ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 7/8 ojú ìwé 3-5
  • Àwọn Àǹfààní àti Ewu—Lílo Oògùn Láìkọ́kọ́rí-Dókítà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Àǹfààní àti Ewu—Lílo Oògùn Láìkọ́kọ́rí-Dókítà
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílo Oògùn Láìkọ́kọ́rí- Dókítà—Ó Léwu Bí?
  • Dídá-Àrùn-Mọ̀ Láìséwu—Báwo?
  • Báwo Ni Ara Rẹ Ṣe Lè Dá Ṣáṣá?
    Jí!—1998
  • Fọgbọ́n Lo Oògùn
    Jí!—1996
  • Ewé àti Egbò Ṣé O Lè Lò Ó fún Ìwòsàn?
    Jí!—2004
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Àwọn Ìlànà Ìtọ́jú Àfirọ́pò
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 7/8 ojú ìwé 3-5

Àwọn Àǹfààní àti Ewu—Lílo Oògùn Láìkọ́kọ́rí-Dókítà

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Brazil

Ọ̀GÁ àgbà ilé iṣẹ́ apoògùn ńlá kan sọ pé: “Òwò lílo oògùn láìkọ́kọ́rí-dókítà ń gbilẹ̀ kárí ayé. Àwọn ènìyàn ń fẹ́ láti máa dá ṣàkóso ọ̀ràn ìlera wọn.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ àwọn ewu kan wà tí ó yẹ kí o mọ̀?

Ó dájú pé egbòogi lè mú ìtura wá, bí a bá lò ó bó ṣe yẹ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn egbòogi insulin àti àwọn egbòogi tí a fi ń gbógun ti kòkòrò àrùn, títí kan àpòpọ̀ àtẹnujẹ fún ìdápadà omi ara tí kò gbówó lérí, tó sì rọrùn pàápàá, ti gba àìlóǹkà ẹ̀mí là. Ìṣòro tó gbàfiyèsí nínú ọ̀ràn lílo oògùn láìkọ́kọ́rí-dókítà ni bí a ṣe lè pinnu ìgbà tí àǹfààní rẹ̀ pọ̀ ju ewu rẹ̀ lọ.

A gbà pé ní àwọn ilẹ̀ kan, ó ṣeé ṣe kí àwọn ìpèsè ìṣègùn títóótun jìnnà tàbí kí wọ́n gbówó lérí jù. Nítorí náà, àwọn ènìyàn ń gbára lé ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn ìwé báyìí-làá-ṣeé bá sọ nípa ìṣègùn. Bákan náà, Fernando Lefèvre, ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Yunifásítì São Paulo, ní Brazil, wí pé, “àwọn ìpolongo tí a ń ṣe fún ará ìlú ń fúnni ní èrò pé ríra egbòogi kan ṣáá lè máa mú kí ara wa dá ṣáṣá, kí ó sì máa le koko.”a Ìyọrísí rẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lo oògùn láti borí ipá tí iṣẹ́ àṣekúdórógbó, àìjẹunrekánú, àti àwọn ìṣòro ìmọ̀lára pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ pàápàá ń ní. Lefèvre ṣàfikún pé: “Kàkà kí àwọn ènìyàn mú ọ̀nà ìgbésí ayé wọn dára sí i, wọ́n ń gbìyànjú láti tán àwọn ìṣòro wọn nípa lílo oògùn láìkọ́kọ́rí-dókítà.” Ta ló sì tilẹ̀ lè sọ bóyá ẹni náà mọ àìsàn tó ń ṣe é gan-an dájú?

Láfikún sí lílo oògùn nítorí àwọn àìsàn bí ẹ̀fọ́rí, ẹ̀jẹ̀ ríru, àti inú rírun, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lo oògùn nítorí hílàhílo, ìbẹ̀rù, àti ìnìkanwà. Dókítà André Feingold sọ pé: “Àwọn ènìyàn ń kàn sí dókítà nítorí pé wọ́n gbà gbọ́ pé lílo oògùn yóò tán ìṣòro náà. Kódà, àwọn amọṣẹ́dunjú oníṣẹ́ ìlera ní ìtẹ̀sí láti máa júwe egbòogi àti àìlóǹkà àyẹ̀wò ìlera fúnni. Kò sí ìsapá kankan láti mọ ipò àtẹ̀yìnwá aláìsàn náà, tí ọ̀nà ìgbésí ayé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ wọn máa ń jẹ́ onídàrúdàpọ̀, onílàásìgbò, tí kò sì gbámúṣé.” Romildo Bueno, ti Àjọ Tí Ń Dènà Lílo Àwọn Egbòogi Tí Ń Yí Èrò Tàbí Ìhùwà Padà Nílòkulò Lágbàáyé, sọ pé: “Dókítà kì í ní àkókò púpọ̀ tó láti fi gbọ́ ti aláìsàn, ó ń yára lé ẹni náà lọ sílé lẹ́yìn ṣíṣe àyẹ̀wò ráńpẹ́, ó sì ń ṣètọ́jú àmì àrùn nìkan.” Lílo oògùn “jẹ́ ọ̀nà ìṣègùn kan láti [yanjú] àwọn ìṣòro àwùjọ ènìyàn.” Bí ó ti wù kí ó rí, dókítà mìíràn kìlọ̀ pé ọ̀pọ̀ aláìsàn ló nílò àwọn egbòogi tí ń yí èrò tàbí ìhùwà padà, tí dókítà baralẹ̀ kọ fún wọn.

Lẹ́yìn jíjíròrò nípa “Àṣà Tó Lòde ti Lílo Egbòogi Tí Ń Gbógun Ti Ìsoríkọ́,” ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ ti Brazil náà, O Estado de S. Paulo, wí pé: “Láìfa ọ̀rọ̀ gùn, sísọ oògùn kan di àṣà tó lòde, bí àṣà irun gígẹ̀, ṣàjèjì gbáà.” Ó fa ọ̀rọ̀ oníṣègùn ọpọlọ, Arthur Kaufman, yọ pé: “Àìsí fífi ojú tó tọ́ wo nǹkan àti àìsí ète nínú ìgbésí ayé ló ń fa ipò tí ń mú kí ìwòsàn gbígbéṣẹ́ kan di ọ̀nà àjàbọ́ lọ́wọ́ gbogbo ipò búburú.” Kaufman ṣàfikún pe: “Ènìyàn túbọ̀ ń dàníyàn nípa ojútùú ojú ẹsẹ̀, nítorí náà, níwọ̀n bí wọ́n ti pàdánù ọkàn-ìfẹ́ nínú wíwá ohun tí ń fa àwọn ìṣòro wọn rí, wọ́n yàn láti máa lo oògùn láti yanjú wọn.” Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ kò léwu láti máa lo oògùn láìkọ́kọ́rí-dókítà?

Lílo Oògùn Láìkọ́kọ́rí- Dókítà—Ó Léwu Bí?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ọ̀kan nínú àwọn àbùdá gbígbàfiyèsí ti ẹ̀ka ìṣègùn ní ọ̀rúndún ogún ni ìmújáde àwọn egbòogi tuntun.” Ṣùgbọ́n ó tún sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn ti jẹ májèlé nídìí lílo oògùn nílòkulò ju lọ́nàkọnà mìíràn lọ.” Dájúdájú, lọ́nà kan náà tí oògùn lè gbà ṣèwòsàn, ó tún lè ṣèpalára. Òǹkọ̀wé Cilene de Castro wí pé, àwọn egbòogi tí kì í jẹ́ kí ènìyàn lè jẹun púpọ̀ “ń nípa lórí ìgbékalẹ̀ iṣan ara, wọ́n sì lè tipa bẹ́ẹ̀ fa àwọn àmì àrùn bí àìróorunsùntó, ìyípadà ọ̀nà ìwà híhù, àti nínú àwọn ọ̀ràn kan pàápàá, wọ́n ń fa ìrànǹrán.” Ó fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá rò pé àwọn egbòogi náà kì í wulẹ̀ jẹ́ kí ènìyàn lè jẹun púpọ̀ ni ń tan ara rẹ̀ jẹ lásán ni. Egbòogi kan lè jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ lílo egbòogi kan lẹ́yìn òmíràn, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ń sọ agbára èkejì di aláìgbéṣẹ́.”

Ọ̀pọ̀ oògùn tí a sábà máa ń lò ló lè dá ọgbẹ́ síni níkùn, wọ́n sì lè fa ìrìndọ̀, èébì, àti ẹ̀jẹ̀ dídà pàápàá. Àwọn oògùn kan lè di àṣà tàbí kí wọ́n ba kíndìnrín àti ẹ̀dọ̀ki jẹ́.

Kódà, àwọn oògùn tó lókìkí pàápàá gba ìfura. Dókítà Efraim Olszewer, ààrẹ ẹgbẹ́ oníṣègùn kan ní Brazil, kìlọ̀ pé: “Àṣà tó lòde ti lílo àwọn egbòogi aṣàlékún èròjà fítámì léwu gidigidi. Kì í ṣe pé àwọn ará ìlú ń lo oògùn láìkọ́kọ́rí-dókítà nìkan ni, ṣùgbọ́n àwọn dókítà tí kò kúnjú ìwọ̀n ń kọ àwọn oògùn tí kò dáni lójú fúnni, wọ́n sì ń gbójú fo àwọn ewu tó rọ̀ mọ́ ọn dá.” Bí ó ti wù kí ó rí, dókítà mìíràn sọ pé, àwọn egbòogi aṣàlékún èròjà fítámì lè pọndandan tàbí kí wọ́n wúlò láti fi wo àwọn àìsàn àti àìtó èròjà ara kan, bí a bá lò wọ́n ní ìwọ̀n yíyẹ.

Dídá-Àrùn-Mọ̀ Láìséwu—Báwo?

Níwọ̀n bí a kò ti lè máa lọ rí dókítà ní gbogbo ìgbà tí ara kò bá rọni, ẹ̀kọ́ ìlera àti lílo oògùn lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu láìkọ́kọ́rí-dókítà lè ṣàǹfààní fún ìdílé wa. Bí ó ti wù kí ó rí, kí a tó lo oògùn èyíkéyìí, ó ṣe pàtàkì pé kí a mọ àrùn tí ń ṣeni dájú. Bí kò bá sí dókítà kankan nítòsí, tàbí bí o kò bá lè sanwó rírí dókítà, ṣíṣàyẹ̀wò ìwé ìtọ́kasí tó kún rẹ́rẹ́ lórí ìṣègùn lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ẹgbẹ́ Oníṣègùn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe ìwé ìtọ́nisọ́nà fún ìdílé nípa ìṣègùn, tí ó ní apá olójú-ìwé 183 kan nínú, tí a to àwọn àmì àrùn sí. Èyí ní àwọn ìbéèrè tí aláìsàn náà lè dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ nínú. Nípa ìlànà yíyọ èyí tí kò kanni sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan yìí, lọ́pọ̀ ìgbà, a lè dá àrùn kan mọ̀.

Ṣùgbọ́n nípa iṣẹ́ ti dókítà ńkọ́? Ìgbà wo ló yẹ kí a wá ìrànlọ́wọ́ amọṣẹ́dunjú? Báwo ni a ṣe lè yẹra fún àṣejù nínú dídààmú nípa ìlera ẹni tàbí dídágunlá sí i? Nínú ayé tí àìsàn ara àti àìsàn tó kan ìrònú àti ara ti gbilẹ̀ yìí, báwo gan-an ni ara wa ṣe lè dá ṣáṣá níwọ̀nba?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láìka àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn dókítà àti àwọn àjọ oníṣègùn ń sọ lòdì sí àṣà pípolówó àwọn oògùn tí dókítà nìkan lè kọ fúnni “fún àwọn ará ìlú ní tààràtà” sí, àṣà náà ti pọ̀ sí i gan-an láìpẹ́ yìí ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Kò sí ìsapá kankan láti mọ ipò àtẹ̀yìnwá aláìsàn náà, tí ọ̀nà ìgbésí ayé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ wọn máa ń jẹ́ onídàrúdàpọ̀, onílàásìgbò, tí kò sì gbámúṣé.”—Dókítà André Feingold

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

Fífi Ewé Ṣètọ́jú Lábẹ́lé

Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá ni onírúurú àwùjọ ènìyàn ti ń fi ewé ṣètọ́jú àwọn àìsàn wọn, tí wọ́n ń lo àwọn ewéko tí wọ́n ń rí ní pápá àti nínú igbó. Kódà, àwọn ewéko ni a fi ṣe ọ̀pọ̀ oògùn ìgbàlódé, bí ewéko digitalis, tí a fi ń ṣètọ́jú àwọn àrùn ọkàn-àyà. Nípa bẹ́ẹ̀, Penelope Ody, ọmọ ẹgbẹ́ Àjọ Oníṣègùn Tewétegbò Orílẹ̀-Èdè ní United Kingdom, sọ nínú ìwé rẹ̀ pé, “ó lé ní 250 ọ̀nà ìtọ́jú tí kò léwu tó wà láti fi wo àwọn àrùn wíwọ́pọ̀ sàn—láti orí ikọ́, òtútù, àti ẹ̀fọ́rí lásán dé orí àwọn ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀ fún àìsàn awọ ara, àìsàn oúnjẹ tí kì í dà, àti àwọn àìsàn ọmọdé.”

Ó kọ̀wé pé: “Nígbà púpọ̀ ni a ti ka fífi ewé ṣèwòsàn sí ‘oògùn àwọn gbáàtúù ènìyàn’—àwọn egbòogi rírọrùn tí a lè lò lábẹ́lé fún àwọn àìsàn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tàbí láti fi ṣàlékún àwọn oògùn tó túbọ̀ lágbára tí àwọn amọṣẹ́dunjú ń kọ fúnni fún àwọn àrùn lílekoko to burú jáì.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́nà àdánidá, ọ̀pọ̀ jù lọ ewé ni kò léwu, a gbọ́dọ̀ fiyè sí wọn dáadáa. Má ṣe lò ju ìwọ̀n tí a sọ lọ, bí àìsàn náà bá sì ń bá a lọ tàbí tí ó ń le sí i, tàbí tí a kò mọ̀ ọ́n dájú, ṣíwọ́ lílo egbòogi abẹ́lé.”—The Complete Medicinal Herbal.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́