Àpẹẹrẹ Bíbá Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi Lò
NÍNÚ Òfin tí Jèhófà Ọlọ́run fún orílẹ̀-ède Ísírẹ́lì, ó rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí nípa ipò tí wọ́n wà ní Íjíbítì gẹ́gẹ́ bí olùwá-ibi-ìsádi. (Ẹ́kísódù 22:21; 23:9; Diutarónómì 10:19) Nítorí náà, ó fún wọn ní ìtọ́ni láti fi inú rere bá àwọn àtìpó tí ń gbé ní àárín wọn lò, bí arákùnrin ní ti gidi.
Òfin Ọlọ́run sọ pé: “Bí àlejò kan [tí ó sábà máa ń jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi] bá ń ṣe àtìpó pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ni ín lára. Kí àlejò tí ń bá a yín gbé kí ó já sí fún yín bí ìbílẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ ẹ bí ara rẹ; nítorí pé ẹ̀yín ti ṣe àlejò ní ilẹ Íjíbítì.”—Léfítíkù 19:33, 34.
Nítorí pé Jèhófà mọ̀ pé ìyà sábà máa ń jẹ àwọn àtìpó olùgbé, tí wọn kò sì láàbò, ó pèsè àwọn òfin pàtó fún ire àti ààbo wọn. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀tọ́ tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí, tí a yọ̀ǹda fún wọn.
Ẹ̀TỌ́ SÍ ÌGBẸ́JỌ́ ÀÌṢÈGBÈ: “Irú òfin kan ni ẹ̀yin óò ní, gẹ́gẹ́ bíi fún àlejò bẹ́ẹ̀ ni fún ìbílẹ̀.” “Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ àlejò po.”—Léfítíkù 24:22; Diutarónómì 24:17.
Ẹ̀TỌ́ SÍ ṢÍṢÀJỌPÍN NÍNÚ ÌDÁ MẸ́WÀÁ: “Ní òpin ọdún mẹ́ta ni kí ìwọ kí ó mú gbogbo ìdá mẹ́wàá ìbísí rẹ wá ní ọdún náà, kí ìwọ kí ó sì gbé e kalẹ̀ nínú ibodè rẹ. Àti ọmọ Léfì, nítorí tí kò ní ìpín tàbí ìní pẹ̀lú rẹ, àti àlejò, àti aláìníbaba, àti opó, tí ń bẹ nínú ibodè rẹ, yóò wá, wọn óò sì jẹ, wọn óò sì yó.”—Diutarónómì 14:28, 29.
Ẹ̀TỌ́ SÍ OWÓ Ọ̀YÀ TÍ Ó YẸ: “Ìwọ kò gbọdọ̀ ni alágbàṣe kan lára tí í ṣe tálákà àti aláìní, ì báà ṣe nínú àwọn arákùnrin rẹ, tàbí nínú àwọn àlejò rẹ tí ń bẹ ní ilẹ̀ rẹ nínú ibodè rẹ.”—Diutarónómì 24:14.
Ẹ̀TỌ́ SÍ IBI ÌSÁDI FÚN ẸNI TÍ Ó BÁ PÀNÌYÀN NÍ ÀÌMỌ̀: “Ìlú mẹ́fà wọ̀nyí ni yóò máa jẹ́ ààbò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti fún àlejò àti fún àtìpó láàárín wọn: kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ kí ó lè sá lọ síbẹ̀.”—Númérì 35:15.
Ẹ̀TỌ́ LÁTI PÈÉṢẸ́: “Nígbà tí ẹ̀yín bá ń ṣe ìkórè ilẹ̀ yín, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣa igun oko rẹ ní àṣàtán, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa èéṣẹ́ ìkórè rẹ. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ pèéṣẹ́ ọgbà àjàrà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ká gbogbo àjàrà ọgbà àjàrà rẹ; kí ìwọ kí ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tálákà àti àlejò: Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.”—Léfítíkù 19:9, 10.
Dájúdájú, Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, ní ìyọ́nú fún àwọn olùwá-ibi-ìsádi, inú rẹ̀ yóò sì dùn bí àwa pẹ̀lú bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àpósítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, . . . kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.”—Éfésù 5:1, 2.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọmọdékùnrin apá òsì: UN PHOTO 159243/J. Isaac