ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 7/1 ojú ìwé 8-11
  • Bí Kristẹndọm Ṣe Di apakan Ayé Yii

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Kristẹndọm Ṣe Di apakan Ayé Yii
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ayé Ṣẹgun Wọn
  • Isin Ijọba Orilẹ-Ede
  • Ilẹ-Ọba ti Ó Pínyà
  • Awọn Ṣọọṣi Protẹstanti ti Orilẹ-Ede
  • Constantine Ńlá—Ṣé Ajàjàgbara fún Ẹ̀sìn Kristẹni Ni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ayédèrú Ijọba kan Yọjú
    “Kí Ijọba Rẹ Dé”
  • Ìsìn Kristian Ìjímìjí àti Orílẹ̀-èdè
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Awọn Kristian Ijimiji ati Ayé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 7/1 ojú ìwé 8-11

Bí Kristẹndọm Ṣe Di apakan Ayé Yii

LẸHIN ìwọ̀n akoko diẹ, Ilẹ-ọba Romu, ninu eyi ti isin Kristian ijimiji ti bẹrẹ, wó lulẹ̀. Ọpọlọpọ awọn opitan jẹwọ pe ìwólulẹ̀ yẹn tun jẹ́ akoko aṣekágbá iṣẹgun fun isin Kristian lori ibọriṣa. Ní sisọ oju-iwoye ti o yatọ, biṣọọbu Anglica naa E. W. Barnes kọwe pe: “Bi ọ̀làjú igbaani ti wólulẹ̀, isin Kristian dáwọ́ jíjẹ́ igbagbọ oníyì-ọlá ti Jesu, tíí ṣe Kristi naa duro: o di isin kan ti o wúlò fun mímú ẹgbẹ-oun-ọgba ayé kan ti o túká wà papọ pẹkipẹki.”—The Rise of Christianity.

Ṣaaju iwolulẹ yẹn, ní awọn ọrundun keji, kẹta, ati ẹkẹrin C.E., ìtàn ṣe akọsilẹ pe ni ọ̀nà pupọ awọn ti wọn jẹwọ pe awọn tẹle Jesu ya ara wọn sọtọ kuro ninu ayé Romu. Ṣugbọn o tun ṣi idagbasoke ipẹhinda ninu ẹkọ-isin, ihuwa, ati eto-ajọ payá, gan-an gẹgẹ bi Jesu ati awọn aposteli rẹ̀ ti sọtẹlẹ. (Matteu 13:36-43; Iṣe 20:29, 30; 2 Tessalonika 2:3-12; 2 Timoteu 2:16-18; 2 Peteru 2:1-3, 10-22) Asẹhinwa-asẹhinbọ ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu ayé Griki-oun-Romu ni a ṣe, awọn kan ti wọn jẹwọ jíjẹ́ Kristian sì tẹwọgba ibọriṣa ayé (iru bii awọn ajọdun rẹ̀ ati ijọsin rẹ̀ ti yèyé abo-ọlọrun ati ọlọrun mẹtalọkan), ọgbọ́n-ìmọ̀-ọ̀ràn atọwọdọwọ rẹ̀ (iru bi igbagbọ ninu aileeku ọkàn), ati iṣabojuto eto-ajọ rẹ̀ (ti a rí ninu ifarahan ẹgbẹ́ awọn alufaa). Iyipada isin Kristian ti a ti sọ dibajẹ yii ni ó fa awọn eniyan gbáàtúù abọriṣa loju mọra ti o sì di ipá kan ti awọn olu-ọba Romu kọ́kọ́ gbiyanju lati parẹ́ ṣugbọn ti wọn wá tẹwọgba lẹhin naa ti wọn sì gbiyanju lati lò fun anfaani tiwọn.

Ayé Ṣẹgun Wọn

Opitan nipa ṣọọṣi Augustus Neander fi ewu ti o wà ninu ibaṣepọ titun yii laaarin “isin Kristian” ati ayé hàn. Bí awọn Kristian bá fi iyara-ẹni-sọtọ wọn kuro ninu ayé rubọ, “iyọrisi rẹ̀ yoo jẹ́ idarudapọ ṣọọṣi pẹlu ayé . . . nipa eyi ti ṣọoṣi yoo padanu ìjẹ́mímọ́ rẹ̀, ati, nigba ti ó bá dabi eyi ti ń ṣẹgun, oun fúnraarẹ̀ ni a ó ṣẹgun,” ni ó kọwe.—General History of the Christian Religion and Church, Idipọ 2, oju-iwe 161.

Ohun ti o ṣẹlẹ niyii. Ni ibẹrẹ ọrundun kẹrin, olu-ọba Romu naa Constantine gbiyanju lati lo isin “Kristian” ti ọjọ rẹ̀ lati so ilẹ-ọba rẹ̀ ti ń túká di koránkorán. Dé ààyè yii, ó fun awọn ti wọn pe araawọn ni Kristian lominira isin ó sì gbé diẹ lara awọn anfaani-iṣẹ ipo alufaa abọriṣa fun ẹgbẹ́ alufaa wọn. Iwe gbédègbéyọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pe: “Constantine mú ṣọọṣi jade wá lati inu ifasẹhin rẹ̀ kuro ninu ayé lati tẹwọgba awọn ẹru-iṣẹ ẹgbẹ-oun-ọgba o sì ṣeranwọ fun ẹgbẹ́-awujọ abọriṣa lati jere itẹwọgba ṣọọṣi.”

Isin Ijọba Orilẹ-Ede

Lẹhin Constantine, Olu-ọba Julian (361 si 363 C.E.) gbé igbesẹ lati lodisi isin Kristian ki o sì mú ibọriṣa padabọsipo. Ṣugbọn ó kùnà, ati ní nǹkan bi 20 ọdun lẹhin naa, Olu-ọba Theodosius I fofinde ibọriṣa o sì fàṣẹ gbé “isin Kristian” onigbagbọ Mẹtalọkan kalẹ gẹgẹ bi isin Ijọba Orilẹ-ede ti Ilẹ-ọba Romu. Pẹlu ìpéye ti o fi ijafafa hàn, opitan ọmọ ilẹ France naa Henri Marrou kọwe pe: “Nigba ti o di opin iṣakoso Theodosius, isin Kristian, tabi lati tubọ ṣe pato, isin Katoliki orthodox, di isin ti a tẹwọgba jakejado ayé Romu.” Isin Katoliki orthodox ti rọ́pò isin Kristian tootọ o sì ti di “apakan ayé.” Isin Ijọba Orilẹ-ede yii yatọ patapata gbáà si isin awọn ọmọlẹhin Jesu ti ijimiji, awọn ẹni ti oun sọ fun pe: “Ẹyin kìí ṣe ti ayé.”—Johannu 15:19.

Opitan ati ọlọgbọn-imọ-ọran ọmọ ilẹ France naa Louis Rougier kọwe pe: “Bi o ti ń tankalẹ, isin Kristian la awọn iyipada ṣiṣajeji kọja debi ti o fi di eyi ti a kò lè dámọ̀ mọ́. . . . Awọn ṣọọṣi atijọ ti awọn talaka, eyi ti a ń bojuto nipasẹ ọrẹ-aanu, di ṣọọṣi ajagunmólú ti o wá fọwọsowọpọ pẹlu awọn alaṣẹ ayé ti o wà nigba ti oun kò lè jẹgaba lé wọn lori.”

Ni ibẹrẹ ọrundun karun-un C.E., “Ẹni Mímọ́” Roman Katoliki naa Augustine kọ lajori iwe rẹ̀ The City of God. Ninu rẹ̀ ni ó ti ṣapejuwe awọn ilu-nla meji, “ti Ọlọrun ati ti ayé.” Ǹjẹ́ iwe yii ha tẹnumọ iyasọtọ ti o wà laaarin awọn Katoliki ati ayé bi? Kò rí bẹẹ. Ọjọgbọn Latourette sọ pe: “Pẹlu otitọ inu, Augustine mọ̀ [pé] awọn ilu-nla meji naa, ti ayé ati ti ọ̀run, ni a dapọmọra.” Augustine fi kọni pe “Ijọba Ọlọrun ti bẹrẹ ni ayé yii ná pẹlu igbekalẹ ṣọọṣi [Katoliki].” (The New Encyclopædia Britannica, Macropædia, Idipọ 4, oju-iwe 506) Nipa bayii, ohunkohun ti o wù ki o lè ti jẹ́ ète Augustine lakọọkọ, awọn àbá-èrò-orí rẹ̀ ní iyọrisi mímú kí Ṣọọṣi Katoliki tubọ jinlẹ sii ninu alaamọri eto oṣelu ayé yii.

Ilẹ-Ọba ti Ó Pínyà

Ní 395 C.E., nigba ti Theodosius I kú, Ilẹ-ọba Romu ni a pín si meji labẹ ofin. Ilẹ-ọba iha Ila-oorun, tabi Byzantine, ní olu-ilu rẹ̀ ní Constantinople (Byzantium tẹlẹri, Istanbul nisinsinyi), ati Ilẹ-ọba iha Iwọ-oorun, ní olu-ilu rẹ̀ (lẹhin 402 C.E.) ní Ravenna, Italy. Gẹgẹ bi abajade rẹ̀, Kristẹndọm di eyi ti a pínníyà niti oṣelu ati pẹlu niti isin. Niti ibatan laaarin Ṣọọṣi ati Ijọba Orilẹ-ede, ṣọọṣi ti o wà ni Ilẹ-ọba iha Ila-oorun tẹle àbá-èrò-orí Eusebius ti Kesarea (alájọgbáyé Constantine Nla). Bí kò ti náání ilana Kristian nipa iyasọtọ gédégédé kuro ninu ayé, Eusebius ronu pe bi olu-ọba ati ilẹ̀-ọba naa bá di Kristian, Ṣọọṣi ati Ijọba Orilẹ-ede yoo di ẹgbẹ́ awujọ Kristian kanṣoṣo, ti olu-ọba yoo sì maa ṣe gẹgẹ bi aṣoju Ọlọrun lori ilẹ̀-ayé. Lapapọ, ipo-ibatan yii laaarin Ṣọọṣi ati Ijọba Orilẹ-ede ni awọn ṣọọṣi Orthodox ti iha Ila-oorun ti tẹle la awọn ọrundun kọja. Ninu iwe rẹ̀ The Orthodox Church, Timothy Ware, biṣọọbu Orthodox, fi abajade naa hàn pe: “Ifẹ orilẹ-ede ẹni ti jẹ́ okunfa iparun Orthodox fun awọn ọrundun mẹwaa ti o kọja.”

Ní iha Iwọ-oorun, olu-ọba Romu ti o kẹhin ni a yọ kuro nípò ní 476 C.E. lati ọwọ́ awọn akóguntini ẹ̀yà ti Germany. Eyi sami si opin Ilẹ-ọba Romu iha Iwọ-oorun. Nipa alafo oṣelu ti o tẹlee, iwe gbédègbéyọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pe: “Agbara titun kan ni a gbekalẹ: Ṣọọṣi Romu, ṣọọṣi biṣọọbu Romu. Ṣọọṣi yii gbagbọ pe oun ni oun gba ipo Ilẹ-ọba Romu ti kò si mọ́.” Iwe gbédègbẹ́yọ̀ yii tẹsiwaju lati wi pe: “Awọn poopu Romu . . . sún awọn ẹ̀tọ́ akoso ṣọọṣi naa siwaju rekọja awọn ààlà ṣọ́ọ̀ṣì-òun-ìlú ó sì mú àbá-èrò-orí ti a pe ni idà meji gbèrú, ni sisọ pe Kristi fun poopu naa ní kìí ṣe kiki agbara tẹmi lori ṣọọṣi nikan ṣugbọn agbara ti ayé paapaa lori awọn ijọba ayé.”

Awọn Ṣọọṣi Protẹstanti ti Orilẹ-Ede

Lati ibẹrẹ de opin ni Aarin Ìgbà Ọ̀làjú, awọn isin Orthodox ati Roman Katoliki ti ń baa bọ̀ lati lọwọ ninu oṣelu, rìkíṣí ayé, ati ogun lọna giga. Ǹjẹ́ awọn Iṣatunṣe Protẹstanti ti ọrundun kẹrindinlogun samisi ipada sí isin Kristian tootọ, ni iyasọtọ kuro ninu ayé bi?

Bẹẹkọ. A kà ninu iwe gbédègbéyọ̀ The New Encyclopædia Britannica pe: “Awọn Alatunṣe Protẹstanti ẹlẹkọọ atọwọdọwọ ti Luther, Calvin, ati Anglica . . . ṣì wà ní isopọmọra gbọyingbọyin pẹlu awọn oju-iwoye Augustine, ẹni ti wọn nimọlara iṣetimọtimọ pataki pẹlu ikọnilẹkọọ isin rẹ̀. . . . Ọkọọkan lara awọn ẹkọ atọwọdọwọ Protẹstanti mẹta pato ti Europe ọrundun kẹrindinlogun . . . rí itilẹhin lati ọ̀dọ̀ awọn alaṣẹ ayé ni Saxony [aarin gbungbun Germany], Switzerland, ati England ó sì duro ní ipò kan-naa ti ó ṣeéfiwéra pẹlu eyi ti ijọba orilẹ-ede wà ninu ṣọọṣi akoko sanmani agbedemeji.”

Dipo kí wọn mú ipada si isin Kristian tootọ wá, awọn Iṣatunṣe naa mú ọpọlọpọ awọn ṣọọṣi jakejado orilẹ-ede tabi ti ààlà ipinlẹ wá sojutaye awọn ti wọn ti wa ojurere lọna ẹ̀tàn pẹlu awọn ijọba orilẹ-ede oṣelu ti wọn sì fi taapọntaapọn kọ́wọ́tì wọn lẹhin ninu awọn ogun wọn. Niti tootọ, awọn ṣọọṣi Katoliki ati Protẹstanti ti ṣagbátẹrù awọn ogun isin. Ninu iwe rẹ̀ An Historian’s Approach to Religion, Arnold Toynbee kọwe nipa iru awọn ogun bẹẹ pe: “Wọn ṣe ìgbésójútáyé awọn Katoliki ati Protẹstanti ni awọn ilẹ France, Netherland, Germany, ati Ireland, ati awọn ẹ̀ya Protẹstanti ní England ati Scotland ti wọn jẹ́ alábàádíje, ninu iwa oníkà ti gbigbiyanju lati tẹ ara wọn rì pẹlu ipá ogun.” Awọn ìwàyá-ìjà ode-oni ti wọn ń pín Ireland ati Yugoslavia tẹlẹri níyà fihàn pe awọn ṣọọṣi Roman Katoliki, Orthodox, ati Protẹstanti ṣì ń lọwọ ninu awọn alaamọri ayé yii lọna jijinlẹ.

Ǹjẹ́ gbogbo eyi ha tumọsi pe isin Kristian tootọ, ti a yasọtọ kuro ninu ayé, kò sí lori ilẹ̀-ayé lonii mọ́ ni bi? Ọrọ-ẹkọ ti o tẹlee yoo dahun ibeere yẹn.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]

BI “ISIN KRISTIAN” ṢE DI ISIN IJỌBA ORILẸ-EDE

ISIN Kristian ni a kò reti pe ki ó jẹ́ apakan ayé yii lae. (Matteu 24:3, 9; Johannu 17:16) Sibẹ, awọn iwe ìtàn sọ fun wa pe ní ọrundun kẹrin C.E., “isin Kristian” di isin Ijọba Orilẹ-ede labẹ ofin ní Ilẹ-ọba Romu. Bawo ni eyi ṣe wáyé?

Lati orí Nero (54 si 68 C.E.) lọ dé ọrundun kẹta C.E., gbogbo awọn olu-ọba Romu kópa yala nipa ṣiṣe inunibini si awọn Kristian ni taarata tabi fífààyè gba ṣiṣenunibini si wọn. Gallienus (253 si 268 C.E.) ni olu-ọba Romu akọkọ lati gbé ipolongo ifaayegbani jade fun wọn. Àní nigba yẹn paapaa, isin Kristian jẹ́ isin ti a kàléèwọ̀ jakejado ilẹ-ọba naa. Lẹhin Gallienus, inunibini naa ń baa lọ, ati labẹ Diocletian (284 si 305 C.E.) ati awọn arọ́pò rẹ̀ ti o tẹlee, ó tilẹ tubọ lekoko sii.

Ikorita iyipada naa dé ni ibẹrẹ ọrundun kẹrin pẹlu ohun ti a fẹnu lasan pè ni iyilọkanpada Olu-ọba Constantine I sí isin Kristian. Nipa “iyilọkanpada” yii, iwe gbédègbẹ́yọ̀ èdè French naa Théo—Nouvelle encyclopédie catholique (Théo—New Catholic Encyclopedia) sọ pe: “Constantine jẹwọ pe oun jẹ́ Kristian olu-ọba kan. Niti gidi, a baptisi rẹ̀ kiki lori ibusun iku rẹ̀.” Bi o tilẹ ri bẹẹ, ní 313 C.E., Constantine ati ajumọ jẹ́ olu-ọba rẹ̀, Licinius, gbé ofin kan jade ti o fun awọn Kristian ati awọn abọriṣa bakan-naa ní ominira isin. Iwe gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pe: “Imugbooro ominira ijọsin fun awọn Kristian nipasẹ Constantine, eyi ti o fihàn pe isin Kristian ni a mọ̀ lọna ti a fàṣẹ si gẹgẹ bi religio licita [ijọsin ti o bofinmu] yàtọ̀ sí isin abọriṣa, jẹ́ igbesẹ oniyiipada tegbotigaga.”

Bi o ti wu ki o ri, iwe gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica polongo pe: “Oun [Constantine] kò fi isin Kristian ṣe isin ilẹ-ọba naa.” Opitan ọmọ ilẹ France naa Jean-Rémy Palanque, mẹmba Ẹgbẹ́ Àpilẹ̀dásílẹ̀ ti ilẹ France, kọwe pe: “Ijọba Orilẹ-ede Romu . . . bi o ti wu ki o ri, wà ní oloriṣa labẹ àṣẹ. Constantine sì nìyí, nigba ti ó ń dìrọ̀ mọ́ isin Kristi, kò fi opin si ipo naa.” Ninu iwe naa The Legacy of Rome, Ọjọgbọn Ernest Barker sọ pe: “[Ijagunmolu Constantine] kò yọrisi ifidimulẹ isin Kristian lẹsẹkẹsẹ gẹgẹ bi isin Ijọba Orilẹ-ede. Ó tẹ́ Constantine lọ́rùn lati rí isin Kristian gẹgẹ bi ọ̀kan lara ijọsin awọn ara-ilu ni ilẹ-ọba naa. Fun aadọrin ọdun ti o tẹlee awọn ààtò ibọriṣa atijọ ni a ń ṣe labẹ ofin ní Romu.”

Nitori naa lori koko yii “isin Kristian” jẹ́ isin ti o bá ofin mu ni Ilẹ-ọba Romu. Nigba wo ní ẹkunrẹrẹ ero-itumọ ọ̀rọ̀ naa, ni o di isin Ijọba Orilẹ-ede labẹ ofin? A kà ninu iwe gbédègbẹ́yọ̀ naa New Catholic Encyclopedia pe: “Ilana [Constantine] ni awọn arọpo rẹ ń bá lọ ayafi Julian [361 si 363 C.E.], ẹni ti iku rẹ̀ mú iṣenunibini rẹ̀ sí isin Kristian wá sopin lojiji. Nikẹhin, ni apa idamẹrin ti o kẹhin ọrundun kẹrin, Theodosius Nla [379 si 395 C.E.] sọ isin Kristian di isin Ilẹ-ọba naa ti o bofinmu ti ó sì tẹ ijọsin oriṣa ti awọn ara-ilu rì.”

Nigba ti ó ń fẹrii eyi hàn ti ó sì ń ṣí ohun ti isin Ijọba Orilẹ-ede yii jẹ́ gan-an paya, akẹkọọ Bibeli jinlẹ ati opitan F. J. Foakes Jackson kọwe pe: “Labẹ Constantine, isin Kristian ati ilẹ-ọba Romu ni a mú wọnu ibaṣepọ. Labẹ Theodosius a so wọn pọ̀ ṣọ̀kan. . . . Lati isinsinyi lọ orukọ naa Katoliki ni a nilati pamọ́ fun awọn ti wọn bọla fun Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ pẹlu ọlá ọgbọọgba. Gbogbo ilana isin olu-ọba yii pata ni a dari si ọ̀nà yii, ti o si yọrisi Igbagbọ Katoliki ti o wá di isin awọn ará Romu kanṣoṣo naa ti ó bá ofin mu.”

Jean-Rémy Palanque kọwe pe: “Nigba ti Theodosius ń wọ̀jàkadì pẹlu ibọriṣa, ó tun ní ojurere sí Ṣọọṣi orthodox [Katoliki]; ofin rẹ̀ ti 380 C.E. paṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ-abẹ rẹ̀ lati jẹwọ igbagbọ Poopu Damasus ati biṣọọbu [onigbagbọ Mẹtalọkan] ti Alexandria ó sì fi ominira isin du awọn ti kò tẹlọrun. Ajọ-igbimọ nla ti Constantinople (381) tun dá gbogbo àdámọ̀ lẹbi, olu-ọba naa sì rí sii pe kò si biṣọọbu kankan ti yoo tì wọn lẹhin. Isin Kristian [onigbagbọ Mẹtalọkan] ti Nicaea ti di isin Ijọba Orilẹ-ede daradara gan-an . . . Ṣọọṣi naa wà ní iṣọkan timọtimọ pẹlu ti Ijọba Orilẹ-ede ó sì gbadun itilẹhin àyàsọ́tọ̀ gédégbé rẹ̀.”

Nipa bayii, kìí ṣe isin Kristian aláìládàlù ti ọjọ́ awọn aposteli ni o di isin Ijọba Orilẹ-ede Ilẹ-ọba Romu. Isin Katoliki ẹlẹkọọ Mẹtalọkan ti ọrundun kẹrin, ti a fipá gbekari awọn eniyan nipasẹ Olu-ọba Theodosius I tí Ṣọọṣi Roman Katoliki sì ń ṣe, ni eyi ti o jẹ apakan ayé niti tootọ nigba naa gẹgẹ bi o ti rí nisinsinyi.

[Credit Line]

Olu-ọba Theodosius I: Real Academia de la Historia, Madrid (Foto Oronoz)

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

Scala/Art Resource, N.Y.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́