ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 5/8 ojú ìwé 31
  • Ta Ló Hùmọ̀ Táì Ọrùn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ló Hùmọ̀ Táì Ọrùn?
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Àṣà Aṣọ Kò Dúró Sójú Kan
    Jí!—2003
  • Bí Bíbélì Èdè Faransé Ṣe Jìjàkadì Láti Máa Wà Nìṣó
    Jí!—1997
  • A Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀tọ́ Àwọn Aláìsàn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 5/8 ojú ìwé 31

Ta Ló Hùmọ̀ Táì Ọrùn?

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKÒRÒYIN JÍ! NÍ GERMANY

NÍ GBOGBO àgbáyé, nǹkan bí 600 mílíọ̀nù ọkùnrin ní ń dè é mọ́rùn déédéé. Ní ilẹ̀ Germany, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ní nǹkan bí 20 táì. Nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin bá ń de táì mọ́ ọrùn, wọn máa ń fi ìkanra ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ló tilẹ̀ dá díde táì sílẹ̀, pàápàá?’ Ibo ni táì ọrùn ti pilẹ̀ ṣẹ̀?

Steenkerke, ìlú kan ní Belgium, ni ó gba ògo jíjẹ́ ìlú tí ó “hùmọ̀” táì ọrùn. Ní 1692, agbo ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọ lu agbo ọmọ ogun ilẹ̀ Faransé kan tí ó wà níbẹ̀ lójijì. Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Germany náà Frankfurter Allgemeine Sonntagszeitung sọ pé, “àwọn ọ̀gá ológun [ilẹ̀ Faransé] kò ní àyè láti múra dáradára. Ṣùgbọ́n wọn yóò yára ta ìdikù ìṣọ̀ṣọ́ ara aṣọ iṣẹ́ wọn ní kókó mọ́ ọrùn díẹ̀, wọn yóò sì ki etí ìdikù náà bọ inú ihò bọ́tìnnì aṣọ àwọ̀lékè wọn. Ẹ ò rí nǹkan, bí táì ọrùn ṣe rí lákọ̀ọ́kọ́ dáyé rẹ̀ nìyẹn.”

Bí ó ti wù kí ó rí, irú ọ̀nà ìwọṣọ tuntun àwọn sójà náà kì í ṣe àṣà ìwọṣọ tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí. Àwọn ògbógi nípa ìtàn táì tọ́ka sí i pé ní àwọn ọ̀rúndún tí ó ṣáájú, àwọn jagunjagun olú-ọba ilẹ̀ China náà Cheng (Shih Huang Ti) máa ń de aṣọ tí ó jọ ìdikù, tí ń fi ipò wọn hàn, mọ́rùn.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àfàìmọ̀ kí ó máà jẹ́ pé èyí tí ó lókìkí jù lọ ni àwọn ìdikù tí àwọn ará Croatia tí ń jagun fún Ọba Louis Kẹrìnlá ilẹ̀ Faransé máa ń dè mọ́rùn. Nígbà ìwọ́de ìjagunmólú kan ní Paris, àwọn ìdikù àwọn ará Croatia wu àwọn ará Faransé débi tí wọ́n fi ń pè wọ́n ní cravates, ọ̀rọ̀ tí ó wá láti inú Cravate, ará Croatia, àwọn pẹ̀lú sì bẹ̀rẹ̀ sí í de àwọn ìdikù náà mọ́rùn. Ìwé agbéròyìnjáde tí a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ náà sọ pé: “Láti ìgbà náà ni àṣà díde táì ọrùn ti bẹ̀rẹ̀ sí í tàn kálẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn sójà ní Steenkerke ni wọ́n kọ́kọ́ fi ìdikù de táì.”

Nígbà Ìṣọ̀tẹ̀ Faransé (1789 sí 1799), ọkùnrin kọ̀ọ̀kan máa ń fi ìtẹ̀sí èrò rẹ̀ lórí ìṣèlú hàn nípa àmì “croat,” tàbí ìdikù, tí ó dè mọ́rùn. Ní ọ̀rùndún kọkàndínlógún, ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn aṣọ̀ṣọ́ ilẹ̀ Europe “bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkíyèsí” irú ìmúra yìí. Ìgbà yẹn ni wọ́n gbé cravat lárugẹ lágbo àwọn ọmọ ogun àti ìṣèlú, ó sì wọ inú àṣà ìwọṣọ gbogbo ọkùnrin lápapọ̀. Lónìí, kì í ṣe pé a tẹ́wọ́ gba táì láàárín àwùjọ àwọn ènìyàn púpọ̀ ní àgbáyé nìkan ni; ó tilẹ̀ jẹ́ kànńpá ní àwọn ibì kan.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Historic Costume in Pictures/Dover Publications, Inc., New York

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́