100 Ọdún Sinimá
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ
NÍ TI gidi, sinimá jẹ́ góńgó àbájáde ìwádìí àti ìfidánrawò ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, tí ó gba nǹkan bí ọdún 75. Ní 1832, ẹ̀rọ phenakistoscope, tí Joseph Plateau, ọmọ ilẹ̀ Belgium, ṣàwárí rẹ̀, ṣàtúntò àwọn àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ títò tẹ̀ léra sí ìrísí àwòrán tí ń rìn. Ní ilẹ̀ Faransé, pẹ̀lú ìrànwọ́ Joseph Niepce àti Louis Daguerre, ó ṣeé ṣe láti gbé ìṣètò onífọ́tò tí ń yí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi padà sí àwòrán kalẹ̀ ní 1839. Ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Emile Reynaud, tún nasẹ̀ èrò yìí síwájú, bí ó ti ṣe ìgbéjáde àwòrán tí ń rìn lọ rìn bọ̀ lára ògiri, èyí tí ẹgbẹẹgbàarùn-ún ènìyán wò láàárín ọdún 1892 sí 1900.
Àṣeyọrí tí ó gbàfiyèsí gan-an nípa sinimá wáyé ní èyí tí ó lé díẹ̀ ní 100 ọdún sẹ́yìn. Ní 1890, olókìkí olùhùmọ̀ ará America kan, Thomas Edison, àti ọmọ ilẹ̀ England tí ń ràn án lọ́wọ́, William Dickson, ṣàgbékalẹ̀ kámẹ́rà kan, tí ó tóbi, tí ó sì tẹ̀wọ̀n tó dùùrù kékeré kan lóòró, Edison sì kọ̀wé béèrè ẹ̀tọ́ oníǹkan fún ohun èèlò ìwòran ẹlẹ́nì kan ṣoṣo, tí a ń pè ní kinetoscope, lọ́dún tí ó tẹ̀ lé e. Àwọn fíìmu rẹ̀, tí a gbà sílẹ̀ sórí ìdànǹdan fíìmù oníhò tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó fẹ̀ ní mìlímítà 35, ni a gbà sílẹ̀ ní ilé iṣẹ́ fíìmù àkọ́kọ́ lágbàáyé, Black Maria, ní West Orange, New Jersey. Àwọn fíìmù wọ̀nyí ń ṣàfihàn onírúurú eré orí ìtàgé ọlọ́pọ̀ ìpín, ìran àpéwò ìta gbangba, àti àwọn ìran ìṣẹ̀lẹ̀ láti ìhà ìwọ̀ oòrùn United States nígbà ìdàgbàsókè rẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìran láti inú àwọn eré olókìkí ní New York. Wọ́n ṣí ilé òwo kinetoscope kìíní ní New York, ní 1894, wọ́n sì kó ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹ̀rọ ránṣẹ́ sí Europe lọ́dún kan náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Edison kò lọ́kàn ìfẹ́ nínú àfihàn sinimá níbẹ̀rẹ̀, a fipá mú un láti ṣe ẹ̀rọ agbáwòrányọ kan, láti fi dènà ìbánidíje. Ẹ̀rọ agbáwòrányọ rẹ̀, vitascope, fara hàn nígbà àkọ́kọ́ ní New York, ní April 1896. Ìdíje lórí ẹ̀tọ́ oníǹkan tí ó tanná ràn lẹ́yìn náà yọrí sí gbígbé ẹgbẹ́ kan kalẹ̀ láti jèrè ẹ̀tọ́ àdáni pátápátá lórí ilé iṣẹ́ sinimá.
Ẹ̀dà kan kinetoscope tí Edison ṣe ni ó sún Auguste àti Louis Lumière, àwọn olùṣèmújáde ní Lyons, ilẹ̀ Faransé, láti hùmọ kámẹ́rà aláfọwọ́yí kan, tí ó lè yàwòrán sórí fíìmù, kí ó sì gbé e jáde sára ògiri. Wọ́n gba ẹ̀tọ́ oníǹkan lórí cinématographe (láti inú kinema, tí ó túmọ̀ sí “ìrìn,” àti graphein, tí ó túmọ̀ sí “láti ṣojú fún,” nínú ède Gíríìkì) wọn ní February 1895, “ilé iṣẹ́ sinimá àkọ́kọ́ lágbàáyé” sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní December 28, ní Grand Café, 14 Boulevard des Capucines, Paris. Lọ́jọ́ kejì, 2,000 ará Paris ya lọ sí Grand Café láti lọ wo àgbàyanu àmújáde sáyẹ́ǹsì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí.
Láìpẹ́, àwọn arákùnrin Lumière bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí ibi ìwòran sinimá, wọ́n sì ń fi àwọn ayàwòrán ránṣẹ́ káàkiri àgbáyé. Láàárín ìwọ̀nba ọdún díẹ̀, wọ́n ti gbé nǹkan bí 1,500 àwọn ibi lílókìkí kárí ayé, tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, irú bí ìgbadé Czar Nicholas Kejì ti Rọ́ṣíà sórí fíìmù.
Sànmánì Ìparọ́rọ́
Ohun tí Georges Méliès, onídán àti olùdásílẹ̀ ibi ìwòran kan ní Paris, rí fa ọkàn ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ra. Ó fẹ́ láti ra cinématographe náà. Èsì tí ó rí gbà ní kedere ni pé: “Rárá o, cinématographe náà kò sí fún títa. Ọlọ́mọkùnrin, ó yẹ kí o ṣọpẹ́ pé kò sí fún títa; ìhùmọ̀ yìí kò níí kẹ́sẹ járí.” Bí ó ti wù kí ó rí, láìfòyà, Méliès bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ohun èèlò tí ó kó wá láti England yàwòran fíìmù. Pẹ̀lú àwòrán àti ìró ohùn sinimá àti eré aláwòrán ara ògiri rẹ̀, Méliès yí ìyàwòrán sinimá padà sí iṣẹ́ ọnà kan. Ní 1902, fíìmu rẹ̀, Le Voyage dans la lune (Ìrìn Àjò Sínú Òṣùpá), jèrè ìtẹ́wọ́gbà kárí ayé. Ní ilé iṣẹ́ rẹ̀ ní Montreuil, lẹ́yìn odi ìlu Paris, ó ṣe fíìmù tí ó lé ní 500—tí a fi ọwọ́ lásán kun púpọ̀ lára wọn.
Nígbà tí ó fi di nǹkan bí 1910, ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn fíìmù tí a ń kó kiri àgbáyé wá láti ilẹ̀ Faransé. Ní pàtàkì, èyí jẹ́ nítorí sísọ tí àwọn arákùnrin Pathé sọ sinimá di ilé iṣẹ́ okòwò ńlá, pẹ̀lú góńgó láti sọ sinimá di “ibi ìwòran, ìwé agbéròyìnjáde, àti ilé ẹ̀kọ́ ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́.”
Ní 1919, Charlie Chaplin, Douglas Fairbanks, David W. Griffith, àti Mary Pickford dá ilé iṣẹ́ United Artists sílẹ̀ láti ba ìjẹgàba ẹgbẹ́ náà lórí iṣẹ́ òwo sinimá jẹ́. Ní 1915, fíìmù Birth of a Nation tí Griffith ṣe ni ó kọ́kọ́ kẹ́sẹ járí lọ́nà gbígbàfiyèsí jù lọ ní Hollywood. Fíìmù alárìíyànjiyàn yìí nípa Ogun Abẹ́lé America fa ìjà ìgboro àti ikú pàápàá nígbà tí wọ́n mú un jáde, nítorí àwọn ọ̀ràn ẹ̀yà ìran tí ó ní nínú. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣàṣeyọrí ńlá gan-an, pẹ̀lú àwọn olùwòran tí ó lé ní 100 mílíọ̀nù, tí ó sọ ọ́ di ọ̀kan lára àwọn sinimá tí ó tí ì mérè wá jù lọ nínú ìtàn. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn fíìmù “gbé America lódindi wọ ilé ìgbafàájì alaalẹ́, ẹgbẹ́ ìnàjú ìgbèríko, ibi ìtajà ọtí líle láìbófinmu àti ìbàjẹ́ ọ̀nà ìwà híhù tí ń wà nínú wọn.” Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí àfihàn àwọn fíìmù ilẹ̀ òkèèrè ní America mọ́, nígbà tí àwọn fíìmù America jẹ́ ìpín 60 sí 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a ń gbé jáde ní àwọn apá ibòmíràn lágbàáyé. A wáá ń lo sinimá bí ọ̀nà láti gbé ọ̀nà ìgbésí ayé ilẹ̀ America àti àwọn ohun àmújáde ilẹ̀ America lárugẹ. Nígbà kan náà, “ìgbékalẹ̀ ìsọnidigbajúgbajà” tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ sọ àwọn ènìyàn bíi Rudolph Valentino, Mary Pickford, àti Douglas Fairbanks di àkúnlẹ̀bọ ní kedere.
Ìró Ohùn àti Àwọ̀ Mèremère
“Màmá, Màmá, ẹ wáá gbọ́ nǹkan!” Èyí ni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí Al Jolson fi fòpin sí sànmánì aásìkí sinimá tí kì í sọ̀rọ̀, tí ó sì gbé èyí tí ń sọ̀rọ̀ jáde fáyé rí nínú fíìmù The Jazz Singer, ní 1927. A ti ń ṣe àṣeyẹ̀wò àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù agbóhùnjáde adúnbárajọ láti ìbẹ̀rẹ̀ sinimá, ṣùgbọ́n kò di nǹkan àmúyangàn títí di àwọn ọdún 1920, nígbà tí a hùmọ ìgbohùnsílẹ̀ oníná mànàmáná àti ẹ̀rọ agbóhùnjáde oní túùbù oníhò. Ìmújáde rẹ̀ kò ṣàìní àwọn ìṣòro tirẹ̀.
A mú ìlò àwọ̀ mèremère wọnú sinimá níbẹ̀rẹ̀ nípa lílo àwọn fíìmù àfọwọ́kùn. Lẹ́yìn náà, a bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn stencil. A ń fọwọ́ kun àwọn fíìmù nítorí kò sí ọ̀nà ìṣèmújáde fíìmù aláwọ̀ mèremère tí ó gbéṣẹ́. Onírúurú ọ̀nà ni a dán wò títí a fi ṣàṣeyọrí Technicolor pẹ̀lú ọnà ìṣèmújáde aláwọ̀ mẹ́ta rẹ̀ ní 1935. Bí ó ti wù kí ó rí, kìkì lẹ́yìn òkìkí kíkàmàmà ti sinimá Gone With the Wind ní 1939 ni a tóó rí lílò àwọ̀ mèremère gẹ́gẹ́ bí amáṣeyọríwá pàtàkì kan.
Ìtànkálẹ̀ Èrò Ìgbà Ogun
Nígbà ìjórẹ̀yìn ti àwọn ọdún 1930, sinimá ni wọ́n ń lò bí “ohun ìnàjú fún àwọn gbáàtúù.” Ṣùgbọ́n bí ayé ti ń sún kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ síhà ogun, iṣẹ́ ìjíhìn sinimá di ti ìtànjẹ àti ìtànkálẹ̀ èrò. Mussolini pe sinimá ní “l’arma più forte,” tàbí “ohun ìjà lílágbára jù lọ,” nígbà tí sinimá wà lábẹ́ Hitler, ó di agbẹnusọ fún ìjọba àjùmọ̀ní ti orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú ète ìpìlẹ̀ náà láti kọ́ àwọn ọ̀dọ́. Àwọn fíìmù bíi Der Triumph des Willens (Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Ìfẹ́ Inú) àti Olympia gbéṣẹ́ ní sísọ àwọn aṣíwáju Nazi di àkúnlẹ̀bọ. Ní ìdà kejì, Jud Süss (Jew Süss) gbé ìkórìíra àwùjọ àwọn Júù lárugẹ. Ní Britain pẹ̀lú, fíìmu Henry V tí Laurence Olivier ṣe ṣiṣẹ́ bí afúnnilókun ní ìmúrasílẹ̀ fún ọjọ́ pàtàkì náà àti àwọn ìjábá tí yóò tẹ̀ lé e.
Yánpọnyánrin
Bí tẹlifíṣọ̀n ṣe túbọ̀ ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó sí i lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn ènìyán bẹ̀rẹ̀ sí í gbélé dípò kí wọ́n máa lọ síbi sinimá. Iye àwọn tí ń lọ síbi sinimá ní United States lọ sílẹ̀, ó dé ìdajì iye ti tẹ́lẹ̀ láàárín ọdún mẹ́wàá péré. Ó di dandan fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé iṣẹ́ sinimá láti kógbá sílé, ìṣèmújáde àwọn fíìmú sì dín kù ní ìdá mẹ́ta, láìka ìmújáde àwọn fíìmù aláwò ńlá àti àwọn gbohùngbohùn amìjìnjìn ní àwọn ọdún 1950 sí. Láti bẹ́gi dínà ìbánidíje yìí, wọ́n ṣe àwọn ìmújáde fíìmù aláìmọye mílíọ̀nu dọ́là tí ó kẹ́sẹ járí lọ́nà gbígbàfiyèsí jù lọ, irú bíi Ten Commandments (1956), tí Cecil B. de Mille ṣe. Àwọn sinimá ilẹ̀ Europe pẹ̀lú fara gbá ìlọsílẹ̀ iye olùwòran.
Ipa Tí Ó Ní Lórí Àwùjọ
A ti pe sinimá ní àwòjíji àwùjọ. Àbájáde rẹ̀ ni pé, ọ̀pọ fíìmù àwọn ọdún 1970 ṣàgbéyọ “àìfararọ, àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, àìnírètí, hílàhílo, àìfinútánni” tí ń bẹ ní àkókò náà, gẹ́gẹ́ bí a ti lè rí i nínú ìtúnmúsọjí àwọn fíìmù ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ àti “ìfàmọ́ra tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí sí ìjọsìn Sátánì àti awo.” Àwọn sinimá oníjàábá ṣiṣẹ́ bí “ohun ìnàjú kúrò nínú ìjábá ojú ayé gidi.” (World Cinema—A Short History) Ní ìdà kejì, àwọn ọdún 1980 fojú winá ohun tí akọ̀ròyìn ọmọ ilẹ̀ Faransé kan pè ní “ìgbìyànjú àmọ̀ọ́mọ̀ṣe láti sọ ìgbégbòdì di ohun ìtẹ́wọ́gbà.” Ìdajì lára àwọn fíìmù tí wọ́n fi hàn níbi Àjọ̀dún Fíìmù ní Cannes ní 1983 ni ó ní ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ tàbí ìbálòpọ̀ takọtabo láàárín ìbátan gẹ́gẹ́ bíi kókó ọ̀rọ wọn. Ìwà ipá ti di ànímọ́ ìdánimọ̀, tàbí kókó ọ̀rọ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ léraléra, fún àwọn fíìmù òde òní. Ní 1992, ìpín 66 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn fíìmu Hollywood ní àwọn ìran ìwà ipá nínú. Nígbà tí ìwà ipá sí máa ń ní ète pàtó látijọ́, ó wulẹ̀ ń jẹ́ láìnídìí nísinsìnyí.
Kí ni ó ti jẹ́ àbájáde irú ìfihàn bẹ́ẹ̀? Ní October 1994, nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin kan àti ọ̀dọ́bìnrin kan, tí kò ní àkọsílẹ̀ ìwà ọ̀daràn kankan tẹ́lẹ̀ já sí ìgboro ìlu Paris, tí wọ́n sì pa ènìyàn 4, a dúrun mọ́ fíìmu Natural Born Killers, nínú èyí tí tọkọtaya kán ti pa ènìyàn 52, ní tààràtà. Síwájú àti síwájú sí i, àwọn onímọ̀ nípa àjùmọ̀gbé àwùjọ ń ṣàníyàn nípa ipá tí ìwà ipá ń ní—ní pàtàkì lórí àwọn ọ̀dọ́, tí irú àwọn ìran sinimá bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ àpẹẹrẹ ìhùwàsí fún. Dájúdájú, kì í ṣe gbogbo fíìmù ní ń gbé ìwà ipá àti ìwà pálapàla lárugẹ. Àwọn fíìmu lọ́ọ́lọ́ọ́ bíi The Lion King ta àwọn fíìmù amáṣeyọríwá tí wọ́n ṣáájú rẹ̀ yọ.
Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde Le Monde ti Paris béèrè ipa tí sinimá ti ní lórí àwùjọ láàárín 100 ọdún tó kọjá, gbajúgbajà aṣefíìmù àti òṣèré kan dáhùn pé, láìka ti pé ó ti “fògo fún ogun, [ó] mú kí jíjẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ ọ̀daràn dáni lọ́rùn, [ó] ṣàgbéyọ àwọn ojútùú tí a fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àti àwọn ọ̀rọ̀ ìsìn onítara, [ó] ṣẹ̀dá ìfojúsọ́nà èké, [ó] gbé ìjọsìn ọrọ̀, ohun ìní, ẹwà ara tí kò wúni lórí, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìlépa aláìjóòótọ́ àti aláìtóótun lárugẹ,” sí, bí ó ti wù kí ó rí, sinimá ti pèsè ọ̀nà àbájáde ṣíṣètẹ́wọ́gbà kúrò nínú àwọn òtítọ́ líle koko ti ìgbésí ayé ojoojúmọ́ fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn.
Bí ìran sinimá bá bẹ̀rẹ̀, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè nímọ̀lára idán pípa kan náà tí ó nípa lórí àwọn ènìyàn tó bẹ́ẹ̀ ní èyí tí ó lé ní 100 ọdún sẹ́yìn.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
“Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá”
Nígbà tí ó fi di ìparí ọdún 1914, nǹkan bí àádọ́talénírínwó ọ̀kẹ́ ènìyàn ní Australia, Europe, New Zealand, àti Àríwá America ti wo sinimá “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá” tí Watch Tower Society gbé jáde lọ́fẹ̀ẹ́. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ oní wákàtí mẹ́jọ náà ní sinimá àti fọ́tò ara ògiri alápá mẹ́rin, tí a mú ṣọ̀kan pẹ̀lú ohùn àti orin. Ọwọ́ ni a fi kun àwọn àwòrán àti fíìmù náà. A wéwèé ṣètò “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò” náà “láti gbé ìmọrírì fún Bíbélì àti ète Ọlọ́run, bí a ti là á lẹ́sẹẹsẹ nínú rẹ̀, ró.” Àwọn kókó pàtàkì ní bí òdòdó ṣe ń tanná àti bí adìyẹ́ ṣe ń pamọ, tí a gbà sílẹ̀ sórí fíìmù nípasẹ̀ ọgbọ́n ìyafọ́tò tí ń mú ohun tí ó gba àkókò gígùn yára kánkán nínú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
“Cinématographe Lumière,” tí a gba ẹ̀tọ́ oníǹkan lé lórí ní February 1895
[Credit Line]
© Héritiers Lumière. Collection Institut Lumière-Lyon
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
© Héritiers Lumière. Collection Institut Lumière-Lyon