ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 119
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sáàmù

      • Mọrírì ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣeyebíye

        • ‘Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè mú ipa ọ̀nà wọn mọ́?’ (9)

        • “Mo fẹ́ràn àwọn ìránnilétí rẹ” (24)

        • “Ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi” (74, 81, 114)

        • “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!” (97)

        • “Òye tó jinlẹ̀ ju ti gbogbo àwọn olùkọ́ mi” (99)

        • “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi” (105)

        • “Òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ” (160)

        • Àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run (165)

Sáàmù 119:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 20:3; Jem 1:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 10

Sáàmù 119:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 19:7
  • +2Kr 31:20, 21

Sáàmù 119:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 38:3

Sáàmù 119:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 5:33; Jer 7:23; Jem 2:10

Sáàmù 119:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ì bá ṣe pé àwọn ọ̀nà mi fìdí múlẹ̀ gbọn-in.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 51:10

Sáàmù 119:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:80

Sáàmù 119:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 10-11

Sáàmù 119:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 10-11

Sáàmù 119:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 6:20, 22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 11-12

    10/1/2002, ojú ìwé 9

Sáàmù 119:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 25:5

Sáàmù 119:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 112:1
  • +Sm 19:13; 37:31

Sáàmù 119:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 15:16
  • +Sm 19:8, 10; 119:72

Sáàmù 119:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:93, 100
  • +Sm 25:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2000, ojú ìwé 15

Sáàmù 119:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jem 1:23-25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2000, ojú ìwé 14-15

Sáàmù 119:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 38:20

Sáàmù 119:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 29:15

Sáàmù 119:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:15

Sáàmù 119:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Yí ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lórí mi.”

Sáàmù 119:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/1997, ojú ìwé 14-15

Sáàmù 119:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:14, 168
  • +Di 17:18-20; Sm 119:105; 2Ti 3:16, 17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2006, ojú ìwé 25

    4/15/2005, ojú ìwé 12

Sáàmù 119:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọkàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 22:15
  • +Sm 119:154; 143:11

Sáàmù 119:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 86:11

Sáàmù 119:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọ̀nà.”

  • *

    Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 145:5

Sáàmù 119:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 12

    7/15/1997, ojú ìwé 14-15

Sáàmù 119:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 141:4; Owe 30:8

Sáàmù 119:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 24:15

Sáàmù 119:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kí ojú tì mí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 19:7
  • +Sm 25:20; 119:80

Sáàmù 119:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Màá sáré ní.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “o mú kí ọkàn mi ní ìgboyà.”

Sáàmù 119:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 48:17; Jo 6:45; Jem 1:5
  • +Sm 119:112

Sáàmù 119:35

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Mú mi rìn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 23:3

Sáàmù 119:36

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Kó má ṣe fà sí èrè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 12:15; 1Ti 6:10; Heb 13:5

Sáàmù 119:37

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 15:39; Owe 4:25; 23:4, 5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 40

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2010, ojú ìwé 20-24

    4/15/2005, ojú ìwé 13

Sáàmù 119:38

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀rọ̀ tí o sọ.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Èyí tí o ṣe fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ.”

Sáàmù 119:39

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 19:9; 119:75

Sáàmù 119:41

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 51:1; 90:14
  • +Sm 119:76

Sáàmù 119:43

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mo dúró de.”

Sáàmù 119:44

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:33

Sáàmù 119:45

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 118:5

Sáàmù 119:46

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 1:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 13

Sáàmù 119:47

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 23:12; Sm 119:174; Ro 7:22

Sáàmù 119:48

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:127
  • +Sm 119:23, 71

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2000, ojú ìwé 15

    1/15/1999, ojú ìwé 10

Sáàmù 119:49

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìlérí tí o ṣe.”

  • *

    Tàbí “Èyí tí o mú kí n dúró dè.”

Sáàmù 119:50

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 94:19; Ro 15:4

Sáàmù 119:51

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:157

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 13-14

Sáàmù 119:52

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 16:5; Di 1:35, 36; 4:3
  • +Ro 15:4

Sáàmù 119:53

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:158; 139:21; Owe 28:4

Sáàmù 119:54

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ní ilé tí mo ti jẹ́ àjèjì.”

Sáàmù 119:55

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 63:6; Ais 26:9

Sáàmù 119:57

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 16:5
  • +Ẹk 19:8

Sáàmù 119:58

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tù ọ́ lójú (wá ẹ̀rín rẹ).”

  • *

    Tàbí “sọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 51:17
  • +Sm 57:1

Sáàmù 119:59

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:101; Ef 5:15

Sáàmù 119:60

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 29:1, 3

Sáàmù 119:61

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:8, 9; 2Kr 29:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2000, ojú ìwé 14

Sáàmù 119:62

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 42:8

Sáàmù 119:63

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 13:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 48

Sáàmù 119:64

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 33:5; 104:13

Sáàmù 119:66

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:9; Sm 94:10; Da 2:21; Flp 1:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/1999, ojú ìwé 10

Sáàmù 119:67

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mo máa ń dẹ́ṣẹ̀ láì mọ̀ọ́mọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:11

Sáàmù 119:68

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 86:5; Mk 10:18
  • +Ais 48:17

Sáàmù 119:70

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “kú tipiri, bí ọ̀rá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:10
  • +Sm 40:8; Ro 7:22

Sáàmù 119:71

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 11:32; Heb 12:9-11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2006, ojú ìwé 14

    4/15/2005, ojú ìwé 14

Sáàmù 119:72

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:18, 19
  • +Sm 19:7, 10; Owe 3:13-15

Sáàmù 119:73

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 22:12; Job 32:8

Sáàmù 119:74

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ni mo dúró dè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:147

Sáàmù 119:75

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:160
  • +Di 32:4; Heb 12:11

Sáàmù 119:76

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀rọ̀ tí o sọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:6; Sm 86:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2010, ojú ìwé 24

Sáàmù 119:77

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 51:1; 103:13; 119:116; Da 9:18; Lk 1:50
  • +Ro 7:22

Sáàmù 119:78

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.”

  • *

    Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:45

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 14

Sáàmù 119:80

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:58
  • +Sm 119:5, 6; 1Jo 2:28

Sáàmù 119:81

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọkàn mi ń kú lọ nítorí.”

  • *

    Tàbí “ni mo dúró dè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 7:7

Sáàmù 119:82

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 69:3
  • +Sm 86:17; 102:2

Sáàmù 119:83

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:61, 176

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 15

Sáàmù 119:84

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 7:6; Ifi 6:9, 10

Sáàmù 119:86

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 142:6

Sáàmù 119:89

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 89:2; 119:152

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 15-16

Sáàmù 119:90

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:9
  • +Sm 104:5; Onw 1:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 15-16

Sáàmù 119:91

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, gbogbo ohun tó dá.

Sáàmù 119:92

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 6:23; Mt 4:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 16

Sáàmù 119:93

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:5; Di 30:16; Jo 6:63; Ro 10:5

Sáàmù 119:94

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 86:2; Ais 41:10
  • +Sm 119:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 16

Sáàmù 119:96

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbòòrò gan-an.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2006, ojú ìwé 14

Sáàmù 119:97

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 40:8
  • +Sm 1:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 5

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2006, ojú ìwé 20

    4/15/2002, ojú ìwé 13-14

    3/15/2001, ojú ìwé 16-17

    10/1/2000, ojú ìwé 15

    11/1/1999, ojú ìwé 11

Sáàmù 119:98

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 19:7; Owe 2:6; 10:8

Sáàmù 119:99

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 11:25; Lk 2:46, 47

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2000, ojú ìwé 15

Sáàmù 119:100

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2021,

Sáàmù 119:101

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 18:23; 119:59

Sáàmù 119:103

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 19:7, 10; Owe 24:13, 14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    5/2017, ojú ìwé 20

Sáàmù 119:104

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:100
  • +Sm 97:10; 101:3; Owe 8:13; 13:5; Ro 12:9

Sáàmù 119:105

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 43:3; Owe 6:23; Ais 51:4; Ro 15:4; 2Ti 3:16, 17; 2Pe 1:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 1

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 1 2018 ojú ìwé 14

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2007, ojú ìwé 14-18

    9/1/2006, ojú ìwé 14

    4/15/2005, ojú ìwé 17

    9/15/2002, ojú ìwé 12

    3/1/2002, ojú ìwé 12

    Jí!,

    7/2007, ojú ìwé 6

Sáàmù 119:107

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 34:19
  • +Sm 119:88; 143:11

Sáàmù 119:108

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọrẹ àtọkànwá ẹnu mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 50:23; Ho 14:2; Heb 13:15
  • +Di 33:10; Ais 48:17

Sáàmù 119:109

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọkàn mi wà ní ọwọ́ mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:61

Sáàmù 119:110

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:87

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 17

Sáàmù 119:111

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ogún mi ayérayé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 19:8; 119:129; Jer 15:16

Sáàmù 119:112

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tẹ ọkàn mi.”

Sáàmù 119:113

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn tí ọkàn wọn pínyà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 18:21; Ifi 3:16
  • +Sm 40:8; 119:97

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2023,

Sáàmù 119:114

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Màá dúró de ọ̀rọ̀ rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 32:7; 91:2
  • +Sm 130:5

Sáàmù 119:115

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 26:5

Sáàmù 119:116

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sọ.”

  • *

    Tàbí “ìtìjú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:10
  • +Sm 25:2; Ro 10:11

Sáàmù 119:117

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:13
  • +Joṣ 1:8; Sm 119:48

Sáàmù 119:118

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 28:9; Sm 95:10

Sáàmù 119:119

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ìdàrọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 2:22; 25:4, 5; Isk 22:18

Sáàmù 119:120

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹran ara.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 18

Sáàmù 119:123

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀rọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 69:3; 143:7
  • +Sm 119:81

Sáàmù 119:124

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 69:16
  • +Sm 143:10

Sáàmù 119:125

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:34; 2Ti 2:7; Jem 1:5

Sáàmù 119:126

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 9:19; Jer 18:23

Sáàmù 119:127

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí a yọ́ mọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 19:9, 10; 119:72; Owe 3:13, 14

Sáàmù 119:128

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àṣẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 19:8
  • +Sm 119:104

Sáàmù 119:129

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

Sáàmù 119:130

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:105; Owe 6:23; 2Kọ 4:6; 2Pe 1:19
  • +Sm 19:7; Owe 1:1, 4; 2Ti 3:15

Sáàmù 119:131

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “mí hẹlẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 42:1; 1Pe 2:2

Sáàmù 119:132

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 1:10, 11; 2Sa 16:11, 12; Ais 38:9, 20
  • +Heb 6:10

Sáàmù 119:133

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mú kí ìṣísẹ̀ mi ṣe tààrà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 19:13; Ro 6:12

Sáàmù 119:134

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Rà mí pa dà.”

Sáàmù 119:135

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “rẹ́rìn-ín sí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 6:25; Sm 4:6

Sáàmù 119:136

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 9:4; 2Pe 2:7, 8

Sáàmù 119:137

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:4
  • +Ifi 16:5, 7

Sáàmù 119:139

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 10:16; Sm 69:9; Jo 2:17

Sáàmù 119:140

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 12:6; 119:160
  • +Sm 119:97

Sáàmù 119:141

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 22:6, 7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 19

Sáàmù 119:142

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 36:6
  • +Ẹk 34:6; Sm 119:160; Jo 17:17

Sáàmù 119:144

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:34

Sáàmù 119:147

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “nígbà tí ọ̀yẹ̀ ń là.”

  • *

    Tàbí “ni mò ń dúró dè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 5:3; 88:13; Mk 1:35

Sáàmù 119:148

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 63:6; Lk 6:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2012, ojú ìwé 29-30

Sáàmù 119:149

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 51:1; Ais 63:7

Sáàmù 119:150

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìwà tó ń ríni lára.”

Sáàmù 119:151

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:7; Sm 46:1; 145:18
  • +Sm 19:9; Jo 17:17

Sáàmù 119:152

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:144; Onw 3:14

Sáàmù 119:153

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 9:13

Sáàmù 119:154

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Gba ẹjọ́ mi rò.”

  • *

    Tàbí “sọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 24:15; Sm 43:1

Sáàmù 119:155

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:15, 18; Sm 73:27; Owe 15:29

Sáàmù 119:156

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 21:13; Sm 86:15; Ais 55:7; 2Kọ 1:3; Jem 5:11

Sáàmù 119:157

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 25:19

Sáàmù 119:158

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 139:21

Sáàmù 119:159

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:40, 88; Ida 3:22

Sáàmù 119:160

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 7:28; Sm 12:6; Jo 17:17

Sáàmù 119:161

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:23
  • +2Ọb 22:19

Sáàmù 119:162

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 15:16

Sáàmù 119:163

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 101:7; 119:29, 104
  • +Sm 1:2

Sáàmù 119:164

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2006, ojú ìwé 14

Sáàmù 119:165

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Kò sí ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan fún wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 1:2, 3; Owe 3:1, 2; Ais 32:17; 48:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2013, ojú ìwé 4-5

    4/15/2005, ojú ìwé 19-20

Sáàmù 119:167

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọkàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 1:2; 40:8; Ro 7:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2000, ojú ìwé 14-19

Sáàmù 119:168

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 139:3; Owe 5:21; 15:11; Heb 4:13

Sáàmù 119:169

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 18:6
  • +1Kr 22:12; Owe 2:3, 5

Sáàmù 119:170

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sọ.”

Sáàmù 119:171

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Kí ìyìn máa dà ní ètè mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 63:5; 71:17; 145:7

Sáàmù 119:172

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 40:9

Sáàmù 119:173

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 60:5
  • +Di 30:19; Joṣ 24:15, 22

Sáàmù 119:174

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 1:2

Sáàmù 119:175

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 9:13, 14; Ais 38:19

Sáàmù 119:176

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 95:7; Lk 15:4; 1Pe 2:25
  • +Onw 12:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2005, ojú ìwé 20

Àwọn míì

Sm 119:12Ọb 20:3; Jem 1:25
Sm 119:2Sm 19:7
Sm 119:22Kr 31:20, 21
Sm 119:3Ais 38:3
Sm 119:4Di 5:33; Jer 7:23; Jem 2:10
Sm 119:5Sm 51:10
Sm 119:6Sm 119:80
Sm 119:9Owe 6:20, 22
Sm 119:10Sm 25:5
Sm 119:11Sm 112:1
Sm 119:11Sm 19:13; 37:31
Sm 119:14Jer 15:16
Sm 119:14Sm 19:8, 10; 119:72
Sm 119:15Sm 119:93, 100
Sm 119:15Sm 25:10
Sm 119:16Jem 1:23-25
Sm 119:17Ais 38:20
Sm 119:191Kr 29:15
Sm 119:21Di 28:15
Sm 119:24Sm 119:14, 168
Sm 119:24Di 17:18-20; Sm 119:105; 2Ti 3:16, 17
Sm 119:25Sm 22:15
Sm 119:25Sm 119:154; 143:11
Sm 119:26Sm 86:11
Sm 119:27Sm 145:5
Sm 119:29Sm 141:4; Owe 30:8
Sm 119:30Joṣ 24:15
Sm 119:31Sm 19:7
Sm 119:31Sm 25:20; 119:80
Sm 119:33Ais 48:17; Jo 6:45; Jem 1:5
Sm 119:33Sm 119:112
Sm 119:35Sm 23:3
Sm 119:36Lk 12:15; 1Ti 6:10; Heb 13:5
Sm 119:37Nọ 15:39; Owe 4:25; 23:4, 5
Sm 119:39Sm 19:9; 119:75
Sm 119:41Sm 51:1; 90:14
Sm 119:41Sm 119:76
Sm 119:44Sm 119:33
Sm 119:45Sm 118:5
Sm 119:46Ro 1:16
Sm 119:47Job 23:12; Sm 119:174; Ro 7:22
Sm 119:48Sm 119:127
Sm 119:48Sm 119:23, 71
Sm 119:50Sm 94:19; Ro 15:4
Sm 119:51Sm 119:157
Sm 119:52Nọ 16:5; Di 1:35, 36; 4:3
Sm 119:52Ro 15:4
Sm 119:53Sm 119:158; 139:21; Owe 28:4
Sm 119:55Sm 63:6; Ais 26:9
Sm 119:57Sm 16:5
Sm 119:57Ẹk 19:8
Sm 119:58Sm 51:17
Sm 119:58Sm 57:1
Sm 119:59Sm 119:101; Ef 5:15
Sm 119:602Kr 29:1, 3
Sm 119:611Sa 26:8, 9; 2Kr 29:1, 2
Sm 119:62Sm 42:8
Sm 119:63Owe 13:20
Sm 119:64Sm 33:5; 104:13
Sm 119:661Ọb 3:9; Sm 94:10; Da 2:21; Flp 1:9
Sm 119:67Sm 119:11
Sm 119:68Sm 86:5; Mk 10:18
Sm 119:68Ais 48:17
Sm 119:70Ais 6:10
Sm 119:70Sm 40:8; Ro 7:22
Sm 119:711Kọ 11:32; Heb 12:9-11
Sm 119:72Di 17:18, 19
Sm 119:72Sm 19:7, 10; Owe 3:13-15
Sm 119:731Kr 22:12; Job 32:8
Sm 119:74Sm 119:147
Sm 119:75Sm 119:160
Sm 119:75Di 32:4; Heb 12:11
Sm 119:76Ẹk 34:6; Sm 86:5
Sm 119:77Sm 51:1; 103:13; 119:116; Da 9:18; Lk 1:50
Sm 119:77Ro 7:22
Sm 119:78Sm 119:45
Sm 119:801Ọb 8:58
Sm 119:80Sm 119:5, 6; 1Jo 2:28
Sm 119:81Mik 7:7
Sm 119:82Sm 69:3
Sm 119:82Sm 86:17; 102:2
Sm 119:83Sm 119:61, 176
Sm 119:84Sm 7:6; Ifi 6:9, 10
Sm 119:86Sm 142:6
Sm 119:89Sm 89:2; 119:152
Sm 119:90Di 7:9
Sm 119:90Sm 104:5; Onw 1:4
Sm 119:92Owe 6:23; Mt 4:4
Sm 119:93Le 18:5; Di 30:16; Jo 6:63; Ro 10:5
Sm 119:94Sm 86:2; Ais 41:10
Sm 119:94Sm 119:15
Sm 119:97Sm 40:8
Sm 119:97Sm 1:2
Sm 119:98Sm 19:7; Owe 2:6; 10:8
Sm 119:99Mt 11:25; Lk 2:46, 47
Sm 119:101Sm 18:23; 119:59
Sm 119:103Sm 19:7, 10; Owe 24:13, 14
Sm 119:104Sm 119:100
Sm 119:104Sm 97:10; 101:3; Owe 8:13; 13:5; Ro 12:9
Sm 119:105Sm 43:3; Owe 6:23; Ais 51:4; Ro 15:4; 2Ti 3:16, 17; 2Pe 1:19
Sm 119:107Sm 34:19
Sm 119:107Sm 119:88; 143:11
Sm 119:108Sm 50:23; Ho 14:2; Heb 13:15
Sm 119:108Di 33:10; Ais 48:17
Sm 119:109Sm 119:61
Sm 119:110Sm 119:87
Sm 119:111Sm 19:8; 119:129; Jer 15:16
Sm 119:1131Ọb 18:21; Ifi 3:16
Sm 119:113Sm 40:8; 119:97
Sm 119:114Sm 32:7; 91:2
Sm 119:114Sm 130:5
Sm 119:115Sm 26:5
Sm 119:116Ais 41:10
Sm 119:116Sm 25:2; Ro 10:11
Sm 119:117Ais 41:13
Sm 119:117Joṣ 1:8; Sm 119:48
Sm 119:1181Kr 28:9; Sm 95:10
Sm 119:119Owe 2:22; 25:4, 5; Isk 22:18
Sm 119:123Sm 69:3; 143:7
Sm 119:123Sm 119:81
Sm 119:124Sm 69:16
Sm 119:124Sm 143:10
Sm 119:125Sm 119:34; 2Ti 2:7; Jem 1:5
Sm 119:126Sm 9:19; Jer 18:23
Sm 119:127Sm 19:9, 10; 119:72; Owe 3:13, 14
Sm 119:128Sm 19:8
Sm 119:128Sm 119:104
Sm 119:130Sm 119:105; Owe 6:23; 2Kọ 4:6; 2Pe 1:19
Sm 119:130Sm 19:7; Owe 1:1, 4; 2Ti 3:15
Sm 119:131Sm 42:1; 1Pe 2:2
Sm 119:1321Sa 1:10, 11; 2Sa 16:11, 12; Ais 38:9, 20
Sm 119:132Heb 6:10
Sm 119:133Sm 19:13; Ro 6:12
Sm 119:135Nọ 6:25; Sm 4:6
Sm 119:136Isk 9:4; 2Pe 2:7, 8
Sm 119:137Di 32:4
Sm 119:137Ifi 16:5, 7
Sm 119:1392Ọb 10:16; Sm 69:9; Jo 2:17
Sm 119:140Sm 12:6; 119:160
Sm 119:140Sm 119:97
Sm 119:141Sm 22:6, 7
Sm 119:142Sm 36:6
Sm 119:142Ẹk 34:6; Sm 119:160; Jo 17:17
Sm 119:144Sm 119:34
Sm 119:147Sm 5:3; 88:13; Mk 1:35
Sm 119:148Sm 63:6; Lk 6:12
Sm 119:149Sm 51:1; Ais 63:7
Sm 119:151Di 4:7; Sm 46:1; 145:18
Sm 119:151Sm 19:9; Jo 17:17
Sm 119:152Sm 119:144; Onw 3:14
Sm 119:153Sm 9:13
Sm 119:1541Sa 24:15; Sm 43:1
Sm 119:1552Ọb 17:15, 18; Sm 73:27; Owe 15:29
Sm 119:1561Kr 21:13; Sm 86:15; Ais 55:7; 2Kọ 1:3; Jem 5:11
Sm 119:157Sm 25:19
Sm 119:158Sm 139:21
Sm 119:159Sm 119:40, 88; Ida 3:22
Sm 119:1602Sa 7:28; Sm 12:6; Jo 17:17
Sm 119:161Sm 119:23
Sm 119:1612Ọb 22:19
Sm 119:162Jer 15:16
Sm 119:163Sm 101:7; 119:29, 104
Sm 119:163Sm 1:2
Sm 119:165Sm 1:2, 3; Owe 3:1, 2; Ais 32:17; 48:18
Sm 119:167Sm 1:2; 40:8; Ro 7:22
Sm 119:168Sm 139:3; Owe 5:21; 15:11; Heb 4:13
Sm 119:169Sm 18:6
Sm 119:1691Kr 22:12; Owe 2:3, 5
Sm 119:171Sm 63:5; 71:17; 145:7
Sm 119:172Sm 40:9
Sm 119:173Sm 60:5
Sm 119:173Di 30:19; Joṣ 24:15, 22
Sm 119:174Sm 1:2
Sm 119:175Sm 9:13, 14; Ais 38:19
Sm 119:176Sm 95:7; Lk 15:4; 1Pe 2:25
Sm 119:176Onw 12:13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
  • 43
  • 44
  • 45
  • 46
  • 47
  • 48
  • 49
  • 50
  • 51
  • 52
  • 53
  • 54
  • 55
  • 56
  • 57
  • 58
  • 59
  • 60
  • 61
  • 62
  • 63
  • 64
  • 65
  • 66
  • 67
  • 68
  • 69
  • 70
  • 71
  • 72
  • 73
  • 74
  • 75
  • 76
  • 77
  • 78
  • 79
  • 80
  • 81
  • 82
  • 83
  • 84
  • 85
  • 86
  • 87
  • 88
  • 89
  • 90
  • 91
  • 92
  • 93
  • 94
  • 95
  • 96
  • 97
  • 98
  • 99
  • 100
  • 101
  • 102
  • 103
  • 104
  • 105
  • 106
  • 107
  • 108
  • 109
  • 110
  • 111
  • 112
  • 113
  • 114
  • 115
  • 116
  • 117
  • 118
  • 119
  • 120
  • 121
  • 122
  • 123
  • 124
  • 125
  • 126
  • 127
  • 128
  • 129
  • 130
  • 131
  • 132
  • 133
  • 134
  • 135
  • 136
  • 137
  • 138
  • 139
  • 140
  • 141
  • 142
  • 143
  • 144
  • 145
  • 146
  • 147
  • 148
  • 149
  • 150
  • 151
  • 152
  • 153
  • 154
  • 155
  • 156
  • 157
  • 158
  • 159
  • 160
  • 161
  • 162
  • 163
  • 164
  • 165
  • 166
  • 167
  • 168
  • 169
  • 170
  • 171
  • 172
  • 173
  • 174
  • 175
  • 176
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sáàmù 119:1-176

Sáàmù

א [Áléfì]

119 Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlẹ́bi* ní ọ̀nà wọn,

Àwọn tó ń rìn nínú òfin Jèhófà.+

 2 Aláyọ̀ ni àwọn tó ń kíyè sí àwọn ìránnilétí rẹ̀,+

Àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wọn wá a.+

3 Wọn kì í hùwà àìṣòdodo;

Wọ́n ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.+

4 O ti pàṣẹ pé

Kí a máa pa òfin rẹ mọ́ délẹ̀délẹ̀.+

5 Ká ní mo lè máa jẹ́ adúróṣinṣin nìṣó*+

Kí n lè máa pa àwọn ìlànà rẹ mọ́!

6 Nígbà náà, ojú ò ní tì mí+

Tí mo bá ń ronú nípa gbogbo àṣẹ rẹ.

7 Màá fi ọkàn tó dúró ṣinṣin yìn ọ́

Nígbà tí mo bá kọ́ nípa àwọn ìdájọ́ rẹ tó jẹ́ òdodo.

8 Màá pa àwọn ìlànà rẹ mọ́.

Má fi mí sílẹ̀ pátápátá.

ב [Bétì]

9 Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?

Tó bá ń kíyè sára, tó sì ń pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+

10 Gbogbo ọkàn mi ni mo fi wá ọ.

Má ṣe jẹ́ kí n yà kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ.+

11 Mo fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ìṣúra nínú ọkàn mi+

Kí n má bàa dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.+

12 Ìyìn ni fún ọ, Jèhófà;

Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.

13 Mo fi ètè mi kéde

Gbogbo àwọn ìdájọ́ tí o ti ṣe.

14 Àwọn ìránnilétí rẹ ń mú inú mi dùn+

Ju gbogbo àwọn ohun míì tó ṣeyebíye.+

15 Màá máa ronú lórí* àwọn àṣẹ rẹ,+

Màá sì máa fojú sí àwọn ọ̀nà rẹ.+

16 Mo fẹ́ràn àwọn òfin rẹ.

Mi ò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.+

ג [Gímélì]

17 Ṣe dáadáa sí èmi ìránṣẹ́ rẹ,

Kí n lè wà láàyè, kí n sì máa pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+

18 La ojú mi kí n lè rí

Àwọn ohun àgbàyanu tó wà nínú òfin rẹ kedere.

19 Àjèjì lásán ni mí lórí ilẹ̀ yìí.+

Má fi àwọn àṣẹ rẹ pa mọ́ fún mi.

20 Ìfẹ́ àwọn ìdájọ́ rẹ

Gbà mí lọ́kàn nígbà gbogbo.

21 O bá àwọn tó ń kọjá àyè wọn wí,

Àwọn ẹni ègún tó ń yà kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ.+

22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,*

Nítorí pé mo ti kíyè sí àwọn ìránnilétí rẹ.

23 Kódà nígbà tí àwọn olórí bá jọ jókòó, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ mi láìdáa,

Àwọn ìlànà rẹ ni èmi ìránṣẹ́ rẹ ń ronú lé lórí.*

24 Mo fẹ́ràn àwọn ìránnilétí rẹ;+

Àwọn ló ń gbà mí nímọ̀ràn.+

ד [Dálétì]

25 Mo* dùbúlẹ̀ nínú eruku.+

Mú kí n máa wà láàyè bí o ṣe sọ.+

26 Mo sọ àwọn ọ̀nà mi fún ọ, o sì dá mi lóhùn;

Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+

27 Jẹ́ kí n mọ ìtumọ̀* àwọn àṣẹ rẹ,

Kí n lè máa ronú lórí* àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+

28 Ẹ̀dùn ọkàn ò jẹ́ kí n* rí oorun sùn.

Fún mi lókun bí o ṣe sọ.

29 Mú ọ̀nà ẹ̀tàn kúrò lọ́dọ̀ mi,+

Kí o sì fi òfin rẹ ṣojú rere sí mi.

30 Mo ti yan ọ̀nà òdodo.+

Mo gbà pé àwọn ìdájọ́ rẹ tọ̀nà.

31 Mo rọ̀ mọ́ àwọn ìránnilétí rẹ.+

Jèhófà, má ṣe jẹ́ kí n rí ìjákulẹ̀.*+

32 Màá yára rìn ní* ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ,

Torí pé o ti wá àyè fún un nínú ọkàn mi.*

ה [Híì]

33 Jèhófà,+ kọ́ mi kí n lè máa tè lé àwọn ìlànà rẹ,

Màá sì tẹ̀ lé e délẹ̀délẹ̀.+

34 Jẹ́ kí n ní òye,

Kí n lè máa tẹ̀ lé òfin rẹ,

Kí n sì máa fi gbogbo ọkàn mi pa á mọ́.

35 Darí mi* ní ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ,+

Torí ó ń mú inú mi dùn.

36 Mú kí ọkàn mi máa fà sí àwọn ìránnilétí rẹ,

Kó má ṣe fà sí èrè tí kò tọ́.*+

37 Yí ojú mi kúrò kí n má ṣe máa wo ohun tí kò ní láárí;+

Mú kí n máa wà láàyè ní ọ̀nà rẹ.

38 Mú ìlérí tí o ṣe* fún ìránṣẹ́ rẹ ṣẹ,

Ká lè máa bẹ̀rù rẹ.*

39 Mú ìtìjú tí mò ń bẹ̀rù kúrò,

Nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ dára.+

40 Wo bí ọkàn mi ṣe ń fà sí àwọn àṣẹ rẹ.

Mú kí n máa wà láàyè nínú òdodo rẹ.

ו [Wọ́ọ̀]

41 Jèhófà, jẹ́ kí n rí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,+

Kí n rí ìgbàlà rẹ bí o ti ṣèlérí;*+

42 Nígbà náà, màá fún ẹni tó ń pẹ̀gàn mi lésì,

Nítorí mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ.

43 Má ṣe mú ọ̀rọ̀ òtítọ́ kúrò ní ẹnu mi,

Nítorí mo gbẹ́kẹ̀ lé* ìdájọ́ rẹ.

44 Èmi yóò máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo,

Títí láé àti láéláé.+

45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní ibi ààbò,*+

Nítorí mò ń wá àwọn àṣẹ rẹ.

46 Èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránnilétí rẹ níwájú àwọn ọba,

Mi ò sì ní tijú.+

47 Mo fẹ́ràn àwọn àṣẹ rẹ,

Àní, mo nífẹ̀ẹ́ wọn.+

48 Màá tẹ́ ọwọ́ mi sókè sí ọ nítorí àwọn àṣẹ rẹ, torí mo nífẹ̀ẹ́ wọn,+

Màá sì máa ronú lórí* àwọn ìlànà rẹ.+

ז [Sáyìn]

49 Rántí ọ̀rọ̀ tí o sọ* fún ìránṣẹ́ rẹ,

Èyí tí o fi mú kí n nírètí.*

50 Ohun tó ń tù mí nínú nìyí nínú ìpọ́njú mi,+

Ọ̀rọ̀ rẹ ló ń mú kí n wà láàyè.

51 Àwọn tó ń kọjá àyè wọn kàn mí lábùkù,

Àmọ́ mi ò yà kúrò nínú òfin rẹ.+

52 Jèhófà, mo rántí àwọn ìdájọ́ rẹ ti ìgbà àtijọ́,+

Wọ́n sì ń tù mí nínú.+

53 Mo gbaná jẹ gidigidi nítorí àwọn ẹni burúkú

Tó ń pa òfin rẹ tì.+

54 Orin ni àwọn ìlànà rẹ jẹ́ fún mi

Níbikíbi tí mo bá ń gbé.*

55 Jèhófà, mò ń rántí orúkọ rẹ ní òru,+

Kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́.

56 Ó ti jẹ́ ìṣe mi,

Nítorí pé mo ti pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.

ח [Hétì]

57 Jèhófà, ìwọ ni ìpín mi;+

Mo ti ṣèlérí pé màá pa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+

58 Mo fi gbogbo ọkàn mi bẹ̀ ọ́;*+

Ṣojú rere sí mi+ bí o ti ṣèlérí.*

59 Mo ti yẹ àwọn ọ̀nà mi wò,

Kí n lè yí ẹsẹ̀ mi pa dà sí àwọn ìránnilétí rẹ.+

60 Mo yára, mi ò sì jáfara

Láti pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.+

61 Okùn àwọn ẹni burúkú yí mi ká,

Àmọ́ mi ò gbàgbé òfin rẹ.+

62 Mo jí ní ọ̀gànjọ́ òru kí n lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ+

Nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ tó jẹ́ òdodo.

63 Ọ̀rẹ́ mi ni gbogbo àwọn tó bẹ̀rù rẹ

Àti àwọn tó ń pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.+

64 Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ kún inú ayé;+

Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.

ט [Tétì]

65 Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ,

O ti hùwà sí ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà tó dáa.

66 Kọ́ mi kí n lè ní làákàyè àti ìmọ̀,+

Nítorí àwọn àṣẹ rẹ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.

67 Kí a tó fìyà jẹ mí, mo máa ń ṣe ségesège,*

Àmọ́ ní báyìí, ohun tí o sọ ni mò ń ṣe.+

68 Ẹni rere ni ọ́,+ àwọn iṣẹ́ rẹ sì dára.

Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+

69 Àwọn tó ń kọjá àyè wọn ti fi irọ́ yí mi lára,

Àmọ́ mò ń fi gbogbo ọkàn mi pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.

70 Ọkàn wọn ti yigbì,*+

Àmọ́ mo fẹ́ràn òfin rẹ.+

71 Ó dára bí a ṣe fìyà jẹ mí,+

Kí n lè kọ́ àwọn ìlànà rẹ.

72 Òfin tí o kéde dára fún mi,+

Ó dára ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún wúrà àti fàdákà lọ.+

י [Yódì]

73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi, tí ó sì mọ mí.

Fún mi ní òye,+

Kí n lè kọ́ àwọn àṣẹ rẹ.

74 Àwọn tó bẹ̀rù rẹ rí mi, wọ́n sì ń yọ̀,

Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*+

75 Jèhófà, mo mọ̀ pé àwọn ìdájọ́ rẹ jẹ́ òdodo+

Àti pé nínú òtítọ́ rẹ ni o fìyà jẹ mí.+

76 Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀+ tù mí nínú,

Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe* fún ìránṣẹ́ rẹ.

77 Ṣàánú mi, kí n lè máa wà láàyè,+

Nítorí mo fẹ́ràn òfin rẹ.+

78 Kí ojú ti àwọn tó ń kọjá àyè wọn,

Nítorí wọ́n ń ṣe ohun tí kò dáa sí mi láìnídìí.*

Àmọ́ èmi yóò máa ronú lórí* àwọn àṣẹ rẹ.+

79 Kí àwọn tó bẹ̀rù rẹ pa dà sọ́dọ̀ mi,

Àwọn tó mọ ìránnilétí rẹ.

80 Kí ọkàn mi jẹ́ aláìlẹ́bi bí mo ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ,+

Kí ojú má bàa tì mí.+

כ [Káfì]

81 Ọkàn mi ń fà sí* ìgbàlà rẹ,+

Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*

82 Ojú mi fẹ́ máa rí ọ̀rọ̀ rẹ+

Nígbà tí mo béèrè pé: “Ìgbà wo lo máa tù mí nínú?”+

83 Nítorí mo dà bí ìgò awọ tí èéfín ti mú kí ó gbẹ,

Àmọ́ mi ò gbàgbé àwọn ìlànà rẹ.+

84 Ọjọ́ mélòó ni kí ìránṣẹ́ rẹ fi dúró?

Ìgbà wo lo máa dá àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi lẹ́jọ́?+

85 Àwọn tó ń kọjá àyè wọn gbẹ́ kòtò fún mi,

Àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́.

86 Gbogbo àṣẹ rẹ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.

Àwọn èèyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí; ràn mí lọ́wọ́!+

87 Díẹ̀ ló kù kí wọ́n pa mí rẹ́ kúrò láyé,

Àmọ́ mi ò pa àwọn àṣẹ rẹ tì.

88 Mú kí n máa wà láàyè nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

Kí n lè máa pa àwọn ìránnilétí tí o sọ mọ́.

ל [Lámédì]

89 Jèhófà, títí láé

Ni ọ̀rọ̀ rẹ yóò wà ní ọ̀run.+

90 Òtítọ́ rẹ wà láti ìran dé ìran.+

O ti fìdí ayé múlẹ̀ gbọn-in, kó lè máa wà nìṣó.+

91 Nípasẹ̀ ìdájọ́ rẹ ni wọ́n* fi wà títí di òní,

Nítorí ìránṣẹ́ rẹ ni gbogbo wọn.

92 Tí kì í bá ṣe pé mo fẹ́ràn òfin rẹ ni,

Mi ò bá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.+

93 Mi ò ní gbàgbé àwọn àṣẹ rẹ láé,

Torí pé nípasẹ̀ wọn lo fi mú kí n wà láàyè.+

94 Tìrẹ ni mo jẹ́; gbà mí sílẹ̀,+

Nítorí pé mo ti wá àwọn àṣẹ rẹ.+

95 Àwọn ẹni burúkú dènà dè mí láti pa mí,

Àmọ́ mò ń fiyè sí àwọn ìránnilétí rẹ.

96 Mo ti rí i pé kò sí ohun tó dáa tí kò kù síbì kan,

Àmọ́ àṣẹ rẹ dára láìkù síbì kan.*

מ [Mémì]

97 Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!+

Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ronú lé e lórí.*+

98 Àṣẹ rẹ mú kí n gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,+

Nítorí pé ó wà pẹ̀lú mi títí láé.

99 Mo ní òye tó jinlẹ̀ ju ti gbogbo àwọn olùkọ́ mi,+

Nítorí pé mò ń ronú lórí* àwọn ìránnilétí rẹ.

100 Mò ń fi òye hùwà ju àwọn àgbààgbà lọ,

Nítorí pé mò ń pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.

101 Mi ò rìn ní ọ̀nà ibi èyíkéyìí,+

Kí n lè máa pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.

102 Mi ò yà kúrò nínú àwọn ìdájọ́ rẹ,

Nítorí o ti kọ́ mi.

103 Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ mà dùn mọ́ òkè ẹnu mi o,

Ó dùn ju oyin lọ lẹ́nu mi!+

104 Àwọn àṣẹ rẹ ló mú kí n máa fòye hùwà.+

Ìdí nìyẹn tí mo fi kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.+

נ [Núnì]

105 Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi

Àti ìmọ́lẹ̀ fún ọ̀nà mi.+

106 Mo ti búra, màá sì mú un ṣẹ,

Kí n lè máa pa àwọn ìdájọ́ rẹ tó jẹ́ òdodo mọ́.

107 A ti fìyà jẹ mí gan-an.+

Jọ̀ọ́ Jèhófà, mú kí n máa wà láàyè bí o ṣe sọ.+

108 Jèhófà, jọ̀ọ́ jẹ́ kí inú rẹ dùn sí ọrẹ ìyìn àtọkànwá mi,*+

Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìdájọ́ rẹ.+

109 Ẹ̀mí mi wà nínú ewu* nígbà gbogbo,

Àmọ́ mi ò gbàgbé òfin rẹ.+

110 Àwọn ẹni burúkú ti dẹ pańpẹ́ dè mí,

Àmọ́ mi ò yà kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ.+

111 Mo fi àwọn ìránnilétí rẹ ṣe ohun ìní mi tí á máa wà títí lọ,*

Nítorí àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.+

112 Mo ti pinnu* láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ

Nígbà gbogbo, màá sì ṣe bẹ́ẹ̀ délẹ̀délẹ̀.

ס [Sámékì]

113 Mo kórìíra àwọn aláàbọ̀-ọkàn,*+

Àmọ́ mo nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ.+

114 Ìwọ ni ibi ààbò mi àti apata mi,+

Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*+

115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi,+

Kí n lè pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́.

116 Tì mí lẹ́yìn bí o ti ṣèlérí,*+

Kí n lè máa wà láàyè;

Má ṣe jẹ́ kí ìrètí mi já sí asán.*+

117 Tì mí lẹ́yìn, kí n lè rí ìgbàlà;+

Nígbà náà, èmi yóò máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìlànà rẹ.+

118 O kọ àwọn tó ń yà kúrò nínú àwọn ìlànà rẹ,+

Nítorí wọ́n jẹ́ onírọ́ àti ẹlẹ́tàn.

119 O kó gbogbo àwọn ẹni burúkú ayé dà nù bíi pàǹtírí.*+

Ìdí nìyẹn tí mo fi nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí rẹ.

120 Ẹ̀rù rẹ mú kí ara* mi máa gbọ̀n;

Mò ń bẹ̀rù àwọn ìdájọ́ rẹ.

ע [Áyìn]

121 Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ òdodo.

Má ṣe fi mí lé ọwọ́ àwọn tó ń ni mí lára!

122 Fi dá ìránṣẹ́ rẹ lójú pé wàá tì í lẹ́yìn;

Kí àwọn tó ń kọjá àyè wọn má ṣe ni mí lára.

123 Ojú mi ti di bàìbàì bí mo ṣe ń dúró de ìgbàlà rẹ+

Àti ìlérí* òdodo rẹ.+

124 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí ìránṣẹ́ rẹ,+

Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+

125 Ìránṣẹ́ rẹ ni mí; fún mi ní òye,+

Kí n lè mọ àwọn ìránnilétí rẹ.

126 Jèhófà, ó ti tó àkókò fún ọ láti gbé ìgbésẹ̀,+

Nítorí wọ́n ti rú òfin rẹ.

127 Ìdí nìyẹn tí mo fi nífẹ̀ẹ́ àwọn àṣẹ rẹ

Ju wúrà, kódà ju wúrà tó dára* lọ.+

128 Nítorí náà, mo gbà pé gbogbo ẹ̀kọ́* tó bá wá látọ̀dọ̀ rẹ tọ̀nà;+

Mo kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.+

פ [Péè]

129 Àwọn ìránnilétí rẹ jẹ́ àgbàyanu.

Ìdí nìyẹn tí mo* fi ń kíyè sí wọn.

130 Ṣíṣí ọ̀rọ̀ rẹ payá ń mú ìmọ́lẹ̀ wá,+

Ó ń fún àwọn aláìmọ̀kan ní òye.+

131 Mo la gbogbo ẹnu mi, mo sì mí kanlẹ̀,*

Nítorí pé ọkàn mi ń fà sí àwọn àṣẹ rẹ.+

132 Yíjú sí mi, kí o sì ṣojú rere sí mi,+

Gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ rẹ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ.+

133 Fi ọ̀rọ̀ rẹ darí ìṣísẹ̀ mi láìséwu;*

Kí aburú kankan má ṣe jọba lórí mi.+

134 Gbà mí* lọ́wọ́ àwọn aninilára,

Màá sì pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.

135 Mú kí ojú rẹ tàn sára* ìránṣẹ́ rẹ,+

Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.

136 Omijé ń dà ní ojú mi

Nítorí àwọn èèyàn kò pa òfin rẹ mọ́.+

צ [Sádì]

137 Olódodo ni ọ́, Jèhófà,+

Àwọn ìdájọ́ rẹ sì tọ́.+

138 Àwọn ìránnilétí rẹ jẹ́ òdodo,

Wọ́n sì ṣeé gbára lé pátápátá.

139 Ìtara mi fún ọ gbà mí lọ́kàn,+

Nítorí àwọn ọ̀tá mi ti gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ.

140 Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́ dáadáa,+

Ìránṣẹ́ rẹ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+

141 Mi ò já mọ́ nǹkan kan, mo sì jẹ́ ẹni ẹ̀gàn;+

Síbẹ̀, mi ò gbàgbé àwọn àṣẹ rẹ.

142 Òdodo rẹ jẹ́ òdodo ayérayé,+

Òfin rẹ sì jẹ́ òtítọ́.+

143 Bí wàhálà àti ìṣòro tilẹ̀ bá mi,

Síbẹ̀, mo fẹ́ràn àwọn àṣẹ rẹ.

144 Òdodo àwọn ìránnilétí rẹ wà títí láé.

Fún mi ní òye,+ kí n lè máa wà láàyè.

ק [Kófì]

145 Gbogbo ọkàn mi ni mo fi pè ọ́. Dá mi lóhùn, Jèhófà.

Màá pa àwọn ìlànà rẹ mọ́.

146 Mo ké pè ọ́; gbà mí!

Màá pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́.

147 Mo ti jí kí ilẹ̀ tó mọ́,* kí n lè kígbe fún ìrànlọ́wọ́,+

Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*

148 Ojú mi là kí àwọn ìṣọ́ òru tó bẹ̀rẹ̀,

Kí n lè ronú lórí* ọ̀rọ̀ rẹ.+

149 Jọ̀wọ́ gbọ́ ohùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+

Jèhófà, mú kí n máa wà láàyè nítorí ìdájọ́ òdodo rẹ.

150 Àwọn tó ń hu ìwà àìnítìjú* sún mọ́ tòsí;

Wọ́n jìnnà réré sí òfin rẹ.

151 Jèhófà, o wà nítòsí,+

Òtítọ́ sì ni gbogbo àṣẹ rẹ.+

152 Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti kọ́ nípa àwọn ìránnilétí rẹ,

Pé o ṣe wọ́n kí wọ́n lè wà títí láé.+

ר [Réṣì]

153 Wo ìyà tó ń jẹ mí, kí o sì gbà mí sílẹ̀,+

Nítorí mi ò gbàgbé òfin rẹ.

154 Gbèjà mi,* kí o sì gbà mí sílẹ̀;+

Mú kí n máa wà láàyè bí o ti ṣèlérí.*

155 Ìgbàlà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú,

Nítorí wọn kò wá àwọn ìlànà rẹ.+

156 Àánú rẹ pọ̀, Jèhófà.+

Mú kí n máa wà láàyè nítorí ìdájọ́ òdodo rẹ.

157 Àwọn ọ̀tá mi àti àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi pọ̀;+

Àmọ́ mi ò yà kúrò nínú àwọn ìránnilétí rẹ.

158 Ojú burúkú ni mo fi ń wo àwọn oníbékebèke,

Torí wọn kì í pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+

159 Wo bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn àṣẹ rẹ!

Jèhófà, mú kí n máa wà láàyè nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+

160 Òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ,+

Gbogbo ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo sì wà títí láé.

ש [Sínì] tàbí [Ṣínì]

161 Àwọn olórí ń ṣe inúnibíni sí mi+ láìnídìí,

Àmọ́ ìbẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ wà lọ́kàn mi.+

162 Ọ̀rọ̀ rẹ ń mú inú mi dùn,+

Bí ẹni tó rí ẹrù púpọ̀ kó lójú ogun.

163 Mo kórìíra irọ́, mo kórìíra rẹ̀ gidigidi,+

Mo nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ.+

164 Ìgbà méje lóòjọ́ ni mò ń yìn ọ́

Nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo.

165 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ;+

Kò sí ohun tó lè mú wọn kọsẹ̀.*

166 Mò ń retí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ, Jèhófà,

Mo sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.

167 Mò* ń pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́,

Mo sì nífẹ̀ẹ́ wọn púpọ̀.+

168 Mò ń pa àwọn àṣẹ àti àwọn ìránnilétí rẹ mọ́,

Nítorí o mọ gbogbo ohun tí mò ń ṣe.+

ת [Tọ́ọ̀]

169 Kí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ dé ọ̀dọ̀ rẹ, Jèhófà.+

Fún mi ní òye nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ.+

170 Kí ìbéèrè mi fún ojú rere wá síwájú rẹ.

Gbà mí bí o ti ṣèlérí.*

171 Kí ìyìn kún ẹnu mi,*+

Nítorí o ti kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.

172 Kí ahọ́n mi máa fi ọ̀rọ̀ rẹ kọrin,+

Nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.

173 Kí ọwọ́ rẹ ṣe tán láti ràn mí lọ́wọ́,+

Nítorí mo ti pinnu pé màá máa pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.+

174 Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, Jèhófà,

Mo sì fẹ́ràn òfin rẹ.+

175 Jẹ́ kí n* máa wà láàyè, kí n lè máa yìn ọ́;+

Kí àwọn ìdájọ́ rẹ máa ràn mí lọ́wọ́.

176 Mo ti ṣìnà bí àgùntàn tó sọ nù.+ Wá ìránṣẹ́ rẹ,

Nítorí mi ò gbàgbé àwọn àṣẹ rẹ.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́