Ìtàn Ìdàgbàsókè Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ
JÁLẸ̀JÁLẸ̀ ìtàn ni ènìyán ti ń jà fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. A ti ṣe àwọn òfin, a ti ja àwọn ogun, àwọn ẹ̀mí sì ti sọnù nítorí ẹ̀tọ́ àtisọ èrò kan jáde ní gbangba.
Èé ṣe tí irú ẹ̀tọ́ tí ó jọ ẹ̀tọ́ àdánidá bẹ́ẹ̀ ṣe lè ru àríyànjiyàn sókè, kódà títí lọ débi ìtàjẹ̀sílẹ̀? Èé ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ, ní ìgbà tí ó ti kọjá àti lọ́ọ́lọ́ọ́, fi rí i bí ohun tí ó pọn dandan láti pààlà sí lílo ẹ̀tọ́ yìí tàbí kí wọ́n fagi lé e?
Ìṣarasíhùwà sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ fún àwọn ènìyán ti ń yí láti ìkangun kan sí òmíràn láti ìgbà pípẹ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ni a ti wò gẹ́gẹ́ bí àǹfààní tí a ní láti gbádùn. Nígbà míràn, a ti kà á sí ìṣòro tí ìjọba tàbí ìsìn ní láti kojú.
Níwọ̀n bí ìtàn ti kún fún àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n jà fitafita fún ẹ̀tọ́ láti sọ èrò kan jáde ní gbangba, èyí tí ó sábà máa ń ṣamọ̀nà sí fífi ìwà ipá ṣenúnibíni sí wọn tàbí pípa wọ́n, ó yẹ kí àtúnyẹ̀wo díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fún wa ní òye jíjinlẹ̀ nípa ìṣòro náà.
Ó ṣeé ṣe kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìtàn lè rántí ọlọ́gbọ́n ìmọ̀ ọ̀ràn ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì náà, Socrates (470 sí 399 ṣááju Sànmánì Tiwa), tí a ka àwọn ojú ìwòye àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ sí ipá tí ń fa ìbàjẹ́ lórí ìwà rere àwọn èwe Áténì. Èyí ṣokùnfa ìyàlẹ́nu ńlá láàárín àwọn aṣáájú òṣèlú àti ìsìn ti àwọn lọ́gàálọ́gàá ilẹ̀ Gíríìkì, ó sì ṣamọ̀nà sí ikú rẹ̀. Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ níwájú ìgbìmọ̀ elétí gbáròyé tí ó ṣèdájọ́ rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ṣì jẹ́ ọ̀kan lára ìgbèjà jíjá gaara jù lọ nípa òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ pé: “Bí ẹ bá ni ẹ fẹ́ láti dá mi sílẹ̀ wàyí látàrí ipò àfilélẹ̀ pé kí n má baà lè sọ èrò mi nínú wíwá ọgbọ́n yìí kiri mọ́, àti pé bí wọ́n bá gbá mi mú lẹ́ẹ̀kan sí i níbi tí mo ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, kíkú ni n óò kú, ó yẹ kí ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin ènìyàn Áténì, èmi yóò ṣègbọràn sí Ọlọ́run dípò yín. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi bá ṣì ń bẹ, tí okun sì wà nínú mi, n kò níí jáwọ́ títẹ̀ lé ọgbọ́n ìmọ̀ ọ̀ràn, àti gbígba ẹnikẹ́ni tí mo bá pàdé nínú yín níyànjú kí n sì rọ̀ ọ́. Èmi yóò ṣe èyí nítorí pé, dájúdájú, ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ nìyí . . .’ Ẹ̀yin ará Áténì, ó sì yẹ kí n máa bá a lọ láti wí pé, ‘Yálà ẹ dá mi sílẹ̀ tàbí ẹ kò dá mí sílẹ̀; àmọ́ ẹ jẹ́ kí ó yé yín pé, n kò jẹ́ ṣe ohun tí ó yàtọ̀ láé, kódà bí mo bá tilẹ̀ ní láti kú nítorí rẹ̀ níye ìgbà.’”
Bí àkókò ti ń lọ, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn Róòmù, ìwọ̀nba ìkálọ́wọ́kò díẹ̀ ló wà lórí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n tún gbé ìkálọ́wọ́kò púpọ̀ sí i karí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ bí ilẹ̀ ọba náà ṣe ń tóbi sí i. Èyí sàmì sí ìbẹ̀rẹ sáà dídágùdẹ̀ jù lọ fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Nígbà ìṣàkóso Tìbéríù (14 sí 37 Sànmánì Tiwa), wọn kò gbà fún àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ lòdì sí ìjọba tàbí àwọn ìlàna rẹ̀. Kì í sì í ṣe Róòmù nìkan ló lòdì sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ; àkókò yìí ni àwọn aṣáájú Júù fipá mú Pọ́ńtíù Pílátù láti pa Jésù nítorí ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, wọ́n sì tún pàṣẹ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ láti dáwọ́ ìwàásù dúró. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú múra tán láti kú dípò kí wọ́n dáwọ́ dúró.—Ìṣe 5:28, 29.
Ní apá àkókò púpọ̀ jù lọ nínú ìtàn, ẹ̀tọ́ ara ìlú tí ìjọba fúnni ni a sábà máa ń yí padà tàbí kí a mú kúrò nígbà tí a bá fẹ́, èyí tí ó ṣamọ̀nà sí ìjàkadì tí ń bá a lọ fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Bẹ̀rẹ̀ ní Sànmánì Agbedeméjì, díẹ̀ lára àwọn ènìyán béèrè fún ìwé àkọsílẹ̀ tí ó to àwọn ẹ̀tọ́ wọn lẹ́sẹẹsẹ, tí a sì pààlà fún ìjọba ní ti àkóso rẹ̀ lórí àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ sí í hùmọ̀ àwọn àbádòfin pàtàkì-pàtàkì. Ọ̀kan lára wọn ni Magna Carta, ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. Lẹ́yìn náà ni Àbádòfin Ẹ̀tọ́ ti England (1689), Ìpolongo Ẹ̀tọ́ ti Virginia (1776), Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ènìyàn ti Ilẹ̀ Faransé (1789), àti Àbádòfin Ẹ̀tọ́ ti United States (1791), jáde.
Ní ọ̀rúndún kẹ́tàdínlógún, ìkejìdínlógún, àti ìkọkàndínlógún, ọ̀pọ̀ àwọn sàràkí-sàràkí nínú ìtàn sọ̀rọ̀ gbe òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lẹ́yìn. Ní 1644, John Milton, eléwì tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ England, tí a lè fi ìwé Paradise Lost rántí rẹ̀ jù lọ, kọ ìwé ìléwọ́ lílókìkí kékeré náà, Areopagitica, gẹ́gẹ́ bí àlàyé lòdì sí ìpààlà sí òmìnira àwọn ilé iṣẹ́ akọ̀ròyìn.
Ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, ìdàgbàsókè òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ England, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ààlà náà wà síbẹ̀. Ní America, àwọn ilẹ̀ ọba ń tẹpẹlẹ mọ́ ẹ̀tọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́rọ̀ ẹnu àti lórí ìwé. Fún àpẹẹrẹ, Ìwé Òfin Àjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Alájọṣe ti Pennsylvania, September 28, 1776, sọ báyìí lápá kan: “Pé àwọn ènìyán ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, àti ti ìwé kíkọ, àti títẹ èrò wọn jáde, nítorí náà, kò yẹ kí a fàṣẹ de òmìnira àwọn ilé iṣẹ́ akọ̀ròyìn.”
Ọ̀rọ̀ yìí ló fún Àtúnṣe Àkọ́kọ́ sí Ìwé Òfin United States lókun ní 1791, tí ó polongo èrò àwọn olùdásílẹ̀ Òfin America lórí ẹ̀tọ́ tí a ṣìkẹ́ tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn pé: “Ìgbìmọ̀ Aṣòfin kò ní ṣòfin kankan nípa ìgbékalẹ̀ ìsìn, tàbí kí ó fagi lé ṣíṣe ìsìn ní fàlàlà; tàbí kí ó ké òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, tàbí ti ìkọ̀ròyìn kúrú; tàbí ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn láti pàdé pọ̀ lálàáfíà, àti láti kọ̀wé sí Ìjọba láti gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ ìjìyà.”
Ọlọ́gbọ́n ìmọ̀ ọ̀ràn ará England ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún náà, John Stuart Mill, ṣe ìwé àròkọ rẹ̀ “On Liberty” jáde ní 1859. A sábà máa ń fa ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yọ, a sì ti tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ lílágbára jù lọ tí ń ṣagbátẹrù òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ogun nítorí ẹ̀tọ́ àtisọ̀rọ̀ fàlàlà ní gbangba kò pin sórí bí àwọn ọdún tí a ronú ìlàlóye sí ní ọ̀rúndún ogún yìí ṣe bẹ̀rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, nítorí àwọn ìsapá láti pààlà sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní America, àwọn ìkéde tí ń gbèjà òmìnira yẹn ti jáde síta láti àwọn ilé ẹjọ́, láti àwọn ilé ẹjọ́ kéékèèké àti láti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ United States.
Adájọ́ Oliver Wendell Holmes, Jr., ti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ United States, sọ èrò ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ jáde nínú àwọn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ díẹ̀. Nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe ìlànà ìdíyelé òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí pé: “Bí ìlànà kankan bá wà nínú Ìwé Òfin náà tí ó béèrè fún ìfarajìn ju òmíràn lọ, ìlànà òmìnira ìrònú ló jẹ́—kì í ṣe òmìnira ìrònú fún àwọn tí wọ́n fara mọ́ wa, àmọ́, òmìnira fún èrò tí kò bá wa lára mu.”—United States ní ìdojúkọ Schwimmer, 1928.
Àìka ìlànà yìí sí ni ó ṣokùnfà àwọn ọ̀ràn ilé ẹjọ́ tí ó mú kí ìṣòro náà máa bá a lọ láàárín òmìnira àti ìfagbára múni. Èrò náà sábà máa ń jẹ́ pé, “Òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ fún èmi—àmọ́ kì í ṣe fún ìwọ.” Nínú ìwé rẹ̀ tí a fún ní àkọlé yìí, Nat Hentoff tọ́ka sí àwọn àpẹẹrẹ tí àwọn olùhára gàgà tí wọ́n jẹ́ olùgbèjà Àtúnṣe Àkọ́kọ́ ti yí èrò wọn nípa òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ padà bìrí nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ronú nípa àǹfààní rẹ̀. Ó tọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nínú èyí tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ United States ti yí díẹ̀ lára àwọn ìpinnu ara rẹ̀ padà, tí ó ní nínú, àwọn kan nínú wọn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn tí ó kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti fi ń jà fún ẹ̀tọ́ láti sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa ìgbàgbọ́ ìsìn wọn. Ó kọ nípa wọn pé: “La àwọn ẹ̀wádún já, àwọn mẹ́ḿbà ìsìn yẹn ti kó ipa pàtàkì jálẹ̀jálẹ̀ sípa mímú kí òmìnira ẹ̀rí ọkàn gbòòrò nípasẹ̀ àwọn ìpẹ̀jọ́ tí ó bófin mu.”
Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ òfin àti àwọn òpìtàn òde òní ti kọ̀wé lọ́pọ̀ yanturu nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹjọ́ tí a ti gbọ́ ní kóòtù láti dáàbò bo òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní ìparí ọ̀rúndún ogún yìí, kì í ṣe ní America nìkan àmọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn pẹ̀lú. Òmìnira ìsìn kò dájú rí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìjọbá lè yangàn nípa òmìnira tí wọ́n nawọ́ rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n lè pàdánù rẹ̀ nígbà tí ìṣàkóso tàbí adájọ́ ilé ẹjọ́ bá yí padà, gẹ́gẹ́ bí ìrírí ti fi hàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú ipò iwájú ní jíjà fún òmìnira tí a ṣìkẹ́ yìí.
Nínú ìwé rẹ̀, These Also Believe, Ọ̀jọ̀gbọ́n C. S. Braden kọ̀wé pé: “Wọ́n [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] ti ṣe iṣẹ́ lílámì fún ìjọba tiwantiwa nípa ìjàkadì wọn láti dáàbò bo ẹ̀tọ́ ará ìlú wọn, nítorí pé nínú ìjàkadì wọn, wọ́n ti ṣe gudugudu méje láti rí àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyẹn gbà fún gbogbo àwùjọ ènìyàn kíkéré jọjọ ní America. Nígbà tí a bá tẹ ẹ̀tọ́ ará ìlú ti ẹgbẹ́ àwùjọ kan lójú, ẹ̀tọ́ ẹgbẹ́ àwùjọ èyíkéyìí mìíràn wà nínú ewu. Nítorí ìdí èyí ni wọ́n fi ṣe ohun pàtó sípa dídáàbò bo díẹ̀ lára àwọn ohun ṣíṣeyebíye jù lọ nínú ìṣàkóso tiwantiwa.”
Ó ṣòro fún àwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òmìnira láti lóye ìdí tí àwọn ìjọba àti ìsìn kan ṣe máa ń fawọ́ òmìnira yìí sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọn. Ó jẹ́ fífi pàtàkì ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn duni, ọ̀pọ̀ ènìyàn jákèjádò ayé sì ń jìyà lábẹ́ ìtẹ̀rì òmìnira yìí. Àwọn ìṣarasíhùwà sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kódà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ń gbádùn ẹ̀tọ́ pàtàkì yìí, yóò ha máa bá a lọ láìdúró sójú kan bí? A óò ha lo èrò òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ láti fi dá èdè pálapàla tàbí èdè àlùfààṣá láre bí? Ní báyìí ná, àwọn ilé ẹjọ́ ń jìjàkadì lórí àríyànjiyàn náà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Socrates sọ̀rọ̀ gbe òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lẹ́yìn
[Credit Line]
Musei Capitolini, Roma