ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 12/15 ojú ìwé 16
  • Nje O Ranti?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nje O Ranti?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí ni àwọn òbí Kristẹni lè ṣe kí wọ́n lè kọ́ àwọn ọmọ wọn?
  • Timgad—Ilu Atijo Tawon Eeyan Ti Gbadun Aye Jije
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Bíbélì Peshitta—Lédè Síríákì Ó Jẹ́ Ká Mọ Àwọn Bíbélì Tí Wọ́n Ṣe Láyé Àtijọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìwọ Ha Rántí Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ǹjẹ́ O Rántí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 12/15 ojú ìwé 16

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

Ṣé ó yẹ kí àwọn Kristẹni máa fi iná sun òkú?

Ẹni tí òkú kú fún ló máa pinnu bóyá wọ́n máa fi iná sun òkú náà tàbí wọn kò ní sun ún. Bíbélì kò sọ̀rọ̀ ní tààràtà nípa irú ọwọ́ tó yẹ ká fi mú àṣà yìí, àmọ́ àkọsílẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n fi iná sun òkú Sọ́ọ̀lù Ọba àti ti Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀, kí wọ́n tó wá sin àwọn egungun wọn. (1 Sám. 31:​2, 8-13)​—6/15, ojú ìwé 7.

Kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀?

Olódodo ni Ọlọ́run ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Ó máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo, olóòótọ́ ni àti adúróṣánṣán. Jèhófà tún jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú. (Diu. 32:4; Sm. 145:17; Ják. 5:11)​—7/1, ojú ìwé 4.

Àwọn ìpèníjà wo lèèyàn lè ní tó bá kó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè láti lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i?

Àwọn ìpèníjà náà ni (1) mímú ara ẹni bá ipò ìṣúnná owó tuntun mu, (2) kíkojú àárò ilé, àti (3) dídá wà. Àwọn tó ti borí ìpèníjà yìí ti rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà.​—7/15, ojú ìwé 4 sí 5.

Kí nìdí tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù fi kórìíra rẹ̀?

Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ Jósẹ́fù gan-an, ó fún un ní ẹ̀wù àrà ọ̀tọ̀ kan. Àwọn arákùnrin Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú rẹ̀, wọ́n sì tà á sí oko ẹrú.​—8/1, ojú ìwé 11 sí 13.

Kí nìdí tí àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa tuntun fi wúlò gan-an tí wọ́n sì rọrùn láti lò?

Ọ̀nà kan náà la gbà ṣe gbogbo ìwé àṣàrò kúkúrú wa tuntun. Ìwé àṣàrò kúkúrú kọ̀ọ̀kan ń mú ká lè ka Bíbélì fún onílé kí a sì bi í ní ìbéèrè. Ìdáhùn yòówù kí onílé mú wá, a lè ṣí ìwé àṣàrò kúkúrú náà, ká sì fi ohun tí Bíbélì sọ hàn án. A tún lè tọ́ka sí ìbéèrè kan tí a máa pa dà wá dáhùn nígbà míì.​—8/15, ojú ìwé 13 sí 14.

Bíbélì wo ni wọ́n ń pè ní Peshitta, tí wọ́n kọ ní èdè Síríákì?

Èdè Síríákì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè ìbílẹ̀ tó wá látinú èdè Árámáíkì, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ó ń lo èdè náà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì tàbí ìkẹta Sànmánì Kristẹni. Ó dà bíi pé èdè Síríákì ni èdè tí wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ àwọn apá kan nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sí. Bíbélì lédè Síríákì làwọn èèyàn wá mọ̀ sí Peshitta.​—9/1, ojú ìwé 13 sí 14.

Kí ni àwọn òbí Kristẹni lè ṣe kí wọ́n lè kọ́ àwọn ọmọ wọn?

Tí àwọn òbí bá fẹ́ mọ àwọn ọmọ wọn dáadáa, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa fetí sí wọn. Ó tún yẹ káwọn òbí máa sapá láti máa bọ́ àwọn ọmọ wọn nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì máa tọ́ wọn sọ́nà tìfẹ́tìfẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí lè ran ọmọ wọn lọ́wọ́ kó lè fa iyèméjì èyíkéyìí tó ní nípa ìjọsìn Jèhófà tu kúrò lọ́kàn rẹ̀.​—9/15, ojú ìwé 18 sí 21.

Àwọn nǹkan wo ni kò ní sí mọ́ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?

Kò ní sí àìsàn mọ́, kò ní sí ikú mọ́, àìríṣẹ́ ò ní sí mọ́, ogun á kásẹ̀ nílẹ̀, kò ní sí àìtó oúnjẹ mọ́, àwọn èèyàn ò sì ní tòṣì mọ́.​—10/1, ojú ìwé 6 sí 7.

Májẹ̀mú wo ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn míì láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi?

Lẹ́yìn Ìrékọjá tí Jésù ṣe kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́, májẹ̀mú náà la lè pè ní májẹ̀mú Ìjọba. (Lúùkù 22:​28-30) Májẹ̀mú yìí mú kó dá wọn lójú pé wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lókè ọ̀run.​—10/15, ojú ìwé 16 sí 17.

Sọ àwọn àpẹẹrẹ méjì látinú Bíbélì tó fi hàn pé ẹni gidi ni Sátánì.

Ìwé mímọ́ sọ pé Sátánì bá Jésù sọ̀rọ̀ kó lè dẹkùn mú un. Bákan náà, nígbà ayé Jóòbù, Sátánì bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi hàn pé ẹni gidi ni Sátánì.​—11/1, ojú ìwé 4 sí 5.

Àwọn wo ni “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀” tí Jákọ́bù sọ̀rọ̀ wọn, bó ṣe wà nínú ìwé Ìṣe 15:14?

Àwọn yìí ni àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù tí Ọlọ́run yàn láti máa jẹ́ ẹ̀yà àyànfẹ́, kí wọ́n lè “polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá” Ẹni tí ó pè wọ́n. (1 Pét. 2:​9, 10)​—11/15, ojú ìwé 24 sí 25.

Ibo ni ìlú Timgad wà, irú ìgbésí ayé wo làwọn tó wà níbẹ̀ sì ń gbé?

Àwọn ará Róòmù ló kọ́ ìlú Timgad sí apá àríwá ilẹ̀ Áfíríkà, (tá a wá mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Algeria lónìí). Ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára òkúta kan tí wọ́n rí níbẹ̀ jẹ́ ká mọ irú ìgbésí ayé táwọn tó wà níbẹ̀ ń gbé, ó ní: “Ká ṣọdẹ, ká lúwẹ̀ẹ́, ká ṣe fàájì, ká ṣẹ̀fẹ̀, ṣáà ti jayé orí ẹ!” Irú èrò yìí ni ìwé 1 Kọ́ríńtì 15:32 mẹ́nu kàn.​—12/1, ojú ìwé 8 sí 10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́