Jíjẹ́ Onídùnnú-ayọ̀ Nínú Ayé Aláìnídùnnú-ayọ̀
Ọ̀RỌ̀ olóòtú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ti January 26, 1995, bẹ̀rẹ̀ pé: “Ó burú pin, ọ̀rúndún Satani nìyí. Kò tí ì sí sànmánì kankan ṣáájú èyí nínú èyí tí àwọn ènìyàn tí ì ní ìtẹ̀sí àti ìyánhànhàn fún pípa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ẹlòmíràn nítorí ẹ̀yà ìran, ìsìn tàbí ẹgbẹ́.”
Àjọ̀dún àádọ́ta ọdún ìdásílẹ̀ àwọn òjìyà aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ní ọgbà ìṣekúpani ti Nazi, ni ó fa sábàbí irú ọ̀rọ̀ olóòtú báyìí. Ṣùgbọ́n, irú ìpànìyàn ní ìpakúpa bẹ́ẹ̀ ṣì ń bá a lọ ní àwọn apá kan Africa àti Ìlà Oòrùn Europe.
Pípa àwùjọ run, pípa ẹ̀yà ìran run, pípa ìran ní ìpakúpa—ohun yòówù tí a lè pè é—ń yọrí sí ìbànújẹ́ ńláǹlà. Síbẹ̀, láàárín rúkèrúdò bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kan ti jẹ́ onídùnnú-ayọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ kí á wo Germany ní àwọn ọdún 1930.
Nígbà tí ó fi di April 1935, Hitler àti ẹgbẹ́ Nazi rẹ̀ ti lé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kúrò lẹ́nu gbogbo iṣẹ́ ìjọba. A tún fòfin ọba mú àwọn Ẹlẹ́rìí, a fi wọ́n sẹ́wọ̀n, a sì rán wọn lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nítorí pé, wọ́n di ìdúró àìdásítọ̀túntòsì Kristian mú. (Johannu 17:16) Ní ìparí August 1936, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a fòfin ọba mú. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn ni a rán lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, níbi tí púpọ̀ jù lọ nínú wọ́n wà títí di 1945, bí wọn kò bá kú. Ṣùgbọ́n, báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe hùwà padà sí ìwà ìkà tí a hù sí wọn ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ náà? Ó lè dà bí ohun tí ó yani lẹ́nu pé, wọ́n lè di ìdùnnú-ayọ̀ wọn mú láìka àìsídùnnú-ayọ̀ tí ó yí wọn ká sí.
“Àpáta Nínú Ẹrẹ̀”
Christine King, òpìtàn ará Britain, fọ̀rọ̀ wá obìnrin Kátólíìkì kan tí ó wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lẹ́nu wo. Ọ̀mọ̀wé King sọ pé: “Ó lo àpólà ọ̀rọ̀ kan tí n kò lè gbàgbé láé. Ó sọ̀rọ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nípa ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ìgbésí ayé, ipò onírìíra tí ó gbé. Ó sì sọ pé òún mọ àwọn Ẹlẹ́rìí, àti pé àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn jẹ́ àpáta nínú ẹrẹ̀. Wọ́n dà bí ibi líle ní gbogbo ibi tí ń yọ̀. Ó sọ pé àwọn nìkan ni kì í bẹ́tọ́ nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ bá ń rìn kọjá. Àwọn nìkan ni kì í fi ìkórìíra hùwà padà sí gbogbo èyí, ṣùgbọ́n wọ́n ń lo ìfẹ́ àti ìrètí, wọ́n sì ní ìmọ̀lára pé ète kan wà.”
Kí ni ó mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa di “àpáta nínú ẹrẹ̀”? Ìgbàgbọ́ tí kò yẹsẹ̀ nínú Jehofa Ọlọrun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, ni. Nítorí náà, gbogbo akitiyan Hitler láti mú kí ìfẹ́ Kristian àti ìdùnnú-ayọ̀ wọn dín kù ni ó kùnà.
Fetí sílẹ̀ bí àwọn méjì tí wọ́n rù ú là ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ṣe ń rántí ní ẹ̀wádún márùn-ún, lẹ́yìn tí wọ́n ti kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ wọn pẹ̀lú àṣeyọrí. Ọ̀kan sọ pé: “Mo máa ń fò fún ayọ̀ ní mímọ̀ pé mo ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ti fífi ìfẹ́ mi àti ìmoore mi sí Jehofa hàn lábẹ́ ipò ìkà búburú jáì. Kò sí ẹni tí ó fipá mú mi ṣe bẹ́ẹ̀! Ní òdì kejì, àwọn ọ̀tá wa tí wọ́n ń halẹ̀ láti mú wa ṣègbọràn sí Hitler ju Ọlọrun lọ ní ń gbìyànjú láti fipá mú wa—ṣùgbọ́n wọn kò ṣàṣeyọrí! Kì í ṣe pé mo láyọ̀ nísinsìnyí nìkan ni, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí ọkàn rere, mo láyọ̀ àní nígbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n pàápàá.”—Maria Hombach, ẹni ọdún 94.
Ẹlẹ́rìí mìíràn sọ pé: “Mo ń fi pẹ̀lú ọpẹ́ àti ayọ̀ bojú wẹ̀yìn wo àwọn ọjọ́ tí mo wà ní ìtìmọ́lé. Àwọn ọdún tí mo lò lábẹ́ Hitler nínú ẹ̀wọ̀n àti àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ jẹ́ èyí tí ó le koko, tí ó sì kún fún ọ̀pọ̀ ìdánwò. Ṣùgbọ́n èmi kì bá tí fẹ́ láti má ṣe rí wọn, nítorí pé wọ́n kọ́ mi láti gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa pátápátá.”—Johannes Neubacher, ẹni ọdún 91.
“Gbígbẹ́kẹ̀ lé Jehofa pátápátá”—ohun tí ó fa sábàbí ìdùnnú-ayọ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ní nìyí. Nípa báyìí, wọ́n nídùnnú-ayọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé aláìnídùnnú-ayọ̀ ni ó yí wọn ká. Ìdùnnú-ayọ̀ wọn hàn kedere nígbà Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ní àwọn oṣù àìpẹ́ yìí. Ẹ jẹ́ kí a ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àpéjọpọ̀ onídùnnú-ayọ̀ wọ̀nyẹn ní ṣókí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Maria Hombach