-
1 Sámúẹ́lì 26:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ábíṣáì wá sọ fún Dáfídì pé: “Ọlọ́run ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí.+ Ní báyìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan péré, mi ò ní ṣe é lẹ́ẹ̀mejì.” 9 Àmọ́, Dáfídì sọ fún Ábíṣáì pé: “Má ṣe é ní jàǹbá, ṣé ẹnì kan lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ẹni àmì òróró Jèhófà,+ kó má sì jẹ̀bi?”+ 10 Dáfídì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa mú un balẹ̀,+ ó sì lè kú lọ́jọ́ kan+ tàbí kó lọ sójú ogun kó sì kú síbẹ̀.+
-
-
Sáàmù 37:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Má banú jẹ́ nítorí ẹni
Tó gbèrò ibi, tó sì mú un ṣẹ.+
-