16 Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,+ ó sì wúlò fún kíkọ́ni,+ fún bíbáni wí, fún mímú nǹkan tọ́,* fún títọ́nisọ́nà nínú òdodo,+17 kí èèyàn Ọlọ́run lè kúnjú ìwọ̀n dáadáa, kó sì lè gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere.
19 Torí náà, a ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a mú kó túbọ̀ dá wa lójú, ẹ sì ń ṣe dáadáa bí ẹ ṣe ń fiyè sí i bíi fìtílà+ tó ń tàn níbi tó ṣókùnkùn (títí ilẹ̀ fi máa mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́+ sì máa yọ) nínú ọkàn yín.