Constantine Ńlá—Ṣé Ajàjàgbara fún Ẹ̀sìn Kristẹni Ni?
Olú Ọba ilẹ̀ Róòmù náà, Constantine, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn kéréje tí ìtàn ti fi àpèlé náà, “Ńlá,” ṣorúkọ wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Kirisẹ́ńdọ̀mù ti fi àwọn gbólóhùn náà, “ẹni mímọ́,” “àpọ́sítélì kẹtàlá,” “ẹni mímọ́ alábàádọ́gba àwọn àpọ́sítélì,” àti ‘ẹni tí Ọlọ́run yàn láti ṣàṣeparí ìyípadà gígalọ́lá jù lọ ní gbogbo ilẹ̀ ayé,’ kún un. Láti ojú ìwòye tí ó yàtọ̀ pátápátá, àwọn kan ṣàpèjúwe Constantine gẹ́gẹ́ bí “atẹ̀jẹ̀sílẹ̀, tí ìwà búburú lílékenkà kó àlèébù bá, tí ó sì kún fún ẹ̀tàn, . . . òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ paraku, tí ó jẹ̀bi ìwà ọ̀daràn burúkú.”
A TI fi kọ́ ọ̀pọ̀ aláfẹnujẹ́ Kristẹni pé Constantine Ńlá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó ṣe ẹ̀sìn Kristẹni láǹfààní jù lọ. Wọ́n gbóṣùbà fún un, fún gbígba àwọn Kristẹni lọ́wọ́ ipò ìnira inúnibíni Róòmù, tí ó sì fún wọn ní òmìnira ìsìn. Síwájú sí i, ó jẹ́ ìgbàgbọ́ tí ó wọ́pọ̀ pé, ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, tí ó fi òtítọ́ tọpasẹ̀ rẹ̀, tí ó ní ìfẹ́-ọkàn lílágbára láti mú ẹ̀sìn Kristẹni tẹ̀ síwájú. Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ìlà Oòrùn àti Ṣọ́ọ̀ṣì Coptic ti polongo Constantine àti ìyá rẹ̀, Helena, ní “ẹni mímọ́.” Wọ́n ń ṣàjọyọ̀ wọn ní June 3 tàbí ní May 21, ní ìbámu pẹ̀lú kàlẹ́ńdà ti ṣọ́ọ̀ṣì.
Ta tilẹ̀ ni Constantine Ńlá? Ipa wo ni ó kó nínú ìdàgbàsókè ẹ̀sìn Kristẹni lẹ́yìn àkókò àwọn àpọ́sítélì? Yóò jẹ́ ohun tí ń lani lóye gidigidi bí a bá jẹ́ kí ìtàn àti àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
Constantine Inú Ìtàn
A bí Constantine, ọmọ Constantius Chlorus, ní Naissus ní Serbia, ní nǹkan bí ọdún 275 Sànmánì Tiwa. Nígbà tí bàbá rẹ̀ di olú ọba àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ ìwọ̀ oòrùn Róòmù ní ọdún 293 Sànmánì Tiwa, ó ń jà lọ́wọ́ nínú ogun Danube, lábẹ́ àṣẹ Olú Ọba Galerius. Constantine padà sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀ tí ń kú lọ ní Britain, ní ọdún 306 Sànmánì Tiwa. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú, ẹgbẹ́ ọmọ ogun sọ Constantine di olú ọba.
Ní àkókò yẹn, àwọn ẹni márùn-ún mìíràn sọ pé àwọn náà jẹ́ Olú Ọba. Àkókò ogun abẹ́lé tí kò dáwọ́ dúró ni ọdún 306 sí 324 Sànmánì Tiwa jẹ́, lẹ́yìn èyí tí Constantine wá di olú ọba kan ṣoṣo láìní ẹni tí ń bá a dù ú. Ìjagunmólú nínú ogun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mú kí orúkọ Constantine wọnú ìwé ìtàn ilẹ̀ Róòmù, ó sì sọ ọ́ di alákòóso kan ṣoṣo ti Ilẹ̀ Ọba Róòmù.
Ní ọdún 312 Sànmánì Tiwa, Constantine ṣẹ́gun ọ̀tá rẹ̀, Maxentius, nínú ogun Afárá Milvian, lẹ́yìn òde Róòmù. Àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Kristẹni sọ pé, nígbà ogun yẹn, àgbélébùú tí iná ń yọ lára rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ Látìn náà, In hoc signo vinces, tí ó túmọ̀ sí “Jàjàṣẹ́gun pẹ̀lú àmì yìí,” wà lára rẹ̀, fara hàn lábẹ́ oòrùn. Wọ́n tún sọ pé, a sọ fún Constantine nínú àlá láti fọ̀dà kọ àwọn lẹ́tà méjì àkọ́kọ́ tí ó bẹ̀rẹ̀ orúkọ Kristi ní èdè Gíríìkì sára apata àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ìtàn yìí kò bá ìtòtẹ̀léra ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn mu. Ìwé náà, A History of Christianity, sọ pé: “Ẹ̀rí nípa àkókò gan-an tí ìran yìí wáyé, ibi tí ó ti wáyé, àti kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ takora.” Nígbà tí wọ́n ń kí Constantine káàbọ̀ sí Róòmù, Ìgbìmọ̀ Gíga Jù Lọ ti àwọn abọ̀rìṣà polongo rẹ̀ ní olórí Olú Ọba àti Pontifex Maximus, ìyẹn ni, baba awo ilẹ̀ ọba náà.
Ní ọdún 313 Sànmánì Tiwa, Constantine lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Olú Ọba Licinius, alákòóso àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ ìlà oòrùn. Nípasẹ̀ Òfin ti Milan, àwọn méjèèjì polongo òmìnira ìjọsìn àti ẹ̀tọ́ ọgbọọgba fún gbogbo àwùjọ ìsìn. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ òpìtàn kò tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì àkọsílẹ̀ yìí, wọ́n sọ pé lẹ́tà àṣẹ lásán tí a ń fi ránṣẹ́ déédéé ni, pé kì í ṣe àkọsílẹ̀ pàtàkì ti ìjọba, tí ń fi ìyípadà nínú ìlànà rẹ̀ fún ẹ̀sìn Kristẹni hàn.
Láàárín ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, Constantine ṣẹ́gun Licinius, alábàádíje rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó ṣẹ́kù, ó sì di alákòóso ayé Róòmù, tì kò ní alábàádíje. Ní ọdún 325 Sànmánì Tiwa, nígbà tí kò tí ì ṣe batisí, ó ṣalága àpérò àkọ́kọ́ ti ṣọ́ọ̀ṣì “Kristẹni” lórí wíwá ìṣọ̀kan àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àgbáyé, tí ó dẹ́bi fún ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Arius, tí ó sì mú àkọsílẹ̀ gbólóhùn nípa àwọn ìgbàgbọ́ ṣíṣekókó, tí a pè ní Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ Nicaea, jáde.
Constantine ṣàìsàn burúkú kan ní ọdún 337 Sànmánì Tiwa. A batisí rẹ̀ nígbà tí ó wà ní bèbè ikú, ó sì kú lẹ́yìn náà. Lẹ́yìn ikú rẹ̀, Ìgbìmọ̀ Gíga Jù Lọ kà á mọ́ àwọn ọlọ́run Ilẹ̀ Róòmù.
Ipa Ìsìn Nínú Ìwéwèé Àfìṣọ́raṣe Constantine
Ní títọ́ka sí ìṣarasíhùwà tí àwọn olú ọba Róòmù ti ọ̀rúndún kẹta àti ìkẹrin ní gbogbogbòò ní sí ìsìn, ìwé náà, Istoria tou Ellinikou Ethnous (Ìtàn Orílẹ̀-Èdè Gíríìkì) sọ pé: “Kódà nígbà tí àwọn tí ó wà lórí ìtẹ́ olú ọba kò tilẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ jíjinlẹ̀ sí ìsìn, wọ́n rí i pé ó pọn dandan láti fún un ní ipò pàtàkì nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìṣèlú wọn, ó kéré tán, kí ọ̀ràn ìsìn hàn nínú ìgbésẹ̀ wọn, láti ṣe ohun tí àwọn ènìyàn fẹ́.”
Dájúdájú, Constantine jẹ́ ọkùnrin tí ó bá àsìkò rẹ̀ yí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀, ó nílò ìtìlẹyìn “àtọ̀runwá,” àwọn ọlọ́run Róòmù, tí wọ́n ti ń di akúrẹtẹ̀, kò sì lè pèsè èyí. Ilẹ̀ Ọba náà, títí kan ẹ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ètò rẹ̀ mìíràn, ń ṣubú, a sì nílò ohun tuntun, tí ó lè fún un lágbára, láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Hidria sọ pé: “Constantine nífẹ̀ẹ́ nínú ẹ̀sìn Kristẹni ní pàtàkì, kì í ṣe kìkì nítorí pé ó ti ìṣẹ́gun rẹ̀ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n nítorí pé ó tún kọ́wọ́ ti ìṣàtúntò ilẹ̀ ọba rẹ̀ lẹ́yìn. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni tí ó wà káàkiri níbi gbogbo wá di alátìlẹ́yìn rẹ̀ ní ti ìṣèlú. . . . Ó fi àwọn bíṣọ́ọ̀bù jàǹkànjàǹkàn àkókò yẹn sọgbà yí ara rẹ̀ ká . . . , ó sì rọ̀ wọ́n láti pa ìṣọ̀kan wọn mọ́.”
Constantine mọ̀ pé òun lè lo ìsìn “Kristẹni”—bí ó tilẹ̀ jẹ́ apẹ̀yìndà, tí ìwà ìbàjẹ́ sì kún inú rẹ̀ nígbà náà—lọ́nà gbígbéṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ipá tí ń fúnni lókun, tí ó ń mú ìṣọ̀kan wá, láti mú kí ìwéwèé ńlá tí ó ti ṣe láti jẹ gàba léni lórí gẹ́gẹ́ bí olú ọba kẹ́sẹ járí. Ní lílo ìpìlẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni apẹ̀yìndà láti rí ìtìlẹ́yìn nínú mímú góńgó ìṣèlú rẹ̀ tẹ̀ síwájú, ó pinnu láti mú àwọn ènìyàn náà ṣọ̀kan lábẹ́ “ẹ̀sìn kátólíìkì,” kan ṣoṣo tàbí ìsìn kan tí ó kárí ayé. A fún àwọn àṣà àti ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà ní orúkọ “Kristẹni.” A sì fún àwọn àlùfáà “Kristẹni” ní ipò, owó oṣù, àti agbára tí a fún àwọn baba awo.
Ní wíwá ìṣọ̀kan ìsìn fún àǹfààní ìṣèlú, ojú ẹsẹ̀ ni Constantine máa ń bi ìyapa èyíkéyìí ṣubú, kò gbé èyí ka ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí ó jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó gbé e ka ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn fọwọ́ sí. Àìfohùnṣọ̀kan ṣọ́ọ̀ṣì “Kristẹni” tí ó ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, ní ti ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́, fún un láǹfààní láti dá sí i, bí ẹni pé òun ni alárinà “tí Ọlọ́run rán.” Nípasẹ̀ ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀ya ẹ̀sìn Donatist ní Àríwá Áfíríkà àti àwọn ọmọlẹ́yìn Arius ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ ọba náà, kíá ni ó mọ̀ pé ìyíléròpadà nìkan kò tó láti mú ìgbàgbọ́ tí ó ṣọ̀kan, tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ wá.a Ìgbìdánwò rẹ̀ láti yanjú àríyànjiyàn ẹ̀kọ́ Arius ni ó mú kí ó pe àpérò ti wíwá ìṣọ̀kan ṣọ́ọ̀ṣì kárí ayé fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn ṣọ́ọ̀ṣì.—Wo àpótí “Constantine àti Àpérò Nicaea.”
Nípa Constantine, òpìtàn Paul Johnson sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé ọ̀kan lára ìdí pàtàkì tí ó fi fàyè gba ẹ̀sìn Kristẹni ni pé ó fún òun àti Orílẹ̀-èdè náà ní àǹfààní láti darí ìlànà Ṣọ́ọ̀ṣì lórí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́.”
Ó Ha Fìgbà Kan Rí Di Kristẹni Bí?
Johnson sọ pé: “Constantine kò fìgbà kan rí fi oòrùn tí ó ń bọ sílẹ̀, kò sì pa àwòrán oòrùn tí ń bẹ lára owó ẹyọ rẹ̀ rẹ́.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Catholic Encyclopedia sọ pé: “Constantine fojú rere kan náà hàn sí ìsìn méjèèjì. Gẹ́gẹ́ bí pontifex maximus, ó bójú tó ìjọsìn ìbọgibọ̀pẹ̀, ó sì dáàbò bo ẹ̀tọ́ rẹ̀.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Hidria sọ pé: “Constantine kò fìgbà kan rí di Kristẹni.” Ó sì fi kún un pé: “Eusebius ti Kesaréà, tí ó kọ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀, sọ pé ó di Kristẹni ní àkókò tí ó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀. Èyí kò jámọ́ nǹkan kan, nítorí ní ọjọ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ náà, [Constantine] rúbọ sí Súúsì, nítorí tí ó tún ní orúkọ oyè náà, Pontifex Maximus.”
Títí di ọjọ́ ikú rẹ̀ ní ọdún 337 Sànmánì Tiwa, Constantine jẹ́ orúkọ oyè ìbọ̀rìṣà náà, Pontifex Maximus, olórí pátápátá nínú ọ̀ràn ìsìn. Ní ti batisí rẹ̀, ó bọ́gbọ́n mu láti béèrè pé, Ojúlówó ìrònúpìwàdà àti ìyípadà ha ṣáájú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti béèrè bí? (Ìṣe 2:38, 40, 41) Ó ha jẹ́ ìrìbọmi pátápátá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ Constantine fún Jèhófà Ọlọ́run bí?—Fi wé Ìṣe 8:36-39.
Ṣé “Ẹni Mímọ́” Ni?
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ó tọ́ kí a pe Constantine ní ẹni Ńlá nítorí àṣeparí rẹ̀, kì í ṣe nítorí irú ẹni tí ó jẹ́. Bí a bá gbé e karí ìwà rẹ̀, ní tòótọ́, yóò wà lára àwọn tí kò tóótun rárá nínú gbogbo àwọn tí a lo orúkọ náà [Ńlá] fún, ní ìgbà àtijọ́ tàbí lóde òní.” Ìwé náà, A History of Christianity, sì fi tó wa létí pé: “Àwọn ìròyìn àtẹ̀yìnwá sọ nípa ìbínú ṣùṣù rẹ̀ àti ìwà òǹrorò rẹ̀ nígbà tí ó bá bínú. . . . Ẹ̀mí ènìyàn kò jọ ọ́ lójú . . . Bí ó ti ń dàgbà sí i ni ìgbésí ayé rẹ̀ níkọ̀kọ̀ túbọ̀ ń burú sí i.”
Ó ṣe kedere pé, Constantine kò níwà ọmọlúwàbí rárá. Olùwádìí ìtàn kan sọ pé, “ìbínú fùfù rẹ̀ ni ìdí pàtàkì tí ó fi ń hùwà ọ̀daràn.” (Wo àpótí “Ìpànìyàn Nínú Ìdílé Ọba.”) Òpìtàn H. Fisher nínú ìwé rẹ̀, History of Europe, jiyàn pé, Constantine kò “níwà Kristẹni.” Àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ kò fi hàn pé ó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ kan, tí ó ti gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀, ẹni tí a lè rí èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run—ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu lára rẹ̀.—Kólósè 3:9, 10; Gálátíà 5:22, 23.
Àbájáde Àwọn Ìsapá Rẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí Pontifex Maximus ìbọ̀rìṣà—tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ olórí ìsìn ti Ilẹ̀ Ọba Róòmù—Constantine gbìyànjú láti kó àwọn bíṣọ́ọ̀bù ti ṣọ́ọ̀ṣì apẹ̀yìndà sòdí. Ó nawọ́ ipò ńlá, òkìkí, àti ọrọ̀ sí wọn, gẹ́gẹ́ bí olóyè ìsìn Orílẹ̀-èdè Róòmù. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Catholic Encyclopedia jẹ́wọ́ pé: “Àwọn bíṣọ́ọ̀bù kan, tí ògo oyè náà ti fọ́ lójú, tilẹ̀ ṣàṣejù débi gbígbóṣùbà fún olú ọba náà gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́, wọ́n sì sọ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò jọba nínú àwọn ọ̀run, gẹ́gẹ́ bíi ti Ọmọ Ọlọ́run.”
Bí ẹ̀sìn Kristẹni apẹ̀yìndà ti jèrè ojú rere ìjọba olóṣèlú, ó túbọ̀ ń di apá kan ayé yìí, apá kan ètò ayé ìsinsìnyí, ó sì sún lọ kúrò nínú ẹ̀kọ́ Jésù Kristi. (Jòhánù 15:19; 17:14, 16; Ìṣípayá 17:1, 2) Nítorí èyí, a da àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà èké—Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn, ọ̀run àpáàdì, pọ́gátórì, àdúrà fún àwọn òkú, ìlò ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà, àwòrán, ère, àti irú nǹkan bẹ́ẹ̀—pọ̀ mọ́ “ẹ̀sìn Kristẹni.”—Fi wé 2 Kọ́ríńtì 6:14-18.
Láti ọ̀dọ̀ Constantine, ṣọ́ọ̀ṣì tún jogún ìtẹ̀sí láti jẹ gàba léni lórí. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, Henderson àti Buck, sọ pé: “A ba ìjẹ́mímọ́ Ìhìn Rere jẹ́, a mú àwọn ààtò àti ayẹyẹ onípọ̀pọ̀ṣìnṣìn wọlé, a fi oyè àti àwọn àjẹmọ́nú ti ayé dá àwọn olùkọ́ ẹ̀sìn Kristẹni lọ́lá, àti pé lọ́nà púpọ̀ jù lọ, a sọ Ìjọba Kristi di ìjọba ayé yìí.”
Níbo Ni Ẹ̀sìn Kristẹni Tòótọ́ Wà?
Àwọn òkodoro ìtàn ṣí òtítọ́ tí ó wà lẹ́yìn “jíjẹ́ ẹni ńlá” Constantine payá. Dípò jíjẹ́ ohun tí Jésù Kristi, Orí ìjọ Kristẹni tòótọ́, dá sílẹ̀, Kirisẹ́ńdọ̀mù, lápá kan, jẹ́ àbájáde ìlépa ìṣèlú àti ìfọgbọ́n ẹ̀wẹ́ darí ọ̀ràn láti ọwọ́ olú ọba abọ̀rìṣà kan. Lọ́nà yíyẹ wẹ́kú, òpìtàn Paul Johnson béèrè pé: “Ṣé ilẹ̀ ọba náà ni ó juwọ́ sílẹ̀ fún ẹ̀sìn Kristẹni ni, àbí ẹ̀sìn Kristẹni ni ó fara rẹ̀ wọ́lẹ̀ lọ́dọ̀ ilẹ̀ ọba náà?”
A lè ran gbogbo àwọn tí ó fẹ́ rọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Kristẹni mímọ́ gaara ní tòótọ́ lọ́wọ́ láti mọ ìjọ Kristẹni tòótọ́ lónìí, kí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ ọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti ṣe tán láti ran àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ́wọ́ láti dá ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀, kí wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run ní ọ̀nà tí ó tẹ́wọ́ gbà.—Jòhánù 4:23, 24.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹ̀sìn Donatist jẹ́ ẹ̀ya ẹ̀sìn “Kristẹni” kan ti ọ̀rúndún kẹrin àti ìkarùn-ún Sànmánì Tiwa. Àwọn ẹlẹ́sìn náà sọ pé ìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ sákírámẹ́ńtì sinmi lórí ìwà rere òjíṣẹ́ náà, àti pé ṣọ́ọ̀ṣì gbọ́dọ̀ yọ àwọn tí ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kúrò nínú jíjẹ́ mẹ́ńbà wọn. Ẹgbẹ́ Arius jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn “Kristẹni” kan ti ọ̀rúndún kẹrin, tí ó sọ pé Jésù Kristi kì í ṣe Ọlọ́run. Arius kọ́ni pé a kò bí Ọlọ́run, kò sì ní ìbẹ̀rẹ̀. A kò lè sọ pé Ọmọ jẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀nà tí Bàbá gbà jẹ́ ẹ, nítorí pé a bí i ni. Ọmọ kò wà láti ayérayé, ṣùgbọ́n, a dá a, ó sì wà nípasẹ̀ ìfẹ́ Bàbá.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Constantine àti Àpérò Nicaea
Ipa wo ni Olú Ọba Constantine, tí kò ṣe batisí, kó nínú Àpérò Nicaea? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Constantine fúnra rẹ̀ ni ó ṣe alága, tí ó ń fi aápọn darí ìjíròrò náà . . . Nítorí ẹ̀rù olú ọba tí ó bà wọ́n, gbogbo bíṣọ́ọ̀bù pátá, àfi àwọn méjì péré, buwọ́ lu ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ náà, kò ti inú ọ̀pọ̀ wá láti ṣe bẹ́ẹ̀.”
Lẹ́yìn ìjiyàn gbígbóná janjan lórí ìsìn fún oṣù méjì, òṣèlú abọ̀rìṣà yìí dá sí i, ó sì fara mọ́ àwọn tí ó sọ pé Jésù ni Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí ó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìwé A Short History of Christian Doctrine sọ pé: “Constantine kò lóye àwọn ìbéèrè tí a ń béèrè nínú ẹ̀kọ́ ìsìn Gíríìkì páà.” Kìkì ohun tí ó mọ̀ ni pé, ìpínyà ìsìn lè jin ilẹ̀ ọba òun lẹ́sẹ̀, ó sì ti pinnu láti mú ilẹ̀ ọba rẹ̀ ṣọ̀kan.
Nípa àkọsílẹ̀ tí ó kẹ́yìn tí a mú jáde nígbà àpérò Nicaea, lábẹ́ ìdarí Constantine, ìwé náà, Istoria tou Ellinikou Ethnous (Ìtàn Orílẹ̀-Èdè Gíríìkì), sọ pé: “Ó ṣàfihàn àìbìkítà [Constantine] nípa ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́, . . . ìtẹpẹlẹmọ́ rẹ̀ nínú gbígbìyànjú láti mú ìṣọ̀kan wà láàárín ṣọ́ọ̀ṣì lọ́nàkọnà, àti nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ìdánilójú tí ó ní pé, gẹ́gẹ́ bí ‘bíṣọ́ọ̀bù àwọn tí ó wà lẹ́yìn òde ṣọ́ọ̀ṣì,’ ohunkóhun tí òun bá sọ nípa ìsìn ni abẹ gé.” Ó ha lè jẹ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó wà lẹ́yìn àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe níbi àpérò yẹn bí?—Fi wé Ìṣe 15:28, 29.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Ìpànìyàn Nínú Ìdílé Ọba
Lábẹ́ àkọlé yìí, ìwé Istoria tou Ellinikou Ethnous (Ìtàn Orílẹ̀-Èdè Gíríìkì) ṣàpèjúwe ohun tí ó pè ní “ìwà ọ̀daràn abẹ́lé, tí ń kóni nírìíra, tí Constantine hù.” Kété lẹ́yìn tí ó gbé ìjọba rẹ̀ kalẹ̀, ó gbàgbé bí a ti ń rí àṣeyọrí tí a kò retí, ó sì wá mọ àwọn ewu tí ó yí i ká. Nítorí tí ó jẹ́ ẹni tí ó máa ń tètè fura síni, tí ó sì ṣeé ṣe kí àwọn apọ́nni, tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò jẹ, ti kì í láyà, ó kọ́kọ́ fura sí ọmọ arákùnrin rẹ̀, Licinianus—ọmọ Olú Ọba bíi tirẹ̀, tí ó ti ṣekú pa—gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣeé ṣe kí ó bá òun dupò. Lẹ́yìn tí ó pa Licinianus, Fausta, ìyàwó Constantine, ṣekú pa Crispus, àkọ́bí Constantine, nítorí ó jọ pé Crispus ń dènà agbára pátápátá tí ì bá bọ́ sọ́wọ́ ọmọ tirẹ̀.
Ìgbésẹ̀ Fausta yìí nígbẹ̀yìngbẹ́yín ni ó fa ikú burúkú tí òun fúnra rẹ̀ kú. Ó jọ bí pé Augusta Helena, tí ó lágbára lórí Constantine, ọmọ rẹ̀, títí dópin, lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn yìí. Inú ríru ṣùṣù, láìnídìí, tí ń ṣàkóso Constantine tún dá kún ṣíṣekúpa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọ̀rẹ́ àti alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀. Ìwé History of the Middle Ages parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Ìṣekúpa—kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pípa—ọmọkùnrin rẹ̀ àti aya rẹ̀, fi hàn pé ẹ̀sìn Kristẹni kò nípa tẹ̀mí kankan lórí rẹ̀.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
A ti lo òbíríkítí yìí ní Róòmù láti ṣe Constantine lógo
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Musée du Louvre, Paris