Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Ní Ẹ̀mí Ìmúratán
ẸLẸ́DÀÁ wa ti fi ẹ̀bùn iyebíye kan dá àwa èèyàn lọ́lá, ìyẹn ni bó ṣe dá wa lọ́nà tá a fi lè yan ohun tó wù wá. Bákan náà, ó máa ń bù kún àwọn tó bá lo òmìnira yìí láti fi mú kí ìjọsìn tòótọ́ gbòòrò, tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ tí wọ́n sì kọ́wọ́ ti ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. Jèhófà ò fẹ́ ká máa ṣègbọràn sí òun torí pé ó di dandan fún wa tàbí torí ìbẹ̀rù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń mọyì rẹ̀ gan-an tó bá jẹ́ pé ojúlówó ìfẹ́ àti ìmọrírì àtọkànwá ló mú ká máa jọ́sìn òun.
Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní aginjù Sínáì, Jèhófà sọ fún wọn pé kí wọ́n kọ́ ibi ìjọsìn. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ gba ọrẹ fún Jèhófà. Kí gbogbo ọlọ́kàn ìmúratán mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Jèhófà.” (Ẹ́kís. 35:5) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè mú ohunkóhun tí wọ́n bá ní wá. Ohun yòówù tí ì báà jẹ́, yálà ó pọ̀ tàbí ó kéré, wọ́n máa lò ó láti fi ṣe ohun tí Jèhófà sọ pé kí wọ́n ṣe. Kí wá làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe?
Bíbélì sọ pé, “olúkúlùkù ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ sún un ṣiṣẹ́” àti “olúkúlùkù ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀ ru ú sókè” ṣe ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe, ‘ọkàn ìmúratán’ ni wọ́n fi ṣe é. Àtọkùnrin àtobìnrin ni wọ́n mú nǹkan wá fún iṣẹ́ Jèhófà, lára ohun tí wọ́n mú wá ni: àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àsomáṣọ, àwọn yẹtí, àwọn òrùka, wúrà, fàdákà, bàbà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì, aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a pa láró pupa, awọ séálì, igi bọn-ọ̀n-ní, àwọn òkúta iyebíye, básámù àti òróró. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, “ohun èlò náà tó fún gbogbo iṣẹ́ tí [wọ́n fẹ́] ṣe, ó tó, ó sì ṣẹ́ kù.”—Ẹ́kís. 35:21-24, 27-29; 36:7.
Kì í ṣe ohun tí wọ́n mú wá ló mú inú Jèhófà dùn, bí kò ṣe ẹ̀mí ìmúratán tí wọ́n fi ń kọ́wọ́ ti ìjọsìn mímọ́. Àwọn èèyàn yìí tún yọ̀ǹda àkókò àti okun wọn. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo àwọn obìnrin . . . fi ọwọ́ wọn rànwú.” Kódà, “gbogbo obìnrin tí ọkàn-àyà wọn sún wọn ṣiṣẹ́ . . . ran irun ewúrẹ́.” Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà fún Bẹ́sálẹ́lì ní ‘ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ gbogbo onírúurú ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà.’ Ọlọ́run fi gbogbo ọgbọ́n ọnà tí Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù nílò kún inú wọn kí wọ́n lè ṣe gbogbo iṣẹ́ tí ó gbé fún wọn.—Ẹ́kís. 35:25, 26, 30-35.
Nígbà tí Jèhófà sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣètìlẹ́yìn, ó dá a lójú pé “gbogbo ọlọ́kàn ìmúratán” máa kọ́wọ́ ti ìjọsìn tòótọ́. Àwọn tó fi ẹ̀mí ìmúratán ṣètìlẹ́yìn ni Jèhófà bù kún jìngbìnnì, ó dáàbò bò wọ́n ó sì mú kí wọ́n láyọ̀. Èyí fi hàn pé Jèhófà máa ń bù kún ẹ̀mí ìmúratán tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá fi hàn, ó sì máa ń fún wọn ní ìmọ̀ àti gbogbo ohun tí wọ́n nílò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. (Sm. 34:9) Bó o ṣe ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa bù kún ẹ̀mí ìmúratán tí o bá fi hàn.