Kò Sí Èrò Nípa Jíjuwọ́sílẹ̀!
ỌWỌ́ Jehofa wà lára àwọn ọmọlẹ́yìn ìjímìjí ti Jesu Kristi. (Iṣe 11:21) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun, wọn fi àìjuwọ́sílẹ̀ lépa ipa ọ̀nà ìdúróṣinṣin. Pé àwọn pẹ̀lú nírìírí ìkóguntini àti inúnibíni mímúná pàápàá jẹ́ òtítọ́ tí a mọ̀-bí-ẹní-mowó nínú ìtàn.
Ìwàtítọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn olùṣòtítọ́ àkọ́kọ́ ti Kristi ti di òtítọ́ tí a mọ̀-bí-ẹni-mowó. Àní ní níná wọn ní ẹ̀mí wọn, wọ́n kọ̀ láti fi ìgbàgbọ́ wọn bánidọ́rẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n èéṣe tí a fi bá wọn lò lọ́nà ìkà bẹ́ẹ̀?
A Kórìíra Wọn Láìnídìí
Bíi ti Jesu, àwọn Kristian tòótọ́ kò ní ìlépa àti èrò-ìgbàgbọ́ ti ayé yìí. (1 Johannu 4:4-6) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìdàgbàsókè ìsìn Kristian “ti yárakánkán gidigidi, ìyọrísírere rẹ̀ sì pẹtẹrí gan-an, tí ó fi jẹ́ pé ìforígbárí bíbùáyà [pẹ̀lú agbára aláyélúwà ti Romu] jẹ́ èyí tí kò ṣeéyẹ̀sílẹ̀,” ni òpìtàn Edmond de Pressensé ṣàkíyèsí.
Lẹ́ẹ̀kanrí Jesu mú orin alásọtẹ́lẹ̀ kan bá araarẹ̀ mú, ní wíwí pé: “Wọ́n kórìíra mi ní àìnídìí.” (Johannu 15:25; Orin Dafidi 69:4) Kí ó tó sọ èyí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó ti kìlọ̀ pé: “Ọmọ-ọ̀dọ̀ kò tóbi ju oluwa rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá tí ṣe inúnibíni sí mi, wọn ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Johannu 15:20) Kì yóò rọrùn láti tẹ̀lé ipasẹ̀ rẹ̀. Ohun kan ni pé, àwọn aṣáájú ìsìn láàárín àwọn Ju yóò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí wọ́n jẹ́ Ju lò gẹ́gẹ́ bí apẹ̀yìndà kúrò nínú ìsìn àwọn Ju. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí a fi dandan béèrè pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu máṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́, wọ́n kọ̀ láti gbà kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ìgbàgbọ́ wọn bánidọ́rẹ̀ẹ́.—Iṣe 4:17-20; 5:27-32.
Nínú gbólóhùn-ẹ̀rí tí ó fifún ìgbìmọ̀ Sanhedrin ti àwọn Ju ní kété lẹ́yìn Pentekosti 33 C.E., ọmọ-ẹ̀yìn náà Stefanu ni a fẹ̀sùn kàn pé ó “ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Mose àti sí Ọlọrun.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀sùn náà jẹ́ oníláìfí ńláǹlà, wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, “inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ní Jerusalemu; a sì tú gbogbo wọn ká jákèjádò àgbègbè Judea òun Samaria, àfi àwọn aposteli.” (Iṣe 6:11, 13; 8:1) Ọ̀pọ̀ ni a sì fi sẹ́wọ̀n.
Àwọn Ju lépa àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu “pẹ̀lú ìkórìíra tí kò ṣeé pẹ̀tù sí,” ni ìwé náà Christianity and the Roman Empire sọ. Họ́wù, ìjọba Romu ti níláti gbégbèésẹ̀ láti dáàbòbo àwọn Kristian lọ́pọ̀ ìgbà! Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ogun Romu yọ aposteli Paulu kúrò nínú ewu láti ọwọ́ àwọn Ju tí wọ́n pinnu láti pa á. (Iṣe 21:26-36) Síbẹ̀, ipò-ìbátan tí ó wà láàárín àwọn Kristian àti àwọn ará Romu ṣì jẹ́ ọ̀kan tí kò rọrùn síbẹ̀.
Romu Mú Inúnibíni náà Gbónájanjan Síi
Ní nǹkan bíi ọdún mẹ́sàn-án lẹ́yìn ikú Stefanu, alákòóso Romu Herodu Agrippa Kìn-ín-ní mú kí a pa aposteli Jakọbu kí ó baà lè jèrè ojúrere àwọn Ju. (Iṣe 12:1-3) Ní àkókò yẹn, ìgbàgbọ́ nínú Kristi ti tànkálẹ̀ dé Romu. (Iṣe 2:10) Ní 64 C.E., ìwọ̀n títóbi nínú ìlú-ńlá yẹn ni iná run. Inúnibíni bíbanilẹ́rù sí àwọn Kristian tẹ̀lé e lẹ́yìn tí Nero dẹ́bi fún wọn nítorí ìjábá náà nínú ìsapá rẹ̀ láti tẹ àhesọ náà rì pé òun ni ó fa àgbáàràgbá iná náà. Òun ha dáná sun ìlú-ńlá náà gẹ́gẹ́ bí àwáwí láti tún un kọ́ sórí ààlà ìpínlẹ́ kan tí ó túbọ̀ lẹ́wà kí ó baà lè yí orúkọ rẹ̀ padà sí Neropolis gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ni bí? Tàbí olú-ọbabìnrin rẹ̀ Poppaea, aláwọ̀se Ju kan tí a mọ̀ mọ ìkórìíra jíjinlẹ̀ sí àwọn Kristian, ni ó nípa lórí ìpinnu rẹ̀ láti fẹ̀sùn kàn wọ́n bí? Kò dá àwọn olùṣèwádìí lójú, ṣùgbọ́n ìyọrísí náà dẹ́rùbani.
Òpìtàn Romu Tacitus sọ pé: “Ìfiniṣẹlẹ́yà ni a fikún ikú; ní fífi awọ ẹranko wọ̀ wọ́n, [àwọn Kristian] ni ajá fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ; a kàn wọ́n mọ́ àgbélébùú; a sọ ara wọn di èyí tí a lè dáná sun, kí ó baà lè jẹ́ pé nígbà tí alẹ́ bá lẹ́, wọ́n a lè ṣeé lò gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀,” ètùfù iná tí a fi ènìyàn ṣe láti tànmọ́lẹ̀ sí ọgbà aláyélúwà. Tacitus, tí kìí ṣe ọ̀rẹ́ àwọn Kristian rárá, fikún un pé: “Bí wọ́n ṣe jẹ̀bi tóo nì, tí wọ́n sì yẹ fún ìfìyàjẹni àfijófin, wọ́n ru ìyọ́nú sókè, níti pé a ń pa wọ́n run, kìí ṣe nítorí ire-àlàáfíà àwọn ará ilú, ṣùgbọ́n nítorí ìwà-ìkà ọkùnrin kan,” Nero.
Àwọn Ìyàtọ̀ Ìfiwéra Ṣíṣe Kedere
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó bá ète Nero mu láti fẹ̀sùn rírun Romu kan àwọn Kristian, òun kò fòfin dè wọ́n rárá tàbí kí ó ka ìsìn Kristian léèwọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsìn kan láàárín Orílẹ̀-Èdè náà. Nítorí náà èéṣe tí àwọn ará Romu fi ń bá inúnibíni náà lọ? Nítorí pé “àpapọ̀ àwùjọ àwọn Kristian kékeré náà ń yọ ayé abọ̀rìṣà tí wíwá fàájì ti yílórí náà lẹ́nu nípasẹ̀ ẹ̀mí-ìsìn àti ìmẹ̀yẹ wọn,” ni òpìtàn Will Durant sọ. Ìyàtọ̀ ìfiwéra tí ó wà láàárín ìsìn Kristian àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ eré ìdíje oníjà ikú ti Romu kò tún gbọ́dọ̀ ga jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àǹfààní kan fún àwọn ará Romu láti rẹ́yìn àwọn Kristian kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ìtura bá ẹ̀rí-ọkàn wọn kọjá ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ pàdánù.
Gẹ́gẹ́ bí agbára ayé kan, ó dàbí ẹni pé Romu kò ṣeé ṣẹ́gun. Àwọn ará Romu gbàgbọ́ pé ìdí kan fún agbára ìjáfáfá wọn níti ológun ni jíjọ́sìn tí wọ́n ń jọ́sìn gbogbo àwọn ọlọrun. Nítorí náà ó ṣòro fún wọn láti lóye ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun kanṣoṣo tí ó jẹ́ ti àwọn Kristian nìkanṣoṣo àti kíkọ̀ tí ó kọ gbogbo ọlọrun yòókù sílẹ̀, títíkan ìjọsìn olú-ọba. Kò yanilẹ́nu pé Romu rí ìsìn Kristian gẹ́gẹ́ bí agbára-ìdarí kan ti ń tẹ ìpìlẹ̀ náà gan-an tí ó jẹ́ ti ilẹ̀-ọba náà rì.
Ohun tí Jíjẹ́rìí Ń Náni
Níhà òpin ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E., aposteli Johannu ni a rán ní ìgbèkùn lọ sí erékùṣù Patmo “nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi.” (Ìfihàn 1:9) Olú-ọba Romu Domitian ni a gbàgbọ́ pé ó wà nídìí èyí. Bí ó ti wù kí ó rí, lójú ìkìmọ́lẹ̀ náà tí a gbékarí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu, nígbà tí ọ̀rúndún náà fi máa yípo, ìsìn Kristian ti tànkálẹ̀ káàkiri Ilẹ̀-Ọba Romu. Báwo ni èyí ṣe wáyé? Ìwé A History of the Early Church sọ pé ìsìn Kristian ni a “sopọ̀mọ́ra nípasẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀.” Bíi ti Johannu, àwọn Kristian ìjímìjí tí a ṣenúnibíni sí kò jẹ́ fi ìgbàgbọ́ wọn bánidọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n wọ́n tẹpẹlẹ mọ́ fífi tìtara-tìtara sọ̀rọ̀ Ọlọrun àti jíjẹ́rìí nípa Jesu.—Iṣe 20:20, 21; 2 Timoteu 4:2.
Inúnibíni sí àwọn Kristian tún gba ọ̀nà mìíràn ní 112 C.E., ọdún méjì lẹ́yìn tí Olú-Ọba Trajan yan Pliny ṣe gómìnà Bitinia (tí ó wà ní àríwá ìwọ̀-oòrùn Turkey nísinsìnyí). Ìṣàbójútó tí ó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ kò mógìírí mọ́, ó sì ti yọrísí ìdàrúdàpọ̀. Àwọn tẹ́ḿpìlì ní a fẹ́rẹ̀ẹ́ kọ̀ sílẹ̀ tán, oúnjẹ ẹran tí a sì ń tà fún àwọn ẹran ìrúbọ ti lọ sílẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àwọn oníṣòwò dá àìlọ́júpọ̀ ìsìn Kristian lẹ́bi, nítorí pé kò ní àwọn ìrúbọ ti ẹran àti ti òrìṣà nínú.
Pliny ṣiṣẹ́ kárakára láti mú ìjọsìn ìbọ̀rìṣà padàbọ̀sípò, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn Kristian ń fi ẹ̀mí wọn dípò kíkọ̀ láti fi wáìnì tàbí tùràrí rúbọ níwájú àwọn ère-ìrántí olú-ọba. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn aláṣẹ Romu gbà pé àwọn Kristian “jẹ́ ènìyàn oníwàrere títayọlọ́lá, ṣùgbọ́n lọ́nà tí kò ṣeé ṣàlàyé wọ́n jẹ́ olùgbéjàko àṣà-àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn àtijọ́,” ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Henry Chadwick sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé jíjẹ́ Kristian kan sì jẹ́ láìfí tí ó la ikú lọ, àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu tòótọ́ kò ní èrò nípa jíjuwọ́sílẹ̀.
“Ìbínú tí ìyípadà àwọn mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé abọ̀rìṣà dá sílẹ̀” tún yọrísí ìkórìíra, ni Ọ̀jọ̀gbọ́n W. M. Ramsay sọ. “Ìgbésí-ayé ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ni a mú nira gidigidi nígbà tí aládùúgbò ẹni kò bá lè faramọ́ àṣà ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ṣákálá kan lásán kìkì nítorí pé ó dọ́gbọ́n túmọ̀sí jíjẹ́wọ́ àwọn ọlọrun òrìṣà tí a ń jọ́sìn fún gẹ́gẹ́ bí òtítọ́,” ni Dókítà J. W. C. Wand sọ. Abájọ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi wo àwọn Kristian ìjímìjí gẹ́gẹ́ bí olùkórìíra aráyé tàbí kà wọ́n sí aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun.
Ìdàgbàsókè Mú Inúnibíni Púpọ̀ Síi Wá
Polycarp, tí a ròyìn rẹ̀ pé a ti ọwọ́ aposteli Johannu kọ́lẹ́kọ̀ọ́, di alàgbà kan tí a bọ̀wọ̀ fún ní ìlú Smirna (Izmir nísinsìnyí). Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ a sun ún lórí òpó-igi ní 155 C.E. Statius Quadratus gómìnà ẹkùn ìpínlẹ̀ Romu kó ogunlọ́gọ̀ jọ. Pápá ìṣeré náà kún fún àwọn òṣónú abọ̀rìṣà tí wọ́n fi Polycarp ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún ṣẹ̀sín fún gbígbìyànjú láti dá ìjọsìn àwọn ọlọrun wọn dúró, àwọn Ju onígbòónára ẹhànnà sì fi pẹ̀lú ìmúratán kó igi-ìdáná jọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n níláti ṣe é ní Ọjọ́-Ìsinmi ńlá.
Tẹ̀lé èyí ni àgbàrá inúnibíni ya lu àwọn Kristian jákèjádò ayé Romu. Lábẹ́ Olú-Ọba Marcus Aurelius, ẹ̀jẹ̀ wọn tilẹ̀ ṣàn bí omi síi. Bí wọ́n bá jẹ́ ọlọ̀tọ̀ Romu, wọ́n a kú nípa idà; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n a ti ọwọ́ ẹranko ẹhànnà kú nínú gbọ̀ngàn ìṣiré olóbìrípo. Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n ṣẹ̀? Kìkì nítorí pé wọ́n jẹ́ Kristian tí ó kọ̀ láti juwọ́sílẹ̀ tàbí láti kọ ìgbàgbọ́ wọn sílẹ̀ lákọ̀tán.
Lyons ìlú France òde-òní jáde wá láti ara Lugdunum ìlú tí Romu gbókèèrè ṣàkóso, tí ó jẹ́ lájorí ibùdó ìṣàbójútó àkóso àti ibi-ìdúró ológun Romu kanṣoṣo tí ó wà láàárín Romu àti Odò Rhine. Ní 177 C.E., ó ti ní àpapọ̀ àwùjọ Kristian tí ó lè lo agbára ìdarí ńlá kan èyí tí àwọn ènìyàn ìlú Romu takò tìbínú-tìbínú. Èyí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí a fún àwọn Kristian ní ìyọ̀ǹda kúrò ní àwọn ibi-ìnàjú ti gbogbo ìlú. Àgbájọ àwọn ènìyànkénìyàn dá rúkèrúdò ìwà-ipá sílẹ̀, inúnibíni tí ó ti ẹ̀yìn rẹ̀ yọ sì pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi tí Kristian kan ko jẹ́ dá a láṣà láti jáde sí gbangba. Gómìnà Romu pàṣẹ pé ki a wá àwọn Kristian rí kí a sì pa wọ́n.
Èrè Náà
Pẹ̀lú ikú àwọn aposteli Jesu àti ìkọjálọ agbára-ìdarí wọn tí ń ṣèdíwọ́, ìpẹ̀yìndà bẹ̀rẹ̀ síí dàgbàsókè láàárín àwọn Kristian aláfẹnujẹ́. (2 Tessalonika 2:7) Ní apá ìparí ọ̀rúndún kẹrin C.E., ìsìn Kristian apẹ̀yìndà di ìsìn Orílẹ̀-Èdè. Ní àkókò náà, ó ti díbàjẹ́ ó sì ti múratán láti juwọ́sílẹ̀ kí ó sì fi araarẹ̀ hàn bí apákan ayé—ohun kan tí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí kò jẹ́ ṣe. (Johannu 17:16) Bí ó ti wù kí ó rí, tipẹ́ ṣáájú ìgbà náà, àwọn ìwé onímìísí mímọ́ ti Bibeli ni a ti parí, tí ó sì ní àkọsílẹ̀ ìgbàgbọ́ Kristian rẹ̀ nínú.
Ìjìyà àti ikú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristian ìjímìjí ha jásí asán bí? Kí á má ríi! Láìsí èrò nípa fífi ìgbàgbọ́ wọn bánidọ́rẹ̀ẹ́, ‘wọ́n fẹ̀rí araawọn hàn gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ àní títí dé ojú ikú a sì fún wọn ní adé ìyè.’ (Ìfihàn 2:10) Àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ṣì ń nímọ̀lára ìgbóná ooru inúnibíni síbẹ̀, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ àti ìwàtítọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ìjímìjí ṣì wà síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orísun ìṣírí ńláǹlà fún wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristian òde-òní ni àwọn pẹ̀lú kò múratán láti fààyè gba èrò jíjuwọ́sílẹ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Nero
Àwòrán Romu aláyélúwà
Pẹpẹ kan tí a yàsọ́tọ̀ fún ìjọsìn Kesari
[Àwọn Credit Line]
Nero: Ìyọ̀ọ̀da onínúure ti British Museum
Museo della Civiltà Romana, Roma
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Marcus Aurelius
[Credit Line]
The Bettmann Archive