Ìpakúpa Ní Èbúté Arthur—Èé Ṣe Tí Ó Fi Ṣẹlẹ̀?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA
NÍ Ọ̀SÁN Sunday, April 28, 1996, ojú ọjọ́ gbádùn mọ́ni ní Ọ̀gangan Ibi Ìtàn ní Èbúté Arthur, ibùdó tí ó gbajúmọ̀ fún àwọn arìnrìn àjò afẹ́ ní Tasmania, Australia. Ilé Oúnjẹ Broad Arrow kún fọ́fọ́ fún àwọn ènìyàn tí ń jẹ oúnjẹ ọ̀sán. Ní nǹkan bí agogo 1:30 ọ̀sán, ọ̀dọ́kùnrin onírun pípọ́n, ẹni ọdún 28 kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹun ọ̀sán tán ní àyè ìjẹun iwájú ilé oúnjẹ náà, wọnú ilé ọ̀hún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn.
Àwọn oníbàárà ṣubú sórí àga wọn pẹ̀lú oúnjẹ lẹ́nu wọn, wọ́n sì kú. Àwọn ọlọ́pàá sọ pé, ó “dà bí ìpakúpa ojú ogun.” Nígbà tí oníbọn náà rò pé gbogbo wọ́n ti kú—ó ti pa 20 ènìyàn—ó yan fanda jáde. Láàárín ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan, ó ti pa iye ènìyàn tí ó ju iye tí ẹnikẹ́ni tí ì pa ní orílẹ̀-èdè Tasmania tí ó wà ní erékùṣù náà, láàárín ọdún mẹ́rin tó ṣáájú lọ!
Síbẹ̀, oníbọn náà ṣì ń bá ìpànìyàn láìdábọ̀ rẹ̀ lọ, tí ó ń fọgbọọgbọ́n pa àwọn tí ó bá kó sí i lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí ó ti ń lọ sí ọ̀nà àbájáde ọ̀gangan ibi ìtàn náà, ó rí Nanett Mikac pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ kéékèèké. Ó pa Nanett àti ọmọ rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà, bí ọmọ ọlọ́dún mẹ́fà ṣe ń gbìyànjú láti sá là, ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tọ̀ ọ́, ó sì yìnbọn pa á níbi tí ìyẹ́n ti fara pamọ́ sí ẹ̀yìn igi kan.
Lẹ́yìn ìyẹn, níbi tí wọ́n ti ń sanwó ní ọ̀nà àbáwọlé ọ̀gangan ibi ìtàn náà, oníbọn náà pa àwọn ènìyàn mẹ́ta tí ń bẹ nínú (ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́) BMW kan, ó sì gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà lọ. Bí ó ti lọ síwájú díẹ̀, ó pàdé àwọn tọkọtaya kan nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mìíràn. Tipátipá, ó ti èyí ọkùnrin mọ́ àyè ìkẹ́rùsí ọkọ̀ BMW náà, ó sì pa obìnrin tí ó wà pẹ̀lú ọkùnrin náà. Ó wáá wa ọkọ̀ náà lọ síwájú díẹ̀ dé ilé èrò Seascape Cottage—ó débẹ̀ ní nǹkan bí agogo 2:00 ọ̀sán. Níbẹ̀ ni ó ti dáná sun ọkọ̀ BMW náà, ó sì de ọkùnrin tí ó fipá jí gbé náà àti àwọn arúgbó tọkọtaya tí ó ni ilé èrò náà nígbèkùn. Ó ti tún pa ènìyàn 12 láti ìgbà tí ó ti kúrò ní ilé èrò náà, tí ó sọ iye ẹni tí ó ti pa di 32. Ó ti pa ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn lára.
Ìwàásù Lọ́sàn-án Sunday
Láàárín àkókò kan náà, Jenny Ziegler àti ìdílé rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ara Ìjọ Èbúté Arthur ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, pàdé pọ̀ ní agogo 1:30 ọ̀sán ní ìmúra sílẹ̀ fún kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ìdílé náà wáá forí lé ìhà Ọ̀gangan Ibi Ìtàn ní Èbúté Arthur. Jenny ń fẹ́ẹ́ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ David Martin, ẹni bí ọ̀rẹ́ tí ó ni ilé èrò Seascape Cottage. Nígbà kan ṣáájú, òun àti Kristẹni arábìnrin mìíràn kan ti gbádùn ìjíròrò Bíbélì pẹ̀lú ọkùnrin náà.
Ìṣẹ́jú díẹ̀ lẹ́yìn agogo 2:00 ọ̀sán, bí Jenny, ọkọ rẹ̀, àti àwọn ọmọ wọ́n ṣe ń sún mọ́ ilé èrò náà, wọ́n rí i tí èéfín ń rú jáde láti ara ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tí ń jóná lórí pápá iwájú ilé náà. Àwọn ọlọ́pàá dá wọn dúró, wọ́n sì sọ fún wọn pé kí wọ́n padà sí ọ̀nà tí wọ́n bá wá. Jenny sọ pé: “Ó jọ pé àyíká náà ń tọ́ka ìjàm̀bá fún wa. Ó jọ pé àwọn ènìyán ti pa àwọn ojú ọ̀nà ibẹ̀ tì lọ́nà ṣíṣàjèjì.”
Bí ó ti wù kí ó rí, láìmọ̀ pé ohunkóhun kù díẹ̀ káà tó ní ti gidi, ìdílé náà yà bàrá kúrò lójú ọ̀nà ńlá náà láti lọ sí etíkun kékeré kan, kí wọ́n sì máa bá iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n wéwèé fún nìṣó. Níbẹ̀, ó jọ pé gbogbo nǹkán rí bí ó ti máa ń rí: Àwọn ọmọdé ń lúwẹ̀ẹ́, àwọn ènìyàn ń rìn létí òkun níhà kejì lọ́hùn-ún, àwọn arúgbó tọkọtaya kán sì jókòó nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn, wọ́n ń kàwé. Jenny sọ pé: “Ọkọ mí tọ̀ wọ́n lọ, ìjíròrò alárinrin kán sì ṣẹlẹ̀. Ó sọ fún wọn pé, ó jọ pé ìṣòro kán ṣẹlẹ̀ ní ojú ọ̀nà ńlá náà, ó sì dábàá pé bí wọ́n bá ṣe tán láti kúrò létíkun náà, kí wọ́n gba ọ̀nà míràn. Mo bá ọ̀dọ́kùnrin kan sọ̀rọ̀ díẹ̀, a sì kúrò níbẹ̀ láìpẹ́ lẹ́yìn náà.”
Ìdílé Ziegler gba ojú ọ̀nà náà lọ síhà Ọ̀gangan Ibi Ìtàn ní Èbúté Arthur. Jenny ṣàlàyé pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wà níbẹ̀, tí wọ́n fi dí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà. A wáá mọ̀ lẹ́yìn náà pé wọ́n fi wọ́n dí àwọn òkú tí wọ́n yìnbọn pa náà, kí àwọn ènìyàn má baà máa rí wọn ni. Ọkùnrin kán sọ fún wa pé: ‘Orí àwé kan ti yí tòun tìbọn lọ́wọ́; nǹkan bí ènìyàn 15 ti kú!’ A rọ̀ wá láti kúrò níbẹ̀ lọ́gán.”
Ó Wá Sópin Ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀
Ìrírí agbonijìgì náà kò tí ì wá sópin, gẹ́gẹ́ bí Jenny ṣe wí: “Pípadà wa lọ sílé jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ adánniwò kan, nítorí pé a kò mọ ibi tí oníbọn náà wà. Nígbàkigbà tí a bá pàdé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mìíràn lójú títì, a máa ń ṣe kàyéfì pé bóyá ó wà nínú rẹ̀. Àní nígbà tí a ti délé láyọ̀ tán pàápàá, a nímọ̀lára pé a lè bọ́ sọ́wọ́ rẹ̀, níwọ̀n bí a ti ń gbé agbègbè àdádó kan, níbi tí ẹnikẹ́ni tí ó bá mojú ilẹ̀ àdúgbò náà lè fìrọ̀rùn sá pamọ́ sí. Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wá ti mọ ibi tí a forí lé lọ́sàn-án yẹn, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ wá láago láti mọ àlàáfíà wa.
“Bí a ṣe ń ronú lórí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ náà, a mọ̀ pé, ká ní a ti ṣe ìbẹ̀wò wa dé ọ̀dọ̀ onílé èrò náà ní ìṣẹ́jú mélòó kan ṣáájú ni, ó ṣeé ṣe kí a wà lára àwọn tí wọ́n kú náà. Ó múni wá rìrì láti ronú pé apànìyàn náà tilẹ̀ lè ti dojú ìbọn rẹ̀ kọ wá bí a ṣe ń dúró bá àwọn ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ níbẹ̀!”
Ní òru Sunday yẹn, ó lé ní 200 ọlọ́pàá tí ó rọ̀gbà yí ilé èrò náà ká, tí wọ́n ń ba mọ́lẹ̀ láti yẹra fún ọta ìbọn tí oníbọn náà ń yìn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ó ṣe kedere pé, ó béèrè fún hẹlikópítà kan láti fi sá lọ, ṣùgbọ́n ìdúnàádúrà náà kò kẹ́sẹ járí lóru náà. Ní nǹkan bí agogo 8:00 òwúrọ̀ Monday, èéfín bẹ̀rẹ̀ sí í rú láti inú ilé náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oníbọn náà fara jóná, síbẹ̀, ó jáde lóòyẹ̀. Wọ́n rí òkú àwọn òǹdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, lára èyí tí onílé èrò tí àwọn Ziegler gbìyànjú láti bẹ̀ wò náà wà, nínú eérú àjókù ilé náà, tí ó sọ iye àwọn tí ó kú di 35.
Èé Ṣe Tí Ó Fi Ṣẹlẹ̀?
Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méje ṣáájú, ní March 13, oníbọn kan ní Dunblane, Scotland, ti wọ ibi ìṣeré ìdárayá ilé ẹ̀kọ́ kan, tí ó sì yìnbọn pa àwọn ọmọ kéékèèké 16 àti olùkọ́ wọn. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àfidáṣà inú ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n látijọ́ rí kan, “Bí ó bá ti ní ọ̀ràn ìtàjẹ̀sílẹ̀ nínú, ó máa ń gbawájú,” èyí di kókó ìròyìn àgbáyé. Àwọn ògbóǹkangí nípa ìwà ẹ̀dá mélòó kan dábàá pé oníbọn ti Australia lè ti máa gbìyànjú láti pa ju iye tí ó kú ní Dunblane lọ. Lọ́nà tí ó gbàfiyèsí, ní United States, ẹni tí wọ́n ń pè ní apànìyàn Zodiac, tí ó ti kó ìpáyà bá New York City fún ọ̀pọ̀ ọdún, sọ pé òún ti gbìyànjú láti pa ju iye ènìyàn tí àwọn apànìyàn tí òún tí ì kà nípa wọn rí pa lọ ni.
Kókó abájọ mìíràn tí ọ̀pọ̀ ènìyán sọ pé ó ń dá kún àjàkálẹ̀ ìpànìyàn náà ni ìbálòpọ̀ àti ìwà ipá tí a ń gbé jáde nínú àwọn fíìmù àti fídíò. Ìwé agbéròyìnjáde Herald Sun ti Australia ròyìn pé: “Àròpọ̀ 2000 fídíò ìwà ipá àti àwòrán ìhòòhò ni a ti fòfin kó lọ láti ilé apànìyàn lọ́pọ̀ yanturu náà ní Èbúté Arthur, Martin Bryant. . . . Ìṣàwárí ibi ìkópamọ́ fídíò náà wáyé nígbà tí àfiyèsí yí sórí ipa tí àwọn sinimá oníwà ipá kó nínú ìpakúpa tí ó ṣẹlẹ̀ ní Èbúté Arthur náà.” Bákan náà ni ìwé agbéròyìnjáde Daily News ti New York ròyìn pé “àpótí àwọn fídíò aláwòrán ìhòòhò méjì wà lórí bẹ́ẹ̀dì” apànìyàn Zodiac tí ó ti jẹ́wọ́ náà.
Nígbà tí ìpakúpa tí ó ṣẹlẹ̀ ní Èbúté Arthur di mímọ̀, àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kán yí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wọ́n ṣe sílẹ̀ padà lọ́gán. Lẹ́yìn náà ni akọ̀ròyìn Penelope Layland kọ àpilẹ̀kọ “Àgàbàgebè Ilé Iṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n Nípa Ìwà Ipá àti Ẹ̀dùn Ọkàn,” tí ó sì sọ pé: “Lọ́nà kan, àìgbé àfihàn àwọn ìwà ipá wọ̀nyẹn sáfẹ́fẹ́ jẹ́ oréfèé, kò sì wà pẹ́. Lọ́la, lọ́sẹ̀ tí ń bọ̀, lóṣù tí ń bọ̀, wọn yóò gbé àfihàn ìwà ipá jáde bí wọ́n ti ń ṣe.”
Bí ó ti wù kí ó rí, láti ní òye jíjinlẹ̀ sí i lórí ìdí tí ìwà ipá fi gbòde kan tó bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí, a ní láti yíjú sí Bíbélì. Ó ti sọ tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn pé “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere.” (Tímótì Kejì 3:1-5) Nípa bẹ́ẹ̀, pípọ̀ tí ìwà ipá ń pọ̀ sí i lóde òní wulẹ̀ ń fi kún ẹ̀rí náà pé, a wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ni, àti pé, òpin ètò ìgbékalẹ̀ yìí ti sún mọ́lé.—Mátíù 24:3-14.
Bí àwọn kán ti lè fura, àwọn ẹ̀mí èṣù—àwọn agbára ẹ̀mí búburú tí a kò lè rí—ń kópa nínú àjàkálẹ̀ ìhùwàsí ẹhànnà, aláìṣènìyàn náà. (Éfésù 6:12) Lẹ́yìn jíjúwe ìléjáde Sátánì Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò ní ọ̀run, Bíbélì sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wáá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òún ní.” (Ìṣípayá 12:7-9, 12) A ń gbé ní àkókò ègbé yẹn nísinsìnyí gan-an, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sì ń lo ọ̀nàkọnà tí wọ́n lè lò láti sún àwọn ènìyàn sí àwọn ìṣe ìwà ipá púpọ̀ sí i.
Síbẹ̀, Sátánì, àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, àti ayé búburú wọn yóò kógbá sílé láìpẹ́, ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run yóò sì mú ayé tuntun òdodo kan wọlé. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10; Pétérù Kejì 3:13; Jòhánù Kìíní 2:17; Ìṣípayá 21:3, 4) Jenny sọ pé: “Ní báyìí ná, a ń ‘sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún,’ ṣùgbọ́n ìfẹ́ ọkàn wa ni láti ṣàjọpín ìrètí Ìjọba tí a ní pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ láwùjọ, tí ọ̀ràn ìbànújẹ́ yìí ti mú gbọ̀n rìrì.”—Róòmù 12:15.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ilé Èrò Broad Arrow, níbi tí ìpakúpa náà ti bẹ̀rẹ̀
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]
Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.