ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/8 ojú ìwé 22-24
  • Músítádì—Kókó Ọ̀rọ̀ Afàfẹ́mọ́ra Gbígbóná Janjan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Músítádì—Kókó Ọ̀rọ̀ Afàfẹ́mọ́ra Gbígbóná Janjan
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Kín-ínkín Alágbára Ńlá
  • Ìṣèmújáde Músítádì Ilẹ̀ Faransé
  • Ìtàn Tí Ó Gùn
  • Àwọn Ọ̀nà Ìṣèmújáde Ìgbàlódé
  • Irúgbìn Kóńkó Tí A Ń Lò fún Ohun Púpọ̀
  • ‘Ẹ Fetí sí Mi, Kí Ẹ sì Lóye Ìtúmọ̀ Rẹ̀’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìwọ Kò Mọ Ibi Tí Yóò Ti Ṣàṣeyọrí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Awọn Àkàwé Ijọba
    “Kí Ijọba Rẹ Dé”
  • Kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Pẹlu Awọn Àkàwé
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 8/8 ojú ìwé 22-24

Músítádì—Kókó Ọ̀rọ̀ Afàfẹ́mọ́ra Gbígbóná Janjan

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ

“LÁÌFÍ gbáà ni ó jẹ́ láti sọ àwọn ọmọge méjì láti ilẹ̀ England, àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ilẹ̀ ọba gíga jù lọ lágbàáyé, di ẹni tí ń jẹ ẹran dídín wọn láìsí músítádì!” Àwọn ọmọ ilẹ̀ Denmark, tí wọ́n wà lára àwọn òléwájú nínu jíjẹ músítádì lágbàáyé, yóò kẹ́dùn pẹ̀lú ìjákulẹ̀ tí àwọn obìnrin olú ẹ̀dá ìtàn inú ìwé ìtàn àròsọ ède Faransé tí a fa ọ̀rọ rẹ̀ yọ lókè yìí ní.a

Àwọn ará Gíríìsì ìgbàanì pe músítádì ní siʹna·pi, “ohun tí ń da ojú láàmú.” Bóyá ohun tí wọ́n ní lọ́kàn ni ọ̀jẹun kan tí ń ṣomi lójú nígbà tí ó jẹun jù. Ọ̀rọ̀ náà “músítádì” wá láti inú ọ̀kan lára àwọn èròjà ìgbàanì tí ohun afóúnjẹládùn máa ń ní, mustum (omi àjàrà tí kò kan). Ọ̀rọ̀ náà lè tọ́ka sí yálà irúgbìn náà, hóró rẹ̀, tàbí afóúnjẹládùn tí ó lè jẹ́ kí ojú rẹ móoru gidigidi.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé hóró náà kò lóòórùn burúkú bí ó bá gbẹ, ó máa ń gbé tajútajú kan tí ń jẹ́ allyl isothiocyanate jáde bí a bá lọ̀ ọ́ pọ̀ mọ́ omi. Òróró tajútajú yìí, tí ó mú kí músítádì ta lẹ́nu, ń ta àwọn awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ sẹ́ẹ̀lì ikùn, tí èyí sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí omijé yọ lójú ẹni tí ń jẹ músítádì, àti ẹni tí ń ṣe é. Láìsí àníàní, èyí ṣàlàyé ìdí tí yperite, ohun ìjà oníkẹ́míkà tí wọ́n lò nínú Ogun Àgbáyé Kìíní, fi di ohun tí a ń pè ní gáàsi músítádì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní músítádì nínú rárá.

Ohun Kín-ínkín Alágbára Ńlá

A lè tètè ṣi òdòdó aláwọ̀ ìyeyè tí ó ní ìrísí aláìlèṣèpalára tí ó pa atayoyo yìí mọ́ sínú ara rẹ̀ mú fún hóró èso rape, tàbí colza. Músítádì àti hóró èso rape wà lára ìdílé Cruciferae, tí wọ́n sọ pé ó ní tó 4,000 irú ọ̀wọ́, tí nǹkan bí 40 lára wọ́n jẹ́ músítádì. Èyí tí a máa ń lò jù lọ ni músítádì funfun (Brassica hirta), músítádì ti India tàbí aláwọ̀ ilẹ̀ (Brassica juncea), àti músítádì dúdú (Brassica nigra), tí ó máa ń tú oruku olóró, múlọ́múlọ́ tí ó lè fa ìléròrò sára jáde.

Bí ó bá ń dàgbà fúnra rẹ̀, músítádì dúdú máa ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lórí ilẹ̀ olókùúta àti lẹ́bàá ọ̀nà àti ní àwọn etídò ní Áfíríkà, India, àti Europe. Ó tún ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní ibi titutù yọ̀yọ̀ lẹ́bàá àwọn òkè Òkun Gálílì, ní Ísírẹ́lì. Bí a bá ṣọ̀gbin rẹ̀ dáradára, ó máa ń yára gbó, ó sì lè dàgbà débi tí yóò “ga tó àwọn igi eléso wa, ní Ìlà Oòrùn ayé, àti lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ní gúúsù ilẹ̀ Faransé pàápàá.”—Dictionnaire de la Bible ti Vigouroux.

Lọ́nà yíyani lẹ́nu, “hóró músítádì” dúdú fúnra rẹ̀ kéré kọjá ààlà. Nígbà tí Jésù wà láyé, òun ni hóró èso tí ó kéré jù lọ lára àwọn hóró èso tí wọ́n máa ń gbìn ní Ísírẹ́lì. (Máàkù 4:31) Ó ní ìwọ̀n ìdábùú òbírí tí ó jẹ́ nǹkan bíi mìlímítà kan, tí èyí mú kí ó yẹ ní lílò gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n kíkéré jù lọ nínú ìwe Talmud.—Berakhot 31a.

Ìyàtọ̀ pípàfiyèsí tí ó wà láàárín hóró músítádì àti irúgbìn rẹ̀ tí ó ti gbó, tí ó sì tóbi dáadáa pèsè àfikún ìtumọ̀ nípa ẹ̀kọ Kristi lórí ìdàgbàsókè “ìjọba àwọn ọ̀run” tí ó wá di ibùwọ̀ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. (Mátíù 13:31, 32; Lúùkù 13:19) Kristi tún lo àkàwé kan tí ń runi sókè láti tẹnu mọ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́ kéréje kan ṣe lè ṣiṣẹ́ tó, ní wíwí pé: “Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ ìwọ̀n hóró músítádì, . . . kò [ní] sí ohunkóhun tí kì yóò ṣeé ṣe fún yín.”—Mátíù 17:20; Lúùkù 17:6.

Ìṣèmújáde Músítádì Ilẹ̀ Faransé

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tún ń gbin músítádì dúdú ilẹ̀ Faransé tí a yàn láàyò ní Alsace, ìlà oòrùn Faransé, ìlú ńlá Dijon, ní Burgundy, ni a wá mọ̀ sí ilé owó músítádì ilẹ̀ Faransé. Níhìn-ín, wọ́n máa ń gbin músítádì sórí ilẹ̀ tí ìmújáde èédú ń mú lọ́ràá déédéé. Eérú igi sísun tí ó wà nílẹ̀ ń mú kí hóró músítádì ní ìtọ́wò tí ó wọyín lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.

Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, lójú àwọn ìyípadà tí ń bá bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ìbánidíje líle koko jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè, ọ̀gbin músítádì lọ sílẹ̀ jọjọ ní Burgundy, èyí sì ṣínà fún colza. Lónìí, ilẹ̀ Faransé ń kó ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún hóró músítádì tí ó nílò wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè, ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún lára èyí sì ń wá láti Kánádà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ náà músítádi Dijon ń tọ́ka sí ọ̀nà ìṣèmújáde tí kì í sì í ṣe orísun rẹ̀, ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ilé iṣẹ́ èròjà afóúnjẹládùn ní ilẹ̀ Faransé ni wọ́n ṣì gbára lé Dijon síbẹ̀. Láìpẹ́ yìí, a ti sapá láti mú kí ọ̀gbin músítádì kọ́fẹ padà ní Burgundy.

Ìtàn Tí Ó Gùn

Tí músítádì bá wà ní ìyẹ̀fun, bí ata, tàbí bí afóúnjẹládùn, ò máa ń mú wọn yánnu ní ìgbà ìjímìjí. Àwọn ará Róòmù máa ń lò ó láti fún àwọn ọbẹ̀ wọn, bíi garum (ìfun àti orí ẹja mọ́ńkẹ̀rẹ̀ nínú omi oníyọ̀) àti muria (ẹja tuna nínú omi oníyọ̀) ní ìtasánsán. Apicius, ògbógi agbọ́únjẹ lọ́nà kíkàmàmà tí ó jẹ́ ará Róòmù, ṣàgbékalẹ̀ ìlànà ìgbọ́únjẹ tirẹ̀ tí ó ní hóró músítádì, iyọ̀, ọtí kíkan, àti oyin, pẹ̀lú èso álímọ́ńdì àti èso pine tí a sè pọ̀ fún àpèjẹ.

Láti Sànmánì Agbedeméjì wá dé ọ̀rúndún kọkàndínlógún, wọ́n fi músítádì tí a ṣe ní àwọn ilé iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ rọ́pò èyí tí a ṣe nílé. Ní ilẹ̀ Faransé, ilé iṣẹ́ àwọn tí ń ṣe músítádì òun ọtí kíkan gbé àwọn ìlànà ìpọntí jáde, wọ́n mú ìmọ́tótó bíbẹ́tọ̀ọ́mu dájú, wọ́n darí títà rẹ̀, wọ́n sì bu owó ìtanràn fún àwọn tí wọ́n bá rúfin. Wọ́n máa ń fi músítádì tí wọ́n ń tà ní olómi tàbí ìdì olóòórùn dídùn tí a óò yọ́ nínú ọtí kíkan kún ẹja gan-an bí ẹran. Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Jeremiah Colman, fẹ́rẹ̀ẹ́ yí gbogbo Ilẹ̀ Ọba Britain lọ́kàn padà láti máa lo ìyẹ̀fun músítádì tirẹ̀, tí a máa ń pò pọ̀ pẹ̀lú omi, mílíìkì, tàbí bíà nígbà tí a bá ń jẹun.

Bí àkókò ti ń lọ, ìṣèmújáde láti ilé iṣẹ́ ńláńlá rọ́pò ilé iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, tí èyí sì mú kí ìmújáde pọ̀ sí i. Ní 1990, ilẹ̀ Faransé tí ó jẹ́ òléwájú aṣèmújáde ní ilẹ̀ Europe, ṣe nǹkan bíi 70,000 tọ́ọ̀nù músítádì àti 2,000 tọ́ọ̀nù onírúurú àwọn afóúnjẹládùn míràn.

Àwọn Ọ̀nà Ìṣèmújáde Ìgbàlódé

Bí músítádì ṣe rí lẹ́nu sinmi púpọ̀ lórí àwọn ọ̀nà tí a gbà ṣèmújáde rẹ̀ àti àwọn èròjà rẹ̀. Wọ́n máa ń ṣa hóró rẹ̀, wọn ń fọ̀ ọ́, wọn ń sá a gbẹ, wọ́n sì ń lọ̀ ọ́ ní ìwọ̀n tí wọ́n fi ṣe àṣírí gidigidi. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń lọ hóró rẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tóó rẹ ẹ́ sínú omi ápù kíkan, omi ọtí kíkan, tàbí verjuice (omi àjàrà kíkan) fún ohun tí ó tó wákàtí 24. Wọ́n máa ń fi gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ àjàrà dúdú ṣe músítádì aláwọ̀ búlúù rẹ́súrẹ́sú. Gbogbo èròjà náà ni a óò lọ̀—ní fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún músítádì ìbílẹ̀—a óò wá ṣà wọ́n nínú ẹ̀rọ ìṣaǹkan tí ń yí bírí láti yọ àwọn èèpo kúrò àti láti mú kí agbára òróró tajútajú náà pọ̀ sí i. Yálà ìtasánsán rẹ̀ yóò lágbára tàbí kò níí lágbára sinmi lórí bí wọ́n ṣe sẹ́ àpòpọ̀ náà kúnnákúnná tó.

Ìpòpọ̀ yóò mú gbogbo ìsọpùtù afẹ́fẹ́ èyíkéyìí tí ó lè mú kí atẹ́gùn wọnú àpòpọ̀ náà, tí yóò wà nínú ọpọ́n ńlá kan fún wákàtí 48 kí ó tóó ṣeé mu. Ó máa ń túbọ̀ ta sánsán sí i fúnra rẹ̀ bí ó ti ń pàdánù ìkorò rẹ̀. Fífi àwọ̀, ìyẹ̀fun, tàbí àwọn amúnǹkandùn kún un yóò mú kí adùn rẹ̀ dín kù tàbí kí ó túbọ̀ wọyín sí i. Lẹ́yìn náà, a óò fi onírúurú òórùn atasánsán kún un: ti ìbílẹ̀ (Roquefort, tarragon), àjèjì (ọ̀gẹ̀dẹ̀, curry), tàbí àtọwọ́dá (ọtí cognac, ṣanpéènì). Ìtasánsán tí músítádì Meaux ní, ó kéré tán, àpapọ̀ òórùn dídùn 11.

Rírọ ọ́ ṣe pàtàkì láti ṣàṣeparí ìgbésẹ̀ náà, nítorí pé atẹ́gùn máa ń yí àpòpọ̀ náà dà di aláwọ̀ ilẹ̀, ooru sì máa ń jẹ́ kí òróró tajútajú rẹ̀ gbẹ. Nítorí náà, ó sábà máa ń dára jù lọ láti gbé músítádì sí ibi títutù, tí ó sì ṣókùnkùn. Ìgò oníke tàbí onígíláàsì tí a rọ músítádì sí, tí a sábà máa ń fi àwọn lébẹ́ẹ̀lì tí a ṣe ọnà àkànṣe sí lára ṣe lọ́sọ̀ọ́, ti rọ́pò ohun èèlò òkúta, ohun èèlò amọ̀, tàbí àwọn ìkòkò amọ̀ àtijọ́, tí a lè rí kìkì níbi tí wọ́n ti ń ṣe orí pẹpẹ àfihàn àwọn ibi àkójọ ohun ìṣẹ̀m̀báyé àti ibi àkójọ àdáni lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn oníṣẹ́ ọnà fiyè gidigidi sí ìrísí ara àwọn ìkòko wọn, ní gbígbìyànjú láti ṣe irú àwọn ọnà gidi náà tí ó “jẹ́ kí a lè mọ ìyàtọ̀ láàárín wọn tí a bá wò wọ́n fìrí.”

Irúgbìn Kóńkó Tí A Ń Lò fún Ohun Púpọ̀

Àwọn ìkòkò ńláńlá tí ń ṣe àwọn ilé ìpoògùn lọ́ṣọ̀ọ́ nígbà kan rí máa ń ní ìyẹ̀fun músítádì nínú fún ète ìṣègùn. Nítorí àwọn èròjà rẹ̀ tí ń gbógun ti èkuru ara, kò sí ọkọ̀ òkun ilẹ̀ Netherlands tí yóò gbéra àjò láìní díẹ̀ lẹ́rù. A ń lo músítádì nínú ọṣẹ ìwẹ̀ tàbí gẹ́gẹ́ bí oògun kòkòrò.

Àwọn ewé irúgbìn músítádì funfun ni a máa ń fi ṣe sàláàdì tí a ń jẹ, a sì tún ṣì ń fi ṣe oúnjẹ ẹran. Òróró jíjẹ tí a yọ láti ara àwọn hóró náà kì í tètè yí dà di olóòórùn burúkú. Ní Éṣíà, àwọn ilé iṣẹ́ ń fi epo rẹ̀ tanná, ó sì ń mú kí ọ̀pọ̀ oúnjẹ ta sánsán.

A ti mẹ́nu kan òdòdó ìbílẹ̀ aláìjámọ́ǹkan yìí nínú onírúurú òwe. Ní Nepal àti India, láti “rí òdòdo músítádì” túmọ̀ sí kí ojú ẹni máa ṣe bàìbàì lẹ́yìn ìmúgbọ̀nrìrì kan. Ní ilẹ̀ Faransé, láti “fa músítádì símú rẹ,” túmọ̀ sí kí inú máa bíni. Ọ̀nà yòówù kí a gbà lo músítádì—òdòdó, afóúnjẹládùn, hóró, òróró, tàbí ìyẹ̀fun—músítádì lè mú kí ìgbésí ayé rẹ nítumọ̀ sí i.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Le Roi des montagnes (Ọba Àwọn Òkè Ńlá), láti ọwọ Edmond About.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Músítádì ń wá ní onírúurú ọ̀nà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́