ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 7/22 ojú ìwé 6-9
  • Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ—A Ha Ń Ṣì Í Lò Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ—A Ha Ń Ṣì Í Lò Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwòrán Arùfẹ́ Ìṣekúṣe Sókè Lórí Kọ̀m̀pútà
  • Àwọn Èrò Yíyàtọ̀ Síra
  • Ìtàn Ìdàgbàsókè Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ
    Jí!—1996
  • Àwòrán Oníhòòhò​—Ó Léwu Àbí Kò Léwu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Kí Nìdí Tí Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Fi Gbilẹ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
    Jí!—2003
  • Ìpalára Tí Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Ń Ṣe
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 7/22 ojú ìwé 6-9

Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ—A Ha Ń Ṣì Í Lò Bí?

A TI wà ní bèbè ọ̀rúndún kọkànlélógún. Láìṣe àníàní, ọ̀rúndún tuntun náà yóò mú àwọn ìrètí, ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé, ìṣesí ìwà rere, èrò nípa àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ gígadabú, àti ìbéèrè fún òmìnira púpọ̀ sí i wá. Ó ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí pé àwọn ojú ìwòye wíwọ́pọ̀ ti ìjọba, ìsìn, àti àwọn ènìyàn tí ń yàtọ̀ síra tẹ́lẹ̀ rí ti ń juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn èrò tuntun àti ohun tí wọ́n ń béèrè fún. Ní ibi púpọ̀, ìbéèrè púpọ̀ wà láti mú àwọn ìkálọ́wọ́kò tí ó wà lórí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti àwọn àlàyé kúrò, láìtàro àbájáde rẹ̀!

Ohun tí àwọn òṣìṣẹ́ rédíò àti tẹlifíṣọ̀n pẹ̀lú àwọn aláyẹ̀wò wọn kò fọwọ́ sí nígbà kan, tí wọ́n sì kà léèwọ̀—ọ̀rọ̀ àlùfààṣá àti àwọn ìran òun ìwà arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè—ti wá di ohun wíwọ́pọ̀ nísinsìnyí ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wọ́n ti kà á sí ohun ìtẹ́wọ́gbà lábẹ́ ìbòjú ẹ̀tọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ!

Àwọn tí wọ́n jáfáfá nínú lílo kọ̀m̀pútà, àtàgbà àtọmọdé, lè fi àwọn àwòrán ìṣe ìbálòpọ̀ aláìmọ́ ráńṣẹ́ sí àwọn kọ́ńtínẹ́ǹtì míràn láàárín ìṣẹ́jú àáyá, kí wọ́n sì jíròrò pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ àti àwọn tí ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe tí ń béèrè fún orúkọ àti àdírẹ́sì fún ìpàdé bòókẹ́lẹ́. Orin tí ó ní àwọn ọ̀rọ̀ tí ń dábàá, tí ó sì ń fún ìṣekúpara-ẹni àti pípa àwọn òbí, ọlọ́pàá, àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba níṣìírí ni a ń gbọ́ lójoojúmọ́ lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n tàbí kí ó wà nínú kásẹ́ẹ̀tì tí àwọn ọmọdé ń gbọ́.

Díẹ̀ lára àwọn tí ń béèrè fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tí a kò ká lọ́wọ́ kò kì yóò gbà pẹ̀lú Adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, Oliver Wendell Holmes, Jr., tí ó kọ̀wé ní ohun tí ó lé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn nínú ìdájọ́ lílókìkí tí ó ṣe kókó kan lórí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ pé: “Òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ kò níí fún ọkùnrin kan lẹ́tọ̀ọ́ láti pariwo irọ́ pé iná wà nínú gbọ̀ngàn ìwòran kan kí ó sì fa ìpayà.” Àbájáde irú ìwà bẹ́ẹ̀ ń hàn gbangba. Nígbà náà, kò bá ọgbọ́n mu fún àwọn ènìyàn kan náà yìí láti ṣàìka ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé ìdájọ́ yẹn sí, kí wọ́n sì hùwà orí kunkun ní kíkọ̀ ọ́ sílẹ̀. Holmes sọ pé: “Kókó abájọ inú gbogbo ọ̀ràn tí ó ṣẹlẹ̀ ni bóyá a lo àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ irú ọ̀rọ̀ tí ó lè dá ewu tí ó fara hàn gbangba tí ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ sílẹ̀, tí yóò fi mú ibi tí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ní ẹ̀tọ́ láti dí lọ́wọ́ wá fún àwọn tí ọ̀rán kàn.”

Àwòrán Arùfẹ́ Ìṣekúṣe Sókè Lórí Kọ̀m̀pútà

Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Ibi gbogbo ni ìbálòpọ̀ wà lónìí, nínú àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, fíìmù, tẹlifísọ̀n, fídíò orin àti lára àwọn pákó ìpolówó ọjà lọ́fíńdà ní ibùdókọ̀. Wọ́n tẹ̀ wọ́n sára káàdì òwò ìsokọ́ra tẹlifóònù fún rírùfẹ́ ìṣekúṣe sókè, wọn sì ń fi wọ́n sábẹ́ ọ̀pá ìnugíláàsì ọkọ̀. . . . Ìfihàn ìrusókè ìbálòpọ̀ ní gbangba ti mọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará America lára gan-an—àlàyé nípa ìdí tí ó fi gba ipò pàtàkì lábẹ́ Àtúnṣe Àkọ́kọ́ [òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ] sì ti mọ́ wọn lára—débi pé agbára káká ni wọ́n fi ń ṣàkíyèsí pé ó wà níbẹ̀.” Bí ó ti wù kí ó rí, ohun kan wà nípa pípa ìbálòpọ̀ ní gbangba àti kọ̀m̀pútà tí ó ti mú ojú ìwòye àti ìtumọ̀ tuntun wá fún ọ̀rọ̀ náà “arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè” pọ̀. Ó ti di ohun ìtẹ́wọ́gbà, tí ó gbalẹ̀ káàkiri, tí ó sì wà kárí ayé.

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ṣe sọ, àwọn tí wọ́n san àsansílẹ̀ owó fún ìgbékalẹ̀ kọ̀m̀pútà fún ìtọ́júpamọ́ ìsọfúnni fún àwọn àgbàlagbà, tí wọ́n fẹ́ láti san owó lóṣooṣù bẹ̀rẹ̀ láti orí dọ́là 10 sí 30 dọ́là, ni a rí ní “ìlú ńlá tí ó lé ní 2,000 ní gbogbo 50 ìpínlẹ̀ àti 40 orílẹ̀-èdè, agbègbè ilẹ̀ àti ẹkùn ìpínlẹ̀ jákèjádò ayé—títí kan àwọn orílẹ̀-èdè bíi China, níbi tí níní àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè lọ́wọ́ ti lè jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí a lè pani nítorí rẹ̀.”

Ìwé ìròyin Time ṣàpèjúwe irú àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè lóri kọ̀m̀pútà kan gẹ́gẹ́ bí “àpò àtọwọ́bọ̀-fa-nǹkan-yọ, tí àwọn ohun ‘tí kò bójú mu’ wà nínú rẹ̀, títí kan àwọn àwòrán agbénidè, ìgbádùn ajẹniníyà, ìtọ̀, ìyàgbẹ́, àti ìbálòpọ̀ pẹ̀lú oríṣiríṣi ẹranko.” Ìfarahàn àwọn ohun báyìí lórí ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kọ̀m̀pútà gbogbogbòò, tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé jákèjádò ayé, gbé àwọn ìbéèrè tí ó lágbára dìde nípa àṣìlò òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.

Ìwé agbéròyìnjáde kan ní Britain sọ pé: “Gbàrà tí àwọn ọmọdé bá ti wà lórí wáyà, kò sí gbígbé àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè bíburú jáì pa mọ́ lórí pẹpẹ ìkẹ́rùsí àwọn alágbàtà ìwé ìròyìn mọ́, ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ọmọdé èyíkéyìí nígbàkúùgbà, ìyẹn sì túmọ̀ sí pé yóò jẹ́ níbi ìkọ̀kọ̀ iyàrá.” A sọ tẹ́lẹ̀ pé ìpín 47 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ilé tí wọ́n ti ní kọ̀m̀pútà ní Britain ni a óò so kọ́ra pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kọ̀m̀pútà nígbà tí ó bá fi máa di ìparí ọdún 1996. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn òbí ní Britain ni kò jẹ́ ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn ìhùmọ̀ onímọ̀ ẹ̀rọ gíga tó àwọn ọmọ wọn. Ní oṣù 18 tí ó kọjá, ‘wíwò káàkiri inú ìgbékalẹ̀ Net’ ti di ọ̀kan lára iṣẹ́ àkókò ọwọ́dilẹ̀ gbígbajúmọ̀ jù lọ láàárín àwọn ọ̀dọ́langba.”

Kathleen Mahoney, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ òfin ní Yunifásítì Calgary, Kánádà, tí ó tún jẹ́ ògbógi nínú ọ̀ràn òfin tí ó yí àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè ká, sọ pé: “Ó yẹ kí àwọn aráàlú mọ̀ pé ohun èèlò agbésọfúnni kiri kan tí a kò ṣàkóso rárá wà tí a lè fi lo àwọn ọmọdé nílòkulò kí a sì kó wọn nífà.” Ọlọ́pàá kan ní Kánádà sọ pé: “Àwọn àmì náà hàn kedere pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè tí ó ní í ṣe pẹ̀lú kọ̀m̀pútà láàárín àwọn ọmọdé yóò gbéra sọ láìpẹ́.” Ọ̀pọ̀ ìgbaninímọ̀ràn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ tí a ṣètò láti ran ìdílé lọ́wọ́ tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé àwòrán ìṣekúṣe tí àwọn ọmọdé ń wò lórí kọ̀m̀pútà àti ipa tí ó lè ní lórí wọ́n “dúró fún ewu tí ó fara hàn gbangba tí ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́wọ́lọ́wọ́.”

Àwọn Èrò Yíyàtọ̀ Síra

Inú bí àwọn ajàfómìnira aráàlú nítorí ìsapá èyíkéyìí tí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin lè ṣe láti pààlà sí irú nǹkan bí àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè lórí kọ̀m̀pútà, ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ tí Adájọ́ Holmes àti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ United States ṣe. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ìmọ̀ òfin ní Havard sọ pé: “Ìkọlù tààràtà ló jẹ́ lòdì sí Àtúnṣe Àkọ́kọ́ náà.” Ìwé ìròyin Time sọ pé, kódà, àwọn gbajúmọ̀ olùpẹ̀jọ́ fi ṣẹlẹ́yà. Ọ̀kan lára wọ́n sọ pé: “Kò lè kojú àyẹ̀wò kínníkínní kódà ní àwọn ilé ẹjọ́ tí ń bójú tó ọ̀ràn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́.” Òṣìṣẹ́ kan ní Ibùdó Ìsọfúnni Ìkọ̀kọ̀ Orí Ohun Abánáṣiṣẹ́ sọ pé: “Ìṣàyẹ̀wò láti ọwọ́ ìjọba ni.” Ìwé ìròyin Time fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ tí ó sọ pé: “Kò yẹ kí Àtúnṣe Àkọ́kọ́ parí síbi tí ìgbékalẹ̀ Internet ti bẹ̀rẹ̀.” Aṣòfin kan ní United States sọ pé: “Ní kedere, ó jẹ́ ìrélànà òmìnira ọ̀rọ̀ kọjá, ó sì jẹ́ ìrélànà ẹ̀tọ́ àwọn àgbàlagbà láti bá ara wọn sọ̀rọ̀ pọ̀ kọjá.”

Ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Ilé Ẹ̀kọ́ Òfin ti New York jiyàn pé ire wà nínú onírúurú ọ̀nà ìfihànjáde ìbálòpọ̀, lọ́nà tí ó ré kọjá ẹ̀tọ́ aráàlú àti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ pé: “Ìran ìbálòpọ̀ lórí ìgbékalẹ̀ Internet lè dára ní ti gidi fún àwọn ọ̀dọ́.” Ìwé ìròyin Time sọ̀rọ̀ lórí ojú ìwòye rẹ̀ pé: “Ibi ààbò tí a ti lè yẹ ohun àfòfindè àti èèwọ̀ wò ni ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra [cyberspace] jẹ́ . . . Ó mú kí ojúlówó ìjíròrò, tí kì í mára ni ẹni nípa ìrísí pípé àti ìfọkànyàwòrán nípa ìbálòpọ̀ ṣeé ṣe.”

Ọ̀pọ̀ àwọn èwe pẹ̀lú, ní pàtàkì àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yunifásítì, ti gbara dì láti fa kùrákù nítorí ìkàléèwọ̀ èyíkéyìí lórí àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè lórí ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kọ̀m̀pútà. Àwọn kan ti rọ́ lọ ní fífi ẹ̀hónú hàn nítorí ohun tí wọ́n kà sí fífi ẹ̀tọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ dù wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ti akẹ́kọ̀ọ́ kan, láìsí iyèméjì, èrò ẹnì kan tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú èrò ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ṣàtakò sí àbá èyíkéyìí tí ó lè fagi lé àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè lórí kọ̀m̀pútà pé: “Mo fura pé gbogbo àwọn tí ń lo ìgbékalẹ̀ Internet ní orílẹ̀-èdè yìí yóò fi ṣẹ̀sín, wọn óò sì kọtí ikún sí i, ní ti àwọn tí ń lo ìgbékalẹ̀ Internet lágbàáyé, yóò sọ United States di ohun àfiṣẹ̀sín.”

Nígbà tí ìwé ìròyin U.S.News & World Report ń ròyìn ọ̀rọ̀ tí òṣìṣẹ́ ẹgbẹ́ òmìnira aráàlú kan sọ, ó wí pé: “Cyberspace [ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kọ̀m̀pútà] lè fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lókun púpọ̀ sí i ju bí Àtúnṣe Àkọ́kọ́ ti ṣe lọ. Ní ti gidi, ó lè ‘ti di ohun tí kò rọrùn gan-an fún ìjọba láti pa àwọn ènìyàn lẹ́nu mọ́.’”

Ní Kánádà, àríyànjiyàn ń ru gùdù lórí ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó ba ìpèsè tí ó wà fún òmìnira ìsọjáde ọ̀rọ̀ ẹni nínú Àkọsílẹ̀ Ìyọ̀ǹda Ẹ̀tọ́ àti Òmìnira jẹ́. A ti fàṣẹ mú àwọn ayàwòrán tí àwọn àwòrán wọ́n ti fa ìrunú àwọn olùṣelámèyítọ́ àti àwọn ọlọ́pàá, tí ó kà wọ́n sí “àlùfààṣá.” Àwọn ayàwòrán àti àwọn alágbàwí òmìnira ọ̀rọ́ ti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti fẹ̀hónú hàn, kí wọ́n sì kéde ìfàṣẹmúni náà gẹ́gẹ́ bí ìpalára sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ wọn. Títí di nǹkan bí ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, àwọn fídíò àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè ni àwọn ọlọ́pàá ń fipá kó léraléra nítorí òfin Kánádà lórí àlùfààṣá, wọ́n sì ń ṣe ìgbẹ́jọ́ lórí wọn, àwọn oníṣòwò tí ń tà wọ́n sì ń jẹ̀bi.

Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo ìyẹn yí padà ní 1992, nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Kánádà dájọ́ nínú ọ̀ràn ẹjọ́ pàtàkì kan pé òmìnira ìsọjáde ọ̀rọ̀ ẹni nínú Àkọsílẹ̀ Ìyọ̀ǹda Ẹ̀tọ́ àti Òmìnira kò fàyè gba ṣíṣe ẹjọ́ lórí irú àwọn ohun àṣemújáde bẹ́ẹ̀. Ìwé ìròyin Maclean’s kọ̀wé pé, ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà “ti mú ìyípadà tí ó lámì wá sínú ẹgbẹ́ àwùjọ Kánádà.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ní ọ̀pọ̀ ìlú ńlá, ní báyìí, àwọn ìwé ìròyìn àti fídíò tí àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè bíburú jáì kún inú wọn ti wọ́ pọ̀ ní àwọn ilé ìtajà igun òpópónà.” Kódà, àwọn èyí tí ilé ẹjọ́ dájọ́ pé a lè fòfin dè ṣì wà lórí àtẹ fún àwọn òǹrajà.

Ọlọ́pàá kan sọ pé: “Mo mọ̀ pé bí o bá wọ ibẹ̀, ìwọ yóò rí àwọn ohun tí ó lè tẹ òfin lójú. Àwọn ohun tí ó ṣeé ṣe kí a fẹ̀sùn kàn wọ́n fún nìyẹn. Ṣùgbọ́n . . . a kò ní àkókò fún ìyẹn.” Wọ́n kò tún ní ẹ̀rí ìdánilójú pé a óò ka àwọn ẹ̀sùn náà sí ojúlówó. Ní sànmánì ṣe-bóo-ti-fẹ́ yìí, àkànṣe ìtẹnumọ́ wà lórí òmìnira ara ẹni tí kò láàlà, tí èrò àwọn aráàlú sì sábà máa ń nípa lórí ilé ẹjọ́. Àmọ́, ohun yòówù kí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀, àríyànjiyàn náà yóò máa bá a lọ láti ru èrò ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí ó sì ń ṣokùnfa àìṣọ̀kan sókè ní ìhà méjèèjì—fún wọn àti lòdì sí wọn.

Ní ìgbà kan, Japan bá ara rẹ̀ lábẹ́ ìkálọ́wọ́kò líle koko nípa òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti ilé iṣẹ́ akọ̀ròyìn. Fún àpẹẹrẹ, ìsẹ̀lẹ̀ kan tí ó wọn 7.9 lórí òṣùwọ̀n Richter, tí ó sì pa àwọn tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan, ni wọn kò lè ròyìn bí ó ṣe jẹ́ gan-an. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀ràn ìwà ìbàjẹ́ àti ti àwọn olólùfẹ́ tí ń pa ara wọn nínú ìfohùnṣọ̀kan ìṣekúpara-ẹni ni wọn kò lè ròyìn. Àwọn olùyẹ̀wòṣàtúnṣe àwọn ìwé agbéròyìnjáde juwọ́ sílẹ̀ fún ìhalẹ̀mọ́ni ìjọba bí ọwọ́ ìdarí ti ń le koko sí i, kódà lórí ohun tí àwọn kan kà sí bínntín. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, a ká àwọn ìkálọ́wọ́kò kúrò, Japan sì gbádùn òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ púpọ̀ sí i àti òmìnira ilé iṣẹ́ akọ̀ròyìn.

Ní ti gidi, ìṣòro náà ń légbá kan sí i dé ìkangun mìíràn bí àwọn ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé ẹ̀fẹ̀ ọmọdé kan ti kún fún àwọn àwòrán àlùfààṣá àti rírùfẹ́ ìṣekúṣe sókè. The Daily Yomiuri, ìwé agbéròyìnjáde kan tí ó gbajúmọ̀ ní Tokyo, sọ nígbà kan pé: “Bóyá ọ̀kan lára ìran tí ń bani lẹ́rù jù lọ fún àjèjì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí Japan ni àwọn ọkùnrin oníṣòwò tí ń ka àwọn ìwé àwòrán ẹ̀fẹ̀ oníṣekúṣe nínú àwọn ọkọ̀ abẹ́lẹ̀ Tokyo. Ní báyìí, ó jọ pé ìtẹ̀sí náà ń nípa lórí àwọn obìnrin ibẹ̀, bí àwọn ìwé àwòrán ẹ̀fẹ̀ ‘bíburú jáì’ ti àwọn obìnrin ti ń fara hàn lórí àtẹ nínú àwọn ilé ìtajà àti ilé ìtajà ńlá.”

Ní 1995, ìwé agbéròyìnjáde tí ó lókìkí náà Asahi Shimbun pe Japan ní “Párádísè Àwòrán Arùfẹ́ Ìṣekúṣe Sókè.” Nígbà tí àwọn olùyẹ̀wòṣàtúnṣe àti àwọn òǹṣèwé ń wá ojútùú àtọwọ́dá sí àwọn àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí dípò àwọn òfin ìjọba, àwọn èwe òǹkàwé yarí. Ẹnì kan yóò ṣe kàyéfì pé, ‘Ohùn ta ni yóò borí níkẹyìn?’

Ní báyìí, òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ tí ń fa àríyànjiyàn púpọ̀ ní ilẹ̀ Faransé. Òǹṣèwé ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Jean Morange, kọ nínú ìwe rẹ̀ lórí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ pé: “Láìsí àníàní, ìtàn òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ kò tí ì dópin, yóò sì máa bá a lọ láti fa ìyapa. . . . Agbára káká ni ọdún kan yóò fi kọjá, tí wọn kò ní gbé fíìmù tàbí ọ̀wọ́ eré orí tẹlifíṣọ̀n kan tàbí ìgbétásì ìpolówó ọjà kan jáde, tí ń fa ìhùwàpadà oníjàgídíjàgan, tí ó tún ń gbé ògbólógbòó àríyànjiyàn tí kò lópin nípa ìṣàyẹ̀wò dìde.”

Àpilẹ̀kọ kan tí ó jáde nínú ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Paris náà, Le Figaro, ròyìn pé ẹgbẹ́ akọrin ọlọ́rọ̀ wótòwótò kan tí ń jẹ́ Ministère amer (Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kíkorò) ń rọ àwọn olólùfẹ rẹ̀ láti pa àwọn ọlọ́pàá. Ọ̀kan lára àwọn ìlà orin wọ́n sọ pé: “Kì yóò sí àlàáfíà àyàfi bí a bá gbẹ̀mí àwọn [ọlọ́pàá].” Agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ náà sọ pé: “Nínú àwo orin wa, a wí fún wọn láti sun àgọ́ ọlọ́pàá, kí wọ́n sì fi [àwọn ọlọ́pàá] rúbọ. Kí ló tún lè bọ́gbọ́n mu ju ìyẹn lọ?” A kò tí ì gbé ìgbésẹ̀ kankan lórí ẹgbẹ́ akọrin ọlọ́rọ̀ wótòwótò náà.

Àwọn ẹgbẹ́ akọrin ọlọ́rọ̀ wótòwótò ní America pẹ̀lú ṣalágbàwí pípa àwọn ọlọ́pàá, wọ́n sì polongo ẹ̀tọ́ láti sọ irú ọ̀rọ̀ ìsọjáde bẹ́ẹ̀ lábẹ́ ìdáàbòbò òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Ní ilẹ̀ Faransé, Ítálì, England àti àwọn orílẹ̀-èdè míràn ní Europe àti jákèjádò ayé, a lè gbọ́ igbe náà láti inú àwùjọ ènìyàn gbogbo tí ń béèrè pé kí a má ṣe pààlà sí òmìnira àtisọ̀rọ̀ ní gbangba, kódà bí ọ̀rọ̀ náà bá jẹ́ “irú ọ̀rọ̀ tí ó lè dá ewu tí ó fara hàn gbangba tí ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ sílẹ̀.” Ìgbà wo ni àríyànjiyàn náà yóò dópin, ìhà ti ta ni yóò sì borí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè lórí kọ̀m̀pútà, “àpò àtọwọ́bọ̀-fa-nǹkan-yọ, tí àwọn ohun ‘tí kò bójú mu’ wà nínú rẹ̀”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́