ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 7/8 ojú ìwé 5-8
  • Báwo Ni Ara Rẹ Ṣe Lè Dá Ṣáṣá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Ara Rẹ Ṣe Lè Dá Ṣáṣá?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbà Tó Yẹ Ká Wá Ìrànwọ́ Ìṣègùn
  • Kí Ni O Lè Ṣe Láti Mú Kí Ara Rẹ Dá Ṣáṣá?
  • Àwọn Àǹfààní àti Ewu—Lílo Oògùn Láìkọ́kọ́rí-Dókítà
    Jí!—1998
  • Fọgbọ́n Lo Oògùn
    Jí!—1996
  • Ìdààmú Àwọn Dókítà
    Jí!—2005
  • Bóo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ìlera Rẹ
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 7/8 ojú ìwé 5-8

Báwo Ni Ara Rẹ Ṣe Lè Dá Ṣáṣá?

ÌTỌ́JÚ jẹ́ kókó ìjíròrò wíwọ́pọ̀ kan. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ọ̀rẹ́ tàbí aládùúgbò ló ń ní ojútùú kan tó yàn láàyò fún àìlera kọ̀ọ̀kan. A lè lóye pé ìfẹ́ láti lo oògùn láìkọ́kọ́rí-dókítà lè lágbára gan-an. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí dókítà ará Brazil kan ṣe sọ, àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n “máa ń wá dókítà nígbà tí àìsàn náà bá ti wọra gan-an nìkan. Wọ́n lè ní ọgbẹ́ awọ ara kan tí kò sàn láìka ọ̀pọ̀ oṣù tí wọ́n ti fi ń lo oògùn láìkọ́kọ́rí-dókítà sí. Nígbà tí wọ́n bá wá lọ rí dókítà, a lè rí i pé wọ́n ní oríṣi jẹjẹrẹ kan tí ó yẹ kí wọ́n ti tọ́jú níbẹ̀rẹ̀.”

Níwọ̀n bí mímọ àrùn níbẹ̀rẹ̀ ti ń gba ẹ̀mí là, dídúrópẹ́ lè fa ìrora púpọ̀. Oníṣẹ́-abẹ kan sọ pé: “Obìnrin ẹni 30 ọdún kan kò tètè rí nǹkan oṣù rẹ̀, inú sì ń kan án nísàlẹ̀ ikùn. Láìkọ́kọ́rí-dókítà, ó kó ọ̀pọ̀ egbòogi apàrora àti egbòogi tí kì í jẹ́ kí ara dunni mì, ìrora náà sì dín kù. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, ẹ̀jẹ̀ dà lára rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi dákú, tí wọ́n sì yára gbé e dìgbàdìgbà wá sí ilé ìwòsàn. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo ṣe iṣẹ́ abẹ fún un, mo sì rí i pé ó lóyún ni. Díẹ̀ ló kù kí ẹ̀mí rẹ̀ bọ́!” Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan ní São Paulo rò pé òun kò ní ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ tó lára ni, ṣùgbọ́n kíndìnrín rẹ̀ ni kò lágbára tó láti ṣiṣẹ́. Nítorí pé ó pẹ́ kó tó gba ìtọ́jú, ojútùú kan ṣoṣo tó ṣeé ṣe ni ìpààrọ̀ kíndìnrín. Dókítà rẹ̀ parí ọ̀rọ̀ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, aláìsàn máa ń lọ́ra láti wá ìtọ́jú, ó máa ń lo oògùn láìkọ́kọ́rí-dókítà, tàbí kí ó máa wá àwọn ọ̀nà mìíràn tí àwọn tí kì í ṣe amọṣẹ́dunjú ń sọ, ó sì wá ń ní àwọn àìsàn bíburú jáì níkẹyìn.”

Dájúdájú, a kò fẹ́ fojú tín-ínrín àwọn àmì tí ara wa ń gbé jáde. Síbẹ̀, báwo ni a ṣe lè yẹra fún fífarajin ìtọ́jú tàbí lílo oògùn láìkọ́kọ́rí-dókítà? A túmọ̀ ìlera sí “ipò ara, ìrònú, tàbí ẹ̀mí tó dá ṣáṣá” tàbí pé ó jẹ́ “bíbọ́ lọ́wọ́ àrùn tàbí ìrora.” Lọ́nà tó dùn mọ́ni, àwọn ènìyàn gbà pé, dé ìwọ̀n àyè kan ṣáá, ọ̀pọ̀ jù lọ àrùn ló ṣeé dènà lóde òní. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Lewis Thomas ṣe sọ, “kàkà kí a wulẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí kò bára mu tí a tò pọ̀ bákan ṣáá, a jẹ́ ẹ̀dá lílera, tó lè wà pẹ́, tí ara rẹ̀ sì dá ṣáṣá.” Nítorí náà, kàkà ‘kí a di asoríkọ́ nítorí àwọn àrùn àfinúrò, kí a sì máa da ara wa láàmú débi tí a fi lè fẹ́rẹ̀ẹ́ para wa,’ ó yẹ kí a fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wa fúnra rẹ̀ àti agbára àrà ọ̀tọ̀ tó ní láti wo ara rẹ̀ sàn. Dókítà tàbí oníṣẹ́ ìṣègùn tó dáńgájíá pẹ̀lú lè ràn wá lọ́wọ́.

Ìgbà Tó Yẹ Ká Wá Ìrànwọ́ Ìṣègùn

Dókítà ará Brazil kan sọ pé a nílò ìrànwọ́ amọṣẹ́dunjú “bí àwọn àmì àrùn bí ibà, ẹ̀fọ́rí, èébì, tàbí ìrora nínú ikùn, tàbí àyà, tàbí oríkèé ọ̀pá ẹ̀yìn kò bá rọlẹ̀ lẹ́yìn lílo egbòogi wíwọ́pọ̀, tí ó sì ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ láìsí ìdí tó hàn kedere kankan, tàbí bí ìrora náà bá le tàbí tí ó pọ̀ gan-an.” Dókítà mìíràn dámọ̀ràn gbígba ìrànwọ́ ìṣègùn nígbàkigbà tí ohun tí ó yẹ kí a ṣe sí àmì àrùn tí a ní kò bá dáni lójú tàbí tí a rò pé ìyàtọ̀ kan wà sí bó ti máa ń rí nígbà mìíràn. Ó fi kún un pé: “Ní gbogbogbòò, nígbà tí ara ọmọdé kan kò bá yá, dípò kí àwọn òbí lo egbòogi fún un láìkọ́kọ́rí-dókítà, wọ́n máa ń yàn láti gba ìrànwọ́ amọṣẹ́dunjú.”

Àmọ́, ǹjẹ́ ìgbà gbogbo ló pọndandan láti lo oògùn? Ǹjẹ́ lílo oògùn lè dá wàhálà mìíràn sílẹ̀? Ǹjẹ́ àwọn ìyọrísí búburú, bí ọgbẹ́ inú tàbí bíba ẹ̀dọ̀ki tàbí kíndìnrín jẹ́, lè ṣẹlẹ̀? Kí ni ó lè ṣẹlẹ̀ bí a bá tún lo oríṣi oògùn mìíràn? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Àwọn aláìsàn tí kì í ti ìmọ̀lára bọ bí wọ́n ṣe ń wo àìsàn wọn, tàbí tí wọ́n tilẹ̀ ń fi òye wò ó kò tó nǹkan.” Síbẹ̀, dókítà kan tó jáfáfá lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé, gbogbo oògùn ló lè ṣèpalára, àti pé ṣàṣà oògùn tí a ń lò lónìí ni kò ní àwọn àbájáde búburú. Ṣáà ka àwọn ìkìlọ̀ nípa ohun tí ó lè wá jẹ́ àbájáde búburú tí wọ́n kọ sára oògùn tí o bá tún rà! Kódà, àwọn oògùn tí a ń rà lórí àtẹ pàápàá lè pani lára tàbí kí wọ́n fa ikú bí a bá ṣì wọ́n lò tàbí tí a lò wọ́n ju bó ti yẹ lọ.

Ìròyìn kan tí Richard A. Knox gbé jáde nínú ìwé ìròyìn The Boston Globe tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ kí a ṣọ́ra pé: “Àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Stanford ròyìn pé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó ní àrùn làkúrègbé tí wọ́n ń lo àwọn oògùn apàrora lójoojúmọ́ ń fara wewu ẹ̀jẹ̀ dídà lójijì tó sì lè pani.” Ó ṣàfikún pé: “Síwájú sí i, àwọn olùwádìí náà kìlọ̀ pé, lílo àwọn oògùn apàrora náà pọ̀ mọ́ àwọn oògùn tí ń gbógun ti ásíìdì tàbí àwọn oògùn wíwọ́pọ̀ tí ń dènà ásíìdì kì í dáàbò boni lọ́wọ́ àwọn àrùn ikùn tó burú jáì, wọ́n sì tilẹ̀ lè mú kí ewu náà pọ̀ sí i.”

Lílo oògùn láìkọ́kọ́rí-dókítà tó wá wọ́pọ̀ ńkọ́? Dókítà kan ní Ribeirão Prêto, Brazil, wí pé: “Mo rò pé yóò ṣàǹfààní bí ẹni gbogbo bá lè máa ní àwọn àkójọ oògùn bí mélòó kan nílé . . . Bí ó ti wù kí ó rí, a ní láti máa lo ọgbọ́n àti òye nínú bí a ó ṣe máa lo oògùn wọ̀nyí.” (Wo àpótí, ojú ìwé 7.) Bákan náà, níní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ nípa ìlera ń mú kí ìgbésí ayé sunwọ̀n sí i. Níwọ̀n bí ipò ẹnì kọ̀ọ̀kan ti yàtọ̀, Jí! kò dámọ̀ràn oògùn, ìtọ́jú, tàbí ìwòsàn àdánidá pàtó kankan.

Kí Ni O Lè Ṣe Láti Mú Kí Ara Rẹ Dá Ṣáṣá?

Jonathan Swift, òǹkọ̀wé kan ní ọ̀rúndún kejìdínlógún kọ̀wé pé: “Àwọn dókítà tó dára jù lágbàáyé ni Dókítà Oúnjẹ, Dókítà Ìfọkànbalẹ̀ àti Dókítà Ìtẹ́lọ́rùn.” Ní tòótọ́, jíjẹ oúnjẹ tí èròjà rẹ̀ pé, fífi ọkàn balẹ̀, àti níní ìtẹ́lọ́rùn jẹ́ àwọn èròjà pàtàkì fún ìlera. Ní òdì kejì, láìka gbogbo ohun tí ìpolówó ọjà ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ń sọ sí, lílo oògùn ṣáá kò lè fún wa ní ìlera. “Lílo oògùn láìnídìí tàbí lọ́nà líléwu pàápàá” lè sọ agbára ìdènà àrùn tó wà nínú ara di ahẹrẹpẹ.—Dicionário Terapêutico Guanabara.

Bí ó ti wù kí ó rí, nípa ṣíṣe ojúṣe wa nínú ọ̀nà ìgbésí ayé wa, àti yíyẹra fún ìjoògùnyó, sìgá mímu, ọtí àmujù, àti lílo ara jù, a lè ṣe ohun púpọ̀ láti mú ìlera wa sunwọ̀n sí i. Marian, tí ó ti lé ní ọmọ 60 ọdún, tí ó sì ti jẹ́ míṣọ́nnárì láti ìgbà pípẹ́ ní Brazil, wí pé: “Mo ti ní ìwọ̀n ìlera bíbọ́gbọ́nmu nípa gbígbé ìgbésí ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì àti jíjẹ oríṣiríṣi oúnjẹ gbígbámúṣé.” Ó tún ṣàlàyé pé: “Mo sábà máa ń fẹ́ láti tètè jí, nítorí náà, títètèsùn ṣe pàtàkì.” Kò yẹ kí a fojú tín-ínrín níní òye àti àṣà ìhùwà gbígbámúṣé, bákan náà sì ni ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe àwọn àyẹ̀wò ìlera látìgbàdégbà òun ìfikùnlukùn tó nítumọ̀ pẹ̀lú dókítà ìdílé tó jáfáfá.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Marian ń fẹ́ láti máa ní ìlera nígbà gbogbo, ó ń ṣọ́ra láti má ṣàìka ìlera rẹ̀ sí, kí ó má sì dààmú nípa rẹ̀ jù. Ó sọ pé: “Mo tún máa ń gbàdúrà fún ìdarí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà nínú ìpinnu tí mo bá ń ṣe nípa ìlera, kí n lè ṣe ohun tí ó bá dára jù fún àkókò tí ń bọ̀, kí n má sì lo àkókò àti owó ju bó ti yẹ lọ nínú ìsapá láti mú ìlera mi sunwọ̀n sí i.” Ó fi kún un pé: “Níwọ̀n bí àìjókòó-gẹlẹtẹ ti ṣe pàtàkì, mo ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run máa ràn mí lọ́wọ́ láti lo ọgbọ́n nípa bí mo ṣe ń lo àkókò àti okun inú mi, kí n má bàa kẹ́ra mi bàjẹ́ láìnídìí, kí n má sì ṣe ju ohun tí agbára mi gbé lọ nígbà kan náà.”

Láti jẹ́ aláyọ̀ ní tòótọ́, a kò lè ṣàìronú kan ọjọ́ ọ̀la. Kódà bí a bá rìnnà kore, tí a sì lera nísinsìnyí, ìyẹn kò mú àrùn, ìrora, ìjìyà, àti ikú nígbẹ̀yìngbẹ́yín kúrò. Ǹjẹ́ ìrètí kan wà pé a óò gbádùn ìlera pípé nígbà kankan láé?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Àǹfààní Ìtọ́jú Ara Ẹni Níwọ̀ntúnwọ̀nsì

Ohun tí o ń jẹ àti èyí tí o ń mu ń nípa púpọ̀ lórí ìlera rẹ. Bí o bá gbìyànjú láti wa ọkọ̀ ti wọ́n ti fi omi lú epo rẹ̀, tàbí tí wọ́n da ṣúgà sí epo náà, wàá ba ẹ́ńjìnnì rẹ̀ jẹ́. Lọ́nà kan náà, bí o bá ń jẹ àwọn pàrùpárù oúnjẹ, tí o ń mu àwọn ohun tí kò lè ṣara lóore, níkẹyìn, wàá di aláìlera. Nínú ayé oníkọ̀ǹpútà yìí, wọ́n ń pe èyí ní “GIGO,” tó túmọ̀ sí “garbage in, garbage out [pàǹtírí wọlé, pàǹtírí jáde].”

Dókítà Melanie Mintzer, ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ ìṣègùn ìdílé, ṣàlàyé pé: “Oríṣi aláìsàn mẹ́ta ló wà: àwọn tí ń gbé àwọn àrùn tí àwọn fúnra wọn lè tọ́jú nílé lọ bá oníṣègùn, àwọn tí ń lo ìpèsè ìtọ́jú ìlera bó ṣe yẹ, àti àwọn tí kì í lọ sọ́dọ̀ oníṣègùn nígbà tí ó bá tilẹ̀ pọndandan pàápàá. Àwọn oríṣi àkọ́kọ́ wulẹ̀ sábà máa ń fi àkókò oníṣègùn àti àkókò òun owó ti ara wọn ṣòfò ni. Àwọn oríṣi kẹta lè máa fi ẹ̀mí ara wọn wewu nípa fífi ìtọ́jú amọṣẹ́dunjú falẹ̀. Àwọn dókítà ń fẹ́ kí ọ̀pọ̀ ènìyàn sí i wà nínú àwùjọ ti àárín.”

“Àwọn ohun méje tó ṣe pàtàkì jù fún ìlera yíyẹ ni: máa jẹ oúnjẹ gbígbámúṣé, kí o sì máa mu ohun tó ń ṣara lóore; máa ṣeré ìmárale déédéé; má mu sìgá; máa sinmi dáadáa; kápá wàhálà másùnmáwo rẹ; máa ní àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà déédéé; sì máa lo ìṣọ́ra tó yẹ láti dín ewu ṣíṣàìsàn àti ṣíṣejàǹbá kù.”—Before You Call the Doctor—Safe, Effective Self-Care for Over 300 Medical Problems, láti ọwọ́ Anne Simons, M.D., Bobbie Hasselbring, àti Michael Castleman.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Àpótí Oògùn Inú Ilé

“A ti díwọ̀n rẹ̀ pé nǹkan bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àmì àrùn—ara dídùn, ìrora, ara bíbó, àti àwọn àmì àìfararọ tàbí àrùn mìíràn—tí àwọn àgbàlagbà tí a lè sọ pé ara wọn dá ń ní, ni wọn kì í kà sí, tí wọn kì í sì í sọ fún ẹnikẹ́ni. . . . Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń lo àwọn oògùn tó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó, bí aspirin 2 fún ẹ̀fọ́rí.”

“Ohun tí ń mú kí èyí ṣeé ṣe lọ́pọ̀ ìgbà ni àpótí oògùn inú ilé. Ó ń gbani lọ́wọ́ rírin ìrìn tí kò pọndandan tí ń náni lówó lọ́ sọ́dọ̀ dókítà tàbí sílé ìwòsàn.”—Complete Home Medical Guide, Kọ́lẹ́ẹ̀jì Àwọn Oníṣègùn àti Àwọn Oníṣẹ́-Abẹ ní Yunifásítì Columbia.

Ìwé yìí kan náà dámọ̀ràn pé kí a ní àpótí oògùn inú ilé tó ní àwọn ohun tí a lè fi di ọgbẹ́, aṣọ tàbí bébà tẹ́ẹ́rẹ́ tó ṣeé fi lẹ ara, báńdéèjì oníhò tí ó mọ́ tónítóní, abá òwú, báńdéèjì, onírúurú nǹkan ìwọ́ra àti ìpara, ìpara tó ní oògùn apakòkòrò nínú, àlùmọ́gàjí, èlò ìdíwọ̀n ìgbóná ara tí a ń kì bọ ẹnu, àti àwọn ohun wíwúlò mìíràn nínú.

Ní ti àwọn oògùn, ó dámọ̀ràn àwọn oògùn oníhóró fún ibà àti ìrora, àwọn oògùn tí ń gbógun ti ásíìdì, oògùn ikọ́, oògùn antihistamine tàbí oògùn tí kì í jẹ́ kí inú kún, oògùn ìyàgbẹ́, àti oògùn ìgbẹ́ gbuuru.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

Ìkìlọ̀

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò nílò kí dókítà kọ wọ́n fúnni, oògùn gidi ni àwọn OTC [oògùn tí a ń rà lórí àtẹ]. Bí ti àwọn tí dókítà ń kọ fúnni, àwọn kan wà tí a kò gbọ́dọ̀ lò pọ̀ mọ́ àwọn mìíràn tàbí tó ní èèwọ̀ oúnjẹ tàbí ohun mímu kan. Bí àwọn oògùn mìíràn ti ń ṣe, àwọn kan nínú wọn lè gbé àwọn àìsàn tó túbọ̀ burú pa mọ́ tàbí kí wọ́n di èyí tí a ń gbára lé. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ fi lílo oògùn kan tí a ń rà lórí àtẹ rọ́pò kíkàn sí dókítà.

“Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn dára, wọ́n sì gbéṣẹ́ . . . Wọ́n ń ṣe ohun tí a fẹ́ kí wọ́n ṣe, wọ́n sì ń ṣe é dáadáa.”—Using Medicines Wisely.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Máa rántí pé kò sí ewé tàbí oògùn kan tí kò léwu rárá

1. Àpótí oògùn akiri-oògùn

2. Akiri-oògùn ní gbangba

3. Àwọn àpò oògùn eléwé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́