Ṣíṣàyẹ̀wò Àwọn Ìlànà Ìtọ́jú Àfirọ́pò
“Ṣíṣètò ìjíròrò láàárín àwọn dókítà òyìnbó tó mọṣẹ́ dunjú àti àwọn tó ń pèsè ìtọ́jú àfirọ́pò ṣe kókó nínú ọ̀ràn bíbójútó àwọn aláìsàn tí wọ́n yàn láti gba ìtọ́jú àfirọ́pò.”
WỌ́N tẹ ọ̀rọ̀ yẹn sínú ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association (JAMA) tó jáde ní November 11, 1998. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “A lè retí láti rí ìdí púpọ̀ sí i tó fi yẹ kí a [jíròrò] nípa bí àwọn èèyàn ṣe ń gba ìtọ́jú àfirọ́pò, ní pàtàkì níwọ̀n bí àwọn elétò ìbánigbófò tó ń bójú tó ọ̀ràn ìlera ti ń fi irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ sínú ohun tí wọ́n ń bá àwọn èèyàn gbé.”
Àwọn aláìsàn tó ń gba ìtọ́jú àfirọ́pò túbọ̀ ń pọ̀ sí i ṣáá ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà oníṣègùn òyìnbó. Síbẹ̀, àwọn kan ò fi ohun tí wọ́n ń ṣe náà tó dókítà òyìnbó tó ń tọ́jú wọn létí. Ìdí nìyẹn tí ìwé Tufts University Health & Nutrition Letter ti April 2000 fi pàrọwà pé: “Ńṣe ni kí o hùwà lọ́nà tí yóò ṣe ọ́ láǹfààní nípa fífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú dókítà rẹ dípò kí o máa ṣe é ní bòókẹ́lẹ́.” Ó tún sọ pé: “Yálà dókítà rẹ fọwọ́ sí i tàbí kò fọwọ́ sí i, ó ṣì lè ṣe ọ́ láǹfààní tí o bá jẹ́ kó gbọ́ nípa rẹ̀.”
Ó sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ewu tó lè yọjú tí a bá lo àwọn oríṣi oògùn ìbílẹ̀ kan pọ̀ mọ́ oògùn òyìnbó. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi tó mọṣẹ́ ìṣègùn dunjú ti mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn tí àwọ́n ń tọ́jú ń gba ìtọ́jú àfirọ́pò, wọ́n yáa gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kí èrò tiwọn alára nípa ìtọ́jú àìsàn dí àwọn lọ́wọ́ fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń pèsè ìtọ́jú àfirọ́pò fún àǹfààní ẹni tí ń gba ìtọ́jú náà.
Láti jẹ́ kí àwọn òǹkàwé wa mọ ohun díẹ̀ nípa ìtọ́jú àfirọ́pò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbà gan-an nísinsìnyí ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, a óò ṣe àlàyé ráńpẹ́ nípa díẹ̀ lára wọn. Ṣùgbọ́n a fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé kì í ṣe pé Jí! ń tọ́ka sí èyíkéyìí lára àwọn ìtọ́jú wọ̀nyí tàbí èyíkéyìí mìíràn gẹ́gẹ́ bí èyí tó dára jù.
Lílo Oògùn Ìbílẹ̀
Lílo àwọn oògùn ìbílẹ̀ wọ̀nyí ló fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ irú ìtọ́jú àfirọ́pò tó wọ́pọ̀ jù lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ti pẹ́ gan-an tí wọ́n ti ń fi oògùn ìbílẹ̀ tọ́jú aláìsàn, ṣùgbọ́n ìwọ̀nba oríṣi ewé mélòó kan ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò rẹ̀. Ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn ewé tí wọ́n fara balẹ̀ ṣèwádìí kínníkínní nípa wọn àti ohun tí wọ́n ń yọ nínú wọn, èyí ló sì fà á tí ìsọfúnni nípa bí wọn kò ṣe léwu àti bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ dáadáa kò fi tó nǹkan. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìsọfúnni tó wà nípa oògùn ìbílẹ̀ ló dá lórí ìrírí táwọn èèyàn tó ti ń lò ó tipẹ́tipẹ́ ní.
Ṣùgbọ́n ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe àwọn ìwádìí mélòó kan tó fi bí àwọn oògùn ìbílẹ̀ kan ṣe wúlò tó hàn nígbà tí a bá ń lò wọ́n fún ẹni tó ní ìṣòro másùnmáwo ráńpẹ́, àìkì í rántí nǹkan nítorí ọjọ́ ogbó, àti àwọn àmì wíwú ẹṣẹ́ tí ń pèsè omi tí ń gbé sẹ́ẹ̀lì àtọ̀. Oògùn ìbílẹ̀ kan tí wọ́n ti ṣèwádìí nípa rẹ̀ ni black cohosh, tí wọ́n mọ̀ sí black snakeroot, bugbane, tàbí rattleroot. Àwọn Àmẹ́ríńdíà se gbòǹgbò náà, wọ́n sì ń fi tọ́jú obìnrin tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá ń yọ ọ́ lẹ́nu àti nígbà tí obìnrin bá fẹ́ bímọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Harvard Women’s Health Watch ti April 2000 ti sọ, àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe ní àìpẹ́ fi hàn pé oògùn tí wọ́n mú láti inú egbòogi black cohosh tó jẹ́ ògidì, tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Jámánì lè gbéṣẹ́ “kó sì mú kí àwọn ìṣòro tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí obìnrin bá ti fẹ́ dáwọ́ ṣíṣe nǹkan oṣù dúró dẹwọ́.”
Ó jọ pé ìdí tí púpọ̀ lára àwọn tó ń béèrè fún irú ìtọ́jú ti ìṣẹ̀dá yẹn fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ronú pé wọn kò fi bẹ́ẹ̀ léwu tó àwọn oògùn tí wọ́n fi kẹ́míkà ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí sábà máa ń jẹ́ òtítọ́, àwọn oògùn ìbílẹ̀ kan wà tí wọ́n sọ pé ó máa ń bá èèyàn jà tó bá yá, ní pàtàkì bí a bá lò wọ́n pọ̀ mọ́ àwọn oògùn mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, oògùn ìbílẹ̀ kan tó wọ́pọ̀ tí wọ́n sọ pé ó máa ń ṣiṣẹ́ fún inú kíkún àti pé ó lè mú kí ẹni tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀ fọn lè mú kí ẹ̀jẹ̀ èèyàn ru, kí ìwọ̀n ìfúnpá rẹ̀ sì ga.
Àwọn oògùn ìbílẹ̀ kan tún wà tó lè mú kí ìwọ̀n tí ẹ̀jẹ̀ fi ń dà lára aláìsàn pọ̀ sí i. Bí a bá lo àwọn oògùn ìbílẹ̀ wọ̀nyí pọ̀ mọ́ àwọn oògùn òyìnbó tó “ń dín ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ kù,” ó lè fa ìṣòro tó le gan-an. Àwọn tí wọ́n ní àìsàn bára kú, bí àtọ̀gbẹ tàbí ẹ̀jẹ̀ ríru, tàbí àwọn tí wọ́n ń lo oògùn mìíràn gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa lílo oògùn ìbílẹ̀.—Wo àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
Ohun mìíràn tó ń fa àníyàn nípa oògùn ìbílẹ̀ ni ọ̀ràn àìsí ìdánilójú pé ọ̀nà tí a gbà ṣe wọ́n jẹ́ ojúlówó. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti gbọ́ ìròyìn pé àwọn oògùn kan ní àwọn èròjà mẹ́táàlì tó lágbára àti àwọn èròjà mìíràn tó ní májèlé nínú. Láfikún sí i, ìwádìí fi hàn pé àwọn oògùn ìbílẹ̀ kan wà tó jẹ́ pé díẹ̀ lára àwọn èròjà tí wọ́n kọ sára wọn pé wọ́n fi ṣe wọ́n ló wà nínú wọn lóòótọ́, tàbí kí èyíkéyìí nínú èròjà wọ̀nyẹn má tilẹ̀ sí nínú wọn rárá. Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí ń ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ láti máa lọ ra àwọn oògùn ìbílẹ̀ àti àwọn oògùn mìíràn lọ́dọ̀ àwọn tí ọ̀pọ̀ mọ̀ pé wọ́n mọṣẹ́ tí wọ́n sì ṣeé fọkàn tẹ̀.
Àwọn Oògùn Aṣàlékún Oúnjẹ
A gbọ́ pé àwọn oògùn aṣàlékún oúnjẹ, bíi fítámì àti èròjà mineral, ti ṣèrànwọ́ nínú dídènà àti títọ́jú àwọn àìlera mélòó kan, lára wọn ni àìtó ẹ̀jẹ̀ lára àti àrùn àìlágbára egungun—kódà wọ́n wúlò fún dídènà àwọn àbùkù tó máa ń wà lára ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Wọ́n ka ìwọ̀n fítámì àti èròjà mineral tí ìjọba dámọ̀ràn pé kéèyàn máa lò lójúmọ́ sí èyí tí kò léwu tó sì wúlò dé ìwọ̀n kan.
Yàtọ̀ sí ìyẹn, ìwọ̀n fítámì tó pọ̀ gan-an tí wọ́n ní ó dára fún ìtọ́jú àwọn àìsàn kan lè kó bá ìlera ẹni. Wọ́n lè lọ ṣèdíwọ́ fún bí ara ṣe ń lo èròjà aṣaralóore tàbí bí àwọn èròjà aṣaralóore mìíràn ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú ara, wọ́n sì tún lè fa ìṣòro tó le gan-an sára tó bá yá. Kò yẹ ká dágunlá sí àwọn tàbí-ṣùgbọ́n yìí, a kò sì gbọ́dọ̀ dágunlá sí àìsí ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀, tó ti lílo ìwọ̀n fítámì tó pọ̀ gan-an lẹ́yìn.
Ìlànà Lílo Ìwọ̀nba Oògùn
Ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1700 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lo ìlànà lílo ìwọ̀nba oògùn gẹ́gẹ́ bí oríṣi ìtọ́jú tí kò le, tó sì tún rọni lọ́rùn ju àwọn ìlànà tó wọ́pọ̀ tí wọ́n ń lò nígbà yẹn. Ìlànà lílo ìwọ̀nba oògùn ni a gbé karí ìlànà “ohun táa bá fẹ́ ní ń woni sàn” àti lórí èròǹgbà lílo oògùn níwọ̀nba tó kéré jọjọ. Bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn oògùn tí wọ́n fi ń ṣe ìwòsàn nínú ìlànà lílo ìwọ̀nba oògùn ni pé wọ́n a máa fi omi lú èròjà oògùn kan léraléra—nígbà mìíràn, wọ́n máa ń fi omi lú u gan-an débi pé kò ní ku ìkankan lára àwọn ohun tíntìntín inú èròjà gidi náà.
Síbẹ̀síbẹ̀, tí a bá fi àwọn oògùn tí a lò níwọ̀nba wéra pẹ̀lú lílo èròjà tí aláìsàn gbà gbọ́ pé ó lè wo òun sàn bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe oògùn ohun tó ń ṣe é, a rí i pé wọ́n ní ipa díẹ̀ nínú títọ́jú àwọn àrùn bí ikọ́ ẹ̀gbẹ, èèwọ̀ ara, àti ìgbẹ́ gbuuru ìgbà ọmọdé. A ka àwọn èròjà tí a ń lò níwọ̀nba sí èyí tí ewu rẹ̀ kéré jọjọ, níwọ̀n bí wọ́n ti máa ń fi omi lú wọn gan-an. Àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n tẹ̀ jáde ní March 4, 1998, nínú ìwé ìròyìn JAMA sọ pé: “Ìlànà lílo oògùn níwọ̀nba lè jẹ́ oríṣi ìtọ́jú tó gbéṣẹ́, tó sì ṣe pàtàkì fún ọ̀pọ̀ aláìsàn tó ní àrùn bára kú tí wọn kò mọ ohun tó jẹ́ ní pàtó. Bí wọn kò bá ki àṣejù bọ ìlànà lílo oògùn níwọ̀nba, ó lè ṣàlékún àwọn oògùn ìgbàlódé gẹ́gẹ́ bí ‘ohun èlò mìíràn lọ́wọ́ wọn.’” Ṣùgbọ́n, nínú àwọn ọ̀ràn pàjáwìrì tó ń wu ẹ̀mí léwu, ó lè túbọ̀ bọ́gbọ́n mu láti gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn òyìnbó.
Ìlànà Ṣíṣàtúnṣe Ìgbékalẹ̀ Ara
Oríṣi ìtọ́jú àfirọ́pò mélòó kan wà tí wọ́n fi máa ń ṣàtúnṣe ìgbékalẹ̀ ara. Ìlànà ṣíṣàtúnṣe ìgbékalẹ̀ ara wà lára àwọn ìtọ́jú àfirọ́pò tí wọ́n sábà ń lò, ní pàtàkì ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. A gbé e karí èròǹgbà náà pé a lè wo èèyàn sàn tí a bá ṣàtúnṣe eegun ẹ̀yìn tí kò tò dáadáa. Ìdí nìyẹn tí àwọn onímọ̀ nípa ìlànà ìṣàtúnṣe ìgbékalẹ̀ ara fi mọ̀ nípa ṣíṣàtúnṣe eegun ẹ̀yìn lámọ̀dunjú tí wọ́n fi ń lè ṣàtúnṣe eegun ẹ̀yìn àwọn tí wọ́n ń tọ́jú.
Kì í ṣe ìgbà gbogbo ni oògùn òyìnbó máa ń lè pèsè ìtura fún ẹni tí ìbàdí ń ro. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn aláìsàn kan tí wọ́n tọ́jú nípa ṣíṣàtúnṣe ìgbékalẹ̀ ara wọn sọ pé ara tu àwọn gan-an. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí ẹ̀rí mìíràn láti fi tì í lẹ́yìn pé wọ́n ti fi ìlànà ṣíṣàtúnṣe ìgbékalẹ̀ ara wo àwọn àìsàn mìíràn àyàfi ìrora.
Lọ́nà tó gbàfiyèsí, tí oníṣègùn kan tó mọṣẹ́ dunjú bá lo ìlànà ṣíṣàtúnṣe ìgbékalẹ̀ ara fún èèyàn, ìlànà náà kì í fi bẹ́ẹ̀ yọni lẹ́nu tó bá yá. Ṣùgbọ́n lẹ́sẹ̀ kan náà, ẹnì kan gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ṣíṣàtúnṣe ọrùn lè yọrí sí ìṣòro tó le gan-an, ó ń fa àrùn ẹ̀gbà àti àrùn rọpárọsẹ̀. Láti dín ewu tó lè tìdí rẹ̀ yọ kù, àwọn ògbógi kan dámọ̀ràn pé kí èèyàn lọ ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀ dáadáa kó lè mọ̀ bóyá irú àtúnṣe ìgbékalẹ̀ ara kan ní pàtó yóò jẹ́ ewu fún òun.
Wíwọ́ Ara
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo àwùjọ ẹ̀dá ni wọ́n ti mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú wíwọ́ ara. Wọ́n tilẹ̀ ròyìn nípa rẹ̀ nínú Bíbélì. (Ẹ́sítérì 2:12) Ìwé ìròyìn British Medical Journal (BMJ) ti November 6, 1999, sọ pé: “Ìlànà wíwọ́ ara kó ipa pàtàkì nínú ọ̀nà tí àwọn ará China àti àwọn ará Íńdíà ń gbà ṣètọ́jú. Per Henrik Ling, tó gbé ohun tí a wá mọ̀ nísinsìnyí sí ìlànà wíwọ́ ara lọ́nà ti àwọn ará Sweden kalẹ̀, ló ṣètò ìlànà wíwọ́ ara lọ́nà ti àwọn ará Yúróòpù ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún.”
Wọ́n sọ pé wíwọ́ ara ló ń mú kí àwọn iṣu ẹran ara dẹ̀, kí ẹ̀jẹ̀ máa káàkiri ara dáadáa, ló sì ń mú àwọn májèlé tó ti kóra jọ sínú ẹran ara kúrò. Ní báyìí, àwọn dókítà ti ń ní kí àwọn èèyàn máa wọ́ ara tí wọ́n bá ní ìṣòro ẹ̀yìn ríro, ẹ̀fọ́rí, àti tí oúnjẹ kò bá dà nínú wọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn tí ẹlòmíràn ń bá wọ́ ara ti sọ nípa bí ó ṣe tù wọ́n lára tó. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Sandra McLanahan ti sọ, “ìpín ọgọ́rin nínú oríṣi ọgọ́rùn-ún àrùn ló ní í ṣe pẹ̀lú àìfararọ, tí èèyàn bá sì wọ́ ara, àìfararọ yóò dín kù.”
Ìwé ìròyìn BMJ sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà wọ́ ara ni kì í fi bẹ́ẹ̀ yọni lẹ́nu tó bá yá. Ohun táa ń fọkàn rò lásán ni kì í jẹ́ kí a máa gba àwọn aláìsàn kan nímọ̀ràn láti máa wọ́ ara (fún àpẹẹrẹ, yíyẹra fún fífọwọ́ ra ibi tí nǹkan gbígbóná ti jóni tàbí kí a yẹra fún wíwọ́ ẹsẹ̀ tàbí apá tí iṣan rẹ̀ dáranjẹ̀) . . . Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé wíwọ́ ara fún ẹni tó ní àrùn jẹjẹrẹ a mú kí àrùn náà túbọ̀ ràn kiri ara rẹ̀.”
E. Houston LeBrun, ààrẹ àná fún Ẹgbẹ́ Ìlànà Wíwọ́ Ara ní Amẹ́ríkà, sọ pé: “Bí ìlànà wíwọ́ ara ti ń gbilẹ̀ sí i, àwọn èèyàn ti wá ń ṣàníyàn nípa bí oníṣègùn tó ń lo ìlànà wíwọ́ ara ṣe tóótun sí, ó sì yẹ kí wọ́n ṣàníyàn lóòótọ́.” Ìwé ìròyìn BMJ dámọ̀ràn pé láti yẹra fún ìwà táwọn tí kò mọṣẹ́ náà dunjú ń hù, “ó yẹ kí àwọn aláìsàn rí i dájú pé oníṣègùn náà forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ àjọ kan tó yẹ, tó ń ṣètọ́jú aláìsàn.” Ìròyìn kan tó jáde lọ́dún tó kọjá sọ pé wọ́n fún àwọn oníṣègùn ní ìwé àṣẹ ní ìpínlẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
Ìlànà Ìwòsàn Akupọ́ńṣọ̀
Akupọ́ńṣọ̀ ni ìlànà ìtọ́jú kan tó ti wọ́pọ̀ gan-an jákèjádò ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú ọ̀nà ni wọ́n ń gbà ṣe ìwòsàn “akupọ́ńṣọ̀,” ó sábà máa ń ní lílo abẹ́rẹ́ tó mọ́ tónítóní nínú, èyí tí wọ́n á kì bọ àwọn apá ibi pàtó kan nínú ara láti fi ṣèwòsàn. Ìwádìí tí a ti ṣe láàárín ẹ̀wádún mélòó kan sẹ́yìn fi hàn pé akupọ́ńṣọ̀ lè ṣiṣẹ́ nínú àwọn ọ̀ràn kan láti jẹ́ kí àwọn kẹ́míkà inú ọpọlọ ṣiṣẹ́, àwọn bíi kẹ́míkà endorphin, tó lè dín ìrora àti ẹ̀yà ara wíwú kù.
Àwọn ìwádìí kan fi hàn pé akupọ́ńṣọ̀ lè gbéṣẹ́ nínú ṣíṣètọ́jú àìsàn bíi mélòó kan àti pé ó jẹ́ oríṣi àfirọ́pò fún ìtọ́jú apàmọ̀lára, kò sì léwu. Àjọ Ìlera Àgbáyé fọwọ́ sí lílo ìlànà akupọ́ńṣọ̀ láti fi wo oríṣi àrùn mẹ́rìnlélọ́gọ́rùn-ún. Ìgbìmọ̀ kan tí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìlera ti Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà yàn fi ẹ̀rí hàn pé akupọ́ńṣọ̀ jẹ́ oríṣi ìlànà tó ṣètẹ́wọ́gbà nínú ṣíṣètọ́jú ìrora tí èèyàn máa ń ní lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ abẹ fún un, iṣan ríro, pajápajá tó ń mú obìnrin nítorí nǹkan oṣù, àti ìrìndọ̀ òun èébì nítorí lílo oògùn oníkẹ́míkà tàbí lílóyún.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wọ́pọ̀ kí ìlànà akupọ́ńṣọ̀ máa yọni lẹ́nu tó bá yá, ṣùgbọ́n èèyàn lè nímọ̀lára pé egbò wà lára òun, kí ara rẹ̀ kú, tàbí kó máa nímọ̀lára bíi pé nǹkan ń gún òun. Bí wọ́n bá fi oògùn nu abẹ́rẹ́ náà dáadáa tàbí tí wọ́n bá ń lo abẹ́rẹ́ kan fún ẹnì kan, èyí lè dín ewu kíkó àrùn kù. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ń lo ìlànà akupọ́ńṣọ̀ láti ṣètọ́jú aláìsàn ni kò ní òye iṣẹ́ ìṣègùn tí wọ́n fi lè dá àìsàn tó ń ṣe èèyàn mọ̀ tàbí tí wọ́n fi lè dámọ̀ràn àwọn oríṣi ìtọ́jú mìíràn tó túbọ̀ ṣe wẹ́kú. Yóò jẹ́ ìwà tí kò bọ́gbọ́n mu láti dágunlá sí ìṣòro àìní òye ìṣègùn láti fi dá àìsàn mọ̀, ní pàtàkì bí a bá ń yan ìlànà akupọ́ńṣọ̀ láti fi dẹwọ́ àwọn àmì àrùn bára kú.
Àwọn Tí O Lè Yàn Nínú Wọn Pọ̀ Rẹpẹtẹ
Àpẹẹrẹ díẹ̀ ni gbogbo èyí tí a ti ń sọ nípa rẹ̀ bọ̀ jẹ́ lára ọ̀pọ̀ oríṣi ìtọ́jú tí wọ́n sábà máa ń pè ní ìlànà ìtọ́jú àfirọ́pò ní àwọn ibì kan. Lọ́jọ́ iwájú, a lè ka díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí àti àwọn mìíràn tí a kò gbé yẹ̀ wò níhìn-ín sí ti ìṣègùn òyìnbó, gan-an bó ti wà ní àwọn apá ibì kan láyé ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Bó ti wù kó rí, àwọn mìíràn lè di èyí tí a kò lò mọ́ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ máà níyì mọ́.
Ó bani nínú jẹ́ pé aráyé ń ní ìrora, àìsàn sì máa ń ṣe wọ́n, Bíbélì náà sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwa mọ̀ pé gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” (Róòmù 8:22) A lè retí nígbà náà pé aráyé yóò máa wá ọ̀nà àbájáde kiri. Ṣùgbọ́n ibo ni a lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ? Jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí àwọn ohun díẹ̀ tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú irú ìtọ́jú tí o lè yàn láti gbà lọ́dọ̀ oníṣègùn.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Lílo Oògùn Ìbílẹ̀ Pọ̀ Mọ́ Oògùn Òyìnbó—Àwọn Ewu Wo Ló Wà Níbẹ̀?
Lọ́pọ̀ ìgbà ni ìkìlọ̀ ti máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn aráàlú pé kí wọ́n yé lo oríṣi àwọn oògùn kan pọ̀ tàbí kí wọ́n má ṣe fi ọtí lò wọ́n. Ǹjẹ́ ewu wà nínú lílo àwọn oríṣi oògùn ìbílẹ̀ kan pọ̀ mọ́ oògùn òyìnbó? Báwo ni àṣà yìí ṣe wọ́pọ̀ tó?
Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ nípa “lílo oògùn òyìnbó pọ̀ mọ́ oògùn ìbílẹ̀.” Ó sọ pé: “Lára ìpín mẹ́rìnlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà tí wọ́n sọ pé àwọn ń lo oògùn òyìnbó déédéé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ẹnì kan lára àwọn márùn-ún (nǹkan bí ìpín méjìdínlógún ààbọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún) ló sọ pé, ó kéré tán, àwọn ń lo oògùn ìbílẹ̀ kan tàbí oògùn fítámì lẹ́ẹ̀kan náà, tàbí pé àwọn ń lò wọ́n pọ̀.” Ó ṣe pàtàkì láti gbọ́ àlàyé nípa àwọn ewu tó lè tìdí irú àṣà bẹ́ẹ̀ wá.
Ó yẹ kí àwọn tí wọ́n ń lo àwọn oríṣi oògùn ìbílẹ̀ kan tún ṣàníyàn nígbà tí wọ́n bá ń gba ìtọ́jú tó béèrè pé kí wọ́n lo oògùn apàmọ̀lára. Dókítà John Neeld, ààrẹ Ẹgbẹ́ Àwọn Oníṣègùn Apàmọ̀lára, ṣàlàyé pé: “A ti gbọ́ àwọn ìròyìn láti ẹnu àwọn kan tọ́ràn kàn pé àwọn oògùn ìbílẹ̀ kan tó wọ́pọ̀, títí kan ginseng àti ọtí òjò ti St. John, lè mú kí ìwọ̀n ìfúnpá ẹni máà dúró sójú kan. Ìyẹn lè léwu gan-an lákòókò tí wọ́n bá pa ìmọ̀lára aláìsàn.”
Dókítà yìí fi kún un pé: “Àwọn mìíràn, bíi ginkgo biloba, atalẹ̀ àti feverfew, lè ṣèdíwọ́ fún dídì ẹ̀jẹ̀, ohun kan tó léwu ní pàtàkì lákòókò pípa ìmọ̀lára inú fọ́nrán tó bo ọpọlọ àti okùn ògóóró ẹ̀yìn—bí ibikíbi ní tòsí okùn ògóóró ẹ̀yìn bá ṣẹ̀jẹ̀, ó lè fa àrùn ẹ̀gbà. Ọtí òjò ti St. John tún lè mú kí àwọn oògùn apanilọ́bọlọ̀ tàbí oògùn apàmọ̀lára kan ní ipa tó lékenkà lára ẹni.”
Ní kedere, ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ nípa àwọn ewu tó lè ṣẹlẹ̀ tí èèyàn bá ń lo àwọn oríṣi oògùn ìbílẹ̀ kan pọ̀ mọ́ oògùn òyìnbó. Ní pàtàkì, ó yẹ kí àwọn aboyún àti àwọn obìnrin tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ mọ ìpalára tí lílo oògùn ìbílẹ̀ àti oògùn òyìnbó pọ̀ lè ṣe fún àwọn ọmọ wọn. Nítorí náà, a rọ àwọn aláìsàn láti bá ẹni tó ń tọ́jú wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn oògùn tí wọ́n bá ń lò, yálà ó jẹ́ àfirọ́pò tàbí kò jẹ́ bẹ́ẹ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ewé “black cohosh”
Wọ́n ti fi àwọn ewé kan wo àwọn àrùn
Ọtí òjò “Saint-John’s-wort”
[Credit Line]
© Bill Johnson/Visuals Unlimited
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kí ara aláìsàn lè yá, òun àti àwọn tó ń tọ́jú rẹ̀ ní láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀