Irú Ìlànà Ìtọ́jú Tí O Yàn
NÍNÚ ìwé tí Dókítà Isadore Rosenfeld kọ nípa ìtọ́jú àfirọ́pò, ó tẹnu mọ́ kókó yìí pé: “Oríṣi ìtọ́jú èyíkéyìí tí a bá fún àwọn aláìsàn mélòó kan tí a ṣà jọ, tí a sì mú kó dá wọn lójú pé yóò ‘ṣiṣẹ́’ lè mú kí ara ìdajì nínú wọn le sí i.”
Èyí ni a ń pè ní ìmúláradá nípa fífi èròjà tí aláìsàn gbà gbọ́ pé ó lè wo òun sàn ṣètọ́jú rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe oògùn ohun tó ń ṣe é nìyẹn, èyí tó túmọ̀ sí pé hóró ṣúgà pàápàá lè ṣiṣẹ́ bí ẹni náà bá gbà gbọ́ pé yóò ṣiṣẹ́. Ìmúláradá nípa fífi èròjà tí aláìsàn gbà gbọ́ pé ó lè wo òun sàn ṣètọ́jú rẹ̀ lè gbani lọ́wọ́ àwọn àmì àrùn tí ń gbéni dè, ìrora, ìrìndọ̀, àárẹ̀, òòyì, àìfararọ, àti ìsoríkọ́ sì wà lára wọn. Kí ni kókó yìí fi hàn?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó fi hàn pé lọ́pọ̀ ìgbà, bí ara ẹnì kan yóò bá yá, ó ṣe pàtàkì pé kí ẹni náà ní ìdánilójú pé ìtọ́jú tí òun gbà yóò ṣiṣẹ́. Bákan náà, ó lè jẹ́ ìwà tó bọ́gbọ́n mu láti wádìí bóyá irú oògùn kan wà tó ń gbọ́ àìsàn náà gan-an, tí kì í ṣe pé yóò wulẹ̀ dẹwọ́ àmì àrùn náà. A lè ṣe èyí nípa ṣíṣàyẹ̀wò nípa bí oògùn náà ṣe ṣiṣẹ́ sí, irú bíi ṣíṣàyẹ̀wò níbi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti yíya àwòrán X ray.
Síbẹ̀, ohun púpọ̀ wà tí ẹnì kan lè ṣe nígbà tó bá ń yan ọ̀nà tó fẹ́ kí oníṣègùn gbà tọ́jú òun.
Àwọn Ìgbésẹ̀ Pàtàkì Láti Gbé
Ohun tó bọ́gbọ́n mu láti kọ́kọ́ ṣe ni kéèyàn ṣèwádìí kó tó ṣe ìpinnu. Béèrè ìbéèrè. Àbájáde wo ni o lè retí? Àǹfààní wo ló wà nínú rẹ̀, ìpalára wo ló lè ṣe, àti pé èló la rò pé yóò náni àti báwo ni ìtọ́jú náà yóò ṣe pẹ́ tó? Bá àwọn tí wọ́n ti gba irú ìtọ́jú tí o ń gbé yẹ̀ wò náà sọ̀rọ̀. Bi wọ́n léèrè bóyá ó ṣe wọ́n láǹfààní. Bó ti wù kó rí, rántí pé gbígbẹ́kẹ̀ lé kìkì gbígbọ́ ìrírí tó gbádùn mọ́ni nípa rẹ̀ lè ṣì ọ́ lọ́nà.
Ó lè máà dára ká dámọ̀ràn irú ìtọ́jú kan tí kì í ṣe ti òyìnbó fún èèyàn, tí irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ bá ń jẹ́ kí á pa àwọn ìtọ́jú tí ẹ̀rí ti fi hàn pé ó ti kẹ́sẹ járí tì, kódà bí àṣeyọrí tí ìtọ́jú oníṣègùn òyìnbó náà ṣe kò bá pọ̀. Wọ́n kọ ìròyìn nípa ẹ̀rí ìpalára tó lè tìdí rẹ̀ yọ sínú ìwé ìròyìn The New England Journal of Medicine. Ìwé ìròyìn náà ṣàpèjúwe bí àrùn jẹjẹrẹ ṣe ràn lára àwọn aláìsàn méjì tí wọ́n kọ̀ láti lo oògùn òyìnbó nígbà tí wọ́n ń lo àwọn oògùn àfirọ́pò. Ọ̀kan lára àwọn aláìsàn náà kú.
Ó bọ́gbọ́n mu pé kí àwọn tí wọ́n ní àwọn àìsàn bára kú tó ń wu ẹ̀mí wọn léwu mọ̀ dájú pé àwọn oníjìbìtì tó ń polówó àwọn oògùn awúrúju lè fi àwọn ṣèjẹ. Ṣọ́ra fún oògùn èyíkéyìí tí wọ́n bá sọ pé ó lè wo igba àrùn. Àpẹẹrẹ kan tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí ni ti fítámì tuntun kan tí wọ́n sọ pé ó ti “wo oríṣiríṣi àrùn sàn bẹ̀rẹ̀ láti orí ìṣòro mímí àti àìní agbára títí dórí àwọn àrùn tí ń wu ẹ̀mí léwu.” Nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò “fítámì” náà, wọ́n rí i pé omi iyọ̀ lásán ni.
Láìsí àní-àní, àwọn oríṣi oògùn àfirọ́pò kan lè jẹ́ kí ara èèyàn le. Bó ti wù kó rí, má retí ohun tí kò ṣeé ṣe. Ó bọ́gbọ́n mu pé kí o máa jẹ àwọn oúnjẹ tó ń ṣara lóore, kí o máa sun oorun tó pọ̀ tó, kí o máa ṣe eré ìmárale tó pọ̀ tó, kí o sì ṣọ́ra nígbà tí o bá ń yan irú ìtọ́jú tí o fẹ́ gbà.
A Rí Ohun Tí A Ń Wá
Ó hàn gbangba pé kò sí oògùn tí ẹ̀dá ènìyàn ṣe tó lè mú gbogbo àìsàn kúrò, tí á sì wá mú ikú tó ń gbẹ̀yìn rẹ̀ kúrò. Èyí jẹ́ nítorí pé a ti jogún àwọn nǹkan wọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ òbí wa àkọ́kọ́, ọkùnrin àkọ́kọ́ náà, Ádámù. (Jóòbù 14:4; Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12) Ọ̀pọ̀ ìtọ́jú tí àwọn oníṣègùn ń fúnni—tó lè jẹ́ oríṣiríṣi—lè ṣèrànwọ́, ṣùgbọ́n wọ́n wulẹ̀ jẹ́ ohun tó ń mú ìtura wá fún ìgbà díẹ̀, tó lè mú kí ẹ̀mí ẹni gùn sí i, tó sì lè mú kí ayé ẹni dùn fún ìgbà díẹ̀ ni. Bó ti wù kó rí, ìwòsàn tó dájú kan wà fún ìṣòro àìlera, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn sì ti mọ̀ nípa rẹ̀.
Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run tí í ṣe Oníṣègùn Títóbi Jù Lọ, ló pèsè ìwòsàn náà. Nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ àti jíjàǹfààní agbára tí ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, pèsè fún ètùtù ẹ̀ṣẹ̀, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti gbádùn ìlera pípé àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé kan tí kò ti ní sí àìsàn! (Mátíù 20:28) Bíbélì ṣèlérí pé nínú ayé tuntun, ‘kò sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.”’—Aísáyà 33:24.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ti rí ìrètí kan ṣoṣo tó dájú fún ìlera pípé