KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN
Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù
Báwo lo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run? A ti gbé ọ̀nà bíi mélòó kan yẹ̀ wò tá a lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn ni:
Mọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, kó o sì máa lò ó.
Máa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nínú àdúrà lóòrèkóòrè kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.
Wàá sún mọ́ Ọlọ́run tó o bá ń lo orúkọ rẹ̀, tó o bá ń bá ń gbàdúrà sí i, tó ò ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tó o sì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́
Ǹjẹ́ ò ń ṣe gbogbo ohun tá a sọ yìí kó o lè sún mọ́ Ọlọ́run? Àbí àwọn ibì kan wà tó yẹ kó o tún ṣe? Ká sòótọ́, ó gba ìsapá, àmọ́ tó o bá tẹra mọ́ ọn, wàá ṣe é yọrí.
Bọ́rọ̀ ṣe rí lára ọmọ Amẹ́ríkà kan tó ń jẹ́ Jennifer nìyẹn, ó ní: “Gbogbo ìsapá tó o bá ṣe kó o lè sún mọ́ Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìbùkún sì pọ̀ níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wàá túbọ̀ gbára lé Ọlọ́run, wàá sì mọ irú ẹni tó jẹ́, ju gbogbo rẹ̀ lọ, wàá túbọ̀ fẹ́ràn rẹ̀. Kò sí ìgbésí ayé tó tún dára jùyẹn lọ!”
Bó o bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tán láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o lè ṣe fún ẹ. A máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láì gba kọ́bọ̀. Àǹfààní sì wà fún ẹ láti máa wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tó wà ládùúgbò rẹ, ìyẹn ibi tí á ti máa ń jíròrò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tó o bá wá síbẹ̀ wàá rí bá a ṣe máa ń ṣe síra wa bí ọmọ ìyá torí pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a sì mọyì ìrẹ́pọ̀ tá a ní pẹ̀lú rẹ̀.a Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí ìdí tí onísáàmù kan fi sọ pé: “Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.”—Sáàmù 73:28.
a Tó o bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí mọ ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ládùúgbò rẹ, sọ fún ẹni tó fún ẹ ní ìwé yìí tàbí kó o lọ sórí ìkànnì www.jw.org/yo. Wo ìlujá tá a pè ní KÀN SÍ WA tó wà ní ìsàlẹ̀ ojúde ìkànnì náà.