Ẹ̀bẹ̀ Òṣìṣẹ́ Amúdàájọ́ṣẹ Kan
Tom Will Lane ni òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ tí Edward Michalec sọ nípa rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ inú “Jí!,” ìtẹ̀jáde December 22, 1996, náà “Mo Gba Okun Láti Kojú Àwọn Àdánwò Níwájú.” Nínú àpilẹ̀kọ náà, Michalec sọ pé:
“Inú bí òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ ìlú ńlá Wharton, Texas, U.S.A., gidigidi. Bí ó ti ń mú mi lọ sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kẹrin, ó kọ kàrá pé: ‘Kí ló ṣe tí ìwọ kì í ṣègbọràn sí àṣẹ?’
“Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo dáhùn pé: ‘Mo ní ẹ̀tọ́ kíkún láti ṣe èyí.’ Èyí túbọ̀ bí òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ náà nínú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í nà mí ní kòbókò. Àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n ń fi ìdí ìbọn wọn lù mí.”
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Mary Perez, obìnrin kan tí ó bá ilé iṣẹ́ Sheriff Lane ṣiṣẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1960, kọ̀wé pé: “Ó mọ̀ pé mo jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ fún mi nípa bí òun ṣe ṣe inúnibíni sí Ed Michalec. Ó ní kí n sọ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù pé òun tọrọ àforíjì fún ohun tí òun ṣe. Ó sọ pé òun kò mọ̀ pé èèyàn dáadáa, tí ń pa òfin mọ́, ni Àwọn Ẹlẹ́rìí. Ó tọrọ àforíjì látọkànwá.”
Mary fi kún un pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ náà kú ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, mo lérò pé lẹ́tà yìí yóò gbé ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.”
Ó wá ṣàlàyé bí òun ṣe di Ẹlẹ́rìí pé: “Ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940 ni wọ́n ṣe inúnibíni sí Arákùnrin Michalec. Èyí ló mú kí ń pinnu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí nígbà tí wọ́n wá sí ilé mi. Kò pẹ́ tí a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èmi àti ọkọ mi ṣèrìbọmi ní 1949.”
Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ mìíràn tí ń fi bí ìdúró tí ẹnì kan mú lórí àwọn ìlànà Kristẹni ṣe lè ní ipa lórí ìwàláàyè àwọn ẹlòmíràn tó hàn kedere. Fún àpẹẹrẹ, àwọn mélòó ni ìdúró onígboyà tí Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù mú ní ọ̀rúndún kìíní ti ní ipa jíjinlẹ̀ lórí wọn?—Ìṣe 5:17-29.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ed Michalec àti Mary Perez, ní àwọn ọdún 1940