ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 12/15 ojú ìwé 11-15
  • Ǹjẹ́ O “Mòye Ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́”?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O “Mòye Ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́”?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • AFÚNRÚGBÌN TÓ SÙN
  • ÀWỌ̀N ŃLÁ NÁÀ
  • ỌMỌ ONÍNÀÁKÚNÀÁ
  • Ìwọ Kò Mọ Ibi Tí Yóò Ti Ṣàṣeyọrí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • ‘Ẹ Fetí sí Mi, Kí Ẹ sì Lóye Ìtúmọ̀ Rẹ̀’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • ‘Ọlọ́run Ló Ń Mú Kí Ó Dàgbà’!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ki ni Àwọ̀n-Ìpẹja ati Ẹja Tumọsi Fun Ọ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 12/15 ojú ìwé 11-15
[Aworan oju iwe 11]

Ǹjẹ́ O “Mòye Ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́”?

“Ó . . . ṣí èrò inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ láti mòye ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́.”​—LÚÙKÙ 24:45.

KÍ LO RÍ KỌ́ NÍNÚ ÀPÈJÚWE TÍ JÉSÙ ṢE NÍPA . . .

  • afúnrúgbìn tó sùn?

  • àwọ̀n ńlá náà?

  • ọmọ onínàákúnàá?

1, 2. Báwo ni Jésù ṣe fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lókun lọ́jọ́ tó jíǹde?

LỌ́JỌ́ tí Jésù jíǹde, méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń rin ìrìn àjò lọ sí abúlé kan tí ó lé díẹ̀ ní kìlómítà mọ́kànlá sí Jerúsálẹ́mù. Inú wọn ṣì bà jẹ́ torí ikú Jésù, àmọ́ wọn ò mọ̀ pé Jésù ti jíǹde. Lójijì ni Jésù fara hàn wọ́n, ó sì ń bá wọn rìn lọ. Ó tu àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjèèjì yìí nínú. Báwo ló ṣe ṣe é? Bíbélì sọ pé: “Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Mósè àti gbogbo àwọn Wòlí ì, ó túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹ mọ́ ara rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn.” (Lúùkù 24:​13-15, 27) Bí Jésù ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, ọkàn wọn bẹ̀rẹ̀ sí í jó fòfò bí ó ti ń “ṣí” Ìwé Mímọ́ payá fún wọn “lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́,” tàbí bó ṣe ń ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké fún wọn.​—Lúùkù 24:32.

2 Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì yẹn pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Bí wọ́n ṣe rí àwọn àpọ́sítélì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tójú wọ́n rí fún wọn. Bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yẹn lọ́wọ́, Jésù fara han gbogbo wọn. Àmọ́, àyà àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ já. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì. Báwo ni Jésù ṣe fún wọn lókun? Bíbélì sọ fún wa pé: “Ó . . . ṣí èrò inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ láti mòye ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́.”​—Lúùkù 24:⁠45.

3. Àwọn ìṣòro wo ló lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ kí ló máa mú ká ní èrò tó tọ́ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

3 Nígbà míì, inú tiwa náà lè bà jẹ́ bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí. Ọwọ́ wa lè dí lẹ́nu iṣẹ́ Olúwa, àmọ́ bí àwọn èèyàn ò ṣe kọbi ara sí iṣẹ́ ìwàásù wa lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. (1 Kọ́r. 15:58) Tàbí kó máa ṣe wá bíi pé àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò ṣe ìyípadà tó bó ṣe yẹ. Kódà, àwọn míì tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè sọ pé àwọn ò ṣèkẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Kí la máa ṣe ká lè ní èrò tó tọ́ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká lóye àwọn àpèjúwe Jésù tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lẹ́kùn-n rẹ́rẹ́. Ẹ jẹ́ ká gbé mẹ́ta yẹ̀ wò nínú àwọn àpèjúwe yẹn àti ẹ̀kọ́ tí a lè rí kọ́ níbẹ̀.

AFÚNRÚGBÌN TÓ SÙN

4. Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa afúnrúgbìn tó sùn?

4 Ka Máàkù 4:​26-29. Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa afúnrúgbìn tó sùn? Ọkùnrin tó fún irúgbìn nínú àpèjúwe yìí ṣàpẹẹrẹ akéde Ìjọba Ọlọ́run kọ̀ọ̀kan. Irúgbìn náà dúró fún ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Afúnrúgbìn náà “sùn ní òru, ó sì dìde ní ojúmọ́,” bí àwa èèyàn ṣe ń gbé ìgbé ayé ojoojúmọ́. Irúgbìn náà dàgbà láàárín àwọn sáà àkókò kan, ìyẹn bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí wọ́n gbìn ín títí tó fi di ìgbà ìkórè. Láàárín àkókò yẹn “irúgbìn náà . . . rú jáde, ó sì dàgbà sókè.” Ìdàgbàsókè tó wáyé ṣẹlẹ̀ “fúnra rẹ̀,” ìyẹn ni pé ó ń ṣẹlẹ̀ díẹ̀díẹ̀ àti ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Lọ́nà kan náà, ìdàgbàsókè nípa tẹ̀mí máa ń wáyé díẹ̀díẹ̀, ó sì máa ń jẹ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Tí ẹnì kan bá ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí débi tó fi pinnu láti sin Ọlọ́run, irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, á sì ṣèrìbọmi.

5. Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe nípa afúnrúgbìn tó sùn?

5 Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe yìí? Jésù lo àpèjúwe yìí láti jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló ń mú kí òtítọ́ dàgbà lọ́kàn àwọn ẹni tó ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́.” (Ìṣe 13:48; 1 Kọ́r. 3:7) À ń gbìn, a sì ń bu omi rin, àmọ́ àwa kọ́ lá máa mú kí irúgbìn náà dàgbà. Torí náà, a ò lè fipá mú ẹnikẹ́ni pé kí ó dàgbà nípa tẹ̀mí tàbí ká mú kó yára dàgbà nípa tẹ̀mí. Ńṣe ni ọ̀rọ̀ wa dà bíi ti afúnrúgbìn inú àpèjúwe yìí, a ò mọ bí ìdàgbàsókè náà ṣe ń wáyé. Bí a ṣe ń sùn, tá à ń jí, a kì í sábà fura sí bí irúgbìn náà ṣe ń dàgbà. Àmọ́ tó bá yá, irúgbìn Ìjọba Ọlọ́run lè so èso. Ẹni tuntun náà lè dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ ìkórè náà, a sì lè jàǹfààní lára tiẹ̀ náà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.​—Jòh. 4:​36-38.

6. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa ìtẹ̀síwájú ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

6 Kí ni a lè rí kọ́ nínú àpèjúwe yìí? Ohun àkọ́kọ́ ni pé, a gbọ́dọ̀ gbà pé àwa kọ́ la máa mú kí ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Tí a bá mọ èyí, a ò ní máa fipá mú ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé kó ṣèrìbọmi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́, àá sì gbà pé ọwọ́ rẹ̀ ló kù sí láti pinnu bóyá ó máa ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ìfẹ́ tí ẹnì kan ní fún Ọlọ́run ló yẹ kó mú kó wù ú láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà kò ní dùn sí irú ìyàsímímọ́ bẹ́ẹ̀.​—Sm. 51:12; 54:6; 110:3.

7, 8. (a) Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni a kọ́ nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa afúnrúgbìn tó sùn? Sọ àpẹẹrẹ kan. (b) Kí ni èyí kọ́ wa nípa Jèhófà àti Jésù?

7 Ìkejì, tí a bá lóye ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú àpèjúwe yìí, a ò ní rẹ̀wẹ̀sì tí a kò bá tí ì rí i kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣe ìyípadà. Ó gba pé ká ṣe sùúrù. (Ják. 5:​7, 8) Tí a bá ti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́, síbẹ̀ tí kò yí pa dà, ká gbà pé kì í ṣe torí pé a jẹ́ aláìṣòótọ́ ni kò ṣe so èso. Àwọn tó bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì ṣe tán láti ṣe ìyípadà ni Jèhófà máa ń jẹ́ kí irúgbìn òtítọ́ dàgbà nínú wọn. (Mát. 13:23) Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ fi bí iye àwọn èèyàn tó ń ṣèrìbọmi ṣe pọ̀ tó díwọ̀n àṣeyọrí wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ó kúkú ṣe tán, ìyẹn kọ́ ni Jèhófà fi ń díwọ̀n àṣeyọrí tá a ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà mọrírì gbogbo ohun tí à ń ṣe tọkàntọkàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láìka irú ọwọ́ táwọn èèyàn fi mú òtítọ́ sí.​—Ka Lúùkù 10:​17-20; 1 Kọ́ríńtì 3:8.

8 Ìkẹta, a kì í sábà rí àwọn ìyípadà tẹ́nì kan ń ṣe nínú ọkàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì ń kọ́ tọkọtaya kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lọ́jọ́ kan tọkọtaya náà sọ fún míṣọ́nnárì yìí pé àwọn fẹ́ di akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi. Arákùnrin yìí sọ fún tọkọtaya náà pé kí wọ́n tó lè tóótun láti di akéde tí kò tí ì ṣèrìbọmi, wọ́n gbọ́dọ̀ fi sìgá mímu sílẹ̀. Ó ya arákùnrin yìí lẹ́nu nígbà tí tọkọtaya náà sọ pé àwọn ti jáwọ́ nínú àṣà yìí láti nǹkan bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn. Kí nìdí tí wọ́n fi jáwọ́? Wọ́n ti wá mọ̀ pé táwọn bá tiẹ̀ ń mu sìgá níbi téèyàn ò ti ní rí àwọn, Jèhófà ń rí àwọn, wọ́n sì mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ìwà àgàbàgebè. Torí náà, àwọn méjèèjì pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe, yálà láti máa mu sìgá níṣojú míṣọ́nnárì tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tàbí kí wọ́n jáwọ́ pátápátá. Àmọ́, torí pé tọkọtaya yìí ti wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n ṣe ìpinnu tí ó tọ́. Òtítọ́ ti ń jinlẹ̀ nínú àwọn tọkọtaya náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé míṣọ́nnárì yìí ò rí ìyípadà ti wọ́n ti ṣe lọ́kàn wọn.

ÀWỌ̀N ŃLÁ NÁÀ

9. Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa àwọ̀n ńlá náà?

9 Ka Mátíù 13:​47-50. Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa àwọ̀n ńlá náà? Jésù fi iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe láàárín àwọn ọmọ aráyé wé àwọ̀n ńlá kan tí wọ́n jù sínú òkun. Bí àwọ̀n ńlá kan ṣe máa ń kó “ẹja onírúurú” jọ rẹpẹtẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa ń fa ọ̀kẹ́ àìmọye onírúurú èèyàn mọ́ra. (Aísá. 60:5) Ẹ̀rí èyí hàn kedere bí a ṣe ń rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó ń wá sáwọn àpéjọ àgbègbè àti síbi Ìrántí Ikú Kristi tí a máa ń ṣe lọ́dọọdún. Àwọn kan nínú àwọn ẹja ìṣàpẹẹrẹ yìí jẹ́ ẹja “àtàtà,” wọ́n sì ń di ara ìjọ Kristẹni. Àmọ́, ẹja “tí kò yẹ” làwọn mí ì, torí kì í ṣe gbogbo àwọn tí a kó jọ ni Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà.

[Aworan oju iwe 14]

Leyin to o ba ti ka Matiu 13:47-50 . . .

10. Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe nípa àwọ̀n ńlá náà?

10 Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe yìí? Yíya àwọn ẹja sọ́tọ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ tí Jésù sọ nínú àpèjúwe yìí kì í ṣe èyí tó máa wáyé nígbà ìdájọ́ ìkẹyìn lákòókò ìpọ́njú ńlá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń tọ́ka sí ìyàsọ́tọ̀ tó máa wáyé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn nínú ètò àwọn nǹkan burúkú yìí. Jésù fi hàn pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ló máa fẹ́ sin Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ló máa ń wá sí ìpàdé wa, àwọn míì sì gbà ká máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ wọn ò ṣe tán láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. (1 Ọba 18:21) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn míì ò wá sí ìpàdé mọ́. Àwọn ọ̀dọ́ mí ì wà tó jẹ́ pé Kristẹni làwọn òbí tó tọ́ wọn dàgbà, síbẹ̀ wọn kò tí ì nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà Jèhófà. Èyí ó wù kó jẹ́, Jésù mú kó ṣe kedere pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tó máa ṣe fúnra rẹ̀. Jésù ka àwọn tó bá pinnu láti sin Jèhófà sí àwọn ohun ọ̀wọ́n tàbí ohun “fífani-lọ́kàn-mọ́ra” tí ó wà “nínú gbogbo orílẹ̀-èdè.”​—Hág. 2:7.

[Aworan oju iwe 15]

. . . wo apeere tode oni

11, 12. (a) Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa àwọ̀n ńlá náà? (b) Kí ni èyí kọ́ wa nípa Jèhófà àti Jésù?

11 Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní nínú àpèjúwe nípa àwọ̀n ńlá náà? Tí a bá lóye ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wa nínú àpèjúwe yìí, a ò ní banú jẹ́ jù tí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ wa bá kọ̀ láti sọ òtítọ́ di tirẹ̀. Èyí lè ṣẹlẹ̀ láìka gbogbo ìsapá wa sí. Ti pé ẹnì kan gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí pé wọ́n tọ́ ẹnì kan dàgbà nínú òtítọ́ kò túmọ̀ sí pé ẹni náà máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. A máa yọ àwọn tí kò fẹ́ fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Jèhófà kúrò láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run.

Awon kan ninu awon to nifee si oro Ijoba Olorun maa sa gbogbo ipa won ki won le maa sin Jehofa (Wo ipinro 9 si 12)

12 Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn tó ti kúrò nínú òtítọ́ kò ní lè pa dà sínú ìjọ Kristẹni? Tàbí tí ẹnì kan bá kọ̀ láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ṣé títí láé ni a máa fi kà á sí ẹni “tí kò yẹ”? Rárá o. Àǹfààní ṣì wà fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kí ìpọ́njú ńlá tó dé. Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: “Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, dájúdájú, èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín.” (Mál. 3:7) Jésù tẹnu mọ́ kókó yìí nínú àpèjúwe míì tó sọ, ìyẹn ni àpèjúwe nípa ọmọ onínàákúnàá.​—Ka Lúùkù 15:​11-32.

ỌMỌ ONÍNÀÁKÚNÀÁ

13. Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ọmọ onínàákúnàá?

13 Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ọmọ onínàákúnàá? Bàbá aláàánú nínú àkàwé yìí ṣàpẹẹrẹ Jèhófà, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́. Ọmọkùnrin tó béèrè fún ìpín tirẹ̀ nínú ogún bàbá rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ṣáko lọ kúrò nínú ìjọ. Wọ́n tipa báyìí di apá kan ayé Sátánì tó dà bí “ilẹ̀ jíjìnnàréré,” tó jìn gan-an sí Jèhófà. (Éfé. 4:18; Kól. 1:21) Àmọ́, àwọn kan pa dà pe orí ara wọn wálé, wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtipadà lè má rọrùn fún wọn. Inú Jèhófà máa ń dùn láti dárí ji àwọn onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà. Tayọ̀tayọ̀ ló sì fi ń gbà wọ́n pa dà.​—Aísá. 44:22; 1 Pét. 2:25.

14. Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe nípa ọmọ onínàákúnàá?

14 Kí nìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe yìí? Jésù lo àpèjúwe yìí láti jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí àwọn tó ti ṣáko lọ kúrò nínú ìjọ pa dà wá sọ́dọ̀ Òun. Gbogbo ìgbà ni bàbá inú àpèjúwe tí Jésù sọ yìí ń retí pé ọmọ òun máa pa dà wálé lọ́jọ́ kan. Nígbà tí bàbá yìí tajú kán rí ọmọ rẹ̀ lọ́ọ̀ọ́kán, kíá ló sáré lọ pàdé rẹ̀ láti kí i káàbọ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ náà “ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn.” Ó yẹ kí àpèjúwe yìí mú kí àwọn tó ti ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà láì jáfara! Àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà lè ti bà jẹ́, ojú sì lè máa tì wọ́n tàbí kó ṣòro fún wọn láti pa dà. Àmọ́, gbogbo ìsapá wọn láti pa dà tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, torí pé ìdùnnú tó kọyọyọ ló máa wà ní ọ̀run nígbà tí wọ́n bá pa dà.​—Lúùkù 15:7.

15, 16. (a) Kí la rí kọ́ nínú àpèjúwe Jésù nípa ọmọ onínàákúnàá? Sọ àpẹẹrẹ kan. (b) Kí ni èyí kọ́ wa nípa Jèhófà àti Jésù?

15 Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní nínú àpèjúwe nípa ọmọ onínàákúnàá? Ó yẹ ká fìwà jọ Jèhófà. Kò yẹ ká sọ ara wa “di olódodo àṣelékè,” ká wá kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ẹni tó ti ronú pìwà dà. Torí èyí lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. (Oníw. 7:16) Ohun mìíràn tún wà tí a lè rí kọ́ nínú èyí. Ìyẹn ni pé ojú “àgùntàn tí ó sọnù” ni ká máa fi wo àwọn tó fi ìjọ sílẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ kà wọ́n sí ẹni tó ti re àjò àrèmábọ̀. (Sm. 119:176) Tá a bá bá ẹnì kan tí wọn kò tíì yọ lẹ́gbẹ́, àmọ́ tó ti ṣáko lọ kúrò nínú ìjọ pàdé, ǹjẹ́ a máa ràn án lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́, ká sì ṣe ohun tó máa jẹ́ kó lè pa dà? Ǹjẹ́ a máa tètè sọ́ fún àwọn alàgbà kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ tó yẹ fún un? A máa ṣe bẹ́ẹ̀, tá a bá fi ẹ̀kọ́ tí a kọ́ nínú àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá sílò.

16 Gbọ́ ohun tí díẹ̀ nínú àwọn tí wọ́n dà bí ọmọ onínàákúnàá lóde òní sọ nípa bí wọ́n ṣe mọrírì bí Jèhófà ṣe fàánú hàn sáwọn àti bí àwọn tó wà nínú ìjọ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́. Arákùnrin kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sẹ́yìn sọ pé: “Ṣe ni ayọ̀ mi ń pọ̀ sí i látìgbà tí wọ́n ti gbà mí pa dà sínú ìjọ, torí mo ti gba ‘àwọn àsìkò títunilára’ látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Ìṣe 3:19) Gbogbo àwọn ará ìjọ ló tẹ́wọ́ gbà mí tí wọ́n sì fìfẹ́ hàn sí mi! Ní báyìí, mo ní àwọn ẹni ọ̀wọ́n tá a jọ ń sin Jèhófà.” Arábìnrin ọ̀dọ́ kan tí ó ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà fún ọdún márùn-⁠ún sọ pé: “Mi ò mọ bí mo ṣe lè ṣàlàyé fún yín bó ṣe rí lára mi nígbà tí mo rí báwọn ará ṣe fìfẹ́ hàn sí mi, gẹ́lẹ́ bí Jésù ṣe sọ ló rí. Ohun àgbàyanu ló jẹ́ láti wà nínú ètò Ọlọ́run, kò láfiwé rárá!”

17, 18. (a) Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni a rí kọ́ nínú àwọn àpèjúwe mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí a gbé yẹ̀ wò yìí? (b) Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

17 Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni a ti rí kọ́ nínú àwọn àpèjúwe mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí? Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ gbà pé a ò lè mú kí ẹnikẹ́ni tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ọwọ́ Jèhófà nìyẹn wà. Ìkejì, a ò lè retí pé gbogbo àwọn tó ń wá sípàdé tí a sì ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló máa pinnu láti sin Jèhófà. Ìkẹta, bí àwọn kan bá tiẹ̀ kúrò nínú òtítọ́ tí wọn ò sì sin Jèhófà mọ́, ẹ má ṣe jẹ́ ká sọ̀rètí nù pé wọn ò lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà mọ́. Tí wọ́n bá sì pa dà, ẹ jẹ́ kí á gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀ kí wọ́n lè mọ̀ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ àwọn.

18 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti máa wá ìmọ̀, òye àti ọgbọ́n. Bí a ti ń ka àwọn àpèjúwe Jésù, ẹ jẹ́ ká bi ara wa pé, kí ni àwọn àpèjúwe yìí túmọ̀ sí? Kí nìdí tí wọ́n fi wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì? Báwo ni a ṣe lè fi àwọn ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nínú àwọn àpèjúwe náà sílò? Kí sì ni wọ́n kọ́ wa nípa Jèhófà àti Jésù? Tí a bá ń ṣe èyí, à ń fi hàn pé a mòye ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́