ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 12/22 ojú ìwé 13-15
  • Èé Ṣe Tí Ọ̀rẹ́ Kòríkòsùn Mi Fi Kó Lọ Síbòmíràn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí Ọ̀rẹ́ Kòríkòsùn Mi Fi Kó Lọ Síbòmíràn?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídojú Kọ Òkodoro Òtítọ́
  • Kíkàn Sí I Déédéé
  • Dídí Àlàfo Náà
  • Ní Ìfojúsọ́nà Wíwà Déédéé
  • N Kò Ṣe Lè Ní Ọ̀rẹ́ Pẹ́ Títí?
    Jí!—1996
  • Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Àwọn Wo Ni Ọ̀rẹ́ Mi Tòótọ́?
    Jí!—2012
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọ̀rẹ́?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 12/22 ojú ìwé 13-15

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Èé Ṣe Tí Ọ̀rẹ́ Kòríkòsùn Mi Fi Kó Lọ Síbòmíràn?

‘Ó JỌ pé o kò rí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ mọ́.’ Ohun tí àwọn ènìyàn máa ń sọ nìyí bí ó bá jọ pé ẹnì kan banú jẹ́ díẹ̀ tàbí tí ó sorí kọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí o kò bá rí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ kan mọ́ ní gidi, ọ̀rọ̀ náà yóò túbọ̀ nítumọ̀.

Bẹ́ẹ̀, ohun pàtàkì ni ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tòótọ́ jẹ́, ó sì ṣeyebíye. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n arákùnrin ni a bí fún ìgbà ìpọ́njú.” (Òwe 17:17) Àwọn ọ̀rẹ́ rere ń pèsè ìbákẹ́gbẹ́ àti ìtìlẹ́yìn fún wa. Wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà ní ti èrò ìmọ̀lára àti nípa tẹ̀mí. Bí àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ojúlùmọ̀ lásán bá tilẹ̀ pọ̀, àwọn ẹni tí o lè gbẹ́kẹ̀ lé, tí o sì lè finú hàn ní gidi sábà máa ń ṣọ̀wọ́n.

Nítorí náà, bí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ bá kó lọ síbòmíràn, a lè lóye pé ọkàn rẹ lè dà rú. Èwe kan tí ń jẹ́ Bryan rántí bí ìmọ̀lára rẹ̀ ṣe rí nígbà tí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ̀ kó lọ síbòmíràn. Ó sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí, n kò lálábàárò, ó sì dùn mí.” Bóyá ìwọ́ nímọ̀lára ohun kan náà.

Dídojú Kọ Òkodoro Òtítọ́

Ríronú lórí ìdí tí ọ̀rẹ́ rẹ fi kó lọ síbòmíràn lè ṣèrànlọ́wọ́. Dájúdájú, kì í ṣe nítorí àìmọrírì ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yín ni. Kíkó lọ síbòmíràn ti di apá kan tí ó fìdí múlẹ̀ nínú ìgbésí ayé òde òní. Lọ́dọọdún ní United States nìkan, ó lé ní mílíọ̀nù 36 ènìyàn tí ń kó lọ síbòmíràn! Gẹ́gẹ́ bí Ọ́fíìsì Ìkànìyàn ní United States ti sọ, ará America tí a lè mú gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ yóò kó lọ síbòmíràn ní ìgbà 12 nígbà ìgbésí ayé rẹ̀.

Kí ló ń fa ìkókiri yìí? Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ni èrèdí rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìdílé ń kó lọ síbòmíràn kí wọ́n baà lè rí iṣẹ́ àti ilé tí ó túbọ̀ dára. Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ogun àti ipò òṣì tí fipá mú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn láti kó lọ síbòmíràn. Bí àwọn èwe sì ti ń dàgbà sí i, ọ̀pọ̀ lára wọ́n ń yàn láti kó lọ síbòmíràn, kí wọ́n sì máa dá gbé. Àwọn kan ń kó lọ síbòmíràn láti lọ ṣègbéyàwó. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Síbẹ̀, àwọn mìíràn lè kó lọ síbòmíràn láti lépa àwọn ire tẹ̀mí. (Mátíù 19:29) Láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀pọ̀ fi ipò ìdẹ̀ra tí ó wà láyìíká tí wọ́n ti di ojúlùmọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ láti sìn ní àwọn agbègbè kan—bóyá ní àwọn ilẹ̀ òkèèrè pàápàá—níbi tí àìní púpọ̀ jù wà fún àwọn Kristẹni òjíṣẹ́. Àwọn kan kó lọ síbòmíràn láàárín orílẹ̀-èdè ìbílẹ̀ wọn láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe ibi tí wọ́n ti ń bójú tó iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ wa, a gbọ́dọ̀ fojú wò ó bí òkodoro òtítọ́ kan nínú ìgbésí ayé pé bí àkókò ti ń lọ, ó ṣeé ṣe kí wọ́n kó lọ síbòmíràn.

Ohun yòó wù kí ó mú kí ọ̀rẹ́ rẹ kó lọ síbomíràn, o lè ṣe kàyéfì nípa bí ìwọ yóò bá kọ́fẹ padà láé nínú àdánù náà. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ó ti bá ìwà ẹ̀dá mu láti nímọ̀lára àìlálábàárò àti ìsoríkọ́ ráńpẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ó ṣeé ṣe kí o mọ̀ pé kíká gúọ́gúọ́ kiri ilé kì yóò mú kí ọ̀ràn náà sunwọ̀n rárá. (Òwe 18:1) Nítorí náà, jẹ́ kí a wo àwọn ohun díẹ̀ tí ó lè ṣèrànwọ́.

Kíkàn Sí I Déédéé

Bryan ọ̀dọ́ gbani nímọ̀ràn pé: “Mọ̀ pé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yín kò tí ì dópin.” Òtítọ́ ni, ó dájú pé kíkó tí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ kó lọ síbòmíràn yóò yí ipò ìbátan yín padà, ṣùgbọ́n kò túmọ̀ sí pé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yín ní láti dáwọ́ dúró. Olùgba àwọn èwe nímọ̀ràn, Ọ̀mọ̀wé Rosemarie White, sọ pé: “Àdánù ṣòro gan-an ní àkókò èyíkéyìí nínú ìgbésí ayé, ṣùgbọ́n ọ̀nà tí a lè gbà kápá rẹ̀ jẹ́ láti wulẹ̀ kà á sí ìyípadà kan, tí kì í sì í ṣe òpin pátápátá.”

Kí ni o lè ṣe láti mú kí ilẹ̀kùn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wà ní ṣíṣí? Gbé àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Dáfídì àti Jónátánì yẹ̀ wò. Láìka bí ọjọ́ orí wọ́n ṣe yàtọ̀ síra tó sí, wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Nígbà tí ipò nǹkan fagbára mú Dáfídì láti sá lọ sí ìgbèkùn, wọn kò ṣàìbá ara wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n tó ya ara wọn. Ní òdì kejì, wọ́n fìdí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn tí kì í kú múlẹ̀, kódà wọ́n dá májẹ̀mú, tàbí àdéhùn, láti máa jẹ́ ọ̀rẹ́ lọ.—Sámúẹ́lì Kìíní 20:42.

Bákan náà, o lè bá ọ̀rẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ kí ó tó gbéra. Jẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ mọ̀ bí o ṣe mọyì ìbádọ́rẹ̀ẹ́ náà àti bí o ṣe fẹ́ kí ẹ máa kàn síra yín tó. Ohun tí Patty àti Melina, àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn tí wọ́n fi 8,045 kìlómítà jìnnà síra ṣe gan-an nìyẹn. Patty ṣàlàyé pé: “A ṣètò láti máa kàn síra.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, irú àwọn ìṣètò bẹ́ẹ̀ lè ṣàìlọ geere, àyàfi bí ẹ bá ṣe àwọn ètò pàtó kan.—Fi wé Ámósì 3:3.

Bíbélì wí fún wa pé nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù kò rí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Gáyọ̀sì, ó ń kàn sí i nípa ‘fífi tàdáwà àti kálámù kọ̀wé sí i.’ (Jòhánù Kẹta 13) Ẹ tún lè ṣe àdéhùn láti máa kọ lẹ́tà tàbí fi káàdì ránṣẹ́ sí ara yín déédéé, bóyá lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ tàbí lẹ́ẹ̀kan lóṣù. Bí àwọn òbí yín bá fara mọ́ sísanwó ìtẹniláago ọlọ́nà jíjìn, bóyá ẹ lè máa tẹ ara yín láago lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì máa gbọ́ ìsọfúnni lásìkò nípa ìgbésí ayé ara yín. Tàbí kí ẹ ṣàdéhùn láti máa fi ìhìn iṣẹ́ tí a gbà sórí kásẹ́ẹ̀tì tàbí téèpù fídíò ránṣẹ́ síra yín. Lọ́jọ́ iwájú, ó tilẹ̀ lè ṣeé ṣe láti ṣètò ìbẹ̀wò lópin ọ̀sẹ̀ tàbí kí ẹ jùmọ̀ lo ìsinmi pọ̀. Nípa báyìí, okùn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ náà lè máa nípọn sí i.

Dídí Àlàfo Náà

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kíkólọ tí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn kan kó lọ síbòmíràn yóò fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ. Ní àbáyọrí rẹ̀, o lè rí i pé o tún ní àkókò púpọ̀ sí i. Ó dára, má ṣe jẹ́ kí àkókò yẹn ṣòfò. (Éfésù 5:16) Lò ó láti ṣe ohun améso rere wá—bóyá o lè kọ́ bí a ṣe lè lo ohun èèlò ìkọrin kan, kọ́ èdè tuntun kan, tàbí kópa nínú ìgbòkègbodò àfipawọ́ kan. Jíjíṣẹ́ fún àwọn tí wọ́n wà ní ipò àìní jẹ́ ọ̀nà améso rere wá mìíràn tí a lè gbà lo àkókò. Bí o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè mú ìpín rẹ nínú ìgbòkègbodò ìwàásù ní gbangba pọ̀ sí i. (Mátíù 24:14) Tàbí o lè bẹ̀rẹ̀ ìdáwọ́lé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí ń ru ọkàn ìfẹ́ sókè.

Síwájú sí i, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì nímọ̀ràn láti “gbòòrò síwájú”—ìyẹn ni pé, láti mú àwọn ẹlòmíràn mọ́ agbo àwọn ọ̀rẹ́ wọn. (Kọ́ríǹtì Kejì 6:13) Bóyá o ti lo àkókò tí ó pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan ṣoṣo péré débi pé o gbójú fo àwọn àǹfààní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ mìíràn dá. Àwọn èwe láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí i pé àǹfààní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ sábà máa ń ṣí sílẹ̀ jaburata nínú àwọn ìjọ àdúgbò wọn gan-an. Nítorí náà, gbìyànjú láti máa tètè dé sí àwọn ìpàdé ìjọ, kí o sì máa dúró díẹ̀ lẹ́yìn náà. Èyí yóò fún ọ ní àkókò sí i láti mọ àwọn ènìyàn. Àwọn àpéjọpọ̀ Kristẹni àti àwọn àpéjọ àríyá kéékèèké ń pèsè àǹfààní mìíràn fún níní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun.

Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀rọ̀ ìṣọ́ra yíyẹ kan tí a lè mú lò ni pé: Má ṣe kánjú àtiní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun débi pé wàá máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn èwe tí wọn kò ní irú àwọn góńgó àti ìlànà tẹ̀mí tí o ní. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè ní ipa búburú lórí rẹ, wọ́n sì lè ṣe ọ́ ní ibi tí ó pọ̀ ju ire lọ. (Òwe 13:20; Kọ́ríńtì Kìíní 15:33) Dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn èwe tí ohun tẹ̀mí jẹ lọ́kàn, tí a mọ̀ sí oníwà rere nìkan.

Tí o bá rí irú ẹni bẹ́ẹ̀, kó wọnú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ nípa wíwéwèé láti máa ṣe nǹkan pọ̀. Ẹ jùmọ̀ jẹun. Ẹ ṣèbẹ̀wò sí ibi ìkóhun-ìṣẹ̀m̀báyé-sí kan. Ẹ jọ rìn pọ̀. Ẹ ṣètò láti lo ọjọ́ kan pọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, ní mímú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tọ àwọn ènìyàn lọ. Pẹ̀lú àkókò àti ìsapá, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tuntun náà lè dàgbà. Nítorí pé ìfẹ́ Kristẹni ní ìtẹ̀sí láti gbilẹ̀—ó ‘ń gbòòrò síwájú’ láti ní àwọn ẹlòmíràn nínú—nígbà tí o bá ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, o kò ní láti ronú pé o jẹ́ aláìṣòótọ́ sí ọ̀rẹ́ rẹ tí ó kó lọ síbòmíràn.

O tún lè lo àǹfààní náà láti túbọ̀ sún mọ́ àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ jù lọ—àwọn òbí rẹ. Wọ́n lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara lè kọ́kọ́ tì ọ́ láti wá ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn. Èwe kan tí ń jẹ́ Josh sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ di pé kí n fipá mú ara mi láti lo àkókò pẹ̀lú wọn, níwọ̀n bí n kò ti fà mọ́ mọ́mì tàbí dádì mi lákòókò náà. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, àwọn ni ọ̀rẹ́ tí mo fà mọ́ jù lọ!”

Bákan náà, rántí pé ó ṣì ní ọ̀rẹ́ kan ní ọ̀run. Bíi Dan, ọmọ ọdún 13 ṣe sọ ọ́, “o kò dá nìkan wà ní ti gidi nítorí pé o ṣì ní Jèhófà.” Bàbá wa ọ̀run wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún wa nípasẹ̀ àdúrà. Òun yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kápá ipò ìṣòro yìí bí o bá gbẹ́kẹ̀ lé e.—Orin Dáfídì 55:22.

Ní Ìfojúsọ́nà Wíwà Déédéé

Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì fúnni nímọ̀ràn yìí pé: “Ìwọ má ṣe wí pé, nítorí kí ni ọjọ́ ìṣáájú ṣe sàn ju ìwọ̀nyí lọ?” (Oníwàásù 7:10) Ní ọ̀rọ̀ míràn, má ṣe máa ronú nípa ìgbà tí ó ti kọjá nìkan; ṣàmúlò ìgbà lọ́ọ́lọ́ọ́ pẹ̀lú gbogbo àyè àǹfààní rẹ̀. Ohun tí Bill, tí ó ti lé díẹ̀ ní 20 ọdún nísinsìnyí, ṣe gan-an nìyẹn nígbà tí kò rí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ̀ mọ́. Ó rántí pé: “Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, n kì í sì í ronú jù lórí àwọn ìgbà tí ó ti kọjá. Mo máa ń gbìyànjú láti múra sílẹ̀ fún ọjọ́ iwájú àti láti máa ronú lórí nǹkan ti ìsinsìnyí.”

Àwọn àbá wọ̀nyí lè ṣèrànlọ́wọ́, síbẹ̀ kíkó tí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn kan kó lọ síbòmíràn ṣì ń bani nínú jẹ́. Ó lè pẹ́ díẹ̀ kí àwọn ìrántí àkókò dáradára tí ẹ ti lò pọ̀ tó má máa fa ìrora fún ọ mọ́. Ṣáà rántí, ìyípadà jẹ́ apá kan ìgbésí ayé, ó sì ń fún ọ ní àǹfààní láti dàgbà dénú, kí o sì dàgbà sókè. Nígbà tí ó jẹ́ pé ó lè má ṣeé ṣe láti fi ẹlòmíràn dípò ọ̀rẹ́ pàtàkì kan pátápátá, o lè mú àwọn ànímọ́ tí yóò mú kí o “rí ojú rere lọ́dọ̀ Olúwa, àti ènìyàn pẹ̀lú” dàgbà. (Sámúẹ́lì Kìíní 2:26) Bí o bá ṣe ìyẹn, ìgbà gbogbo ni ìwọ yóò máa ní ẹnì kan tí ìwọ yóò máa pè ní ọ̀rẹ́!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Dídágbére fún ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ̀ jẹ́ ìrírí aronilára kan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́