ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 12/1 ojú ìwé 8-10
  • Timgad—Ilu Atijo Tawon Eeyan Ti Gbadun Aye Jije

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Timgad—Ilu Atijo Tawon Eeyan Ti Gbadun Aye Jije
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÍ TÍ WỌ́N FI TẸ ÌLÚ NÁÀ DÓ
  • BÍ ÀWỌN ARÁ RÓÒMÙ ṢE FA OJÚ WỌ́N MỌ́RA
  • BÍ ÌLÚ TIMGAD ṢE PA RUN
  • “JAYÉ ORÍ Ẹ!”
  • Nje O Ranti?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Mímúra Àwọn Orílẹ̀-Èdè Sílẹ̀ fún “Ẹ̀kọ́ Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Bí Kristẹndọm Ṣe Di apakan Ayé Yii
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Kò Sí Èrò Nípa Jíjuwọ́sílẹ̀!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 12/1 ojú ìwé 8-10

Timgad—Ìlú Àtijọ́ Táwọn Èèyàn Ti Gbádùn Ayé Jíjẹ

NÍ ọdún 1765, olùṣèwádìí ọmọ ilẹ̀ Scotland tó ń jẹ́ James Bruce rí ohun kan tó yà á lẹ́nu ní aginjù Algeria. Ó kófìrí òpó bìrìkìtì kan táwọn ará Róòmù kọ́! Kò mọ̀ pé ọ̀gangan ibi tóun dúró sí gan-⁠an ni àwọn ará Róòmù kọ́ ìlú tó tóbi jù lọ sí láyé àtijọ́ ní Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà. Ìlú Thamugadi ni wọ́n máa ń pe ibẹ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ìlú Timgad ni wọ́n mọ̀ ọ́ sí báyìí.

Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-⁠ún ọdún lẹ́yìn náà, àwọn awalẹ̀pìtàn láti ilẹ̀ Faransé bẹ̀rẹ̀ sí í hú àwókù ìlú Timgad jáde lọ́dún 1881. Wọ́n rí i pé láìka bí agbègbè náà ṣe jẹ́ aṣálẹ̀ sí, ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ làwọn aráàlú ibẹ̀ ń gbé. Àmọ́, kí ló dé táwọn ará Róòmù fi kọ́ ìlú ńlá yìí sírú aṣálẹ̀ bẹ́ẹ̀? Kí sì la lè rí kọ́ nínú ìtàn ìlú yẹn àti lára àwọn tó gbébẹ̀?

ÌDÍ TÍ WỌ́N FI TẸ ÌLÚ NÁÀ DÓ

Nígbà tí àkóso àwọn ará Róòmù nasẹ̀ dé Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣáájú sànmánì Kristẹni, ńṣe làwọn darandaran tó wà lágbègbè yẹn gbógun tì wọ́n. Kí àwọn ọmọ ogun Róòmù lè paná ọ̀tẹ̀ yìí kí wọ́n sì fa ojú àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà náà mọ́ra, àwọn sójà tó wà nínu ẹgbẹ́ ogun Augustan Kẹta kọ́ àwọn ilé ẹ̀ṣọ́ tó ní ògiri gìrìwò sí àwọn agbègbè olókè ńlá tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè tá à ń pè ní Algeria báyìí. Ìgbà tó yá ni wọ́n kọ́ ìlú Timgad àmọ́ wọ́n ní nǹkan kan lọ́kàn tí wọ́n fi kọ́ ọ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ológun ni wọ́n kọ́ ìlú Timgad fún, wọ́n tún fẹ́ fi ẹwà ìlú náà fa ojú àwọn ọmọ Áfíríkà tó ń gbógun tì wọ́n mọ́ra, kí wọ́n lè dáwọ́ wàhálà tí wọ́n ń fà dúró. Òjé náà sì jẹ wọ́n. Ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì táwọn ará Róòmù ń gbé ní ìlú yẹn bẹ̀rẹ̀ sí wu àwọn ọmọ Áfíríkà tó wá tajà níbẹ̀. Àwọn ọmọ Áfíríkà yìí bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọ̀nà tí wọ́n á fi dí aráàlú Timgad àmọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù nìkan ni wọ́n fún láṣẹ láti gbé nínú ìlú yẹn. Fún ìdí yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Áfíríkà dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ogun Róòmù fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] kí àwọn àti àwọn ọmọ wọn lè gba ìwé ẹ̀rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù.

Nígbà tó ṣe, àwọn ọmọ Áfíríkà yìí bẹ̀rẹ̀ sí í wá ipò ńláńlá fún ara wọn, àwọn míì di olóyè nílùú náà, àwọn mí ì sì joyè láwọn ìlú mí ì tí àwọn ará Róòmù tẹ̀ dó. Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ táwọn ará Róòmù dá yìí gbéṣẹ́ gan-an torí pé, lẹ́yìn àádọ́ta [50] ọdún tí wọ́n tẹ ìlú náà dó, àwọn ọmọ Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà ló pọ̀ jù nílùú Timgad.

BÍ ÀWỌN ARÁ RÓÒMÙ ṢE FA OJÚ WỌ́N MỌ́RA

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn ṣọ́ọ̀bù ibi ọjà tó ní àwọn òpó rìbìtì

Báwo láwọn ará Róòmù ṣe fa ojú àwọn ọmọ Áfíríkà yìí mọ́ra? Ohun kan ni pé, ìlànà orí-ò-ju-orí tí olóṣèlú ará Róòmù kan tó ń jẹ́ Cicero gbé kalẹ̀ ni wọ́n ń tẹ̀ lé ní ìlú yẹn. Èyí ló mú kí wọ́n pín ilẹ̀ wọn lọ́gbọọgba láàárín àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù àtàwọn ọmọ Áfíríkà tó ń gbébẹ̀. Ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ́ àwọn ilé tó wà nílùú yẹn tún kọjá bẹ́ẹ̀. Àwọn ilé náà jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà márùndínláàádọ́rin [65] níbùú àti lóròó, pẹ̀lú àwọn ojú pópó tó ṣe tóóró. Gbogbo bí nǹkan ṣe wà létòlétò ní ìlú yẹn wú àwọn ọmọ Áfíríkà náà lórí.

Bákan náà, àwọn aráàlú máa ń wá sí ibi àpérò ní ọjọ́ ọjà láti wá gbọ́ àwọn ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tàbí kí wọ́n wá dára yá bó ṣe máa ń rí ní ọ̀pọ̀ ìlú táwọn ará Róòmù tẹ̀ dó. Àwọn ọmọ Áfíríkà tó jẹ́ pé ibi aṣálẹ̀ gbígbẹ táútáú lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn òkè ńlá ni wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ wá dẹni tó ń gbé nílùú tó ní àwọn òpó tó ń ṣíji bo èèyàn lọ́wọ́ oòrùn. Wọ́n tún ní àwọn ibi ìwẹ̀ tó tura tó sì tutù minimini, gbogbo èèyàn ló sì wà fún. Ìgbà míì sì rèé, wọ́n lè máa gbafẹ́ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ wọn lẹ́bàá ìsun omi tó mọ́ lóló. Bí àlá ní gbogbo nǹkan yìí rí lójú wọn, èyí sì mú kí ara tù wọ́n nílùú náà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Òkúta tí wọ́n gbẹ́ ère òòṣà mẹ́talọ́kan sí lára níbi itẹ́ òkú

Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará Róòmù kọ́ gbọ̀ngàn ìwòran ńlá kan tó fa ọkàn àwọn ọmọ Áfíríkà náà mọ́ra. Gbọ̀ngàn náà ní àyè ìjókòó tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500], èrò rẹpẹtẹ láti ìlú Timgad àtàwọn ìlú míì tó wà lágbègbè yẹn ló sì máa ń wá wòran níbẹ̀. Oríṣiríṣi eré ìdárayá tó kún fún ìṣekúṣe àti ìwà ipá táwọn ará Róòmù kúndùn ni wọn máa ń ṣe nínú gbọ̀ngàn ìwòran yẹn.

Ohun míì táwọn ará Róòmù tún fi mú àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà yìí mọ́lẹ̀ ni ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Róòmù. Ńṣe ni wọ́n gbẹ́ onírúurú àwòrán àwọn òòṣà wọn sára ilẹ̀ àti ògiri ibi ìwẹ̀ tí wọ́n kọ́. Nígbà tó sì jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni àwọn èèyàn ń wẹ̀, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ imú ẹlẹ́dẹ̀ wọ ọgbà, àwọn òòṣà àti àṣà inú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Róòmù wá dara fún àwọn náà. Gbogbo ọgbọ́n táwọn ará Róòmù dá láti mú káwọn ọmọ Áfíríkà yìí tẹ́wọ́ gba àṣà Róòmù ló gbéṣẹ́ débi pé nígbà tó yá, àwọn ọmọ Áfíríkà náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ àwòrán àwọn òòṣà tiwọn àti tàwọn ará Róòmù sára òkúta tí wọ́n mọ síbi àwọn itẹ́ òkú.

BÍ ÌLÚ TIMGAD ṢE PA RUN

Ọdún 100 sànmánì Kristẹni ni olú-ọba Trajan tẹ ìlú Timgad dó, látìgbà yẹn sì ni wọ́n ti ń gbin ọkà, òróró ólífì àti wáìnì ní gbogbo agbègbè Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà. Kò sì pẹ́ tó fi di pé ibẹ̀ ni wọ́n tí ń kó ọ̀pọ̀ àwọn ọjà wá sí ìlú Róòmù. Ìlú Timgad gbèrú gan-an lábẹ́ àkóso àwọn ará Róòmù tó fi jẹ́ pé ìlú ọ̀hún kún fọ́fọ́ débi tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi lọ ń gbé ní òde ìlú náà.

Àmọ́ àwọn tó ń gbé inú ìlú àtàwọn tó nílẹ̀ ló ń rówó nínú òwò tí wọ́n ń ṣe pẹ̀lú àwọn ará Róòmù, ìwọ̀nba táṣẹ́rẹ́ ló ń ṣẹ́ sápò àwọn àgbẹ̀ tó ń forí ṣe fọrùn ṣe. Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-⁠ún ọdún kẹta sànmánì Kristẹni, ìwà ìrẹ́jẹ àti owó orí gegere sú àwọn àgbẹ̀ yìí, ìyẹn ló bí rògbòdìyàn tó wáyé lẹ́yìn náà. Díẹ̀ nínú àwọn àgbẹ̀ yẹn tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì fi ìjọ sílẹ̀, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni kan tó ń jẹ́ Donatist, ìyẹn àwọn tó kọminú sí ìwà ìbàjẹ́ tó wà nínú ìjọ Kátólíìkì.​—Wo àpótí náà “Kristẹni aláfẹnujẹ́ ni àwọn ẹlẹ́sìn Donatist.”

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni wọ́n fi ja ogun abẹ́lé àti ìjà ẹ̀sìn, táwọn oníjàgídíjàgan sì tún gbógun tì wọ́n. Nígbà tó yá, àwọn ará Róòmù ò lè ṣàkóso níbẹ̀ mọ́, nígbà tó sì di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà sànmánì Kristẹni, àwọn ẹ̀yà Lárúbáwá gbógun tì wọ́n, wọ́n sì dáná sun ìlú yẹn pátápátá. Bí ìlú Timgad ṣe ròkun ìgbàgbé nìyẹn fún ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún.

“JAYÉ ORÍ Ẹ!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Òkúta tí wọ́n rí níbi àpérò náà kà pé: “Ká ṣọdẹ, ká lúwẹ̀ẹ́, ká ṣe fàájì, ká ṣẹ̀fẹ̀, ṣáà ti jayé orí ẹ!””

Nígbà táwọn awalẹ̀pìtàn ń hú àwókù ìlú Timgad, wọ́n rí ohun tó pa wọ́n lẹ́rìn-ín lára òkúta kan tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí lédè Látìn níbi àpérò ìlú náà. Ohun tí wọ́n kọ síbẹ̀ ni pé: “Ká ṣọdẹ, ká lúwẹ̀ẹ́, ká ṣe fàájì, ká ṣẹ̀fẹ̀, ṣáà ti jayé orí ẹ!” Òpìtàn ilẹ̀ Faransé kan sọ pé “àwọn kan ka ọ̀rọ̀ yìí sí ìwà ọgbọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú èrò bẹ́ẹ̀ kì í múni ronú nípa ọjọ́ ọ̀la.”

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọjọ́ pẹ́ táwọn ará Róòmù ti ń gbé ìgbésí ayé “ṣáà ti jayé orí ẹ.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Kristẹni ayé àtijọ́ sọ nípa àwọn kan tó jẹ́ pé ìgbésí ayé wọn ò ju “Kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” Àwọn ará Róòmù kì í fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré, síbẹ̀ fàájì ti jàrábà wọn, bóyá ni wọ́n máa ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ fáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe bá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kẹ́gbẹ́, ó ní: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”​—1 Kọ́ríńtì 15:​32, 33.

Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] ọdún ti ìlú Timgad ti pa run, síbẹ̀ irú ìgbésí ayé táwọn èèyàn ń gbé nígbà yẹn lọ́hùn-ún làwọn èèyàn ṣì ń gbé lónìí. Ọ̀pọ̀ ni kò mọ̀ ju fàájì lọ. Tiwọn ni pé káwọn ṣáà ti jayé orí àwọn láìka ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká ní ojú ìwòye tó ṣe kedere, ó ní: “Ìran ayé yìí ń yí padà.” Ó wá gbà wá nímọ̀ràn pé ‘ká má ṣe lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.’​—1 Kọ́ríńtì 7:31.

Àwókù ìlú Timgad jẹ́rìí sí i pé kéèyàn jayé orí ẹ̀ kọ́ ló ń mú ayọ̀ wá, òun kọ́ ló sì ń mú kéèyàn gbé ayé ire. Àmọ́ tá a bá fẹ́ láyọ̀, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”​—1 Jòhánù 2:17.

Kristẹni aláfẹnujẹ́ ni àwọn ẹlẹ́sìn Donatist

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ibi ìtẹ̀bọmi ìlú Timgad fi bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe gbilẹ̀ nígbà yẹn hàn

Wọ́n ṣàwárí àwókù Ṣọ́ọ̀ṣì kan tó ní ibi ìtẹ̀bọmi ní apá ìwọ̀ oòrùn ìlú Timgad. Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin sànmánì Kristẹni, ẹ̀sìn Donatist, ìyẹn àwọn Kristẹni tó yapa kúrò lára Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì gbèrú gan-⁠an lágbègbè yẹn.

Àwọn Donatist yìí ò fẹ́ kí àwọn olú-ọba Róòmù máa dá sí ọ̀ràn ṣọ́ọ̀ṣì. Wọ́n ní àwọn kì í sì ṣe apá kan ayé torí pé ‘ṣọ́ọ̀ṣì mímọ́’ làwọn. Àmọ́ irọ́ gbuu ni wọn pa torí ohun tí wọ́n ń ṣe lábẹ́lẹ̀ kò mọ́ rárá. Wọ́n ń kópa nínú rògbòdìyàn ìṣèlú, wọ́n tún ṣagbátẹrù àwọn àgbẹ̀ tó ń bá àwọn onílẹ̀ àtàwọn agbowó orí fa wàhálà. Èyí mú kí àwọn aláṣẹ bẹnu àtẹ́ lù wọ́n. Ẹnu lásán ni àwọn ẹlẹ́sìn Donatist yìí fi sọ pé àwọn mọ́, wọ́n ò mọ́ síbì kankan rárá.​—Jòhánù 15:19.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́