Ẹ̀rí Ìgbàgbọ́ Wọn
ỌDÚN 1995 ni ó pé 50 ọdún tí a sọ àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ẹgbẹ́ Nazi dòmìnira. Jákèjádò ilẹ̀ Europe, àwọn tí ẹgbẹ́ Nazi fìyà jẹ ṣàjọ̀dún àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní àwọn àwùjọ ńláńlá, tí àwọn olórí Orílẹ̀-Èdè wá sí ní Auschwitz, Bergen-Belsen, Buchenwald, Dachau, Ravensbrück, Sachsenhausen, àti àwọn àgọ́ mìíràn. Èrò kan tí ó wá sójútáyé léraléra ni, “Kí a má ṣe gbàgbé láé!”
Nítorí ìdí yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣàgbékalẹ̀ àwọn àfihàn ní Europe láàárín ọdún àyájọ́ náà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí ni ìjọba Hitler kó kúrò nílùú tí wọ́n sì fàṣẹ dè mọ́lẹ̀ nítorí pé wọ́n kọ̀ láti wárí fún Hitler, àti láti ṣètìlẹ́yìn fún ìsapá ológun náà. Láti 1933 lọ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn ni a fi sẹ́wọ̀n, wọ́n sì kú nítorí ọ̀nà tí wọ́n gbà bá wọn lò.
Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló mọ̀ nípa ohun tí wọ́n fojú winá rẹ̀. Èyí ló fa gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “àwọn òjìyà tí a gbàgbé nínú ìtàn.” Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n là á já sọ ìfẹ́ ọkàn wọn láti ṣì máa rántí àwọn ìdílé àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí, tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n, tí wọ́n dá lóró, tàbí tí wọ́n ṣìkà pa, àti láti sọ ẹ̀rí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tí àwọn Bibelforscher, orúkọ tí a fi mọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, fi sílẹ̀ di mímọ̀.
Ní September 29, 1994, Ibi Àfihàn Ohun Ìrántí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ ti United States, ní Washington, D.C., ṣonígbọ̀wọ́ ìpàdé àpérò kan nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àwọn ọgbà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ náà. Ètò ìṣèrántí ìmúpadàṣọ̀kan ńlá méjì ni àwọn tí wọ́n la iṣẹ́ninísẹ̀ẹ́ àgọ́ náà já ṣe ní ilẹ̀ Faransé, ní March 28, 1995, ní Strasbourg àti ní March 30, ní Paris. Ó múni káàánú gan-an láti gbọ́ tí àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti darúgbó nísinsìnyí, tí wọ́n ṣì jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun ní 50 ọdún lẹ́yìn náà, sọ àwọn ìrírí wọn. Ní April 27, a ṣe ìpàdé kan tí ó fara jọ ọ́ nítòsí Berlin, ní Brandenburg, Germany, níbi tí wọ́n ti ṣekú pa ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí nípa bíbẹ́ wọn lórí. Ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, púpọ̀ lára àwọn olùlàájá náà wá síbi ayẹyẹ tí Ìpínlẹ̀ Brandenburg ṣètò rẹ̀, wọ́n sì bẹ àwọn onírúurú àgọ́ wò.
Àfihàn Lédè Faransé
Níbi ìmúpadàṣọ̀kan wọ̀nyí, àfihàn kan tí ó ní àkọlé náà “Mémoire de Témoins” (Ẹ̀rí Àwọn Ẹlẹ́rìí) ni a gbé kalẹ̀. Láti May 1995 sí April 1996, ó káàkiri ìlú ńlá 42 ní ilẹ̀ Faransé àti onírúurú àwọn ìlú ńlá ní Belgium àti ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé ní Switzerland. Ní pàtàkì jù lọ, Ẹlẹ́rìí Jehofa Ọlọrun ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n kópa nínú àfihàn náà. Àmọ́ wọ́n tún jẹ́rìí sí ìyà tí àwọn àti àwọn ẹlòmíràn forí tì nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Wọ́n jẹ́ ẹ̀rí àkópọ̀ èròǹgbà àìráragba-nǹkan-sí tí ó fa ìjìyà àti ikú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn nítorí ẹ̀yà ìran tàbí ìsìn wọn. Síwájú sí i, ẹ̀rí àwọn Ẹlẹ́rìí tú bí àwọn aláfẹnujẹ́ Kristian ṣe nífẹ̀ẹ́ sí Messia èké náà, Hitler, ju Jesu Kristi lọ, fó; pé wọ́n kórìíra dípò kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn; wọ́n sì fẹ́ ìwà ipá dípò àlàáfíà.
Àfihàn náà ní nǹkan bí 70 àwòrán ara pátákó, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé—ìdásílẹ̀ àgọ́ náà ní Dachau àti Oranienburg, ní March 1933; àwọn Òfin Nuremberg láti “dáàbò bo ọmọ ilẹ̀ Germany,” ní September 1935; Anschluss, tàbí ìparapọ̀ Austria pẹ̀lú Germany, ní March 1938; Kristallnacht (Alẹ́ Oníkristali), ní November ọdún kan náà, nígbà tí wọ́n tú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ṣọ́ọ̀bù àwọn Júù fínnífínní, tí wọ́n sì fàṣẹ ọba mú àwọn ènìyàn tí ó lé ní 30,000, tí wọ́n sì lé wọn kúrò nílùú; fífòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé; ìkógunti Soviet Union, ní June 1941; àti ṣíṣojú àánú pa àwọn olókùnrùn, láti 1939 sí 1941.
Àwọn àwòrán ara pátákó bíi mélòó kan tọ́ka sí ìlànà ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi kọ́ àwọn ọ̀dọ́ inú ẹgbẹ́ Èwe Hitler àti ìfani lọ́kàn mọ́ra tí àwọn ìwọ́de ńláńlá ẹgbẹ́ Nazi ní Nuremberg gbé síwájú àwọn ènìyàn gbáàtúù. Àwọn fọ́tò rán àwọn ènìyàn létí nípa kíkọ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kọ̀ láti jẹ́jẹ̀ẹ́ ìtúúbá fún aṣáájú, kí wọ́n sì bẹ́rí fún Hitler. Àwọn àwòrán ara pátákó mìíràn fi bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe jìyà nítorí ìsọfúnni elékèé àti bí wọ́n ṣe pín àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé ìléwọ́ tí ń tú àṣírí ìloninílòkulò tí ẹgbẹ́ Nazi lò àwọn ènìyàn lọ́nà ríré kọjá ààlà láti 1935 lọ hàn.
Àwọn Ìrírí Ara Ẹni
Nǹkan bí 40 àwòrán ara pátákó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìrírí àwọn ọkùnrin àti obìnrin ṣákálá lásán tí wọ́n wá jákèjádò ilẹ̀ Europe tí wọ́n ṣe inúnibíni sí, tí wọ́n tilẹ̀ pa nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Àwọn olùlàájá ṣètìlẹ́yìn fún àfihàn náà nípa wíwá síbẹ̀, àwọn àlejò sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. Àwọn ọmọdé pa rọ́rọ́ nígbà tí Louis Arzt ń sọ ìtàn rẹ̀. Láti Mulhouse ní ilẹ̀ Faransé ni wọ́n ti mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí Germany nítorí pé ó kọ̀ láti sọ “Heil Hitler!” ní ilé ẹ̀kọ́. “Sójà SS kan lù mí nítorí pé mo kọ̀ láti wárí fún Hitler. Ó fún mi ní ẹgba 30. Ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, ó gbọ́wọ́ lé mi léjìká, ó sì gbìyànjú láti tàn mí jẹ nítorí ìmọ̀lára mi. ‘Ronú nípa ìyá rẹ. Inú rẹ̀ yóò dùn gan-an láti rí ọ. Ohun tí o kàn máa ṣe ni kí o sọ pé “Heil Hitler!” ìwọ yóò sì padà sílé.’ Ó ṣòro fún ọmọ ọdún 12,” ni ó fi kún un. Ìrírí Joseph Hisiger, tí ó fi búrẹ́dì rẹ̀ ọ̀sẹ̀ kan ṣe pàṣípààrọ̀ fún Bibeli lọ́wọ́ ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì, mú ọ̀pọ̀ káàánú.
Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí a gbà sórí fídíò lẹ́nu àwọn tí wọ́n kó lọ sínú àgọ́ nígbà náà lọ́hùn-ún jẹ́ apá fífanimọ́ra mìíràn níbi àfihàn náà. Díẹ̀ lára àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà ni a ṣe níbi tí àwọn àgọ́ náà wà gangan—fún àpẹẹrẹ, ní Ebensee ní Austria àti Buchenwald àti Sachsenhausen ní Germany. Àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò míràn gba ọ̀rọ̀ nípa onírúurú apá ìgbésí ayé nínú àgọ́ tàbí ìrántí àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n kó lọ sínú àgọ́ lọ́mọdé sílẹ̀.
Ṣíṣíṣọ Lójú Ayẹyẹ Náà
Wọ́n fi ayẹyẹ ráńpẹ́ kan ṣí ìbẹ̀rẹ̀ àfihàn kọ̀ọ̀kan, níbi tí aṣojú kan fún àwọn tí wọ́n kó lọ sínú àgọ́ nígbà náà lọ́hùn-ún ti ṣàlàyé okun tẹ̀mí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní láti dúró tiiri lòdì sí ètò ìjọba Nazi. Àwọn tí wọ́n kó lọ sínú àgọ́, tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí pẹ̀lú àwọn òpìtàn àti àwọn òṣìṣẹ́ bíi mélòó kan, títí kan mínísítà ilẹ̀ Faransé kan tẹ́lẹ̀ rí, pẹ̀lú fi inúure tẹ́wọ́ gba ìkésíni láti sọ̀rọ̀.
Ẹnì kan tí wọ́n mú lọ sínú àgọ́ nígbà náà lọ́hùn-ún, tí ó mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Buchenwald, sọ nípa wọn pé: “N kò mọ ìsọ̀wọ́ àwọn kankan tí wọ́n kó lọ sínú àgọ́, yàtọ̀ sí àwọn Júù, tí a hùwà sí lọ́nà búburú bíi tiwọn: wọ́n nà wọ́n, wọ́n tẹ́ wọn, wọ́n fàbùkù kàn wọ́n, wọ́n fún wọn ní iṣẹ́ tí ń nini lára jù lọ. Bí kì í bá ṣe ti ìgbàgbọ́ wọn, wọn kì bá lè kápá rẹ̀. Mo bọ̀wọ̀ gíga jù lọ fún wọn, mo sì kan sáárá sí wọn.”
Ìhùwàpadà
Ó lé ní 100,000 ènìyàn tí wọ́n wá síbi àfihàn náà. Ní àwọn ibì kan, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn, tí àwọn ògowẹẹrẹ wà lára wọn, tò lọ jàńtìrẹrẹ láti wọnú gbọ̀ngàn àfihàn náà. Ọ̀pọ̀ àwọn àlejò kọ ọ̀rọ̀ ráńpẹ́ nípa bí ìmọ̀lára wọn ti rí sínú ìwé àlejò. Fún àpẹẹrẹ, ògowẹẹrẹ kan kọ pé: “Sabrina ni orúkọ mi. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mí, n óò sì fẹ́ láti jẹ́ ẹni tí ó láyà bíi Ruth kí n lè wu Jehofa.”a
Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa àfihàn náà. Lápapọ̀, ní ìlú kọ̀ọ̀kan, àpilẹ̀kọ kan tàbí méjì fara hàn nínú àwọn ìwé ìròyìn àdúgbò. Ní àfikún, àwọn ilé iṣẹ́ rédíò ládùúgbò sábà máa ń polongo àfihàn náà, wọ́n sì máa ń gbé àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ nípa ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn tí wọ́n kó lọ sí àgọ́ nígbà náà lọ́hùn-ún sáfẹ́fẹ́. Ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n àdúgbò gbé àwọn ìròyìn ráńpẹ́ jáde. Ìròyìn kan tí wọ́n gbé jáde sọ pé àfihàn náà jẹ́ “ìtàn rírọrùn tí ó sọ nípa kọ́lọ́fín ohun tí kò ṣeé fẹnu sọ àmọ́ tí ó gogò. Ó jẹ́ ‘Ẹ̀rí Àwọn Ẹlẹ́rìí’ tí ó bọ̀wọ̀ fún iyì tí a kò lè mú kúrò láé.”
Ìrántí 50 ọdún ìsọdòmìnira náà yóò wà pinpin lọ́kàn àwọn tí wọ́n là á já. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í sábà jẹ́ ohun tí ó bára dé nígbà tí a bá rántí àwọn ìrírí aronilára, sísọ wọ́n fún àwọn ẹlòmíràn àti sísọ àwọn ìrántí náà jáde sójútáyé, mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí lè fún ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn lókun. Wọ́n kà á sí àǹfààní láti kópa nínú àfihàn yìí àti láti mú àwọn ẹ̀tanú àti àìmọ̀kan tí ó ṣì wà lẹ́yìn 50 ọdún kúrò. Lékè gbogbo rẹ̀, wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn nínú mímọ̀ pé ẹ̀rí àwọ́n mú ọlá wá fún Ọlọrun wọn, Jehofa, ó sì fi dáni lójú pé àwọn ẹlòmíràn kì yóò gbàgbé ohun tí wọ́n forí tì gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wọ́n kó Ruth Danner lọ sínú àgọ́ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, wọ́n sì há a mọ́ àgọ́ mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wo 1980 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe jáde, ojú ewé 105.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ìjọba Hitler kó lọ sínú àgọ́, tí ó sì há mọ́ sọ ìtàn wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú “The Golden Age” ṣáátá ibi àṣekọjá ààlà ètò ìjọba Nazi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Nǹkan bí 70 àwòrán ara pátákó sọ ìtàn bí ẹgbẹ́ Nazi ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé tí wọ́n kọ̀ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn