ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 12/1 ojú ìwé 11
  • Ki Lawon Ohun To Ye Kó O Mo Nipa Odun Keresi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ki Lawon Ohun To Ye Kó O Mo Nipa Odun Keresi?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orísun Kérésìmesì Òde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Kérésìmesì—Èé Ṣe Táwọn Ará Ìlà Oòrùn Ayé Pàápàá Fi Ń Ṣe É?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Keresimesi—Eeṣe Ti Ó Fi Gbajúmọ̀ Tobẹẹ ni Japan?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ṣé Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Ṣe Ọdún Kérésìmesì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 12/1 ojú ìwé 11

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Kí lohun tó yẹ kó O mọ̀ nípa ọdún Kérésì?

Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí gbádùn kí wọ́n máa ṣọdún Kérésì. Àwọn kan máa ń ṣàjọyọ̀ ní àkókò yẹn pẹ̀lú ẹbí àti ọ̀rẹ́, àwọn míì sì máa ń sapá lákòókò náà kí wọ́n lè sún mọ́ Ọlọ́run tàbí kí wọ́n máa ṣètọrẹ àánú fáwọn oníbáárà. Oore ṣíṣe ni gbogbo nǹkan yìí, kò sì sóhun tó burú níbẹ̀. Síbẹ̀, ó yẹ ká ṣọ́ra torí pé ọdún Kérésì ní bó ṣe jẹ́.

Ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ kíyè sí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣọdún Kérésì rò pé ọjọ́ ìbí Jésù làwọn ń ṣe. Àmọ́ àwọn òpìtàn sọ pé kò sẹ́ni tó mọ ọjọ́ pàtó tí wọ́n bí Jésù. Ìwé The Christian Book of Why, sọ pé: “Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò ya ọjọ́ kankan sọ́tọ̀ láti máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù” torí pé wọn ò fẹ́ “ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà.” Ọ̀rọ̀ yìí ò jọni lójú torí Bíbélì ò fìgbà kan rí sọ pé Jésù ṣe ọjọ́ ìbí tara rẹ̀, áńbọ̀sìbọ́sí ọjọ́ ìbí ti ẹlòmíì. Ohun kan tí Jésù pàṣẹ pé ká máa ṣe ni ìrántí ikú rẹ̀.​—Lúùkù 22:19.

Èkejì ni pé àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà lónírúurú ni wọ́n yọ síra, tí wọ́n wá sọ di àṣà Kérésì. Irú bíi Bàbá Kérésì, lílo igi àfòmọ́ àtàwọn igi Kérésì mí ì, fífúnni lẹ́bùn, títan àbẹ́là, oríṣiríṣi nǹkan ọ̀ṣọ́ tí wọ́n máa ń fi ewé igi ṣe àtàwọn orin Kérésì. Nígbà tí ìwé The Externals of the Catholic Church ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àṣà yìí, ó ní: “Nígbà tá a bá ń fún ara wa lẹ́bùn Kérésì, tá a sì ń ṣe ilé àti ṣọ́ọ̀ṣì wa lọ́ṣọ̀ọ́ fún Kérésì, mélòó nínú wa ló mọ̀ pé àṣà ìbọ̀rìṣà là ń tẹ̀ lé?”

“Nígbà tá a bá ń fún ara wa lẹ́bùn Kérésì, tá a sì ń ṣe ilé àti ṣọ́ọ̀ṣì wa lọ́ṣọ̀ọ́ fún Kérésì, mélòó nínú wa ló mọ̀ pé àṣà ìbọ̀rìṣà là ń tẹ̀ lé?” ​—⁠Ìwé náà, The Externals of the Catholic Church

Àmọ́, tó o bá rò pé kò sí ohun tó burú nínú gbogbo nǹkan tá a kà sílẹ̀ yìí, wo ìdí kẹta tó jẹ́ ká mọ ewu tó wà níbẹ̀. Ọlọ́run ò fẹ́ ká fi igbá kan bọ̀kan nínú tó bá di ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, kò tiẹ̀ fẹ́ àṣà ìbọ̀rìṣà èyíkéyìí nínú ìjọsìn mímọ́ rẹ̀ rárá. Jèhófà Ọlọ́run rán wòlíì Ámósì pé kó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìgbọràn pé: “Mo kórìíra, mo kọ àwọn àjọyọ̀ yín . . . Mú yánpọnyánrin àwọn orin rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi.”​—Ámósì 5:​21, 23.

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi sọ̀rọ̀ tó lágbára bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá ṣe ká lè mọ ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Jèróbóámù, ọba wọn àkọ́kọ́ gbé ère ọmọ màlúù wúrà sí ìlú Bẹ́tẹ́lì àti ìlú Dánì. Ó wá sọ pé kàkà kí wọ́n máa lọ jọ́sìn Ọlọ́run bó ṣe yẹ ní tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n kúkú máa jọ́sìn àwọn ère tóun gbé kalẹ̀. Ó tún ṣètò onírúurú àjọyọ̀, ó sì yan àwọn àlùfáà láti bójú tó àwọn ayẹyẹ náà.​—1 Àwọn Ọba 12:​26-33.

Ó lè dà bíi pé ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe yẹn ò burú tó bẹ́ẹ̀ náà, ṣebí torí kí wọ́n lè jọ́sìn Ọlọ́run kí wọn sì ṣèfẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ṣe dá ọgbọ́n yẹn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ tó lágbára tí Ọlọ́run rán wòlíì Ámósì láti sọ jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi wo irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run tún rán wòlíì Málákì láti sọ fún wọn pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:6) Àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí jẹ́ ká rí ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ọdún Kérésì táwọn èèyàn ń ṣe lónìí.

Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ti mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ayẹyẹ yìí, wọ́n pinnu pé àwọn ò ní ṣọdún Kérésì mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹbí àti ọ̀rẹ́, wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ fáwọn aláìní nígbàkigbà tó bá wù wọ́n, tágbára wọn sì gbé e.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́