Ìlera Tó Sunwọ̀n—Ṣe Ìtọ́sọ́nà Tuntun Ni?
Àwọn nǹkan tó jẹ àwọn èèyàn lógún tó ọ̀ràn ìlera kò tó nǹkan. Nígbà mìíràn, ó máa ń jọ pé bí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni onírúurú àlàyé ṣe pọ̀ tó. Dípò gbígbè síhà kan, Jí! gbìyànjú láti fi ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí ròyìn nípa bí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ṣe ń lọ gba ìtọ́jú tí wọ́n máa ń pè ní ìtọ́jú àfirọ́pò. Kì í ṣe pé a ń tọ́ka sí èyíkéyìí lára àwọn ìtọ́jú tí a óò jíròrò tàbí èyíkéyìí mìíràn gẹ́gẹ́ bí èyí tó dára jù. Ọ̀pọ̀ ìtọ́jú ni a kò mẹ́nu kàn—àwọn kan wọ́pọ̀, àwọn kan sì ń fa awuyewuye. A gbà gbọ́ pé líla àwọn èèyàn lóye ní gbogbo gbòò wúlò; àwọn ìpinnu nípa ọ̀ràn ìlera jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni látòkèdélẹ̀.
OLÚKÚLÙKÙ ló ń fẹ́ ní ìlera. Ṣùgbọ́n ọwọ́ èèyàn lè ṣàìtẹ ìlera pípé, gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè rí i nínú iye èèyàn tó ní ìṣòro ìlera. Lójú àwọn kan, ó jọ pé àwọn tó ń ṣàìsàn lónìí pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ.
Láti lè ṣẹ́gun àìsàn, ọ̀pọ̀ dókítà fẹ́ràn láti máa kọ oògùn tí àwọn ilé iṣẹ́ tí ń ṣe oògùn ṣe, tí wọ́n sì ń polówó rẹ̀ kíkankíkan. Lọ́nà tó gbàfiyèsí, irú àwọn oògùn wọ̀nyẹn ti wá ń tà gan-an ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, láti orí bílíọ̀nù dọ́là mélòó kan lọ́dún lọ sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún. Kí ni èyí wá yọrí sí?
Àwọn oògùn tí dókítà kọ fún àwọn èèyàn ní ilé ìwòsàn ti ran ọ̀pọ̀ lára wọn lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ara àwọn kan tí wọ́n ń lo oògùn kò yá síbẹ̀, ó tilẹ̀ ń burú sí i ni. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn kan ti yíjú sí gbígba ìtọ́jú láwọn ọ̀nà mìíràn.
Ibi Tí Ọ̀pọ̀ Ń Yíjú Sí
Ní àwọn ibi tó ti jẹ́ pé àwọn oògùn ìgbàlódé tó wọ́pọ̀ ni lájorí ohun tí wọ́n fi ń wo àwọn èèyàn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá ń yíjú sí ohun tí wọ́n pè ní ìtọ́jú àfirọ́pò, tàbí àfikún. Ìwé ìròyìn Consumer Reports ti May 2000 sọ pé: “Ó jọ pé ìdènà ńlá tó ti wà láàárín àwọn ìtọ́jú àfirọ́pò àti àwọn ìṣègùn ìgbàlódé ti ń wó.”
Ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association (JAMA), ti November 11, 1998, sọ pé: “Àwọn ìlànà ìṣègùn àfirọ́pò, tí wọ́n sọ pé ó ń yí ipò àìsàn ara padà, tó ṣeé ṣe kí wọ́n má fi kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìṣègùn tàbí kí wọ́n máà sí ní àwọn ilé ìwòsàn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lápapọ̀, ni àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn, àwùjọ àwọn oníṣègùn, àwọn aṣojú ìjọba, àti àwọn aráàlú ti darí àfiyèsí sí.”
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń lọ lọ́wọ́ ti fi hàn, ìwé ìròyìn Journal of Managed Care Pharmacy ṣàlàyé ní ọdún 1997 pé: “Tẹ́lẹ̀ rí, àwọn oníṣègùn òyìnbó ń ṣiyè méjì nípa fífi oògùn àfirọ́pò tọ́jú èèyàn, ṣùgbọ́n ilé ẹ̀kọ́ ìṣègùn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà [ìròyìn kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé márùndínlọ́gọ́rin ni wọ́n] ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní iṣẹ́ lórí ìṣègùn àfirọ́pò bí akẹ́kọ̀ọ́ bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, títí kan yunifásítì ti Harvard, Stanford, Yunifásítì ti Arizona, àti Yale.”
Ìwé ìròyìn JAMA sọ ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn ń ṣe láti mú kí ìlera wọn sunwọ̀n sí i. Ó sọ pé: “Ní ọdún 1990, a fojú díwọ̀n pé ẹnì kan nínú èèyàn márùn-ún (iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún) tó gbé àìlera pàtàkì kan lọ sọ́dọ̀ dókítà òyìnbó ló ń lo oògùn àfirọ́pò kan. Ìpín yìí pọ̀ sí i dé nǹkan bí ẹnì kan nínú èèyàn mẹ́ta (iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín méjìlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún) lọ́dún 1997.” Àpilẹ̀kọ náà tún sọ pé: “Àwọn ìwádìí tí a ṣe láwọn orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé àwọn oògùn àfirọ́pò wọ́pọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ní àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá.”
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn JAMA ti sọ, iye àwọn tó lo oògùn àfirọ́pò láìpẹ́ yìí láàárín oṣù méjìlá jẹ́ ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún ní Kánádà, ìpín mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ní Finland, àti ìpín mọ́kàndínláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ní Ọsirélíà. Ìwé ìròyìn JAMA sọ pé: “Bí àwọn èèyàn ṣe ń wá oògùn àfirọ́pò kiri ti wá gbàfiyèsí gan-an ni.” Ní pàtàkì, òótọ́ lọ̀rọ̀ náà nítorí pé ó ṣọ̀wọ́n kí á rí àwọn oògùn àfirọ́pò lára ohun tí àwọn elétò ìbánigbófò ń báni dá sí. Nítorí náà, àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn JAMA náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ó ṣeé ṣe kí bí wọ́n ṣe ń lò ó ní lọ́ọ́lọ́ọ́ má tò bí wọ́n á ṣe máa lò ó bó bá di pé àwọn elétò ìbánigbófò bá ń túbọ̀ báni gbé ìnáwó àwọn oògùn àfirọ́pò lọ́jọ́ iwájú.”
Ìtẹ̀sí láti pa àwọn oògùn àfirọ́pò pọ̀ mọ́ àwọn oògùn òyìnbó ti jẹ́ àṣà gbogbo gbòò tó ti wà tipẹ́ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Dókítà Peter Fisher, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ìwòsàn Royal London Tí Wọ́n Ti Ń Fi Oògùn Pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ Woni Sàn, sọ pé àwọn oríṣi oògùn àfirọ́pò ti “fẹ́rẹ̀ẹ́ di lájorí oògùn òyìnbó tí wọ́n fi ń wo aláìsàn ní ibi púpọ̀. Kò tún sí oríṣi ìṣègùn méjì mọ́, ìyẹn ìṣègùn òyìnbó àti ìṣègùn àfirọ́pò. Èyí tó wà báyìí ni ìṣègùn tó dára tàbí ìṣègùn tí kò dára.”
Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ògbóǹtagí oníṣègùn lónìí ti wá ń mọyì oògùn òyìnbó àti àwọn oògùn àfirọ́pò. Dípò kí wọ́n máa kàn án nípá fún aláìsàn kan láti gba yálà oríṣi oògùn kan tàbí òmíràn, ńṣe ni wọ́n ń dámọ̀ràn pé kí wọ́n máa lo ohunkóhun tó bá ṣáà ti ṣe aláìsàn náà láǹfààní lára onírúurú oògùn tí a fi ń woni sàn.
Kí ni díẹ̀ lára àwọn oríṣi ọ̀nà tí a ń gbà woni sàn, tí a ń pè ní ìtọ́jú àfirọ́pò? Ìgbà wo àti ibo ni díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí ti wá? Àti pé èé ṣe tí ọ̀pọ̀ èèyàn tó bẹ́ẹ̀ fi ń lò wọ́n?