ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sekaráyà 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sekaráyà

      • Ìran 5: Ọ̀pá fìtílà kan àti igi ólífì méjì (1-14)

        • ‘Kì í ṣe nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi’ (6)

        • Má ṣe pẹ̀gàn ọjọ́ tí nǹkan bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ (10)

Sekaráyà 4:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:31; 1Ọb 7:48, 49
  • +Ẹk 25:37

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2022, ojú ìwé 15

Sekaráyà 4:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 4:11, 14; Ifi 11:3, 4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2022, ojú ìwé 15

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 163-164

Sekaráyà 4:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 17:45; Ho 1:7
  • +Ond 6:34; 15:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2022, ojú ìwé 15

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2006, ojú ìwé 22-23

Sekaráyà 4:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 40:4
  • +Ẹsr 3:2; Hag 1:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2006, ojú ìwé 23-24, 25-26

Sekaráyà 4:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 3:8, 10; 5:14, 16
  • +Ẹsr 6:14; Sek 6:12

Sekaráyà 4:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọjọ́ àwọn ohun kékeré?”

  • *

    Ní Héb., “òkúta, tánganran.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 3:12; Hag 2:3
  • +2Kr 16:9; Owe 15:3; Jer 16:17; Ifi 5:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2022, ojú ìwé 16-17

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 85-86

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 164-165

Sekaráyà 4:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 4:2, 3

Sekaráyà 4:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ẹ̀ka igi tó so èso wọ̀ǹtìwọnti.

Sekaráyà 4:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Hag 2:4; Ifi 11:3, 4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2022, ojú ìwé 18

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 163-164

Àwọn míì

Sek. 4:2Ẹk 25:31; 1Ọb 7:48, 49
Sek. 4:2Ẹk 25:37
Sek. 4:3Sek 4:11, 14; Ifi 11:3, 4
Sek. 4:61Sa 17:45; Ho 1:7
Sek. 4:6Ond 6:34; 15:14
Sek. 4:7Ais 40:4
Sek. 4:7Ẹsr 3:2; Hag 1:1
Sek. 4:9Ẹsr 3:8, 10; 5:14, 16
Sek. 4:9Ẹsr 6:14; Sek 6:12
Sek. 4:10Ẹsr 3:12; Hag 2:3
Sek. 4:102Kr 16:9; Owe 15:3; Jer 16:17; Ifi 5:6
Sek. 4:11Sek 4:2, 3
Sek. 4:14Hag 2:4; Ifi 11:3, 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sekaráyà 4:1-14

Sekaráyà

4 Áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pa dà wá, ó sì jí mi, bí ìgbà tí wọ́n jí ẹni tó ń sùn. 2 Ó wá bi mí pé: “Kí lo rí?”

Mo sì sọ pé: “Wò ó! mo rí ọ̀pá fìtílà kan tí wọ́n fi wúrà ṣe látòkèdélẹ̀,+ abọ́ kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà méje wà lórí rẹ̀,+ àní méje, àwọn fìtílà orí rẹ̀ sì ní ọ̀pá méje. 3 Igi ólífì méjì sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ ọ̀kan ní apá ọ̀tún abọ́ náà, èkejì ní apá òsì rẹ̀.”

4 Lẹ́yìn náà, mo bi áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Olúwa mi, kí làwọn nǹkan yìí túmọ̀ sí?” 5 Áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ bá bi mí pé: “Ṣé o ò mọ ohun tí àwọn nǹkan yìí túmọ̀ sí ni?”

Mo fèsì pé: “Mi ò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.”

6 Ó wá sọ fún mi pé: “Ohun tí Jèhófà sọ fún Serubábélì nìyí: ‘“Kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun tàbí nípasẹ̀ agbára,+ bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 7 Báwo ni tìẹ ṣe jẹ́ ìwọ òkè ńlá? Wàá di ilẹ̀ pẹrẹsẹ*+ níwájú Serubábélì.+ Òun yóò mú òkúta tó wà lókè jáde bí àwọn èèyàn ṣe ń kígbe pé: “Ó mà dára o! Ó mà dára o!”’”

8 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 9 “Serubábélì ló fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí,+ ọwọ́ rẹ̀ náà ni yóò sì parí rẹ̀.+ Ẹ ó sì mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló rán mi sí yín. 10 Ta ló pẹ̀gàn ọjọ́ tí nǹkan bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́?*+ Inú wọn á dùn, wọ́n á sì rí okùn ìwọ̀n* ní ọwọ́ Serubábélì. Àwọn méje yìí ni ojú Jèhófà, tó ń wò káàkiri ayé.”+

11 Mo wá bi í pé: “Kí ni igi ólífì méjì yìí túmọ̀ sí, tó wà ní apá ọ̀tún àti apá òsì ọ̀pá fìtílà náà?”+ 12 Mo tún bi í lẹ́ẹ̀kejì pé: “Kí ni ìdì méjì ẹ̀ka* igi ólífì náà túmọ̀ sí, tó ní òpó wúrà méjì tí òróró wúrà ń ṣàn jáde láti inú rẹ̀?”

13 Ó wá bi mí pé: “Ṣé o ò mọ ohun tí àwọn nǹkan yìí túmọ̀ sí ni?”

Mo dáhùn pé: “Mi ò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.”

14 Ó sọ pé: “Àwọn yìí ni àwọn ẹni àmì òróró méjì tí wọ́n ń dúró ní ẹ̀gbẹ́ Olúwa gbogbo ayé.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́