùn rẹ̀, wọ́n sì gba ìwé ìròyìn mélòó kan lọ́wọ́ mi.
M. C., United States
Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni Ẹ ṣeun fún ọ̀wọ́ náà, “Nígbà Tí Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni Kì Yóò Sí Mọ́!” (May 22, 1996) Ní ṣíṣàjọpín ìwé ìròyìn náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, mo rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin mọyì àwọn àbá lórí bí a ṣe lè yẹra fún ìfòòró àti ohun tí ó yẹ láti ṣe bí a bá fòòró ẹni. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, èmi fúnra mi nírìírí ìfìbálòpọ̀-fìtínà-ẹni níbi iṣẹ́, mo sì fẹjọ́ sun àwọn ọlọ́pàá. Wọ́n gbóríyìn fún mi nítorí ọ̀nà tí mo gbà bójú tó ipò náà.
A forúkọ bò ó láṣìírí, Germany
Mo kún fún ìmoore fún àwọn àpilẹ̀kọ náà. Mo wà ní ọdún kejì nílé ẹ̀kọ́ gíga báyìí, mo sì ti nírìírí ìfòòró, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa rẹ̀ rí. Àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí ràn mí lọ́wọ́ láti máa fi àṣírí han àwọn òbí àti olùkọ́ mi. Ó ṣeé ṣe fún mi nísinsìnyí láti fìgboyà kojú àwọn afòòró-ẹni.
K. Y., Japan
Mo jẹ́ akọ̀wé, ọmọ ọdún 21, agbanisíṣẹ́ mi sì fìbálòpọ̀ fòòró mi láìpẹ́ yìí. Mo gba ìtẹ̀jáde Jí! yìí nígbà tí mo ṣì ń ronú lórí bí n óò ṣe sọ ìmọ̀lára mi fún un. Mo fún agbanisíṣẹ́ mi ní ẹ̀dà kan, tí ó kà. Ó tọrọ àforíjì, ó sì ṣèlérí pé òun kò tún níí ṣe ohun tí òun ṣe sí mi mọ́ láé.
D. N. I., Nàìjíríà
Mo mọrírì bí ẹ ṣe mú kókó ọ̀ràn pàtàkì yí wá sí ojútáyé, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn fọ́tò yín ṣe fi hàn, àwọn ọkùnrin nìkan ní ń fòòró ẹni. Ó ṣe kedere pé ojú ìwòye tí ẹ ń fúnni fì sápá kan.
H. T., United States
Ọ̀pọ̀ jù lọ olùṣèwádìí sọ pé àwọn obìnrin tí wọ́n fi ìbálòpọ̀ fòòró pọ̀ rẹpẹtẹ ju àwọn ọkùnrin lọ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn àpilẹ̀kọ náà gbà pé wọ́n lè fìbálòpọ̀ fòòró àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, ní fífúnni ní àwọn àpẹẹrẹ pàtó.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àpilẹ̀kọ lórí kókó yìí máa ń tẹnu mọ́ kìkì ohun tí àwọn obìnrin lè ṣe láti dáàbò bo ara wọn, ṣùgbọ́n, wọ́n kì í ka kíkọ́ àwọn ọkùnrin láti bọ̀wọ̀ fún àwọn obìnrin sí. Ó ṣe tán, bí kò bá sí àwọn afòòró-ẹni, kò níí sí ìfòòró. Àpilẹ̀kọ yín jíròrò “Ìwà Yíyẹ fún Àwọn Ọkùnrin.” Nítorí èyí, ó yẹ fún ìgbóríyìn.
O. C., Taiwan