ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 11/8 ojú ìwé 16-18
  • Ṣé Kí N Sọ fún Ẹnì Kan Pé Mo Níṣòro Ìsoríkọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Kí N Sọ fún Ẹnì Kan Pé Mo Níṣòro Ìsoríkọ́?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá Àwọn Òbí Rẹ Sọ̀rọ̀
  • Bíbá Ọ̀rẹ́ Kan Sọ̀rọ̀
  • “Ẹ Máa Sọ Àwọn Ohun Tí Ẹ Ń Tọrọ Di Mímọ̀ fún Ọlọ́run”
  • Kí Ni Kí N Ṣe Bí Àwọn Míì Bá Fọ̀rọ̀ Wọn Lọ̀ Mí?
    Jí!—2005
  • Ṣé N Kúkú Para Mi?
    Jí!—2008
  • Àbí Kí N Para Mi Ni?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Mo Ṣe Ní Láti Wà Láìní Òbí?
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 11/8 ojú ìwé 16-18

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ṣé Kí N Sọ fún Ẹnì Kan Pé Mo Níṣòro Ìsoríkọ́?

“Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí mo bá níṣòro ìsoríkọ́, n kì í fẹ́ sọ fún ẹnikẹ́ni nítorí àwọn èèyàn lè máa rò pé oníyọnu ọmọ ni mí. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá mo wá rí i pé ó yẹ kí n máa sọ fún ẹnì kan nípa rẹ̀ kí wọ́n lè ràn mí lọ́wọ́.”—Alejandro, ọmọ ọdún mẹ́tàlá.

“Nígbà tí mo bá ní ìṣòro ìsoríkọ́, n kì í tọ àwọn ọ̀rẹ́ mi lọ nítorí mi ò rò pé wọ́n lè ràn mí lọ́wọ́. Wọ́n á kàn máa fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ ni.”—Arturo, ọmọ ọdún mẹ́tàlá.

Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló máa ń ní ìsoríkọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.a Ṣùgbọ́n nítorí pé o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, tí o kò sì tíì ní ìrírí tó pọ̀ tó, pákáǹleke ìgbésí ayé lè tètè mú ọkàn rẹ pòrúurùu. Ohun tí àwọn òbí rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àti àwọn olùkọ́ rẹ ń retí pé kí o ṣe; bí ara àti ìmọ̀lára rẹ ṣe ń yí padà nígbà ìbàlágà; tàbí ríronú pé o kò lè dá nǹkan kan ṣe láṣeyọrí nítorí àwọn àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí o ń ṣe—gbogbo nǹkan wọ̀nyí lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ bá ọ.

Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ó dára láti wá ẹnì kan finú hàn. Beatriz tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ pé: “Bí mi ò bá rí ẹni sọ ìṣòro mi fún, àfàìmọ̀ kí ikùn mi máà bẹ́ lọ́jọ́ kan.” Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń pa ìṣòro wọn mọ́ra—ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà pé ó máa ń kọ́lé ìrẹ̀wẹ̀sì sí wọn lára. María de Jesús Mardomingo, tí í ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n ní Ẹ̀ka Ìmọ̀ Ìṣègùn ní Madrid, sọ pé ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé ìṣòro ìnìkanwà tó le jù lọ́ máa ń yọ àwọn ọ̀dọ́ lẹ́nu tí wọ́n máa ń bá ọ̀ràn wọn débi gbígbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí kò ṣàṣeyọrí láti ṣekú para wọn sọ pé àwọn kò tíì rí àgbàlagbà kan tí àwọn lè máa sọ̀rọ̀ fún, tí àwọn sì lè finú hàn.

Ìwọ ńkọ́? Ṣé o ní ẹnì kan tí o lè máa sọ̀rọ̀ fún nígbà tí o bá rẹ̀wẹ̀sì? Bí o kò bá ní, ta ni o lè tọ̀ lọ?

Bá Àwọn Òbí Rẹ Sọ̀rọ̀

Alejandro, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ṣàpèjúwe ohun tí òun máa ń ṣe tí òun bá ní ìṣòro ìsoríkọ́, ó wí pé: “Màmá mi ni mo máa ń tọ̀ lọ nítorí pé láti ìgbà tí wọ́n ti bí mi ló ti jẹ́ alátìlẹyìn mi, ó sì máa ń ki mí láyà. Mo tún máa ń tọ bàbá mi lọ nítorí pé òun náà ti ní irú ìrírí tó jọ tèmi rí. Bí inú mi kò bá dùn tí mi ò sì sọ fún ẹnikẹ́ni, ńṣe ló máa ń burú sí i.” Rodolfo, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá, sọ pé: “Nígbà mìíràn, olùkọ́ wa máa ń fojú bù mí kù, á sì bá mi wí, ìyẹn sì máa ń bà mí nínú jẹ́ gan-an. Ilé ìtura ni mo ti máa ń lọ sunkún. Nígbà tó yá, mo sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ìyá mi, ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro náà. Ká ní mi ò sọ fún un nípa rẹ̀ ni, inú mi ì bá bàjẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

Ǹjẹ́ o ti ronú nípa bíbá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ tọmọ-tòbí? Bóyá o ronú pé wọn kò ní lóye ìṣòro rẹ dáadáa. Ṣùgbọ́n ṣé bó ṣe rí nìyẹn? Wọ́n lè máà lóye gbogbo hílàhílo táwọn ọ̀dọ́ ń kojú rẹ̀ láyé òde òní; ṣùgbọ́n ṣé o kò rò pé wọ́n lè mọ̀ ọ́ dáadáa ju bí ẹlòmíràn ṣe lè mọ̀ ọ́ láyé yìí lọ? Alejandro sọ pé: “Nígbà mìíràn, kì í rọrùn fún àwọn òbí mi láti bá mi kẹ́dùn kí wọ́n sì lóye bó ṣe rí lára mi.” Bó ti wù kó rí, ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé mo lè tọ̀ wọ́n lọ.” Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ya àwọn ọ̀dọ́ lẹ́nu láti rí bí àwọn òbí wọn ṣe lóye ìṣòro wọn dáadáa tó! Nítorí pé wọ́n dàgbà jù ọ́ lọ àti pé wọ́n nírìírí jù ọ́ lọ, lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n lè fún ọ ní ìmọ̀ràn tó wúlò—èyí rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì bí ọjọ́ bá ti pẹ́ tí wọ́n ti ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò.

Beatriz tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan yẹn sọ pé: “Nígbà tí mo bá bá àwọn òbí mi sọ̀rọ̀, mo máa ń rí ìṣírí àti ojútùú tó gbéṣẹ́ sí àwọn ìṣòro mi.” Nígbà náà, pẹ̀lú ìdí rere ni Bíbélì fi gba àwọn ọ̀dọ́ nímọ̀ràn yìí pé: “Ìwọ ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́, má sì ṣe ṣá òfin ìyá rẹ tì. Fetí sí baba rẹ tí ó bí ọ, má sì tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ kìkì nítorí pé ó ti darúgbó.”—Òwe 6:20; 23:22.

Lóòótọ́, á ṣòro láti finú han àwọn òbí rẹ bí àárín yín kò bá gún régé. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Catalina González Forteza ti sọ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga fi hàn pé èrò pé àwọn ò jámọ́ nǹkan kan ló sún àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn ti gbìyànjú rí láti gbẹ̀mí ara àwọn láti ṣe bẹ́ẹ̀, àárín àwọn àti àwọn òbí wọn kò sì gún régé. Ní òdì kejì ìyẹn, ní gbogbo gbòò, àwọn ọ̀dọ́ tí “àárín àwọn àti ìyá àti bàbá wọn gún régé” ló máa ń yẹra fún irú ìrònú bíba ayé ara ẹni jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Nítorí náà, fọgbọ́n ṣiṣẹ́ lórí níní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ. Sọ jíjíròrò pẹ̀lú wọn déédéé dàṣà. Máa sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ fún wọn. Máa béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn. Irú ìjíròrò tí ń tuni lára bẹ́ẹ̀ lè mú kó túbọ̀ rọrùn láti tọ̀ wọ́n lọ bí o bá ní ìṣòro.

Bíbá Ọ̀rẹ́ Kan Sọ̀rọ̀

Àmọ́, ǹjẹ́ kò ní túbọ̀ rọrùn láti sọ ìṣòro tí o ní fún ojúgbà rẹ? Lóòótọ́, ó dára láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tí o lè gbẹ́kẹ̀ lé. Òwe 18:24 sọ pé, “ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” Ṣùgbọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ojúgbà rẹ lè bá ọ kẹ́dùn, kí wọ́n sì ràn ọ́ lọ́wọ́, wọ́n lè ṣàì máa fún ọ ní ìmọ̀ràn tó dára jù lọ nígbà gbogbo. Ó ṣe tán, wọn kò ní ìrírí nípa ìgbésí ayé ju èyí tí ìwọ alára ní. Ṣé o rántí Rèhóbóámù? Ọba ni ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì. Dípò kó gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin tí wọ́n dàgbà dénú, tí wọ́n sì nírìírí, ohun táwọn ojúgbà rẹ̀ sọ ló gbọ́. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ó kàgbákò! Rèhóbóámù pàdánù ìtìlẹyìn ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ̀, ó sì tún pàdánù ojú rere Ọlọ́run.—1 Àwọn Ọba 12:8-19.

Ìṣòro mìíràn tó wà nínú fífinú han àwọn ojúgbà ẹni lè jẹ́ ọ̀ràn ti pípa àṣírí mọ́. Arturo, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọkùnrin tí mo mọ̀ ló máa ń sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ wọn nígbà tí inú wọ́n bá bà jẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà tó bá yá, àwọn ọ̀rẹ́ wọn á lọ tú gbogbo àṣírí náà fún àwọn ẹlòmíràn, wọ́n á sì máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.” Irú ohun kan náà ṣẹlẹ̀ sí Gabriela, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá. Ó sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, ó wá hàn sí mi pé ọ̀rẹ́ mi ń lọ sọ ọ̀rọ̀ àṣírí mi fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan, nítorí náà, mi ò tún finú hàn án mọ́. Lóòótọ́ mo máa ń bá àwọn ẹgbẹ́ mi sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n mo máa ń gbìyànjú láti má ṣe sọ àwọn ohun tó lè pa mí lára tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíràn.” Nítorí náà, tí o bá ń wá ìrànlọ́wọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí o wá a lọ sọ́dọ̀ ẹni tí kì í “ṣí ọ̀rọ̀ àṣírí ẹlòmíràn payá.” (Òwe 25:9) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ẹni tó jù ọ́ lọ.

Nítorí náà, bí o kò bá rí ìrànlọ́wọ́ gbà nílé nítorí ìdí kan, kò burú tí o bá wá ọ̀rẹ́ kan tí o lè finú hàn, ṣùgbọ́n rí i dájú pé ó jẹ́ ẹni tó ti ní ìrírí nínú ìgbésí ayé, tó sì mọ àwọn ìlànà Bíbélì. Ó dájú pé àwọn èèyàn tó ní ànímọ́ tí a ṣàpèjúwe yẹn wà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Liliana, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, sọ pé: “Mo ti finú han àwọn kan lára àwọn Kristẹni arábìnrin mi, ìyẹn sì dára gan-an. Níwọ̀n bí wọ́n ti dàgbà jù mí lọ, ìmọ̀ràn wọn yè kooro. Wọ́n ti di ọ̀rẹ́ mi.”

Tí ipò tẹ̀mí rẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí jó rẹ̀yìn ńkọ́? Bóyá inú rẹ ti bàjẹ́ gan-an débi pé o kì í gbàdúrà mọ́, tí o kì í sì í ka Bíbélì mọ́. Bíbélì gbani nímọ̀ràn nínú Jákọ́bù 5:14, 15 pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn láàárín yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà. Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde.” Àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n ní ìrírí nínú ríran àwọn èèyàn tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí wọ́n ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí lọ́wọ́ wà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Má ṣe lọ́ra láti bá wọn sọ̀rọ̀. Bíbélì sọ pé irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lè dà “bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.”—Aísáyà 32:2.

“Ẹ Máa Sọ Àwọn Ohun Tí Ẹ Ń Tọrọ Di Mímọ̀ fún Ọlọ́run”

Bó ti wù kó rí, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” ni orísun ìrànlọ́wọ́ tó dára jù lọ. (2 Kọ́ríńtì 1:3) Tí inú rẹ bá bàjẹ́ tí o sì sorí kọ́, fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Fílípì 4:6, 7 sílò, ó wí pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” Jèhófà ń fẹ́ láti tẹ́tí sí ọ nígbà gbogbo. (Sáàmù 46:1; 77:1) Àti pé nígbà mìíràn, àdúrà gan-an lo nílò láti tù ọ́ nínú.

Bí inú rẹ bá ń bàjẹ́ tàbí tí o ń sorí kọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, má ṣe gbàgbé pé irú ohun kan náà ti ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ mìíràn rí. Bí àkókò ti ń lọ, irú ohun tó ń ṣe ọ náà á lọ kúrò. Ṣùgbọ́n ní báyìí ná, má ṣe bo ìyà mọ́ra. Jẹ́ kí ẹnì kan mọ̀ pé ohun kan ń dà ọ́ láàmú. Òwe 12:25 sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” Báwo ni o ṣe lè rí “ọ̀rọ̀ rere” tí ń fúnni níṣìírí yẹn? Ó jẹ́ nípa sísọ fún ẹnì kan nípa rẹ̀—ẹni tó ní ìrírí, ìmọ̀, àti ọgbọ́n tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá tí yóò fún ọ ní ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ tí o nílò.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí ìmọ̀lára ìbànújẹ́ náà kò bá dáwọ́ dúró, ó lè jẹ́ àmì pé èèyàn ní ìṣòro ìdààmú ọkàn tàbí àbùkù ara tó le koko. A dámọ̀ràn pé kí o lọ rí oníṣègùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Wo àpilẹ̀kọ náà “Jija-àjàṣẹ́gun nínú Ìjà-ogun Lodisi Ìsoríkọ́,” nínú ìtẹ̀jáde March 1, 1990, ti Ilé Ìṣọ́ tí í ṣe èkejì ìwé ìròyìn wa yìí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]

“Nígbà tí mo bá bá àwọn òbí mi sọ̀rọ̀, mo máa ń rí ìṣírí àti ojútùú tó gbéṣẹ́ sí àwọn ìṣòro mi”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run ló lè gbà ọ́ nímọ̀ràn dáadáa, kì í ṣe àwọn ojúgbà rẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́