ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/8 ojú ìwé 20-21
  • “Fàdákà Ń Bẹ ní Potosí!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Fàdákà Ń Bẹ ní Potosí!”
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìkólẹ́rú
  • Bábílónì
  • Ọrọ̀ Àlùmọ́nì Ti A Lò Nílò Àpà
  • Bí Àwọn Ará Inca Ṣe Pàdánù Ilẹ̀ Ọba Wọn Oníwúrà
    Jí!—1998
Jí!—1996
g96 8/8 ojú ìwé 20-21

“Fàdákà Ń Bẹ ní Potosí!”

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ BOLIVIA

Ọdún 1545 ni ọdún náà, ní kìkì ọdún 12 lẹ́yìn tí Francisco Pizarro ṣẹ́gun Ilẹ̀ Ọba Inca títóbi náà. Àwọn ará Sípéènì rí ọ̀dọ́kùnrin ọmọ India kan tí ń jí fàdákà àìfọ̀ wà láti ibi ìkọ̀kọ̀ kan ní Àwọn Òkè Ńlá Andes tí ń jẹ́ Bolivia nísinsìnyí. Wọ́n ń pe ibẹ̀ ní Potosí. Lójijì, ọ̀rọ̀ náà ti tàn kálẹ̀ pé: “Fàdákà wà ní Potosí!” Láìka ìgbà òtútù tí ń bọ̀ sí, àwọn ènìyán rọ́ lọ jà fún ẹ̀tọ́ oníǹkan ní agbègbè náà. Fàdákà àìfọ̀ náà níye lórí gan-an lọ́nà yíyani lẹ́nu—ògidì fàdákà ṣíṣeyebíye ní ìwọ̀n 50 nínú ọgọ́rùn-ún! Láàárín oṣù 18, 14,000 ènìyán ti ń gbé ní Potosí.

FÀDÁKÀ àìfọ̀ náà wà ní ẹ̀bá òkè ńlá kan tí ó ga tó 4,688 mítà sókè ìtẹ́jú òkun. Àyíká náà kò fani mọ́ra, ó fẹ́rẹ̀ máà ní koríko, ó sì ga ré kọjá orí àwọn igi. Fàdákà àìfọ̀ tí ó níye lórí gidigidi náà ni a ń yọ́ nínú ààrò tí ó ṣeé gbé kiri tí ẹ̀fúùfù ń fẹ́ná sí èédú rẹ̀ dé ìwọ̀n ìgbóná tí ó yẹ. Olùṣàkọsílẹ̀ ìtàn kan lákòókò náà ṣàpèjúwe rírí 15,000 ààrò tí ń ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan náà. Ní alẹ́, ńṣe ni wọ́n máa ń dà bí ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ àwọn ìràwọ̀.

Ìlú tí ó wà lẹ́bàá òkè ńlá náà ni a kọ́ gátagàta pẹ̀lú àwọn òpópónà tóóró, tí ó ṣe kọ́lọkọ̀lọ láti pèsè ààbò díẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù títutù nini. Òpìtàn R. C. Padden kọ̀wé pé: “A ronú pé kò sí ìṣètò, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìlànà, ní pàtàkì nítorí pé a kò retí pé kí fàdákà náà pọ̀ jọjọ.” Ṣùgbọ́n ó pọ̀ jọjọ. Òkè ńlá náà, tí a ń pè ní Cerro Rico (Òkè Ńlá Ṣíṣeyebíye), wáá di èyí tí ó ní ọ̀kan lára ibi títóbi jù lọ tí fàdákà wà tí a tí ì rí rí.

Ìkólẹ́rú

Àwọn ará Sípéènì forí ti àwọn àìfararọ apániláyà nínú ìwákiri wọn fún fàdákà. Lọ́pọ̀ ìgbà ni oúnjẹ ń wọ́n, tí omi ń léèérí, tí ibi ìwakùsà náà sì ń jẹ́ eléwu. Ojú ọjọ́ títutù nini náà gbé ìṣòro líle koko kan kalẹ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn tí wọ́n gbìyànjú láti fi iná eléèédú mú ara wọn gbóná jìyà lọ́wọ mímí májèlé afẹ́fẹ́ olóró carbon monoxide sínú.

Kò pẹ́ tí àwọn ará Sípéènì rí ọ̀nà tí wọn óò gbà dín ìnira wọn kù. Gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun, wọ́n fipá kó àwọn ọmọ India tí wọ́n ni ilẹ̀ náà lẹ́rú. Ìwé agbéròyìnjáde Bolivian Times ti La Paz sọ pé: “Mílíọ̀nù mẹ́jọ àwọn ọmọ India tí wọ́n jẹ́ ẹrú ni a ròyìn pé wọ́n ṣègbé,” tí wọ́n kú, ní ibi ìwakùsà Potosí, nígbà ìṣàkóso àgbókèèrèṣe. Ìwà ìkà, ìloni lálòjù, àti àrùn mú kí iye ènìyán dín kù lọ́nà bíburú jáì. Abájọ tí olùṣàkọsílẹ̀ ìtàn kan ní ọdún 1550 fi pe Potosí ní “ẹnu ọ̀na hẹ́ẹ̀lì”!

Bábílónì

Ní ọdún 1572, Potosí tóbi ju ìlú ńlá èyíkéyìí tí ó wà ní Sípéènì lọ. Ní 1611, wọ́n sọ pé ó ní 160,000 olùgbé nínú, ó sì tóbi bákan náà pẹ̀lu Paris àti London. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá tí ó lọ́rọ̀ jù lọ lágbàáyé. Àṣà tó lòde níbẹ̀ ni wíwọ aṣọ sílíkì tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe ọ̀ṣọ́ sí lára. Ó jọ pé bí o bá rówó san lo tóó lè gbádùn ohun afẹ́ èyíkéyìí: sílíkì láti China, ate láti England, aṣọ tí a fọwọ́ hun láti Naples, lọ́fínńdà láti Arébíà. Àwọn olùgbé ibẹ̀ ń fi kápẹ́ẹ̀tì láti Páṣíà, àwọn ohun òṣọ́ ilé láti Flanders, àwòrán láti Ítálì, gíláàsì láti Venice, ṣe ilé wọn lọ́ṣọ̀ọ́.

Ṣùgbọ́n bí ọrọ̀ àlùmọ́nì Potosí ti pọ̀ tó ni ìwà ipá ibẹ̀ ṣe pọ̀ tó. Ìjà tí ó mú ìtàjẹ̀sílẹ̀ dání jẹ́ ìran àpéwò ojoojúmọ́ ní àwọn gbàgede ìwòran. Àwọn ilé tẹ́tẹ́ àti ilé aṣẹ́wó kò lóǹkà. Potosí wáá di ibi tí a mọ̀ sí Bábílónì.

Ọ̀kan lára àwọn lájorí ète àwọn aṣẹ́gun ará Sípéènì ni láti gbé ìsin Kátólíìkì wọn kalẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ America. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, báwo ni àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni yìí ṣe lè dáre fún èrè gọbọi tí wọ́n rí jẹ nínú òwò ẹrú? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ lára àwọn olùre ṣọ́ọ̀ṣì ké gbàjarè lòdì sí àwọn ìwà àìṣèdájọ́ òdodo náà, àwọn mìíràn ronú pé òwò ẹrú bọ́gbọ́n mu nípa sísọ pé ìwà ìṣìkàgbonimọ́lẹ̀ àwọn ará Sípéènì kò tó ìwà ìṣìkàgbonimọ́lẹ̀ àwọn ará Inca. Wọ́n sọ pé àwọn ọmọ India rẹlẹ̀ lọ́lá, wọ́n sì ní ìtẹ̀sí àdánidá sí ìwà abèṣe—nípa bẹ́ẹ̀, ó sàn jù kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ ní àwọn ibi ìwakùsà. Síbẹ̀, àwọn mìíràn sọ pé kíkó àwọn ọmọ India wá ṣiṣẹ́ ní àwọn ibi ìwakùsà náà jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ó pọn dandan fún yíyí wọn lọ́kàn padà sí ìsin Kátólíìkì.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìtán fi hàn pé àwọn àlùfáà wà lára àwọn tí wọ́n lọ́rọ̀ jù lọ ní Potosí. Òpìtàn Mariano Baptista sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì náà gẹ́gẹ́ bí àjọ kan, àti àwọn aṣojú rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, jẹ́ apá kan olùjàǹfààní nínú agbo ìkónífà” àwọn ọmọ India. Òpìtàn yìí fa ọ̀rọ gómìnà kan yọ tí ó ṣàròyé ní ọdún 1591 pé àwọn àwùjọ àlùfáà náà “kó àwọn ọmọ India nífà pẹ̀lú ìwọra àti ìlépa ire ara ẹni púpọ̀ ju bí àwọn ọ̀gbẹ̀rí ti ṣe lọ.”

Ọrọ̀ Àlùmọ́nì Ti A Lò Nílò Àpà

Sípéèni ti jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀, àmọ́ fún ẹ̀wádún díẹ̀ kan, ọrọ̀ rẹ̀ sọ ọ́ di alágbára gíga jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n irú ipò ire àǹfààní yẹn kò tọ́jọ́. Nígbà tí ìwe Imperial Spain—1469-1716, láti ọwọ́ J. H. Elliott, ń sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí ọrọ̀ Sípéènì fi kùnà láti fún un ní àwọn ire àǹfààní pípẹ́ títí, ó wí pé: “Àwọn ibi ìwakùsà ní Potosí mú ọrọ̀ púpọ̀ wá fún orílẹ̀-èdè náà; bí owó kò bá tó lákòókò kan, yóò tún dé jaburata lákòókò míràn nígbà tí ẹrù ọrọ̀ àlùmọ́nì náà bá dé Seville. Àbọ̀rọ̀ máa wéwèé, àbọ̀rọ̀ máa fowó pamọ́, àbọ̀rọ̀ máa ṣiṣẹ́?”

Wọ́n lo ọrọ̀ àlùmọ́nì Potosí nílò àpà; ìwọko gbèsè lọ́nà lílámì gan-án máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n máa ń sọ lákòókò náà, dídé ẹrù ọrọ̀ àlùmọ́nì dà bí òjò fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ń fọ́n sórí òrùlé fún ìgbà díẹ̀ tí oòrùn yóò sì lá a gbẹ. Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, olùṣàkíyèsí kan ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún sọ nípa ìjórẹ̀yìn Sípéènì pé: “Kò lọ́rọ̀, nítorí pé ó lo gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ nílò àpà.”

Ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, Potosí jó rẹ̀yìn nígbà tí fàdákà tán, àmọ́ ṣáá, ó tún kọ́fẹ padà nígbà tí tánńganran di ohun pàtàkì. Ní báyìí, tánńganran kò fi bẹ́ẹ̀ lókìkí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Potosí ṣì jẹ́ agbègbè onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ fún ìṣèmújáde àti ìwakùsà. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìn àjò afẹ́ ń bẹ Potosí wò láti gbádùn ìfanimọ́ra ìṣàkóso àgbókèèrèṣe rẹ̀. Wọ́n tún lè ṣàkíyèsí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ rẹpẹtẹ, tí a kò lo ọ̀pọ̀ lára wọn mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí sí ọkàn ìfẹ́ tí ń dín kù fún ìsin Kátólíìkì.

Lónìí, Potosí jẹ́ ohun ìránnilétí búburú jáì nípa ìyà kíkàmàmà tí ìwọra, ìtànjẹ ìṣèlú, àti ìṣinilọ́nà ìsìn ń fi jẹ ènìyàn, ìránnilétí apá pàtàkì kan nínú ìtàn ilẹ̀ Bolivia tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpè náà: “Fàdákà wà ní Potosí!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́