ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/22 ojú ìwé 11-13
  • Fọgbọ́n Lo Oògùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fọgbọ́n Lo Oògùn
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àǹfààní Ní Ìfiwéra Pẹ̀lú Ewu
  • Oògùn Agbógunti Kòkòrò Àrùn —Agbára àti Àbùkù Rẹ̀
  • Ṣé Abẹ́rẹ́ Gbígbà Sàn Ju Tábúlẹ́ẹ̀tì?
  • Gbàrọgùdù Oògùn
  • Ìṣòro ti Ipò Òṣì
  • Ṣe O Nílò Oògùn Ní Ti Gidi?
  • Oògùn—Ta Ló Ń Lò Ó?
    Jí!—2001
  • Báwo Ni Ara Rẹ Ṣe Lè Dá Ṣáṣá?
    Jí!—1998
  • Ṣé Àrùn Éèdì Máa Dópin? Bó Bá Rí Bẹ́ẹ̀, Lọ́nà Wo?
    Jí!—2002
  • Àkóbá Tí Oògùn Olóró Ń Ṣe fún Àwọn Ọ̀dọ́
    Jí!—2003
Jí!—1996
g96 9/22 ojú ìwé 11-13

Fọgbọ́n Lo Oògùn

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NÀÌJÍRÍÀ

OBÌNRIN náà sọ pé orí ń fọ́ òun, inú sì ń run òun. Dókítà bá a sọ̀rọ̀ díẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó kọ ìwọ̀n abẹ́rẹ́ ibà tí yóò gbà fún ọjọ́ mẹ́ta, parasítàmọ̀ (acetaminophen) láti dá ẹ̀fọ́rí dúró, oríṣi oògùn méjì tí yóò dẹ̀rọ̀ ohun tó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ọgbẹ́ inú, àwọn oògùn amáratuni fún àníyàn rẹ̀, àti ní paríparí rẹ̀, ní àfikún sí àwọn tí a kà sílẹ̀ wọ̀nyí, ó wọn multivitamins fún un. Owó tí wọ́n ní kí ó san pọ̀, ṣùgbọ́n obìnrin náà kò jiyàn. Ó fi ibẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ìdùnnú, pẹ̀lú ìdánilójú pé àwọn oògùn náà yóò yanjú àwọn ìṣòro òun.

Irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ sọ́dọ̀ dókítà kò ṣàjèjì ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Ìwádìí kan tí a ṣe ní orílẹ̀-èdè ńlá kan nibẹ̀ fi hàn pé àwọn olùtọ́jú aláìsàn ní àwọn ilé ìwòsàn gbogbogbòò ń ka ìpíndọ́gba 3.8 oríṣiríṣi oògùn fún aláìsàn kọ̀ọ̀kan ní gbogbo ìgbà tó bá wá. Ọ̀pọ̀ ènìyán rò pé, ní tòótọ́, dókítà tó bá ń kọ oògùn púpọ̀ fúnni jẹ́ dókítà dáradára.

Bóyá a lè lóye ìdí tí àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà fi ń ní ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ nínú oògùn bí a bá ronú nípa bí ọ̀ràn ìlera ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀. Ní ohun tí ó lé ní 40 ọdún sẹ́yìn, òǹkọ̀wé John Gunther kọ nípa àwọn ìgbà àtètèkọ́ṣe pé: “Kì í ṣe pé Etíkun Ìṣòwò Ẹrú yìí . . . ṣekú pa àwọn adúláwọ̀ nìkan ni; ó ṣekú pa àwọn òyìnbó pẹ̀lú, òun sì ni ìhà Áfíríkà tí a mọ̀ nínú ìtàn gẹ́gẹ́ bíi ‘Sàréè Òyìnbó.’ Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ẹ̀fọn ni ọba Etíkun Guinea láìsí iyàn nípa rẹ̀. Ibà pọ́njú, ibà blackwater, òtútù ibà, ni ohun ìjà burúkú tí ọba yìí yàn. Bí ipò ojú ọjọ́ Etíkun Ìwọ̀ Oòrùn náà ti ń ṣekú pani lọ́nà burúkú tó kì í ṣe ọ̀ràn tó fara sin, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìrántí tí kò pa run. Ìròyìn kúkúrú afàfẹ́mọ́ra kan ṣàpèjúwe àyànṣaṣojú orílẹ̀-èdè nílẹ̀ òkèèrè kan tí wọ́n yàn sí Nàìjíríà láìpẹ́ yìí, tí ń béèrè nípa owó ìfẹ̀yìntì rẹ̀. Ọ̀gá rẹ̀ ní Ọ́fíìsì Orílẹ̀Èdè náà dá a lóhùn pé: ‘Owó ìfẹ̀yìntì kẹ̀? Èèyàn mi, kò sí ẹni tó tí ì lọ sí Nàìjíríà tí í wà láàyè pẹ́ tó di ẹni tí í fẹ̀yìn tì.’”

Ipò nǹkan ti yàtọ̀. Lónìí, oògùn ti wà láti fi bá àwọn àrùn tí ẹ̀fọn ń tàn kálẹ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn àrùn míràn pẹ̀lú jà. Abẹ́rẹ́ àjẹsára nìkan ti dín iye àwọn tí èéyi, ikọ́ fée, àrùn ipá, àti àkọ èfù ń pa kù gidigidi. Ọpẹ́lọpẹ́ abẹ́rẹ́ àjẹsára tó jẹ́ kí a fòpin sí àrùn ìgbóná. Rọpárọsẹ̀ pẹ̀lú lè wáá di àrùn àtijọ́ láìpẹ́.

Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn ará Áfíríkà fi gbà gbọ́ jinlẹ̀jinlẹ̀ nínú agbára oògùn. Dájúdájú, irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ kò mọ sí Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà nìkan. Ní United States, àwọn dókítà máa ń júwe oògùn tí ó lé ní bílíọ̀nù 55 fúnni lọ́dọọdún. Ní ilẹ̀ Faransé, ní ìpíndọ́gba, àwọn ènìyán ń ra 50 páálí oògùn oníhóró lọ́dọọdún. Ní Japan pẹ̀lú, kòlà-kò-ṣagbe ènìyàn kan máa ń ná ju 400 dọ́là (U.S.) lọ sórí oògùn lọ́dọọdún.

Àwọn Àǹfààní Ní Ìfiwéra Pẹ̀lú Ewu

Àwọn oògùn ìgbàlódé ti ṣe ribiribi nínú ríran ẹ̀dá ènìyàn lọ́wọ́. Bí a bá lò wọ́n lọ́nà títọ́, wọ́n ń mú ìlera pípé wá, àmọ́ bí a kò bá lò wọ́n lọ́nà títọ́, wọ́n lè ṣèpalára, wọ́n tilẹ̀ lè pani. Fún àpẹẹrẹ, ní United States, nǹkan bí 300,000 ènìyàn ni a ń dá dúró sí ilé ìwòsàn lọ́dọọdún nítorí pé ara wọ́n kọ oògùn, àwọn 18,000 sì ń kú.

Láti fọgbọ́n lo oògùn, ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé ipa ewu sábà máa ń wà. Oògùn èyíkéyìí, kódà aspirin, lè mú ìyọrísí búburú wá. Ó ṣee ṣe kí ìyọrísí búburú tó pọ̀ jù wà bí o bá lo onírúurú oògùn pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan. Oúnjẹ àti omi tún máa ń nípa lórí bí oògùn ṣe ń ṣiṣẹ́ lára rẹ, ó sì lè mú kí ìyọrísí rẹ̀ le tàbí kí ó dẹwọ́.

Àwọn ewu mìíràn wà. Ara rẹ lè máa kọ irú oògùn kan. Bí o kò bá lo oògùn bí wọ́n ṣe kọ ọ́—ìwọ̀n tó yẹ fún ìwọ̀n àkókò tó yẹ—ó ṣeé ṣe kí ó má ṣàǹfààní fún ọ, ó sì lè pa ọ́ lára. Ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ bí dókítà rẹ bá kọ oògùn tí kò tọ́ tàbí oògùn tí kò pọn dandan. Ńṣe ni o ń fi ẹ̀mí wewu pẹ̀lú bí o bá ń lo àwọn oògùn tí ọjọ́ tí kọjá lórí rẹ̀, tí kò dára tó, tàbí tí ó jẹ́ gbàrọgùdù.

Láti dín àwọn ewu náà kù, ó yẹ kí o mọ púpọ̀ tó nípa oògùn èyíkéyìí tí o bá ń lò. O lè jàǹfààní gidigidi nípa mímọ àwọn òkodoro òtítọ́.

Oògùn Agbógunti Kòkòrò Àrùn —Agbára àti Àbùkù Rẹ̀

Láti ìgbà tí a ti ṣàwárí àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn ní nǹkan bí 50 ọdún sẹ́yìn, wọ́n ti gba ẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn là. Wọ́n ti ṣẹ́pá àwọn àrùn afoniláyà, bí ẹ̀tẹ̀, ikọ́ ẹ̀gbẹ, òtútù àyà, ibà scarlet, àti rẹ́kórẹ́kó. Wọ́n tún ti kó ipa pàtàkì nínú wíwo àwọn àkóràn míràn sàn.

Dókítà Stuart Levy, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìṣègùn ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ìṣègùn ti Yunifásítì Tufts ní United States, sọ pé: “[Àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn] ti mú ìyípadà tegbòtigaga wá bá ìmọ̀ ìṣègùn. Àwọn ni èròjà kan ṣoṣo tí ó tí ì yí ìtàn ìmọ̀ ìṣègùn padà jù lọ.” Aláṣẹ mìíràn nínú ìmọ̀ ìṣègùn sọ pé: “Àwọn ni òkúta igun ilé tí a kọ́ ìmọ̀ ìṣègùn òde òní lé lórí.”

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí o tóó sáré lọ béèrè fún wọn lọ́dọ̀ dókítà rẹ, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìhà búburú rẹ̀. Bí a kò bá lo àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn lọ́nà títọ́, wọ́n lè ṣe ìpalára tí ó pọ̀ ju ire lọ. Èyí jẹ́ nítorí pé àwọn oògùn agbógunti kòkòrò ń ṣiṣẹ́ nípa gbígbógun ti àwọn bakitéríà inú ara, wọ́n sì ń pa wọ́n. Ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà kọ́ ni wọ́n máa ń pa gbogbo bakitéríà tí ń ṣèpalára; ìgbóguntì náà kì í ran oríṣi àwọn bakitéríà kan. Kì í ṣe pé àwọn oríṣi tí oògùn kì í ràn wọ̀nyí ń là á já nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún máa ń pọ̀ sí i, wọ́n sì máa ń lọ láti ara ẹnì kan sí òmíràn.

Fún àpẹẹrẹ, penicillin máa ń ṣiṣẹ́ gan-an fún wíwo àwọn àkóràn sàn. Ní báyìí, lápá kan, nítorí pé àwọn oríṣi bakitéríà tí oògùn kì í ràn ń pọ̀ sí i, àwọn ilé iṣẹ́ oògùn ń ta ọgọ́rọ̀ọ̀rún oríṣiríṣi penicillin.

Kí ni o lè ṣe láti yẹra fún ìṣòro? Bí o bá nílò àwọn oògùn agbógunti kòkòrò ní ti gidi, rí i dájú pé dókítà tí ó tóótun ló kọ ọ́, kí wọ́n sì wá láti orísun tí ó yẹ. Má ṣe yọ dókítà rẹ lẹ́nu láti tètè kọ oògùn agbógunti kòkòrò—ó lè fẹ́ láti ṣe àyẹ̀wò ìwádìí àrùn láti rí i dájú pé èyí tí òun yóò kọ jẹ́ èyí tí ó yẹ fún àìsàn rẹ.

Ó tún ṣe pàtàkì pé kí o lo ìwọ̀n tó yẹ fún ìwọ̀n àkókò tó yẹ. Ó yẹ kí o lo ìwọ̀n oògùn agbógunti kòkòrò náà tán pátápátá, kódà bí ara rẹ bá ti ń yá kí o tóó tán.

Ṣé Abẹ́rẹ́ Gbígbà Sàn Ju Tábúlẹ́ẹ̀tì?

“Abẹ́rẹ́ ni mo fẹ́ gbà!” Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ló máa ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. A gbé irú ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ bẹ́ẹ̀ ka orí ìpìlẹ̀ èrò ìgbàgbọ́ pé a tú oògùn náà dà sínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀, ó sì ń woni sàn lọ́nà tó túbọ̀ lágbára ju ti tábúlẹ́ẹ̀tì tàbí ti oògùn oníhóró lọ. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, a sábà máa ń rí ‘àwọn dókítà agábẹ́rẹ́’ láìníwèé àṣẹ ní àwọn ọjà.

Abẹ́rẹ́ gbígbà ní ewu tí àwọn oògùn oníhóró àti tábúlẹ́ẹ̀tì kò ní. Bí abẹ́rẹ́ náà kò bá mọ́, aláìsàn náà lè kó àrùn mẹ́dọ̀wú, àrùn ipá, kódà àrùn AIDS pàápàá. Abẹ́rẹ́ dídọ̀tí tún lè fa ìwúlé aronilára. Àwọn ewu yóò pọ̀ sí i bí ó bá jẹ́ ẹni tí kò tóótun ló gún abẹ́rẹ́ náà.

Bí o bá ní láti gba abẹ́rẹ́ ní ti gidi, rí i dájú pé ẹni tí ó tóótun ní ti ìmọ̀ ìṣègùn ló gún un. Fún ààbò rẹ, máa rí i dájú nígbà gbogbo pé abẹ́rẹ́ àti ike abẹ́rẹ́ náà jẹ́ èyí tí kò ní kòkòrò àrùn.

Gbàrọgùdù Oògùn

Òwò ńlá ní iṣẹ́ ìpoògùn jẹ́ kárí ayé, ó ń pa nǹkan bí 170 bílíọ̀nù dọ́là (U.S.) wọlé lọ́dọọdún, gẹ́gẹ́ bí Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ti sọ. Pẹ̀lú ìháragàgà láti fi ipò ọ̀ràn náà ṣèfà jẹ, àwọn ènìyànkénìyàn ti ń ṣe ayédèrú oògùn. Ayédèrú oògùn jọ ojúlówó oògùn—bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn lébẹ́ẹ̀lì àti ohun tí a kó wọn sí—àmọ́ wọn kò wúlò.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn gbàrọgùdù oògùn wà níbi gbogbo, ní pàtàkì, wọ́n wọ́pọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, wọ́n sì ń mú àbájáde bíbani nínú jẹ́ wá. Ní Nàìjíríà, àwọn ọmọdé 109 ni àìṣiṣẹ́ kíndìnrín pa lẹ́yìn tí wọ́n lo oògùn olómi apàrora tí ó ní omi ìdọ̀tí nínú. Ní Mexico, àwọn tí ara wọ́n jóná jìyà àkóràn awọ ara láti inú ohun tí ó yẹ kí ó wò wọ́n sàn tí ó ní lẹ́búlẹ́bú pákó, kọfí, àti ìdọ̀tí nínú. Ní Burma, ibà lè ti pa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ará abúlé nítorí lílo gbàrọgùdù oògùn tí kò bá otútù ibà jà. Àjọ WHO sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn tí wọ́n wà nínú ewu jù lọ ni àwọn òtòṣì gan-an, tí wọ́n ń ronú nígbà míràn pé ìdúnàádúrà dáradára ló jẹ́ tí àwọ́n bá ra oògùn tó dà bí èyí tí ń ṣiṣẹ́ dáradára tí ilé iṣẹ́ tí a bọ̀wọ̀ fún kan ṣe.”

Báwo ni o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ gbàrọgùdù oògùn? Rí i dájú pé ohun tí o rà wá láti orísun tí gbogbo ènìyán mọ̀ sí rere, irú bí ẹ̀ka ìpòògùn ní ilé ìwòsàn. Má ṣe rà á lọ́wọ́ àwọn tí ń kiri ọjà lópòópónà. Apòògùn kan ní Benin City, Nàìjíríà, kìlọ̀ pé: “Títa oògùn wulẹ̀ jẹ́ òwò lójú àwọn tí ń ta oògùn lópòópónà ni. Ńṣe ni wọ́n ń ta oògùn bíi pé dáyá tàbí bisikíìtì ni. Lọ́pọ̀ ìgbà ló máa ń jẹ́ pé àwọn oògùn tí wọ́n ń ta kò dára fún lílò mọ́ tàbí kí ó jẹ́ gbàrọgùdù. Àwọn ènìyàn náà kò mọ nǹkan kan nípa àwọn oògùn tí wọ́n ń tà.”

Ìṣòro ti Ipò Òṣì

Owó tí ẹnì kan ní ló sábà máa ń pinnu irú ìtọ́jú ìṣègùn tí yóò rí gbà. Láti dín ìnáwó kù àti láti má ṣe fi àkókò ṣòfò, àwọn ènìyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lè pa dókítà tì, kí wọ́n sì lọ tààràtà sí ilé ìtajà oògùn láti ra oògùn tí òfin sọ pé dókítà gbọ́dọ̀ kọ kí a tóó rà á. Nítorí pé wọ́n ti lo oògùn náà rí tàbí nítorí pé àwọn ọ̀rẹ́ wọn ló júwe rẹ̀ fún wọn, wọ́n mọ ohun tí wọ́n fẹ́ẹ́ lò fún àìsàn wọn. Ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n fẹ́ lè máà jẹ́ ohun tí wọ́n nílò.

Àwọn ènìyán máa ń gbìyànjú láti dín ìnáwó kù ní àwọn ọ̀nà míràn pẹ̀lú. Dókítà kan ṣe àyẹ̀wò àrùn fún aláìsàn kan, ó sì kọ irú oògùn kan. Aláìsàn mú oògùn tí ó kọ náà lọ sí ibi ìtajà oògùn, àmọ́ ó rí i pé ó wọ́n. Nítorí náà, dípò kí àwọn ènìyán wá owó sí i, wọ́n sábà máa ń ra oògùn tí kò wọ́n jù tàbí kí wọ́n ra àwọn kan lára àwọn oògùn tí a kọ fún wọn.

Ṣe O Nílò Oògùn Ní Ti Gidi?

Bí o bá nílò oògùn ní ti gidi, wádìí ohun tí o ń kó mì. Má ṣe jẹ́ kí ojú tì ọ́ láti wádìí lọ́wọ́ dókítà tàbí apòògùn nípa oògùn tí wọ́n kọ fún ọ. O ní ẹ̀tọ́ láti mọ̀. Ó ṣe tán, ìwọ ni ara yóò ro.

Bí o kò bá lo oògùn rẹ dáradára, ara rẹ lè máà yá. Ó yẹ kí o mọ ìwọ̀n tí ó yẹ kí o lò, ìgbà tí ó yẹ kí o lò ó, àti bí ó ṣe yẹ ki o lò ó pẹ́ tó. Ó tún yẹ kí o mọ irú oúnjẹ, ohun mímu, àti àwọn oògùn míràn tàbí àwọn ìgbòkègbodò tí ó yẹ kí ó yẹra fún nígbà tí o bá ṣì ń lò ó. Ó sì tún yẹ kí o mọ àwọn ìyọrísí búburú tí ó lè ṣẹlẹ̀ àti ohun tí ó yẹ kí o ṣe bí wọ́n bá ṣẹlẹ̀.

Fi sọ́kàn pẹ̀lú, pé àwọn oògùn kì í mú ojútùú wá fún gbogbo ìṣòro àìlera. O lè ṣàìnílò oògùn rárá. Ìwé ìròyìn World Health, ìtẹ̀jáde kan tí àjọ WHO ṣe, sọ pé: “Lo oògùn, kìkì nígbà tí o bá nílò rẹ̀. Ìsinmi, oúnjẹ tí ó jíire àti ọ̀pọ̀ ohun mímu sábà máa ń tó láti ṣàǹfààní fún ẹnì kan láti sàn.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Eléwì ará Róòmù kan kọ̀wé ní nǹkan bí 2,000 ọdún sẹ́yìn pé: “Ẹgbẹ̀rún àìsàn nílò ẹgbẹ̀rún ìwòsàn.” Lónìí, eléwì náà ì bá ti kọ̀wé pé, ‘Ẹgbẹ̀rún àìsàn nílò ẹgbẹ̀rún oògùn oníhóró’! Ní ti gidi, ó jọ pé àìsàn kọ̀ọ̀kan ló fẹ́rẹ̀ẹ́ ní oògùn oníhóró kọ̀ọ̀kan tí ó wà fún un, yálà gidi tàbí àfinúrò. Gẹ́gẹ́ bí Báǹkì Àgbáyé ti sọ, nǹkan bí 100,000 oríṣiríṣi oògùn ló wà jákèjádò ayé, tí a fi ohun tí ó lé ní 5,000 èròjà lílágbára ṣe.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Bí A Ṣe Lè Fọgbọ́n Lo Oògùn

1. Má ṣe lo àwọn oògùn tí ọjọ́ ti kọjá lórí wọn.

2. Rà láti orísun tí gbogbo ènìyán mọ̀ sí rere. Má ṣe rà lọ́wọ́ àwọn tí ń kiri lópòópónà.

3. Rí í dájú pé o lóye ìtọ́ni, o sì tẹ̀ lé e.

4. Má ṣe lo oògùn tí a kọ fún ẹlòmíràn.

5. Má ṣe tẹpẹlẹ mọ́ abẹ́rẹ́ gbígbà. Àwọn oògùn tí a ti ẹnu lò máa ń ṣiṣẹ́ dáradára bákan náà.

6. Kó oògùn sí ibi tí ó tutù, tí kò sí lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ọmọdé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́