ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 12/8 ojú ìwé 16-18
  • Mo Ṣe Ní Láti Wà Láìní Òbí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Ṣe Ní Láti Wà Láìní Òbí?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kì Í Ṣe Ẹ̀bi Rẹ
  • Ìrírí Agbonijìgì
  • Rírí Ìrànlọ́wọ́
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ̀yin Èwe Ẹ Lè Múnú Àwọn Òbí Yín Dùn Tàbí Kẹ́ Ẹ Bà Wọ́n Nínú Jẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Bíbọlá fún Àwọn Òbí Wa Àgbàlagbà
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 12/8 ojú ìwé 16-18

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Mo Ṣe Ní Láti Wà Láìní Òbí?

“Ṣé bí ìgbésí ayé mi ṣe rí láìní òbí lẹ fẹ́ mọ̀? Nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan, mo lè wí pé ó kún fún ìbànújẹ́ gan-an. Ó ṣòro gan-an láti dàgbà láìní òbí tí yóò fi ìfẹ́ hàn síni.” —Joaquín.

“Ìṣòro tó nira jù lọ tí mo dojú kọ ni àwọn ọjọ́ tí àwọn òbí wá ń buwọ́ lu èsì ìdánwò. Inú mi bà jẹ́ gan-an, mo sì nímọ̀lára ìnìkanwà. Ó ṣì máa ń ṣe mí bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.” —Abelina, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.

Ọ̀RÀN àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tí ń dàgbà láìní òbí jẹ́ ọ̀ràn ìbànújẹ́ kan lákòókò wa. Ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù, ogun ti sọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún di ọmọ òrukàn. Ní Áfíríkà, àjàkálẹ̀ àrùn AIDS ti ṣe irú ọṣẹ́ kan náà. Àwọn òbí ti gbé àwọn ọmọ kan jù nù. Ogun àti ìjábá àdánidá ti ya àwọn ìdílé kan nípa.

Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí wọ́pọ̀ ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì pàápàá. Fún àpẹẹrẹ, léraléra ni Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kan ìṣòro tí ń bá àwọn ọmọ òrukàn fínra. (Sáàmù 94:6; Málákì 3:5) Ogun àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani nínú jẹ́ mìíràn tún ń ya àwọn ìdílé nípa nígbà náà lọ́hùn-ún. Bíbélì sì sọ nípa ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí a mú kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí kan láti Síríà gbé e sá lọ.—2 Àwọn Ọba 5:2.

Bóyá o jẹ́ ọ̀kan lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èwe tí àwọn pẹ̀lú bá ara wọn nípò ẹni tí kò ní òbí. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wàá mọ irú ìrora ọkàn tí irú ipò bẹ́ẹ̀ lè fà. Èé ṣe tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí ọ?

Kì Í Ṣe Ẹ̀bi Rẹ

Ǹjẹ́ o máa ń rí i tí o máa ń ronú, bóyá Ọlọ́run ń fi èyí jẹ ọ́ níyà ni? Àbí bóyá ńṣe ni inú máa ń bí ọ sí àwọn òbí rẹ gan-an nítorí pé wọ́n kú—bíi pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ kú ni. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, jẹ́ kí ó yé ọ pé kì í ṣe pé Ọlọ́run ń bínú sí ọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe pé àwọn òbí rẹ mọ̀ọ́mọ̀ yàn láti fi ọ́ sílẹ̀ ni. Ikú jẹ́ ìpín tí ń fa ìbànújẹ́ fún ẹ̀dá aláìpé, ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òbí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kódà nígbà tí àwọn ọmọ wọn ṣì kéré. (Róòmù 5:12; 6:23) Ẹ̀rí fi hàn pé Jósẹ́fù, bàbá ọ̀wọ́n tí ó gba Jésù Kristi tọ́, pàápàá kú.a Dájúdájú, kì í ṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí tí Jésù dá.

O tún ní láti mọ̀ pé a ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1-5) Ìwà ipá, ogun, àti ìwà ọ̀daràn ti ṣekú pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ní ọ̀rúndún yìí. “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀,” tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni, sì ti ṣekú pa àwọn mìíràn. (Oníwàásù 9:11) Bí ó ti wù kí ikú àwọn òbí rẹ̀ dùn ọ́ tó, kì í ṣe ẹ̀bi rẹ. Dípò kí o máa dá ara rẹ lẹ́bi tàbí kí o jẹ́ kí ìbànújẹ́ bò ọ́ mọ́lẹ̀, máa fi ìrètí àjíǹde tí Ọlọ́run ṣe tu ara rẹ nínú.b Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Abelina, tí a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀, sọ pé: “Ìfẹ́ mi fún Jèhófà àti ìrètí àjíǹde ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an.”

Bí àwọn òbí rẹ bá ṣì wà láàyè, àmọ́ tí wọ́n já ọ sílẹ̀ ńkọ́? Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn òbí tọ́ àwọn ọmọ wọ́n dàgbà, kí wọ́n sì pèsè fún wọn. (Éfésù 6:4; 1 Tímótì 5:8) Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn òbí kan ti fi àìní “ìfẹ́ni àdánidá” hàn sí àwọn ọmọ wọn lọ́nà tó bani lẹ́rù. (2 Tímótì 3:3) Ní ti àwọn mìíràn, ohun tó fa jíjá wọn sílẹ̀ náà ni ipò òṣì lílégbá kan, ìjoògùnyó, ìfinisẹ́wọ̀n, tàbí ìmutípara. Òtítọ́ ni pé àwọn òbí kan tún wà tí wọ́n já àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ kìkì nítorí ìmọtara-ẹni-nìkan. Ohun yòówù kó fà á, àìsí lọ́dọ̀ àwọn òbí ẹni ń fa ìbànújẹ́. Àmọ́ ṣá o, èyí kò túmọ̀ sí pé nǹkan kan ń ṣe ọ́ tàbí pé o ní láti máa fi ẹ̀bi dá ara rẹ lóró. Ní gidi, àwọn òbí rẹ ni wọn yóò jíhìn fún Ọlọ́run nípa ìwà tí wọ́n bá hù sí ọ. (Róòmù 14:12) Àmọ́, bí ó bá jẹ́ ìṣòro tó ju agbára àwọn òbí rẹ lọ, bí ìjábá àdánidá kan tàbí àìsàn, ló fipá sún wọn láti má ṣe wà pẹ̀lú rẹ, nígbà náà, kì í ṣe ẹjọ́ ẹnikẹ́ni! Ìrètí wíwà pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan síi wà níbẹ̀, kódà bó bá jọ pé ìrètí yẹn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ nígbà mìíràn pàápàá.—Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 46:29-31.

Ìrírí Agbonijìgì

Ní báyìí ná, o lè ní ìṣòro lílekoko bí mélòó kan. Ìwádìí kan tí Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ṣe, tí wọ́n pè ní Children in War, ṣàlàyé pé: “Àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́ ni wọ́n máa ń wà nínú ewu jù—àwọn tí wọ́n . . . ń dojú kọ àwọn ìdènà lílé jù lọ fún lílà á já, tí wọn kò ní ìtìlẹ́yìn fún ìdàgbàsókè gidi, tí a sì ń fìyà jẹ. Yíya ọmọ kan nípa kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ lè jẹ́ ọ̀kan lára àdánù agbonijìgì tí ó bá ọmọ náà.” Bóyá o bá ara rẹ ní ipò tí o ti ń bá ìsoríkọ́ àti ìjákulẹ̀ jà.

Rántí Joaquín, tí a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀. Àwọn òbí rẹ̀ kò gbé pọ̀ mọ́, wọ́n sì já òun àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sílẹ̀. Ọmọ ọdún kan péré ni nígbà yẹn, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ló wá tọ́ ọ dàgbà. Ó ṣàlàyé pé: “Mo máa ń béèrè ìdí tí a kò fi ní òbí bí ti àwọn ọ̀rẹ́ mi. Bí mo bá sì rí bàbá kan tí ń bá ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣeré, mo máa ń fẹ́ pé kó jẹ́ bàbá mi.”

Rírí Ìrànlọ́wọ́

Bí ó ti wù kí títọ́ni dàgbà láìsí àwọn òbí níbẹ̀ ṣòro tó, kò túmọ̀ sí pé o kò ní ní láárí. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹ́yìn, wàá là á já, wàá sì tún ní láárí. Ó lè jọ pé èyí ṣòro fún ọ láti gbà gbọ́, pàápàá bí ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn bá ń bá ọ fínra. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, o ní láti mọ̀ pé, irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ kò ṣàrà ọ̀tọ̀, àti pé kò ní máa pọ́n ọ lójú títí ayé. Ní Oníwàásù 7:2, 3, a kà pé: “Ó sàn láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju láti lọ sí ilé àkànṣe àsè . . . Ìbìnújẹ́ sàn ju ẹ̀rín, nítorí nípa ìfàro ojú ni ọkàn-àyà fi ń di èyí tí ó wà ní ipò tí ó sàn jù.” Bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe ohun àrà ọ̀tọ̀, ó sì ń ṣe ọpọlọ lóore láti sunkún, kí a sì banú jẹ́ nígbà tí ohun ìbànújẹ́ kan bá ṣẹlẹ̀. Ó tún lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti fi àṣírí han ọ̀rẹ́ kan tí ó lóye tàbí ẹnì kan tí ó dàgbà dénú nínú ìjọ, kí o sì sọ nípa ìrora ọkàn tí o ń ní.

Ní tòdodo, ohun kan lè fẹ́ sùn ọ ya ara rẹ láṣo. Àmọ́, Òwe 18:1 kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” Ó dára láti wá ìrànlọ́wọ́ ẹnì kan tí ó ní inúure, tí ó sì lóye. Òwe 12:25 wí pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” Kìkì tí o bá sọ fún ẹnì kan nípa “àníyàn” rẹ ni o lè gbọ́ “ọ̀rọ̀ rere” yẹn.

Ta ni o lè sọ fún? Wá ìrànlọ́wọ́ nínú ìjọ Kristẹni. Jésù ṣèlérí pé ibẹ̀ ni o ti lè rí “àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá” tí yóò nífẹ̀ẹ́ rẹ, tí yóò sì bìkítà nípa rẹ. (Máàkù 10:30) Joaquín sọ pé: “Kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni ará mú kí n rí ìgbésí ayé lọ́nà tí ó yàtọ̀. Lílọ sí ìpàdé déédéé mú kí n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí i, kí n sì fẹ́ láti sìn ín. Àwọn ará tí wọ́n dàgbà dénú ran ìdílé mí lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, wọ́n sì gbà wá nímọ̀ràn. Lónìí, díẹ̀ lára àwọn ọmọ ìyá mi jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.”

Tún rántí pé Jèhófà jẹ́ “baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba.” (Sáàmù 68:5, 6) Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, Ọlọ́run rọ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti fi àánú àti òdodo bá àwọn ọmọ òrukàn lò. (Diutarónómì 24:19; Òwe 23:10, 11) Ó sì bìkítà lọ́nà kan náà nípa àwọn èwe tí wọn kò lóbìí lónìí. Nítorí náà, gbàdúrà sí Ọlọ́run, pẹ̀lú ìdánilójú pé ó bìkítà nípa rẹ àti pé yóò dá ọ lóhùn. Dáfídì Ọba kọ̀wé pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí. Ní ìrètí nínú Jèhófà; jẹ́ onígboyà, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ jẹ́ alágbára.”—Sáàmù 27:10, 14.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èwe kan tí kò lóbìí ń dojú kọ ìpèníjà mélòó kan lójoojúmọ́. Ibo ni wàá máa gbé? Báwo ni wàá ṣe máa rówó gbọ́ bùkátà? Àpilẹ̀kọ kan tí ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú yóò jíròrò bí o ṣe lè ṣàṣeyọrí nínú kíkápá àwọn kan lára ìpèníjà wọ̀nyí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kí Jésù tó kú, ó ní kí ọmọlẹ́yìn Jòhánù máa bójú tó ìyá òun, èyí kì bá tí rí bẹ́ẹ̀ ká ní Jósẹ́fù, bàbá tí ó gbà á tọ́, ṣì wà láàyè ni.—Jòhánù 19:25-27.

b Fún ìsọfúnni nípa mímú ikú òbí kan mọ́ra, wo àwọn àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .” tí ó jáde nínú Jí!, ìtẹ̀jáde August 22 àti September 8, 1994.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]

“Ìfẹ́ mi fún Jèhófà àti ìrètí àjíǹde ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè nímọ̀lára ìdáwà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́, kí wọ́n sì fún ọ níṣìírí wà nínú ìjọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́