‘Ẹ Fetí sí Mi, Kí Ẹ sì Lóye Ìtúmọ̀ Rẹ̀’
“Ẹ fetí sí mi, gbogbo yín, kí ẹ sì lóye ìtúmọ̀ rẹ̀.” —MÁÀKÙ 7:14.
1, 2. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ kò fi lóye ọ̀rọ̀ Jésù?
ẸNÌ kan lè gbọ́ ohùn ẹni tó ń bá a sọ̀rọ̀. Ó tiẹ̀ lè dá ohùn ẹni náà mọ̀. Àmọ́, ǹjẹ́ ó máa ṣe é láǹfààní kankan tí kò bá lóye ohun tí ẹni náà ń sọ? (1 Kọ́r. 14:9) Lọ́nà kan náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù. Kódà, èdè tó yé wọn ló fi bá wọn sọ̀rọ̀. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo wọn ló lóye ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fún àwùjọ èèyàn tó ń bá sọ̀rọ̀ pé: “Ẹ fetí sí mi, gbogbo yín, kí ẹ sì lóye ìtúmọ̀ rẹ̀.”—Máàkù 7:14.
2 Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ kò fi lóye ohun tí Jésù sọ? Ohun tó fà á ni pé, àwọn kan ti gbin ohun tí kò tọ́ sọ́kàn, wọ́n sì ní èrò òdì. Jésù sọ nípa irú àwọn yìí pé: “Ẹ fi ọgbọ́n féfé pa àṣẹ Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan láti di òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín mú ṣinṣin.” (Máàkù 7:9) Àwọn èèyàn yìí ò tiẹ̀ gbìyànjú rárá láti mọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ. Wọn ò fẹ́ yí ìwà àti èrò wọn pa dà. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n kàn ń fi etí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ lásán, àmọ́ wọ́n ti sé ọkàn wọn pa gbọn-in gbọn-in! (Ka Mátíù 13:13-15.) Báwo ni a ṣe lè ṣí ọkàn wa sílẹ̀ ká lè jàǹfààní nínú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù?
BÁ A ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ NÍNÚ ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ JÉSÙ
3. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ Jésù fi yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
3 Ó ṣe pàtàkì pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Jésù sọ fún wọn pé: “Aláyọ̀ ni ojú yín nítorí pé wọ́n rí, àti etí yín nítorí pé wọ́n gbọ́.” (Mát. 13:16) Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ Jésù fi yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àmọ́ tí kò yé àwọn míì? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé, wọ́n ṣe tán láti béèrè ìbéèrè, wọ́n sì sapá kí wọ́n lè lóye ohun tí Jésù ń sọ. (Mát. 13:36; Máàkù 7:17) Ìkejì, wọ́n ṣe tán láti mú kí ohun tí wọ́n ti gbà gbọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ sí i lọ́kàn wọn. (Ka Mátíù 13:11, 12.) Ìkẹta, wọ́n ṣe tán láti fi àwọn ohun tí wọ́n ti gbọ́ tí wọ́n sì ti lóye sílò nígbèésí ayé wọn, wọ́n sì tún sapá láti fi kọ́ àwọn ẹlòmíì.—Mát. 13:51, 52.
4. Àwọn nǹkan mẹ́ta wo ló ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ lóye àwọn àpèjúwe Jésù?
4 Tí a bá fẹ́ lóye àwọn àpèjúwe Jésù, a ní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́. Èyí sì gba pé ká ṣe ohun mẹ́ta kan. Àkọ́kọ́, ó yẹ ká fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ká sì ṣàṣàrò lórí ohun tí Jésù sọ, ká ṣe ìwádìí ká sì béèrè àwọn ìbéèrè tó bá yẹ. Èyí ló máa jẹ́ ká ní ìmọ̀. (Òwe 2:4, 5) Ìkejì ni pé, ó yẹ ká wo bí ìmọ̀ tí a ní yìí ṣe bá àwọn ohun tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ mu, ká sì ronú lórí àǹfààní tí ohun tá a mọ̀ yìí máa ṣe wá. Èyí ló máa jẹ́ ká ní òye. (Òwe 2:2, 3) Ní Paríparí rẹ̀, ká fi àwọn ohun tí a ti kọ́ sílò nígbèésí ayé wa. Èyí ló máa fi hàn pé a ní ọgbọ́n.—Òwe 2:6, 7.
5. Ṣàpèjúwe ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìmọ̀, òye àti ọgbọ́n.
5 Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìmọ̀, òye àti ọgbọ́n? Jẹ́ ká ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí: Ká sọ pé o fẹ́ sọdá títì, o sì rí i tí mọ́tò kan ń sáré bọ̀ lọ́ọ̀ọ́kán. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, o mọ̀ pé mọ́tò ń bọ̀, ìmọ̀ nìyẹn. Lẹ́yìn ìyẹn, o mọ̀ pé tí o bá sọdá mọ́tò yẹn máa gbá ẹ, òye nìyẹn! Lo bá dúró kí mọ́tò náà kọjá, ọgbọ́n nìyẹn! Abájọ tí Bíbélì fi tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ ká “fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́,” torí pé ẹ̀mí wa rọ̀ mọ́ ọn!—Òwe 3:21, 22; 1 Tím. 4:16.
6. Àwọn ìbéèrè mẹ́rin wo ni a máa béèrè bí a ti ń ṣàyẹ̀wò méje nínú àwọn àpèjúwe Jésù? (Wo àpótí tó wà lójú ìwéàpótí.)
6 Nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, a máa ṣàyẹ̀wò méje nínú àwọn àpèjúwe tí Jésù lò. Bí a ó ti máa gbé àwọn àpèjúwe náà yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan, a máa béèrè àwọn ìbéèrè bíi: Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe náà? (Èyí á jẹ́ ká ní ìmọ̀.) Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe náà? (Èyí á jẹ́ ká ní òye.) Báwo la ṣe lè fi àwọn ohun tí a kọ́ sílò nígbèésí ayé wa, ká sì tún fi kọ́ àwọn ẹlòmíì? (Èyí ni ọgbọ́n.) Paríparí rẹ̀ ni pé, kí ni èyí kọ́ wa nípa Jèhófà àti Jésù?
HÓRÓ MÚSÍTÁDÌ
7. Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe nípa hóró músítádì?
7 Ka Mátíù 13:31, 32. Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa hóró músítádì? Hóró músítádì náà ṣàpẹẹrẹ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tí ìhìn tí à ń wàásù ń mú jáde, ìyẹn ni ìjọ Kristẹni. Bí hóró músítádì ṣe jẹ́ “tín-ń-tín jù lọ nínú gbogbo irúgbìn,” bẹ́ẹ̀ náà ni ìjọ Kristẹni kò ju kékeré lọ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, láàárín ọdún mélòó kan, ìjọ Kristẹni ti yára gbèrú. Ó sì ti gbilẹ̀ lọ́nà tó kàmàmà. (Kól. 1:23) Bí ìjọ Kristẹni ti ń yára gbèrú ṣàǹfààní gan-an, torí Jésù sọ fún wa pé, ‘àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run rí ibùwọ̀ láàárín àwọn ẹ̀ka rẹ̀.’ Àwọn ẹyẹ yìí ṣàpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ èèyàn tí wọ́n ń rí oúnjẹ tẹ̀mí, ibòji àti ibùwọ̀ nínú ìjọ Kristẹni.—Fi wé Ìsíkíẹ́lì 17:23.
8. Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe nípa hóró músítádì?
8 Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe yìí? Ó lo bí hóró músítádì ṣe máa ń yára gbèrú láti fi ṣàpèjúwe agbára tí Ìjọba Ọlọ́run ní láti gbòòrò, láti dáàbò boni àti láti borí gbogbo ìdènà. Láti ọdún 1914 ni apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run ti ń gbòòrò sí i lọ́nà tó gọntíọ! (Aísá. 60:22) Àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ ètò yìí ń rí ààbò nípa tẹ̀mí. (Òwe 2:7; Aísá. 32:1, 2) Bákan náà, ó ti hàn gbangba pé kò sí ohunkóhun tó lè dáwọ́ bí ìhìn rere nípa Ìjọba náà ṣe ń gbòòrò síwájú sí i yìí dúró, ó sì ń tẹ̀ síwájú láìfi àtakò èyíkéyìí pè.—Aísá. 54:17.
9. (a) Kí ni a lè rí kọ́ nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa hóró músítádì? (b) Kí ni èyí kọ́ wa nípa Jèhófà àti Jésù?
9 Kí ni a lè rí kọ́ nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa hóró músítádì? Ó lè jẹ́ pé àdúgbò tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí là ń gbé tàbí kí iṣẹ́ ìwàásù wa má fi bẹ́ẹ̀ mú èso jáde. Síbẹ̀, tí a bá ń rántí pé Ìjọba Ọlọ́run lágbára láti borí gbogbo ìdènà, èyí máa mú ká lè fara dà á. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Arákùnrin Edwin Skinner dé sí orílẹ̀-èdè Íńdíà ní ọdún 1926, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn kò tó nǹkan. Nígbà tó sì kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀, kò fi bẹ́ẹ̀ méso jáde dáadáa. Àmọ́, ó ń bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó, ó sì rí bí ìhìn Ìjọba náà ṣe ń borí gbogbo ìdènà. Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Íńdíà ti ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógójì [37,000] lọ. Iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2013 sì ju ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́fà [108,000] lọ. Tún wo àpẹẹrẹ míì tó fi hàn pé ìhìn rere Ìjọba náà ń gbòòrò síwájú sí i. Ọdún 1926 tí Arákùnrin Skinner dé orílẹ̀-èdè Íńdíà ni iṣẹ́ ìwàásù ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Sáńbíà. Ní báyìí iye àwọn akéde tó ń wàásù níbẹ̀ ju ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ààbọ̀ [170,000] lọ. Iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2013 sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [763,915]. Èyí túmọ̀ sí pé nínú èèyàn méjìdínlógún ní Sáńbíà ẹnì kan nínú wọn pésẹ̀ síbẹ̀. Ìbísí ńlá gbáà léyìí jẹ́!
ÌWÚKÀRÀ
10. Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ìwúkàrà?
10 Ka Mátíù 13:33. Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ìwúkàrà? Àpèjúwe nípa ìwúkàrà yìí ń tọ́ka sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti bí ìhìn náà ṣe ń yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà. “Gbogbo ìṣùpọ̀” ìyẹ̀fun náà ṣàpẹẹrẹ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè. Bí ìwúkàrà ṣe sọ ìyẹ̀fun náà di wíwú ṣàpẹẹrẹ bí ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run ṣe tàn kálẹ̀ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù náà. Èyí yàtọ̀ sí hóró músítádì, èèyàn lè tètè rí bí hóró náà ṣe ń gbèrú, àmọ́ èèyàn lè máà kọ́kọ́ kíyè sí bí ìwúkàrà ṣe ń tàn káàkiri. Àkókò díẹ̀ á kọjá kó tó ṣe kedere pé ó ti ń gbèrú.
11. Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe nípa ìwúkàrà?
11 Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe yìí? Ó lò ó láti fi jẹ́ kó ṣe kedere pé ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lágbára láti tàn kálẹ̀ dé ibi gbogbo kó sì tún mú kí ìyípadà wà. Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti tàn dé “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Àmọ́, àwọn àyípadà yìí kì í sábà tètè hàn sójútáyé, èèyàn tiẹ̀ lè máà kọ́kọ́ kíyè sáwọn àyípadà kan tó ń wáyé. Ṣùgbọ́n ní ti gidi àyípadà ń wáyé, èyí kì í ṣe bí iye àwọn tó ń gba ìhìn Ìjọba náà ṣe ń pọ̀ sí i, àmọ́ bí ìhìn rere tó ń tàn kálẹ̀ ṣe ń yí ìwà àwọn èèyàn pa dà sí rere.—Róòmù 12:2; Éfé. 4:22, 23.
12, 13. Sọ àpẹẹrẹ bí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń gbèrú gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣàlàyé nínú àpèjúwe nípa ìwúkàrà.
12 Lọ́pọ̀ ìgbà, táwọn èèyàn bá kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere, ó di ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn kí ipa tí ìhìn rere náà ní lórí wọn tó ṣe kedere. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1982, tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Franz àti Margit, tí wọ́n ń sìn tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Brazil, lọ wàásù ní ìlú kékeré kan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀, lára wọn ni obìnrin kan pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rin. Nígbà yẹn, èyí tó dàgbà jù nínú àwọn ọmọkùnrin tí obìnrin náà bí jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá. Ọmọ náà máa ń tijú gan-an, ó sì máa ń wá bó ṣe máa sá pa mọ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ tó bẹ̀rẹ̀. Nígbà tó yá, tọkọtaya náà lọ sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì mìíràn, torí náà wọn ò lè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà mọ́. Àmọ́, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lẹ́yìn náà, tọkọtaya yìí lọ sí ìlú yẹn. Kí ni wọ́n rí? Ìjọ ti wà ní ìlú yẹn, kódà àwọn akéde mọ́kàndínláàádọ́rin [69] ló wà nínú ìjọ náà, mẹ́tàlá nínú wọn ni aṣáájú-ọ̀nà déédéé, Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun ni wọ́n sì ti ń ṣèpàdé. Ọmọkùnrin tó máa ń tijú nígbà yẹn ńkọ́? Òun ni olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà nínú ìjọ yẹn báyìí! Bíi ti ìwúkàrà tí Jésù sọ nínú àpèjúwe rẹ̀, ìhìn rere Ìjọba náà ti gbèrú, ó sì ti yí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn pa dà. Inú tọkọtaya náà dùn gan-an!
13 Kódà, láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, agbára tí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ń yí àwọn èèyàn pa dà. Ìyàlẹ́nu ló máa ń jẹ́ fún wa nígbà tí a bá gbọ́ nípa bí ìhìn rere náà ti tàn kálẹ̀ tó ní irú àwọn orílẹ̀-èdè yìí. Bí àpẹẹrẹ, ọdún 1910 ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé orílẹ̀-èdè Cuba. Arákùnrin Russell sì ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ lọ́dún 1913. Àmọ́, iṣẹ́ náà ò fi bẹ́ẹ̀ gbèrú níbẹ̀rẹ̀. Báwo ni nǹkan ṣe wá rí lórílẹ̀-èdè Cuba báyìí? Nǹkan ti yàtọ̀ gan-an, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà níbẹ̀ ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún [96,000] lọ, àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2013 tó ọ̀kẹ́ mọ́kànlá ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án àti ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [229,726]. Èyí sì túmọ̀ sí pé ẹnì kan nínú èèyàn méjìdínláàádọ́ta [48] ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lórílẹ̀-èdè náà. Kódà, láwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti dé àwọn àgbègbè tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rò pé iṣẹ́ ìwàásù kò ní fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti ṣe níbẹ̀.a—Oníw. 8:7; 11:5.
14, 15. (a) Báwo ni ẹ̀kọ́ tí a kọ́ nínú àpèjúwe nípa ìwúkàrà ṣe lè ṣe wá láǹfààní lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? (b) Kí ni èyí kọ́ wa nípa Jèhófà àti Jésù?
14 Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wa nínú àpèjúwe nípa ìwúkàrà? Tá a bá ṣàṣàrò lórí ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù sọ yìí, a ò ní máa ṣàníyàn nípa bí ìhìn Ìjọba náà ṣe máa tàn dé ọ̀dọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí kò tíì gbọ́ ìhìn náà. Jèhófà ló ń darí ohun gbogbo. Àmọ́, kí ni iṣẹ́ tiwa? Bíbélì sọ pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere, yálà níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, tàbí kẹ̀, bóyá àwọn méjèèjì ni yóò dára bákan náà.” (Oníw. 11:6) Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún yẹ ká máa gbàdúrà pé kí iṣẹ́ ìwàásù náà máa gbèrú sí i pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa.—Éfé. 6:18-20.
15 Bákan náà, a kò gbọ́dọ̀ rẹ̀wẹ̀sì tí iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe kò bá tètè mú èso jáde. A kò gbọ́dọ̀ tẹ́ńbẹ́lú “ọjọ́ àwọn ohun kékeré.” (Sek. 4:10) Ó tiẹ̀ lè yà wá lẹ́nu pé iṣẹ́ ìwàásù náà lè wá méso jáde wọ̀ǹtì-wọnti ju bí a ṣe rò lọ!—Sm. 40:5; Sek. 4:7.
OLÓWÒ ARÌNRÌN-ÀJÒ ÀTI ÌṢÚRA TÍ A FI PA MỌ́
16. Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa olówò arìnrìn-àjò àti ìṣúra tí a fi pa mọ́?
16 Ka Mátíù 13:44-46. Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa olówò arìnrìn-àjò àti ìṣúra tí a fi pa mọ́? Nígbà ayé Jésù, àwọn olówò kan máa ń rìnrìn àjò dé ìyànníyàn Òkun Íńdíà kí wọ́n lè ra péálì tó níye lórí gan-an. Olówò arìnrìn-àjò náà ṣàpẹẹrẹ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tí wọ́n sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. “Péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga” dúró fún òtítọ́ ṣíṣeyebíye nípa Ìjọba Ọlọ́run. Torí pé olówò náà mọ bí péálì náà ṣe níye lórí tó, ó múra tán láti ta gbogbo ohun tí ó ní “kánmọ́kánmọ́” kí ó lè rà á. Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ nínú pápá tó sì rí ìṣúra “tí a fi pa mọ́.” Ọ̀ràn ti ọkùnrin yìí yàtọ̀ sí ti olówò náà torí òun ò wá ìṣúra kiri. Àmọ́ bíi ti olówò náà, ọkùnrin yìí ṣe tán láti ta gbogbo ohun tí ó ní kí ó lè ra ìṣúra náà.
17. Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe nípa olówò arìnrìn-àjò àti ìṣúra tí a fi pa mọ́?
17 Kí nìdí tí Jésù fi lo àwọn àpèjúwe méjèèjì yẹn? Jésù ń fìyẹn sọ fún wa pé ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lèèyàn máa ń gbà rí òtítọ́. Àwọn kan ń wá òtítọ́ kiri, wọ́n sì ti sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè rí i. Ní ti àwọn mí ì, wọn ò wá òtítọ́ kiri, àmọ́ wọ́n rí i, bóyá nígbà tí wọ́n wàásù fún wọn. Èyí ó wù kó jẹ́, àwọn méjèèjì mọ bí ohun tí wọ́n rí ṣe níye lórí tó, wọ́n sì ṣe tán láti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí ìṣúra tí ó níye lórí yìí lè di tiwọn.
18. (a) Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní nínú àwọn àpèjúwe méjèèjì yìí? (b) Kí ni èyí kọ́ wa nípa Jèhófà àti Jésù?
18 Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní nínú àwọn àpèjúwe méjèèjì yìí? (Mát. 6:19-21) Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ èmi náà lè ṣe bíi tàwọn ọkùnrin yìí? Ǹjẹ́ èmi náà ka òtítọ́ sí ohun iyebíye? Ǹjẹ́ mo ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan kan torí kí n lè di òtítọ́ yìí mú ṣinṣin, àbí mò ń jẹ́ kí àwọn nǹkan míì, bí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ pín ọkàn mi níyà kúrò nínú òtítọ́ yìí?’ (Mát. 6:22-24, 33; Lúùkù 5:27, 28; Fílí. 3:8) Bí ìdùnnú tá a ní torí pé a rí òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run bá ṣe jinlẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni ìpinnu wa láti fi í sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa ṣe máa lágbára tó.
19. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Ǹjẹ́ ká máa fi hàn pé a ti fetí sílẹ̀, a sì lóye ìtumọ̀ àwọn àpèjúwe Ìjọba Ọlọ́run. Má gbàgbé pé kì í ṣe pé ká kàn lóye àwọn àpèjúwe yìí nìkan, àmọ́ ká máa fi àwọn ẹ̀kọ́ tí a kọ́ nínú wọn sílò. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa ṣàyẹ̀wò àwọn àpèjúwe mẹ́ta mìíràn àti àwọn ẹ̀kọ́ tí a lè rí kọ́ nínú wọn.
a O lè rí irú ìrírí yìí kà nípa àwọn orílẹ̀-èdè míì irú bí Argentina, nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn (2001 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 186); Ìlà Oòrùn Jámánì nínú (1999 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 83); Papua New Guinea nínú (2005 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 63); àti Erékùṣù Robinson Crusoe nínú (Ilé Ìṣọ́ June 15, ọdún 2000, ojú ìwé 9).