ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Oníwàásù 8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù

      • Lábẹ́ àkóso èèyàn aláìpé (1-17)

        • Pa àṣẹ ọba mọ́ (2-4)

        • Ìjọba èèyàn ń pani lára (9)

        • Nígbà tí a kò bá tètè mú ìdájọ́ ṣẹ (11)

        • Máa jẹ, máa mu, kí o sì máa yọ̀ (15)

Oníwàásù 8:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìtúmọ̀ ọ̀ràn.”

Oníwàásù 8:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 24:21, 22; Ro 13:1; Tit 3:1; 1Pe 2:13
  • +2Sa 5:3

Oníwàásù 8:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 10:4
  • +1Ọb 1:5, 7; Owe 20:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 16

Oníwàásù 8:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 2:24, 25

Oníwàásù 8:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìdájọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 13:5; 1Pe 3:13
  • +1Sa 24:12, 13; 26:8-10; Sm 37:7

Oníwàásù 8:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìdájọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 3:17

Oníwàásù 8:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “èémí; afẹ́fẹ́.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ìwà burúkú kò lè gba ẹni burúkú sílẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 89:48

Oníwàásù 8:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

  • *

    Tàbí “ìṣeléṣe; àdánù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:13, 14; Mik 7:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 31

    Jí!,

    No. 3 2017 ojú ìwé 6

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2002, ojú ìwé 4-5

Oníwàásù 8:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 10:7

Oníwàásù 8:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 10:4, 6
  • +1Sa 2:22, 23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2010, ojú ìwé 4

Oníwàásù 8:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 34:9; 103:13; 112:1; Ais 3:10; 2Pe 2:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/1997, ojú ìwé 17-18

Oníwàásù 8:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 37:10; Ais 57:21
  • +Job 24:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/1997, ojú ìwé 17-18

Oníwàásù 8:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó ń tojú súni.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 7:15
  • +Sm 37:7; 73:12

Oníwàásù 8:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 100:2
  • +Onw 2:24; 3:12, 13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 44

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    10/1/1996, ojú ìwé 14

Oníwàásù 8:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “iṣẹ́.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “àwọn èèyàn ò sùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 1:13; 7:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 16

Oníwàásù 8:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 3:11; Ro 11:33
  • +Job 28:12; Onw 7:24; 11:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 16

Àwọn míì

Oníw. 8:2Owe 24:21, 22; Ro 13:1; Tit 3:1; 1Pe 2:13
Oníw. 8:22Sa 5:3
Oníw. 8:3Onw 10:4
Oníw. 8:31Ọb 1:5, 7; Owe 20:2
Oníw. 8:41Ọb 2:24, 25
Oníw. 8:5Ro 13:5; 1Pe 3:13
Oníw. 8:51Sa 24:12, 13; 26:8-10; Sm 37:7
Oníw. 8:6Onw 3:17
Oníw. 8:8Sm 89:48
Oníw. 8:9Ẹk 1:13, 14; Mik 7:3
Oníw. 8:10Owe 10:7
Oníw. 8:11Sm 10:4, 6
Oníw. 8:111Sa 2:22, 23
Oníw. 8:12Sm 34:9; 103:13; 112:1; Ais 3:10; 2Pe 2:9
Oníw. 8:13Sm 37:10; Ais 57:21
Oníw. 8:13Job 24:24
Oníw. 8:14Onw 7:15
Oníw. 8:14Sm 37:7; 73:12
Oníw. 8:15Sm 100:2
Oníw. 8:15Onw 2:24; 3:12, 13
Oníw. 8:16Onw 1:13; 7:25
Oníw. 8:17Onw 3:11; Ro 11:33
Oníw. 8:17Job 28:12; Onw 7:24; 11:5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Oníwàásù 8:1-17

Oníwàásù

8 Ta ló dà bí ọlọ́gbọ́n? Ta ló mọ ojútùú ìṣòro?* Ọgbọ́n tí èèyàn ní máa ń mú kí ojú rẹ̀ dán, ó sì máa ń mú kí ojú rẹ̀ tó le rọ̀.

2 Mo ní: “Pa àṣẹ ọba mọ́+ nítorí o ti búra níwájú Ọlọ́run.+ 3 Má ṣe yára kúrò níwájú rẹ̀.+ Má ṣe lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó burú;+ torí ohun tó bá wù ú ló lè ṣe, 4 nítorí ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé;+ ta ló sì lè bi í pé, ‘Kí lò ń ṣe?’”

5 Ẹni tó ń pa àṣẹ mọ́ kò ní rí ibi,+ ọkàn ọlọ́gbọ́n á sì mọ àkókò àti ọ̀nà tó yẹ láti gbà ṣe nǹkan.*+ 6 Gbogbo ọ̀ràn ló ní àkókò àti ọ̀nà tó yẹ kéèyàn gbà ṣe é,*+ torí wàhálà aráyé pọ̀ gan-an. 7 Nítorí kò sẹ́ni tó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀, ta ló lè sọ bó ṣe máa ṣẹlẹ̀ fún un?

8 Bí kò ṣe sí èèyàn tó lágbára lórí ẹ̀mí* tàbí tó lè dá ẹ̀mí dúró, bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó lágbára lórí ọjọ́ ikú.+ Bí ẹnikẹ́ni kò ṣe lè dá ara rẹ̀ sílẹ̀ lójú ogun, bẹ́ẹ̀ ni ìwà burúkú kò ní jẹ́ kí àwọn tó ń hù ú yè bọ́.*

9 Gbogbo èyí ni mo ti rí, mo sì fọkàn sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ ọ̀run,* ní àkókò tí èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára* rẹ̀.+ 10 Mo tún rí i tí wọ́n ń sìnkú àwọn ẹni burúkú, àwọn tó máa ń wọlé, tí wọ́n sì ń jáde ní ibi mímọ́, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi gbàgbé wọn ní ìlú tí wọ́n ti hu irú ìwà yìí.+ Asán ni èyí pẹ̀lú.

11 Nítorí pé a kò tètè mú ìdájọ́ ṣẹ lórí ìwà burúkú,+ ọkàn àwọn èèyàn le gbagidi láti ṣe búburú.+ 12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ lè ṣe búburú ní ọgọ́rùn-ún ìgbà, kó sì pẹ́ láyé, síbẹ̀ mo mọ̀ pé ó máa dára fún àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀.+ 13 Àmọ́ kò ní dára fún ẹni burúkú,+ bẹ́ẹ̀ ni kò lè mú kí àwọn ọjọ́ rẹ̀ tó dà bí òjìji gùn,+ nítorí kò bẹ̀rù Ọlọ́run.

14 Ohun kan wà tó jẹ́ asán* tó ń ṣẹlẹ̀ láyé: Àwọn olódodo wà tí aráyé ń hùwà sí bíi pé wọ́n ti ṣe ibi,+ àwọn ẹni burúkú sì wà tí aráyé ń hùwà sí bíi pé wọ́n ti ṣe rere.+ Mo sọ pé asán ni èyí pẹ̀lú.

15 Nítorí náà, ìmọ̀ràn mi ni pé kéèyàn máa yọ̀,+ torí kò sí ohun tó dára fún èèyàn lábẹ́ ọ̀run* ju pé kó jẹ, kó mu, kó sì máa yọ̀; kí inú rẹ̀ máa dùn bó ṣe ń ṣiṣẹ́ àṣekára ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,+ tí Ọlọ́run tòótọ́ fún un lábẹ́ ọ̀run.

16 Mo fi ọkàn mi sí mímọ ọgbọ́n àti sí rírí gbogbo ohun* tó ń lọ nínú ayé,+ kódà mi ò fojú ba oorun* ní ọ̀sán tàbí ní òru. 17 Mo wá wo gbogbo iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, mo sì rí i pé aráyé kò lè lóye ohun tó ń lọ lábẹ́ ọ̀run.*+ Bó ti wù kí aráyé sapá tó, kò lè yé wọn. Kódà, tí wọ́n bá sọ pé ọgbọ́n àwọn gbé e láti mọ̀ ọ́n, wọn ò lè lóye rẹ̀ ní ti gidi.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́