Wíwo Ayé
Póòpù Sọ Pé, Àwọn Ènìyàn Ló Lẹ̀bi, Kì Í Ṣe Ṣọ́ọ̀ṣì
Nínú lẹ́tà kan tí Póòpù John Paul Kejì kọ sí àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn aláṣẹ ìlú, àti àwọn ènìyàn Rwanda, ó gbìyànjú láti yọ Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì nínú jíjíhìn fún ìpalápalù ẹ̀yà tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ní 1994. Ó wí pé: “A kò lè mú ṣọ́ọ̀ṣì náà jíhìn fún àwọn ìwà láìfí tí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ tí wọ́n ti hùwà lòdì sí òfin ìlànà ìgbàgbọ́ hù.” Síbẹ̀síbẹ̀, póòpù náà tún sọ pé: “Gbogbo àwọn mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì náà tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ lákòókò ìpalápalù ẹ̀yà náà gbọ́dọ̀ mọ́kàn láti kojú àwọn àbájáde àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá.” Ó hàn gbangba pé èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí póòpù yóò sọ̀rọ̀ ní gbangba nípa ẹ̀sùn pé àwọn àlùfáà ní Rwanda kópa, wọ́n sì ṣètìlẹ́yìn fún ìṣìkàpànìyàn tí ó gba ẹ̀mí nǹkan bí 500,000 ènìyàn àti ẹ̀sùn pé àwọn alákòóso Kátólíìkì kò gbé ìgbésẹ̀ kankan láti dá a dúró. Oníròyìn Luigi Accattoli, láti Vatican, kọ nínú ìwé agbéròyìnjáde Corriere della Sera ti Ítálì pé, ọ̀rọ̀ tí póòpù sọ pé kí àwọn Kátólíìkì má gbìyànjú láti yẹ ìdájọ́ òdodo sílẹ̀ “kan ọ̀ràn tí ń fa ìbínú,” ní ti pé “àwọn àlùfáà tí wọ́n ti wá ibi ìsádi lọ sí ilẹ̀ òkèèrè wà lára àwọn tí a fi ẹ̀sùn ìpalápalù ẹ̀yà náà kàn.” Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ènìyàn Rwanda ni wọ́n jẹ́ Kátólíìkì.
“Àwọn Ìdílé Ń Yí Pa Dà”
Ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail sọ pé: “Ìdílé kan tí a lè mú bí àpẹẹrẹ ní Kánádà ni ipò rẹ̀ ti yí pa dà bìrí gan-an débi pé àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti bí àwọn ọmọ jẹ́ ìpín 44.5 péré nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo ìdílé ibẹ̀.” Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra, “ní 1961, iye àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti bí àwọn ọmọ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 65 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo àwọn ìdílé ní Kánádà.” Iye mìíràn tí ń múni ta gìrì ni iye ìgbéyàwó àjọgbà, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìlọ́po mẹ́ta, láti orí 355,000 ní 1981 sí 997,000 ní 1995. Ìwádìí náà, tí Statistics Canada ṣe, tún sọ pé: “Bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀, ìtúngbèéyàwó-ṣe àti ìgbéyàwó àjọgbà bá ṣì ga bẹ́ẹ̀, a lè retí ìyípadà bìrí púpọ̀ sí i nínú ipò ìdílé.”
Ohun Tí Ó Fa Ilẹ̀ Faransé Mọ́ra Nínú Awo
Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times béèrè pé: “Kí ló dé tí àwọn ará ilẹ̀ Faransé fi ń lo àkókò tí ó pọ̀ gan-an lọ́dọ̀ àwọn aríran àti àwọn abẹ́mìílò lóde òní? Ìròyìn sọ pé púpọ̀ púpọ̀ sí i àwọn ará ilẹ̀ Faransé ń bẹ àwọn woṣẹ́woṣẹ́ àti àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìjẹ́pàtàkì òǹkà wò. . . . Ìjọba ní ẹ̀rí pé idán pípa ń gbilẹ̀ sí i. Lọ́dún tó kọjá, àwọn aláṣẹ agbowó-orí sọ pé àwọn asanwó-orí tí iye wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 50,000, iye púpọ̀ jù lọ tí a tí ì rí, ti sọ pé iye tí ń wọlé fún wọn jẹ́ láti inú iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí awòràwọ̀, oníṣègùn ìbílẹ̀, abẹ́mìílò àti àwọn iṣẹ́ tí ó jọra. Ní ìfiwéra, iye àwọn àlùfáà Roman Kátólíìkì ní orílẹ̀-èdè náà kò tó 36,000, tí àwọn oníṣègùn ọpọlọ sì jẹ́ 6,000.” Fún àwọn kan, ìgbòkègbodò náà tọ́ka sí ìbẹ̀rù ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún yìí. Àwọn mìíràn wò ó gẹ́gẹ́ bí àbájáde ìjórẹ̀yìn àwọn àjọ fífìdí múlẹ̀, bí ẹ̀sìn. Àwọn oníṣẹ́ yìí sọ pé agbo àwọn oníbàárà àwọn ti yí pa dà gan-an ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn obìnrin ló pọ̀ jù lọ lára àwọn oníbàárà wọn. Ní báyìí, iye àwọn ọkùnrin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ̀ tó ti àwọn obìnrin. Dípò yíyẹ iṣẹ́ wò nípa àìsàn àti ọ̀ràn ìfẹ́, àwọn ènìyàn ń yẹ iṣẹ́ wò nípa àwọn iṣẹ́ wọn.
Àwọn Ẹ̀rọ Ìtajà ní Japan
Ìwé agbéròyìnjáde The Washington Post sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tí kò sí nínú ẹ̀rọ ìtajà kan ní Japan.” Àwọn ẹ̀rọ ìtajà ń pín àwọn ẹ̀bùn tí a wé, àwọn ike ìkósọfúnnisí, ọtí bíà, ṣòkòtò péńpé àwọn akànṣẹ́, ẹyin, òkúta iyebíye, erin tí a fi tìmùtìmù ṣe, àkànpọ̀ ìbọ̀sẹ̀ àti pátá, kámẹ́rà aṣeégbéjùnù, àti ohunkóhun mìíràn tí o lè ronú kàn. “Àwọn ẹ̀rọ ìrajà tí a kò ní bẹ̀rẹ̀ kí a tóó lò ó” tí ń gbé nǹkan fúnni ní ọ̀gangan àyà, àwọn ẹ̀rọ tí a ṣe níbàǹbalẹ̀ tí kò ní díni lójú, àti àwọn ẹ̀rọ tí a fi òdòdó tàbí àwọn ohun ọnà mèremère mìíràn ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pàápàá wà. Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé: “Japan tóbi tó ìwọ̀n Montana gẹ́lẹ́, àmọ́ àwọn ẹ̀rọ ìtajà tí ó wà níhìn-ín fẹ́rẹ̀ẹ́ tó èyí tí ó wà ní gbogbo United States. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹ̀rọ ìtajà ní Japan ni a gbé síta; ọ̀kan tilẹ̀ wà ní orí Òkè Ńlá Fuji tí òjò dídì bò.” Àwọn nǹkan olówó ńlá ni a lè pín fúnni ní ìta nítorí pé ìwọ̀n ìmọ̀ọ́mọ̀ ba ohun ìní jẹ́ kò pọ̀ ní Japan. Àyè gbówó lórí, nítorí náà àwọn tí wọ́n ní ilé ìtajà ń lò àwọn ẹ̀rọ ìtajà láti mú kí àyè ibi ìkóǹkansí wọn fẹ̀ sí i. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo igun òpópónà ni a ti lè rí wọn ní Tokyo. Bí ó ti wù kí ó rí, inú ń bí àwọn àwùjọ kan pé ọmọdé èyíkéyìí tí ó bá lè ki owó ẹyọ mélòó kan bọ ẹ̀rọ náà lè rí ohun ọlọ́tí, ọtí bíà, àti sìgá gbà.
“Ìbẹ́sílẹ̀ Ìwà Ọ̀daràn” Àwọn Aṣẹ̀ṣẹ̀di Ọ̀dọ́langba
Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ nípa ìròyìn kan tí Àpérò Lórí Ìwà Ọ̀daràn ní America, àjọ àwọn agbẹjọ́rò àti àwọn ògbógi agbófinró gbé jáde pé: “Ìwà ọ̀daràn oníwà ipá ní United States jẹ́ ‘bọ́ǹbù olóró tí ń ka àkókò’ tí yóò bú gbàù ní ọdún díẹ̀ sí i. Nígbà tí àwọn àgbàlagbà ń hùwà ọ̀daràn oníwà ipá níwọ̀nba, ìwọ̀n ìwà ọ̀daràn oníwà ipá tí àwọn ọ̀dọ́langba ń hù ti ròkè lálá láàárín ẹ̀wádún tí ó kọjá. . . . Ìran àwọn ọ̀dọ́langba kọ̀ọ̀kan ti kún fún ìwà ipá púpọ̀ ju èyí tí ó ṣáájú wọn láti àwọn ọdún 1950 lọ.” Nígbà tí ó bá fi máa di ọdún 2005, iye àwọn ọmọkùnrin ọlọ́dún 14 sí 17 yóò fi ìpín 23 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i, ìlọsókè yí ló sì ń da àwọn ògbógi láàmú. Ní ṣíṣàníyàn nípa pé àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ọ̀daràn nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé ni ọ̀daràn tí ó burú jù lọ, John J. DiIulio, Kékeré, tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìṣèlú àti àwọn àlámọ̀rí aráàlú ní Yunifásítì Princeton, sọ pé: “A wà ní àkókò ìtura ráńpẹ́ tí ó ṣáájú ìbẹ́sílẹ̀ ìwà ọ̀daràn.” Ìròyìn rẹ̀, tí a ṣàkójọ fún Àpérò Lórí Ìwà Ọ̀daràn ní America, fi hàn pé àwọn ènìyàn tí a ti fàṣẹ mú rí, àmọ́ tí a ti dá wọn sílẹ̀ lábẹ́ àyẹ̀wò, tí a fún ní òmìnira lábẹ́ àbójútó, tàbí ìdásílẹ̀ ṣáájú ìgbẹ́jọ́ ní ń lọ́wọ́ nínú nǹkan bí ìdá mẹ́ta lára gbogbo ìwà ọ̀daràn oníwà ipá. Ìròyìn náà sọ pé, ìjọba ló ni ẹrù iṣẹ́ láti dáàbò bo àwọn tí ó ń ṣàkóso lé lórí, àmọ́ ó ń kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀ Ń Gbagbára Sí I
Ìwé agbéròyìnjáde The Hartford Courant sọ pé, ní òpin ọdún 1996, ilé ìwòsàn kan ní Hartford, Connecticut, U.S.A., dara pọ̀ mọ́ àwọn 56 mìíràn jákèjádò orílẹ̀-èdè náà tí wọ́n ní “ibùdó tí kì í lo ẹ̀jẹ̀ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn ṣíṣèwádìí nípa èròǹgbà náà, àwọn alábòójútó ilé ìwòsàn rí i pé ìfẹ́ ọkàn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn aláìsàn míràn mọ́.” Nípa lílo oògùn àti àwọn ìlànà iṣẹ́ abẹ gíga, àwọn dókítà ń pààrọ̀ ẹ̀yà inú ara àti oríkèé egungun ara àti iṣẹ́ abẹ ọkàn àyà, àrùn jẹjẹrẹ, àti àwọn iṣẹ́ abẹ mìíràn—gbogbo rẹ̀ láìní lílo ẹ̀jẹ̀ nínú. Ní àfikún, ọ̀pọ̀ àwọn amọsẹ́dunjú abójútó ìlera ń jẹ́wọ́ mímọ àwọn ewu tí ó wà nínú gbígba ẹ̀jẹ̀ sára ní gbangba nísinsìnyí. Dókítà David Crombie, Kékeré, ọ̀gá àgbà àwọn oníṣẹ́ abẹ ní Ilé Ìwòsàn Hartford, jẹ́wọ́ gbà láìṣẹ̀tàn pé: “Mo kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn mi ní àkókò tí a ka ẹ̀jẹ̀ sí tọ́níìkì. Nísinsìnyí, a ń kà á sí májèlé.” Léraléra ni Bíbélì ti dẹ́bi fún gbígba ẹ̀jẹ̀ sínú ara.—Jẹ́nẹ́sísì 9:4; Léfítíkù 17:14; Ìṣe 15:28, 29; 21:25.
Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Ha Ń Kó Másùnmáwo Bá Ọ Bí?
Àwọn tẹlifóònù alágbèéká, àwọn ìhùmọ̀ agbàsọfúnni ahangooro, àwọn ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni, àwọn kọ̀ǹpútà tí a ń lò nínú ilé, àti àwọn ìhùmọ̀ aṣèyípadà-àmì-ìsọfúnni ti yí ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ pa dà tegbòtigaga. Bí ó ti wù kí ó rí, Dókítà Sanjay Sharma, tí ó ní ọkàn ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú ṣíṣètọ́jú másùnmáwo, lérò pé ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tuntun yìí ti tún ya bo ibi ìkọ̀kọ̀ àti àkókò ìgbafàájì àwọn ènìyàn. Àbájáde rẹ̀ jẹ́ ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí ń kó másùnmáwo báni. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star ti sọ, “másùnmáwo jẹ́ lájorí okùnfà àìsàn, àìlèmú irú jáde àti ikú àìtọ́jọ́.” Àwọn àbáyọrí rẹ̀ ní nínú, ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn ọkàn àyà, ìmọ̀lára tí kò dúró sójú kan, ẹ̀fọ́rí, iṣan tí kò fara rọ, àìróorunsùn-tó, ìsoríkọ́, àti àìlágbára ètò ìgbékalẹ̀ adènà àrùn. Báwo ni o ṣe lè dènà dídi ẹni tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ń kó másùnmáwo bá? Dájúdájú, ó sábà máa ń bọ́gbọ́n mu láti kàn sí dókítà rẹ. Ní àfikún, ìròyìn náà dámọ̀ràn eré ìmárale déédéé, gbígba ìsinmi lópin ọ̀sẹ̀, àti gbígba oòrùn sára lójoojúmọ́, tí “ń ṣokùnfà ìtúsílẹ̀ àwọn omi ìsúnniṣe tí ń gbógun ti ìsoríkọ́ àti másùnmáwo.” Ní paríparí rẹ̀, “yí agogo inú tẹlifóònù àti ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni rẹ pa. Jẹ́ kí ẹ̀rọ tí ń gba ohùn sílẹ̀ nínú tẹlifóònù máa dáhùn tẹlifóònù.”
Ẹyẹ Blackbird Tí Ń Dún Bí Agogo Ìdágìrì Ọkọ̀ Ayọ́kẹ́lẹ́
Àwọn ẹyẹ blackbird ń dá ìṣòro ṣíṣàjèjì sílẹ̀ ní ìlú Guisborough ní Àríwá Yorkshire ti England—wọ́n ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn ta gìrì jí lójú oorun nídàájí nípa sísín àwọn agogo ìdágìrì inú àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ jẹ. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London ròyìn pé: “Nígbà tí àwọn tí wọ́n ni wọ́n bá sá jáde láti lọ ko àwọn olè lójú, wọ́n sábà máa ń rí ẹyẹ blackbird kan tí ń kọrin lọ́wọ́.” Olùgbé àdúgbò kan sọ pé: “Ó ní ìró ohùn àti ìwọ̀n ohùn gẹ́lẹ́ bíi ti agogo ìdágìrì ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Orí gbogbo wa yóò dà rú.” Kò sì ní sí ìsinmi púpọ̀. Bí ẹyẹ kan ti ń dá orin tuntun kan fún òmíràn, ìró rẹ̀ lè wá di èyí tí ó wọ́pọ̀ gan-an. Ní gidi, nǹkan bí 30 lára àwọn irú ọ̀wọ́ ẹyẹ ilẹ̀ Britain ni wọ́n lè sín àwọn ìró mìíràn jẹ. Ẹyẹ starling wíwọ́pọ̀ ni ó ní ẹ̀bùn jù lọ nínú gbogbo wọn, ó sì lè fìrọ̀rùn sín ìró ìpè àwọn ẹyẹ mìíràn jẹ. A mọ ọ̀kan tí ó máa ń sín dídún agogo tẹlifóònù jẹ lọ́nà tí ń jẹ́ gidi débi pé a kò lè mọ̀ ìyàtọ̀ láàárín dídún ti ayédèrú àti ti tẹlifóònù gangan.
Àjọ̀dún Àwọn Kèfèrí Ṣì Wọ́pọ̀
Ìwé agbéròyìnjáde Folha de S. Paulo ti Brazil ròyìn pé, Ọjọ́ Jòhánù Mímọ́ Oníbatisí “kò ní nǹkan púpọ̀ láti ṣe pẹ̀lú ẹni mímọ́ Kátólíìkì náà ju bí ènìyàn ṣe rò lọ.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọ̀dún náà “bọ́ sọ́jọ́ kan náà pẹ̀lú ọjọ́ tí wọ́n sọ pé wọ́n bí ẹni mímọ́ náà, . . . ayẹyẹ gidi náà jẹ́ ti iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà.” Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde ń ṣàkójọ àwọn ìwádìí onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn náà, Câmara Cascudo, ó sọ pé: “Àwọn ìsìn awo nípa oòrùn tí ó jẹ́ ti àwọn ará Germany àti àwọn ti Celt” ṣayẹyẹ àjọ̀dún náà nígbà ìkórè “kí a baà lè lé àwọn ẹ̀mí èṣù ayanilágàn, àwọn kòkòrò ọkà, àti ọ̀dá dà nù.” Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn Potogí gbé àjọ̀dún náà wá sí Brazil. Apá fífanimọ́ra kan nínú àjọ̀dún náà tí ó ṣì wà síbẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ni títan iná Jòhánù Mímọ́. Ibo ni àṣà yí ti pilẹ̀ ṣẹ̀? Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Àṣà náà . . . ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìjọsìn ọlọ́run oòrùn, tí wọ́n ń júbà kí ó má baà lọ jìnnà sí ilẹ̀ ayé àti kí wọ́n má baà fara gbá àkókò òtútù tí ó mú jù.”