ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 10/8 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrírí Agbonijìgì Tí Maggy Ní àti Ìbùkún Mi
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 10/8 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Bíbójútó Ọ̀ràn Ìnáwó Mo dúpẹ́ fún ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Báwo Ni O Ṣe Lè Bójú Tó Ọ̀ràn Ìnáwó Rẹ?” (December 22, 1996) Mo máa ń náwó jù, n kò sì ní ìkóra-ẹni-níjàánu tó. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn tí mo ka àwọn àpilẹ̀kọ náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi ètò sí ọ̀nà tí mo ń gbà náwó. Nísinsìnyí, bí ojú mi bá wọ nǹkan kan, mo máa ń bi ara mi léèrè bóyá mo nílò ohun tí mo rí náà ní ti gidi.

J. B., Brazil

Ó ti pé oṣù márùn-ún tí ọkọ mi kò ti ní iṣẹ́ lọ́wọ́, a sì ní ọmọ mẹ́ta láti bójú tó. Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi díẹ̀ lára àwọn àbá tí ó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà sílò. Mo ra ìwé kan, mo fa ilà mélòó kan sí i, mo sì ṣe ìwéwèé ìnáwó kan. Lọ́nà yí, ó ti ṣeé ṣe fún wa láti ṣún owó wa ná fún oṣù mẹ́ta tó kọjá, a sì ṣì ní owó díẹ̀ nílẹ̀ fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò retí. Wíwéwèé ìnáwó gbéṣẹ́ gan-an!

L. S., Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech

Kíkojú Àwọn Àdánwò Mo nímọ̀lára àìgbọ́dọ̀máṣe láti sọ̀rọ̀ nípa àpilẹ̀kọ náà, “Mo Gba Okun Láti Kojú Àwọn Àdánwò Níwájú.” (December 22, 1996) Ọ̀nà tí Edward Michalec gbà forí ti díẹ̀ lára àwọn ipò lílekoko jù lọ mú mi lọ́kàn. Ìfẹ́ rẹ̀ fún Jèhófà, ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, àti òtítọ́ hàn kedere nínú ìwà ìdúróṣinṣin àti ìfaradà onísùúrù rẹ̀.

K. B., United States

Ìrírí Agbonijìgì Tí Maggy Ní Ẹ ṣeun tí ẹ gbé àpilẹ̀kọ náà, “Ìrírí Agbonijìgì Tí Maggy Ní àti Ìbùkún Mi” (December 22, 1996), jáde. Ó ṣòro fún mi láti má sunkún bí mo ti ń kà nípa ìrúbọ tí ìyá yìí ṣe ní àwọn ọjọ́ tó kẹ́yìn tó lò láyé kí ó baà lè bí ọmọbìnrin rẹ̀ kí ara rẹ̀ yá gágá. Mo tún mọrírì ọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀ pé ìrora òun ń dín kù díẹ̀díẹ̀ bí òun ti ń sọ nípa pípàdánù ìyàwó òun—kókó ọ̀rọ̀ tí a lè ní ìtẹ̀sí láti yẹra fún tí a bá ń bá àwọn ẹbí ẹni tó kú sọ̀rọ̀. Mo fojú sọ́nà láti mọ Maggy nígbà àjíǹde.

L. S. C., Sípéènì

Àpilẹ̀kọ náà ṣàṣefihàn bí àwa tí a wà nínú ìjọ ṣe lè fi àníyàn gidi hàn fún ara wa. Àwọn Kristẹni ará pèsè oúnjẹ fún ọkọ Maggy fún ọ̀pọ̀ oṣù, wọ́n sì tún fún un ní aṣọ fún ọmọ rẹ̀. Ẹ wo irú ẹ̀kọ́ tí èyí jẹ́ fún wa láti ṣe púpọ̀ sí i ju wíwulẹ̀ fi káàdì ránṣẹ́ tàbí kí a tẹni láago lórí tẹlifóònù lọ!

P. L., United States

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín tọkàntọkàn fún àpilẹ̀kọ yìí. Ìyàwó mi kú nínú ìjàǹbá ọkọ̀ ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn tí Maggy kú, ó sì fi ọmọ mẹ́jọ sílẹ̀ fún mi. Mo mọ ìrora tí Lorne Wilkins ní tí ó sì jẹ́ dandan pé yóò ṣì ní. Ẹ ṣeun fún gbígbé irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ jáde fún wa. Ní tòótọ́, wọ́n jẹ́ ìtìlẹ́yìn àti ìṣírí fún gbogbo àwọn tí wọ́n la irú ìrírí agbonijìgì bẹ́ẹ̀ kọjá.

B. B., ilẹ̀ Faransé

Ọ̀rẹ́ Kòríkòsùn Kó Lọ Mo fẹ́ láti fi ìmọrírì mi jíjinlẹ̀ hàn fún àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Ọ̀rẹ́ Kòríkòsùn Mi Fi Kó Lọ Síbòmíràn?” (December 22, 1996) Àkókò tó dé sí bá a mu gẹ́lẹ́. Láìpẹ́, ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi yóò kó lọ; òun àti ọkọ rẹ̀ ń lọ ṣiṣẹ́ sìn ní ìjọ kan níbi tí àìní ti wà fún àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo bá a yọ̀ gan-an, mo mọ̀ pé ayun rẹ̀ yóò yun mi gan-an. Ẹ ṣeun fún ìmọ̀ràn gbígbámúṣé yín.

R. A., Ítálì

Ẹ kò lè finú wòye bí àpilẹ̀kọ náà ṣe ru mí sókè tó nígbà tí alábòójútó àyíká wa, òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò, kúrò lọ́dọ̀ wa láti lọ sìn ní àgbègbè tuntun kan. Ó ti ṣaájò mi gan-an nípa tẹ̀mí àti ti èrò ìmọ̀lára. Gẹ́gẹ́ bí fọ́tò inú àpilẹ̀kọ náà ṣe fi hàn, dídágbére jẹ́ ìrírí aronilára kan. Ẹ wo bí àwọn àbá tí ẹ dá ṣe bọ́ sákòókò tó ní ríràn mí lọ́wọ́ láti kojú ìdáwà náà.

J. D., Nàìjíríà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́