ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 1/8 ojú ìwé 13-18
  • Bí Àwọn Ará Inca Ṣe Pàdánù Ilẹ̀ Ọba Wọn Oníwúrà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Àwọn Ará Inca Ṣe Pàdánù Ilẹ̀ Ọba Wọn Oníwúrà
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ló Wà Ṣáájú Àwọn Ará Inca?
  • Ìtàn Àròsọ àti Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Ní Gidi
  • Tẹ́ńpìlì Dídángbinrin ti Oòrùn Náà
  • Báwo Ni A Ṣe Mú Kí Ilẹ̀ Ọba Náà Ṣọ̀kan?
  • Owó Orí Mita
  • Àwọn Akóguntini Láti Àríwá
  • Ìbẹ̀rẹ̀ Òpin Náà
  • Olú Ọba Inca Tí Ó Jẹ Kẹ́yìn
  • Àwọn Àtọmọdọ́mọ Inca Ti Òde Òní
  • Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Mú Ìyípadà Wá
  • Cuzco—Olú Ìlú Ìgbàanì Ti Àwọn Ará Inca
    Jí!—1997
  • “Fàdákà Ń Bẹ ní Potosí!”
    Jí!—1996
  • Wíwàásù Ìjọba Náà Lórí Òkè Altiplano ní Peru
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Jí!—1998
g98 1/8 ojú ìwé 13-18

Bí Àwọn Ará Inca Ṣe Pàdánù Ilẹ̀ Ọba Wọn Oníwúrà

LÁTI ỌWỌ́ ASỌJÚKỌ̀RÒYÌN JI! NÍ PERU

Oòrùn ti là. Ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ tí ó tàn sára òkè ńlá Andes tí òjò dídì bo orí rẹ̀ fún un ní àwọ̀ osùn rẹ́súrẹ́sú. Àwọn tí wọ́n tètè jí lára àwọn Àmẹ́ríńdíà gbádùn ìlọ́wọ́ọ́wọ́ọ́ tí ń gbọn òtútù tí ó mú wọn nítorí ìtutùnini òru ní ibi tí ó ga ní mítà 4,300 náà nù. Díẹ̀díẹ̀, ìtànṣán oòrùn náà dé orí tẹ́ńpìlì oòrùn tí ó wà ní àárín olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Inca náà, Cuzco, (tí ó túmọ̀ sí “Agbedeméjì Ayé”). Ìtànṣán oòrùn ń kọ mànà lára àwọn ògiri oníwúrà. Àwọn ẹranko Ilama, vicuñas, àti igún condor tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe ń dán gbinrin ní àgbàlá olú ọba Incaa ní iwájú tẹ́ńpìlì náà. Àwọn tí ń kọjá lọ n fi ọwọ́ ko ẹnu, wọ́n sì ń ju ọwọ́ náà ní jíjọ́sìn ọlọ́run wọn, oòrùn. Ẹ wo bí ọpẹ́ wọn ti pọ̀ tó pé wọ́n wà láàyè, tí oòrùn tí ń ṣètìlẹ́yìn fún ìwàláàyè wọn sì ń bù kún wọn, bí wọ́n ṣe gbà gbọ́!

LÁÀÁRÍN ọ̀rúndún kẹrìnlá sí ìkẹrìndínlógún, ilẹ̀ ọba oníwúrà ńlá kan ń ṣàkóso ní etíkun ìwọ̀ oòrùn Gúúsù Amẹ́ríkà. Bí ó ti jẹ́ pé àwọn olùyàwòrán ìgbékalẹ̀ ilé àti àwọn oníṣẹ́-ọwọ́ ní ń ṣàkóso níbẹ̀, àwọn ará Inca jẹ́ àwùjọ ènìyàn tí a ṣètò jọ láti mú àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà wọn sunwọ̀n sí i. Ilẹ̀ Ọba Inca àgbàyanu náà nasẹ̀ ààlà rẹ̀ fún ohun tí ó tó 5,000 kìlómítà, láti ìhà gúúsù Colombia òde òní títí dé Ajẹntínà. Ní tòótọ́, “àwọn olú ọba Inca rò pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ayé ni àwọn ń ṣàkóso.” (National Geographic) Wọ́n gbà gbọ́ pé kò sí ohun kan lẹ́yìn ààlà ilẹ̀ ọba wọn, tí ó dára tó láti jagun gbà. Síbẹ̀, àwọn tí ń gbé apá ibòmíràn lágbàáyé kò mọ̀ pé ilẹ̀ ọba yìí wà.

Ta ni àwọn ará Inca? Ibo ni orírun wọn?

Ta Ló Wà Ṣáájú Àwọn Ará Inca?

Àwọn ohun iyebíye tí a wà jáde nínú ilẹ̀ fi hàn pé kì í ṣe àwọn ará Inca ni wọ́n kọ́kọ́ ń gbé kọ́ńtínẹ́ǹtì náà. Àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ mìíràn tí wọ́n lajú dáradára ti wà ṣáájú wọn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn awalẹ̀pìtàn ti ka àwọn wọ̀nyí sí àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ Lambayeque, àwọn Chavin, àwọn Mochica, àwọn Chimu, àti ti àwọn Tiahuanaco.

Àwùjọ àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ dé ibẹ̀ náà ń jọ́sìn onírúurú ẹranko—jaguar, puma, àti ẹja pàápàá. Ìjúbà fún àwọn òrìṣà òkè tàn kálẹ̀ láàárín wọn. Àwọn ọnà tí wọ́n fi amọ̀ ṣe fi hàn pé àwọn ẹ̀yà kan ń jọ́sìn ìbálòpọ̀. Nítòsí Adágún Titicaca, lápá òkè ní ààlà ilẹ̀ tí ó wà láàárín Peru àti Bolivia, ẹ̀yà kan kọ́ tẹ́ńpìlì kan tí ó ní àwọn ìṣàpẹẹrẹ nǹkan ọmọkùnrin, tí wọ́n ń jọ́sìn nínú àwọn ààtò ìlèmúrújáde, kí Pacha-Mama, tí ó túmọ̀ sí “Yèyé Ayé” lè jẹ́ kí wọ́n kórè oko dídára.

Ìtàn Àròsọ àti Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Ní Gidi

Ní nǹkan bí ọdún 1200 ni àwọn ará Inca fara hàn. Gẹ́gẹ́ bí aṣàkọsílẹ̀ ìtàn náà, Garcilaso de la Vega, ọmọ bíbí inú ọmọbìnrin ọba kan ní Inca, tí ó sì jẹ́ agbọ́pàágun ará Sípéènì, tí ó tún jẹ́ onílẹ̀, ti sọ, ìtàn àròsọ sọ pé, ọlọ́run oòrùn, tí í ṣe bàbá olú ọba Inca àkọ́kọ́ náà, Manco Capac, rán òun àti arábìnrin tàbí aya rẹ̀ wá sí Adágún Titicaca láti wá fa gbogbo ènìyàn wọnú ìjọsìn oòrùn. Lónìí, wọ́n ṣì ń sọ ìtàn àtẹnudẹ́nu yìí fún àwọn ọmọdé ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí a pa ti ìtàn àròsọ tì, ó lè jẹ́ láti inú ẹ̀yà kan lára àwọn tí wọ́n wà ní Adágún Titicaca, ìyẹn Tiahuanacos, ni àwọn ará Inca ti pilẹ̀ ṣẹ̀. Bí àkókò ti ń lọ, ilẹ̀ ọba tí ń tàn kálẹ̀ náà mú púpọ̀ lára iṣẹ́ àwọn ẹ̀yà tí wọ́n ṣẹ́gun, tí a ṣètò jọ dáradára náà ṣe, wọ́n ń fẹ ojú àwọn odò lílà àti àwọn ilẹ̀ títẹ́jú tí ó ti wà tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń mú wọ́n sunwọ̀n sí i. Àwọn ará Inca ta yọ nínú kíkọ́ àwọn ilé ńláńlá. Èrò tí ó pọ̀ wà nípa bí àwọn olùyàwòrán ìgbékalẹ̀ ilé wọn ṣe lè yàwòrán odi àti tẹ́ńpìlì Sacsahuaman, tí ń wo ìlú ńlá Cuzco láti ibi gíga kan. Wọ́n mọ àwọn òkúta ràbàtàràbàtà onítọ́ọ̀nù 100 pọ̀. Wọn kò fi sìmẹ́ǹtì mọ wọ́n pọ̀. Àwọn ìsẹ̀lẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ rí àwọn òkúta mímọpọ̀ tí a rí lára ògiri ìlú ńlá ìgbàanì náà, Cuzco, gbé ṣe.

Tẹ́ńpìlì Dídángbinrin ti Oòrùn Náà

Ní ìlú ńlá ọlọ́ba náà, Cuzco, àwọn ará Inca ṣètò ẹgbẹ́ àlùfáà kan fún ìjọsìn oòrùn nínú tẹ́ńpìlì kan tí wọ́n fi òkúta tí a dán kọ́. Wọ́n fi ògidì wúrà àti fàdákà ṣe inú rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́. Pa pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ àlùfáà, wọ́n kọ́ àwọn àkànṣe ilé ìsìn, irú èyí tí wọ́n ṣe àtúnkọ́ rẹ̀ ní tẹ́ńpìlì oòrùn ti Pachácamac, lẹ́yìn odi ìlú Lima. Wọ́n ń dá àwọn wúńdíá tí wọ́n lẹ́wà jù lọ lẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà tí wọ́n wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́jọ láti jẹ́ ‘wúńdíá oòrùn.’ Àwọn ẹ̀rí tí a wà nínú ilẹ̀ fi hàn pé àwọn ará Inca fi àwọn ènìyàn rúbọ pẹ̀lú. Wọ́n fi àwọn ọmọdé rúbọ sí apus, tàbí àwọn òrìṣà òkè. A ti rí òkú àwọn ọmọdé kan tí ó ti di yìnyín lórí òkè Andes.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Inca àti àwọn ẹ̀yà àtètèkọ́ṣe kò mọ bí a ti ń kọ̀wé, wọ́n gbé ìlànà pípa àkọsílẹ̀ mọ́ kan kalẹ̀ ní lílo ohun tí wọ́n ń pè ní quipu. Èyí jẹ́ “ìhùmọ̀ kan tí wọ́n fi fọ́nrán ńlá kan tí a so àwọn fọ́nrán kéékèèké aláwọ̀ oríṣiríṣi mọ́, tí a sì ta kókó wọn ṣe, tí àwọn ará Peru ìgbàanì lò” gẹ́gẹ́ bí ohun ìránnilétí fún àwọn tí a yanṣẹ́ fún láti tọ́jú àkọsílẹ̀ ẹrù àti ti ìtàn.—Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary.

Báwo Ni A Ṣe Mú Kí Ilẹ̀ Ọba Náà Ṣọ̀kan?

Àwọn òfin aláìgbagbẹ̀rẹ́ àti ìwéwèé àfìṣọ́raṣe fìdí ìjọba àpapọ̀ kan ṣoṣo náà múlẹ̀ ṣinṣin. Ohun àìgbọdọ̀máṣe àkọ́kọ́ ni pé kí gbogbo ará ibẹ̀ kọ́ Quechua, èdè àwọn ará Inca. Ìwé El Quechua al Alcance de Todos (Quechua Lárọ̀ọ́wọ́tó Gbogbo Ènìyàn) sọ pé, a ka “èdè Quechua sí èyí tí ó kún rẹ́rẹ́ jù lọ, tí ó yàtọ̀ jù lọ, tí ó sì gbayì jù lọ lára àwọn èdè àdúgbò ní Gúúsù Áfíríkà.” Nǹkan bíi mílíọ̀nù márùn-ún ènìyàn ṣì ń sọ ọ́ ní àwọn òkè ńlá Peru, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn míràn ní àwọn orílẹ̀-èdè márùn-ún tí wọ́n ti wà lára ilẹ̀ ọba náà tẹ́lẹ̀ rí sì ń sọ ọ́ síbẹ̀. Àwùjọ àwọn ènìyàn kan ní gúúsù ìlà oòrùn Adágún Titicaca ṣì ń sọ Aymara, èdè àdúgbò kan tí a mú wá láti inú èdè Quechua tí ó ti wà kí Inca tó yọjú.

Sísọ èdè Quechua ní ipa amúniṣọ̀kan lórí àwọn ẹ̀yà tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 100 tí a ṣẹ́gun náà, ó sì jẹ́ àrànṣe fún curaca (baálẹ̀) abúlé, tí ń ṣàkóso àwùjọ kọ̀ọ̀kan. Wọ́n yan ilẹ̀ ibi tí ìdílé kọ̀ọ̀kan yóò máa ro fún un. Lẹ́yìn ìjagunmólú, olú ọba Inca fàyè gba kí àwọn ènìyàn máa jó ijó ìbílẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣe ọdún ìbílẹ̀, ó sì pèsè àwọn eré orí ìtàgé àti eré àṣedárayá kí gbogbo àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àkóso rẹ̀ lè ní ìtẹ́lọ́rùn.

Owó Orí Mita

Owó kò ní ìwọ̀n tí a fi ń ṣírò rẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ọba náà, èyí sì túmọ̀ sí pé wúrà pàápàá kò já mọ́ nǹkan kan lójú ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Ohun tí ń dá wọn lọ́rùn lára rẹ̀ ni pé ó ń kọ mànà nínú oòrùn. Owó orí kàn ṣoṣo tí a béèrè lọ́wọ́ wọ́n ni mita (lédè Quechua, “pípín iṣẹ́ gbà”), òun ni ohun àbèèrèfún tí àwọn ará ìlú ń pín ṣe, ní kíkópa nínú iṣẹ́ agbára ti líla ọ̀pọ̀ títì Inca àti kíkópa nínú àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé. Wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ Àmẹ́ríńdíà sí iṣẹ́ lábẹ́ òfin.

Ní lílo àwọn òṣìṣẹ́ mita náà, àwọn ọ̀gá olùṣe-ọ̀nà ará Inca náà ṣe ìsokọ́ra àwọn ọ̀nà tí ó gùn ju 24,000 kìlómítà! Bẹ̀rẹ̀ láti Cuzco, àwọn ará Inca ṣe irú títì kan tí wọ́n fi òkúta tẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó dé àwọn ibi jíjìnnà síra gan-an ní ilẹ̀ ọba náà. Àwọn òjíṣẹ́ tí wọ́n ti dá lẹ́kọ̀ọ́, tí a ń pè ní chasqui, ní ń gba àwọn ọ̀nà náà. Wọ́n fi wọ́n sí àwọn ahéré ní ibi tí ó tó kìlómítà kan sí mẹ́ta síra. Bí chasqui kan tí ń mú ìsọfúnni kan bọ̀ bá dé, chasqui tí ó kàn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í sáré lọ pẹ̀lú rẹ̀, bí ẹni tí ń gbé ìsọfúnni láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan dé ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn. Ní lílo irú ìṣètò yí, wọ́n máa ń dé ibi tí ó jìnnà tó 240 kìlómítà lóòjọ́. Ní àkókò tí kò pẹ́, olú ọba Inca tó wà lórí àléfà yóò rí ìsọfúnni láti gbogbo ilẹ̀ ọba rẹ̀.

Olú ọba Inca náà kọ́ àwọn àká ńláńlá sí àwọn ojú ọ̀nà náà. Wọ́n kó oúnjẹ àti aṣọ tí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Inca yóò máa lò bí wọ́n bá wà lẹ́nu ìrìn àjò ìṣẹ́gun kún inú wọn. Olú ọba Inca máa ń yẹra fún ogun nígbà tí ó bá ṣeé ṣe. Ní lílo ìwéwèé àfìṣọ́raṣe, ó rán àwọn amí láti ké sí àwọn ẹ̀yà míràn láti wá sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀, kìkì bí wọ́n bá tẹ́wọ́ gba ìjọsìn oòrùn. Bí wọ́n bá gbà, yóò gbà wọ́n láyè láti máa bá a lọ nínú ẹ̀yà wọn, tí àwọn olùdánilẹ́kọ̀ọ́ olú ọba Inca tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ yóò sì máa darí wọn. Bí wọ́n bá kọ̀, wọ́n di òjìyà ìpalára ìṣẹ́gun aláìláàánú. Agbárí òkú àwọn ọ̀tá ni wọ́n ń lò bí ife tí wọ́n fi ń mu chicha, ọtí líle kan tí wọ́n fi àgbàdo ṣe.

Lábẹ́ ìṣàkóso olú ọba Inca kẹsàn-án, Pachacuti (láti 1438 lọ), ọmọkùnrin rẹ̀ Topa Inca Yupanqui, àti àgbà òṣèlú ajagunṣẹ́gun náà, Huayna Capac, ni ilẹ̀ ọba náà mú àwọn ààlà rẹ̀ fẹ̀ sí i láìjáfara, ó sì dé ibi tí ó jìnnà jù lọ láti àríwá sí gúúsù. Ṣùgbọ́n èyí kò tọ́jọ́.

Àwọn Akóguntini Láti Àríwá

Ní nǹkan bí ọdún 1530, ajagunṣẹ́gun ará Sípéènì náà, Francisco Pizarro, àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ wá láti Panama, bí àwọn ìròyìn nípa wúrà tí ó wà ní ilẹ̀ àìmọ̀ tí ogun abẹ́lé ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ náà ti fi ẹ̀tàn fà wọ́n mọ́ra. Ọmọba Huáscar, tí ó jẹ́ ajogún tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìtẹ́ náà, ni ọbàkan rẹ̀, Atahuallpa, tí ń sún mọ́ olú ìlú náà ti ṣẹ́gun, tí ó sì ti fi í sẹ́wọ̀n.

Lẹ́yìn tí wọ́n fi tìpátìkúùkù wọ ìlú ńlá Cajamarca, tí ó wà láàárín ilẹ̀ náà, Atahuallpa tí ó fipá gba àkóso náà gba Pizarro àti àwọn ènìyàn rẹ̀ tọwọ́tẹsẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ará Sípéènì lo àdàkàdekè, wọ́n sì ṣàṣeyọrí láti gbé e kúrò lórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀, wọ́n sì mú un ní ìgbèkùn, wọ́n sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ẹnu yà, tí wọn kò sí ní ìmúrasílẹ̀ lákòókò kan náà.

Síbẹ̀síbẹ̀, kódà bí wọ́n ti mú Atahuallpa ní ìgbèkùn, ó ń ja ogun abẹ́lé náà lọ. Ó rán àwọn oníṣẹ́ lọ sí Cuzco láti lọ pa ọbàkan rẹ̀, Inca Huáscar àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ará ìdílé ọba. Láìmọ̀, ó mú kí ìṣẹ́gun Pizarro túbọ̀ rọrùn.

Bí Atahuallpa ti rí ìwọra tí àwọn ará Sípéènì ní fún wúrà àti fàdákà, ó ṣèlérí láti kó àwọn ère wúrà àti fàdákà kún iyàrá ńlá kan gẹ́gẹ́ bí ohun ìràpadà fún ìdásílẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò ṣàǹfààní kankan. Lẹ́ẹ̀kan sí i àdàkàdekè tún wọ̀ ọ́! Lẹ́yìn tí wọ́n kó ohun ìràpadà tí ó ṣèlérí náà jọ, wọ́n kọ́kọ́ ṣèrìbọmi lọ́nà ti Kátólíìkì fún Atahuallpa, Inca kẹtàlá, tí àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé kà sí abọ̀rìṣà, wọ́n sì yí i lọ́rùn pa lẹ́yìn náà.

Ìbẹ̀rẹ̀ Òpin Náà

Ìmúnígbèkùn àti pípa tí wọ́n pa Atahuallpa jẹ́ àjálù tí ó mú ìparun wá fún Ilẹ̀ Ọba Inca. Ṣùgbọ́n àwọn Àmẹ́ríńdíà ibẹ̀ yarí fún àwọn akóguntini náà, ilẹ̀ ọba náà sì joró ikú fún 40 ọdún mìíràn.

Nígbà tí àwọn alátìlẹ́yìn sì dé, Pizarro àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ hára gàgà láti gbéra lọ sí Cuzco láti lọ gba sí i lára wúrà ilẹ̀ Inca. Nínú ìwákiri yìí, àwọn ará Sípéènì lo ìdánilóró lọ́nà rírorò láti gbọ́ àṣírí ibi tí ìṣúra wà lẹ́nu àwọn Àmẹ́ríńdíà tàbí láti dẹ́rù ba àwọn alátakò èyíkéyìí, kí wọ́n sì pa wọ́n.

Bí arákùnrin Huáscar, Ọmọba Manco Kejì, tí oyè Inca (Manco Inca Yupanqui) kàn, ti tẹ̀ lé Pizarro, ó tiraka dé Cuzco, ó sì wá ibẹ̀ tinútòde láti kó gbogbo ìṣúra wúrà kíkàmàmà tí ó wà níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ère oníwúrà ibẹ̀ ni wọ́n yọ́ fún Sípéènì. Abájọ tí àwọn olè ojú òkun tí wọ́n jẹ́ ará England ṣe hára gàgà láti gba ọkọ̀ òkun ilẹ̀ Sípéènì tí ó kó ìṣúra iyebíye ilẹ̀ Peru! Bí Pizarro ti di ẹrù ìṣúra jabíjabí, ó dorí kọ etíkun, níbi tí ó tẹ ìlú ńlá Lima dó sí ní 1535 gẹ́gẹ́ bí ibùjókòó ìjọba rẹ̀.

Manco Inca Yupanqui, tí ó ti wá rí ìlàlóye kíkúnrẹ́rẹ́ nípa ìwọra àti àdàkàdekè àwọn ajagunṣẹ́gun náà, kẹ̀yìn sí wọn. Àwọn mìíràn pẹ̀lú ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ará Sípéènì, ṣùgbọ́n níkẹyìn àwọn Àmẹ́ríńdíà ní láti sá lọ sí àwọn ibi àdádó láti lè dènà bí wọ́n bá ti lè ṣe tó. Ìlú ńlá mímọ́ Machu Picchu tí ó fara sin sáàárín àwọn òkè ńlá ì bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi ìsádi aláàbò náà.

Olú Ọba Inca Tí Ó Jẹ Kẹ́yìn

Nínú ìgbésẹ̀ àṣekágbá, Tupac Amarú, ọmọkùnrin Manco Inca Yupanqui, di olú ọba Inca ní (1572). Àwọn olórí Sípéènì ń ṣàkóso Peru lákòókò yí. Góńgó tí alákòóso náà, Toledo, ń lépa jẹ́ láti rẹ́yìn àwọn ará Inca. Ó kó àwọn ọmọ ogun púpọ̀ rẹpẹtẹ wọ àgbègbè Vilcabamba. Wọ́n ká Tupac Amarú mọ́ inú igbó. Wọ́n mú òun àti ìyàwó rẹ̀ tí ó lóyún lọ pa ní Cuzco. Àmẹ́ríńdíà ẹ̀yà Cañari kan gbé idà ìbẹ́nilórí sọ́rùn Tupac Amarú. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Àmẹ́ríńdíà tí wọ́n kóra jọ sí gbàgede ìlú náà pohùnréré ẹkún bí wọ́n ti bẹ́ olú ọba Inca wọn lórí pékú. Wọ́n dá àwọn olórí ogun rẹ̀ lóró kú tàbí kí wọ́n yẹgi fún wọn. Wọ́n fi ìwà òǹrorò mú ìṣàkóso àwọn Inca wá sópin.

Àwọn olórí tí a yàn sípò náà, pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé àti àwọn àlùfáà Kátólíìkì, bẹ̀rẹ̀ sí í tan ipa ìdarí rere àti búburú wọn kálẹ̀ díẹ̀díẹ̀ sórí àwọn Àmẹ́ríńdíà tí a ti kà sí ẹrú lásánlàsàn láti ìgbà pípẹ́. A fipá mú ọ̀pọ̀ lára wọn láti ṣiṣẹ́ ní àwọn ibi ìwakùsà wúrà tàbí fàdákà, tí ọ̀kan lára wọn jẹ́ òkè ńlá tí ògidì fàdákà pọ̀ sí, ní Potosí, Bolivia. Láti la àwọn ipò àìláàánú náà já, àwọn Àmẹ́ríńdíà tí wọ́n ń fìyà jẹ náà fàbọ̀ sórí lílo ewé coca nítorí ipa ìdarí oògùn líle tí ó ní. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún ni Peru àti Bolivia tó gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ Sípéènì.

Àwọn Àtọmọdọ́mọ Inca Ti Òde Òní

Ipò wo ni àwọn àtọmọdọ́mọ Inca wà ní sànmánì òde òní? Olú ìlú Peru, Lima, bíi ti àwọn ìlú ńlá òde òní mìíràn, kún fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ ìlú. Ṣùgbọ́n ní àwọn àgbègbè ìpínlẹ̀ rẹ̀, ńṣe ló jọ pé gbogbo nǹkan wà bí ó ti wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Àwọn àlùfáà Kátólíìkì ni wọ́n ṣì ń darí ọ̀pọ̀ àwọn abúlé àdádó. Lójú àwọn àgbẹ̀ Àmẹ́ríńdíà, ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tí ó wà ní gbàgede abúlé náà jẹ́ ibi tí ń pe èrò wá. Ọ̀pọ̀ ère àwọn ẹni mímọ́ tí wọ́n tún ṣe dáradára, àwọn iná aláwọ̀ mèremère, pẹpẹ oníwúrà, àwọn àbẹ́là tí wọ́n tàn, àwọn ààtò ìsìn àràmàǹdà tí àlùfáà ń fi orin ṣe, àti pàápàá àwọn ijó àti ọdún ìbílẹ̀—gbogbo ìwọ̀nyí ń tẹ́ àìní rẹ̀ fún ìnàjú lọ́rùn. Ṣùgbọ́n irú àwọn ìnàjú jíjojúnígbèsè bẹ́ẹ̀ kò tí ì mú àwọn ìgbàgbọ́ àtayébáyé kúrò. Lílò tí wọ́n sì ń lo ewé coca, tí wọ́n ronú pé ó ní agbára àràmàǹdà, ṣì ń ní ipa lórí ìgbésí ayé púpọ̀ wọn.

Pẹ̀lú ẹ̀mí aláìṣeéṣẹ́gun tí wọ́n ní, àwọn àtọmọdọ́mọ àwọn ará Inca wọ̀nyí—tí púpọ̀ lára wọn jẹ́ ọmọ ẹ̀yà méjì nísinsìnyí—ti gbìyànjú pa àwọn ijó àti irú orin huaino wọn fífani-lọ́kànmọ́ra mọ́. Kódà bí wọn kò bá yára mọ́ àwọn àjèjì níbẹ̀rẹ̀, wọ́n máa ń fi ìwà aájò àlejò tí a bí mọ́ wọn hàn. Lójú àwọn tí wọ́n mọ àwọn àtọmọdọ́mọ Ilẹ̀ Ọba Inca wọ̀nyí—àwọn tí wọ́n ń ṣàkíyèsí ìlàkàkà wọn ojoojúmọ́ láti máa wà nìṣó, tí wọ́n lè bá wọn lò, tí wọ́n sì lè fún wọ́n ni àfiyèsí, kí wọ́n sì ṣaájò wọn—ìtàn wọn ń bani nínú jẹ́ gbáà!

Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Mú Ìyípadà Wá

Nínú ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò kan tí Jí! ṣe pẹ̀lú Valentin Arizaca, àtọmọdọ́mọ àwọn Àmẹ́ríńdíà tí ń sọ èdè Aymara láti abúlé Socca ní orí Adágún Titicaca, ó sọ pé: “Kí n tó di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, orúkọ lásán ni mo fi ń jẹ́ Kátólíìkì. Èmi àti àwọn díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi ń ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ìṣe ìbọ̀rìṣà. Mo ń jẹ ewé coca pẹ̀lú, àmọ́ mo ti fi gbogbo ìyẹn sílẹ̀ nísinsìnyí.”

Bí Petronila Mamani, ẹni ọdún 89, ti rántí dáradára nípa ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tí ó mú kí ó máa wà nínú ìbẹ̀rù ṣíṣàìtẹ́ apus lọ́rùn léraléra, ó wí pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń mú ẹbọ lọ láti tu àwọn òrìṣà òkè lójú àti láti rí i dájú pé ẹ̀mí mi dè. N kò fẹ́ láti mú wọn bínú lọ́nàkọnà kí n má baà fi ẹ̀mí wewu àwọn àjálù tí ó lè tìdí rẹ̀ wá. Nísinsìnyí tí mo ti darúgbó, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ láti fojú ọ̀tọ̀ wo àwọn nǹkan. Ọpẹ́lọpẹ́ Bíbélì àti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo ti bọ́ lọ́wọ́ irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ ọ̀pọ̀ àwọn Àmẹ́ríńdíà tí ń sọ èdè Quechua àti Aymara láti mọ ìwé kà. Àwọn pẹ̀lú wá ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́nà yí, a ti ń dá ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Àmẹ́ríńdíà ará Inca àti ti Sípéènì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mú ìgbésí ayé wọn gbé pẹ́ẹ́lí. Wọ́n tún ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì nípa ayé tuntun aláìṣègbè, alálàáfíà, àti olódodo, tí yóò fìdí múlẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ayé láìpẹ́.—Pétérù Kejì 3:13; Ìṣípayá 21:1-4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ náà, “Inca” lè tọ́ka sí alákòóso gíga jù lọ ti Ilẹ̀ Ọba Inca, ó sì tún lè tọ́ka sí àwọn ọmọ ìbílẹ̀.

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ilẹ̀ Ọba Oníwúrà ti Àwọn Ará Inca

GÚÚSÙ AMẸ́RÍKÀ

Cuzco

Potosí

ILẸ̀ ỌBA INCA

ÒKUN CARIBBEAN

ÒKUN PÀSÍFÍÌKÌ

COLOMBIA

ECUADOR

ÒKÈ ŃLÁ ANDES

PERU

Cajamarca

Lima

Pachácamac

Vilcabamba

Machu Picchu

Cuzco

Adágún Titicaca

BOLIVIA

CHILE

AJẸNTÍNÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Lókè: Tẹ́ńpìlì àtètèkọ́ṣe ti oòrùn jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì yí ní Cuzco

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Lápá òsì: Ère ìṣàpẹẹrẹ nǹkan ọmọkùnrin nínú tẹ́ńpìlì kan ní Chucuito kí ilẹ̀ Inca tó wà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Lápá ọ̀tún: Ẹ̀jẹ̀ àwọn ohun ìrúbọ àwọn ará Inca ṣàn lára àwọn òkúta gbígbẹ́ wọ̀nyí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Lápá ọ̀tún: Ilẹ̀ títẹ́jú tí a bomi rin ní Machu Picchu, nítòsí Cuzco

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Nísàlẹ̀: Ohun tí a rí lódì kejì ẹnu ọ̀nà àtayébáyé kan ní Machu Picchu

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Apá ọ̀tún nísàlẹ̀: Àwọn òkúta onítọ́ọ̀nù 100 ti tẹ́ńpìlì ológiri ńláńlá ìgbàanì ní Sacsahuaman

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́