Àwọn Ìtọ́jú Àfirọ́pò—Ìdí Tó Fi Jẹ́ Pé Òun Lọ̀pọ̀ Èèyàn Ń Yíjú Sí
ÌLÀNÀ ìtọ́jú àfirọ́pò ní onírúurú ọ̀nà ìwòsàn àti ìtọ́jú nínú. Ọ̀pọ̀ wọn la kó pọ̀ sábẹ́ orúkọ kan náà, ìyẹn ni lílo ohun ìṣẹ̀dá pọ́ńbélé, tó jẹ́ oríṣi ìtọ́jú tó ní í ṣe pẹ̀lú lílo àwọn ohun ìṣẹ̀dá tàbí ara fúnra rẹ̀ láti mú kí ara máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ kí ó lè wo ara rẹ̀ sàn. Mélòó kan lára àwọn oríṣi ìlànà ìtọ́jú yìí, tí àwọn èèyàn ti máa ń lò fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ni iṣẹ́ ìṣègùn ìgbàlódé ti kọ̀ sílẹ̀ tàbí kí wọ́n ti pa tì tipẹ́tipẹ́.
Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Journal of the American Medical Association, ẹ̀dà ti August 27, 1960, sọ pé fífi ohun tó tutù sójú ibi tí nǹkan ti jóni jẹ́ ohun tí “àwọn èèyàn ayé àtijọ́ mọ̀ ṣùgbọ́n ó jọ pé àwọn oníṣègùn àti àwọn ọ̀gbẹ̀rì ti pa á tì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìtọ́kasí tó wà káàkiri nínú oríṣiríṣi ìwé fohùn ṣọ̀kan, wọ́n sì ti irú ìlànà ìtọ́jú yìí lẹ́yìn, síbẹ̀ àwọn èèyàn kì í lò ó níbi gbogbo lónìí. Ní gidi, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn oníṣègùn ń sọ pé, ‘kò sẹ́ni tó ń lò ó,’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó mọ ìdí rẹ̀.”
Bó ti wù kó rí, ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí fífi omi tútù tàbí ohun tó tutù ba ibi tí nǹkan ti jóni tún ti di ìlànà tí wọ́n ń lò nínú ìṣègùn òyìnbó. Ìwé ìròyìn The Journal of Trauma, ti September 1963, sọ pé: “Àwọn èèyàn ti wá ní ìfẹ́ sí lílo omi tútù láti kọ́kọ́ fi tọ́jú ibi tí nǹkan ti jóni láti ìgbà tí Ofeigsson àti Schulman ti kọ ìròyìn wọn ní ọdún 1959 àti 1960. A ti ń lo ìlànà yìí látọdún tó kọjá láti tọ́jú àwọn aláìsàn; àbáyọrí rẹ̀ sí wúni lórí.”
Ìlànà fífi omi tútù ṣe ìtọ́jú náà kò fi bẹ́ẹ̀ léwu, ó sì ń mú kí ara tu aláìsàn. Nínú ìlànà ìtọ́jú àfirọ́pò, wọ́n tún ń lo omi lásán lónírúurú ọ̀nà láti fi ṣètọ́jú àwọn àìsàn, àti pé nísinsìnyí onírúurú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ làwọn oníṣègùn òde òní tẹ́wọ́ gbà.a
Bákan náà, àwọn tó mọṣẹ́ ìtọ́jú àfirọ́pò dunjú sábà máa ń fi ewé wo àìsàn. Ohun táwọn èèyàn ń lò fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún—kódà ẹgbẹẹgbẹ̀rún—ọdún nìyẹn ní àwọn apá ibì kan lágbàáyé. Fún àpẹẹrẹ, ní Íńdíà, fífi oògùn ìbílẹ̀ wo àìsàn ti jẹ́ lájorí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà tọ́jú aláìsàn. Lónìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé níbi gbogbo ni ọ̀pọ̀ àwọn tó mọṣẹ́ ìṣègùn òyìnbó dunjú ti mọ agbára ìwòsàn tí àwọn ewé kan ní.
Ìrírí Kan Tó Kàmàmà
Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, Richard Willstätter, tó wá di akẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣesí èròjà kẹ́míkà inú ohun ọ̀gbìn, gbégbèésẹ̀ nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́mọdé Sepp Schwab, ọmọ ọdún mẹ́wàá kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Kòkòrò kan wọ ẹsẹ̀ Sepp, ó sì bà á jẹ́ débi pé dókítà kan sọ pé ńṣe ni wọ́n máa gé ẹsẹ̀ náà kí ẹ̀mí ọmọ náà lè wà, ṣùgbọ́n àwọn òbí Sepp ní kí wọ́n dúró di ọjọ́ kejì kí wọ́n tó gé ẹsẹ̀ náà. Kó tó di ìgbà tí wọ́n máa gé e, wọ́n tọ olùṣọ́ àgùntàn kan tí wọ́n ti gbọ́ pé ó máa ń fi ewé wo àìsàn lọ. Olùṣọ́ àgùntàn wá oríṣi ewé mélòó kan, ó gé wọn wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ títí wọ́n fi dà bí ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀ tí wọ́n ti sè, ó sì fi í lẹ́ ojú ọgbẹ́ náà.
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ọgbẹ́ náà ti sàn díẹ̀, ni wọ́n bá tún sún ìgbà tí wọ́n máa gé ẹsẹ̀ náà síwájú. Wọ́n ò yé lo ewé náà, nígbà tó sì ṣe, ọgbẹ́ náà sàn pátápátá. Willstätter tún lọ kọ́ nípa oògùn pípò ní Yunifásítì Munich ní Jámánì, nígbà tó yá, ó gba ẹ̀bùn Nobel nítorí àwọn àwárí rẹ̀ nínú ìwádìí tó ṣe nípa àwọn èròjà aláwọ̀ tó wà nínú àwọn ohun ọ̀gbìn, ní pàtàkì èròjà chlorophyll. Ní pàtàkì, nǹkan bí ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn oògùn òyìnbó tí a ń lò nísinsìnyí ló ń wá láti inú àwọn kẹ́míkà tí a ń rí nínú ewé lápá kan tàbí lódindi.
Ìdí Tó Fi Yẹ Láti Lo Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì
Síbẹ̀, ó yẹ ká mọ̀ pé tó bá di ọ̀ràn kí oníṣègùn tọ́jú èèyàn, ohun tó jẹ́ bí idán lára ẹnì kan lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ lára ẹlòmíràn. Bí oríṣi oògùn kan yóò bá ṣiṣẹ́, èyí sinmi lórí àwọn ohun bíi mélòó kan, títí kan irú àrùn tó ń ṣeni àti bó ṣe le tó àti bí ara aláìsàn náà ṣe rí. Kódà, àkókò tí ó lò ó lè ṣe pàtàkì pẹ̀lú.
Àwọn ìlànà àfirọ́pò kì í sábà yára ṣiṣẹ́ bíi ti ìṣègùn òyìnbó, ìdí nìyẹn tí àrùn kan tí wọn ì bá ti wò sàn tipẹ́tipẹ́ ká ní wọ́n ti tètè ṣàwárí rẹ̀ kí wọ́n sì lo oògùn sí i fi lè di nǹkan ńlá tí wọ́n ní láti lo oògùn tó lágbára gan-an sí i—tàbí kí wọ́n tilẹ̀ torí rẹ̀ ṣiṣẹ́ abẹ fúnni—láti lè gba ẹ̀mí ẹni là. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè máà bọ́gbọ́n mu láti ranrí mọ́ oríṣi ìlànà ìtọ́jú kan bíi pé òun nìkan ni ọ̀nà tí a lè gbà wo àìsàn kan.
Ìlànà ìtọ́jú àfirọ́pò yàtọ̀ sí ọ̀nà ìṣègùn òyìnbó lọ́nà tí wọ́n ń gbà fi bójú tó àìlera ẹni. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi tọ́jú ẹni máa ń ní í ṣe pẹ̀lú dídènà àìsàn, wọ́n sì máa ń sinmi lé ọ̀nà tí ẹnì kan ń gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ àti àyíká rẹ̀ àti bí àwọn kókó wọ̀nyí ṣe ní ipa lórí ìlera rẹ̀. Ká sọ ọ́ lọ́nà mìíràn, ní gbogbo gbòò, àwọn tó ń lo ìlànà ìtọ́jú àfirọ́pò máa ń wo èèyàn lódindi dípò wíwo ẹ̀yà ara kan tàbí ipò àìsàn kan.
Láìsí àní-àní, ohun kan tó ń mú kí ìlànà ìtọ́jú àfirọ́pò fani mọ́ra gan-an ni èrò náà pé ohun tí Ọlọ́run dá ni wọ́n ń lò àti pé ìlànà náà kò fa kólekóle, kò sì fi bẹ́ẹ̀ léwu tó ìlànà tí àwọn oníṣègùn òyìnbó ń lò. Nítorí náà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ló ń fẹ́ láti mọ àwọn ìlànà ìtọ́jú tí kò léwu tó sì gbéṣẹ́, a óò mẹ́nu kan àpẹẹrẹ díẹ̀ lára àwọn ìlànà ìtọ́jú àfirọ́pò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Jí!, December 22, 1988, ojú ìwé 25 sí 26.