ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/08 ojú ìwé 16-19
  • Ṣé N Kúkú Para Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé N Kúkú Para Mi?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Ń Fà Á
  • Kí Lọ̀nà Àbáyọ?
  • Nǹkan Máa Ń Yí Padà
  • Àdúrà Ṣe Pàtàkì
  • Tó Bá Jẹ́ Ọ̀ràn Nípa Ìlera
  • Àbí Kí N Para Mi Ni?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • O Lè Rí Ìrànwọ́
    Jí!—2001
  • Nígbà Tí Ìrètí Àti Ìfẹ́ Bá Tún Wà
    Jí!—1998
  • Pípa Ara Ẹni—Ìṣòro Wíwọ́pọ̀ Láàárín Àwọn Ọ̀dọ́
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 7/08 ojú ìwé 16-19

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Ṣé N Kúkú Para Mi?

Ọ̀kẹ́ àìmọye ọ̀dọ́ ló ń gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn lọ́dọọdún. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló sì ń pàpà para wọn. Torí pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ń gbẹ̀mí ara wọn, ni ìwé ìròyìn “Jí!” fi rí i pé ọ̀rọ̀ yìí tó ó sọ.

“ẸJẸ́ n kú. Ikú yá jẹ̀sín.” Ta ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn? Ṣé ẹnì kan tí ò gba Ọlọ́run gbọ́ ni? Ṣé ẹnì kan tó ti fi Ọlọ́run sílẹ̀ ni? Àbí ẹni tí Ọlọ́run ti kọ̀ ni? Rárá o. Ọkùnrin kan tó fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run àmọ́ tí nǹkan tojú sú ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, Jónà lorúkọ rẹ̀.a (Jónà 4:3, ìtumọ̀ Today’s English Version) Bíbélì ò sọ pé Jónà fẹ́ para ẹ̀. Síbẹ̀, ohun tó ń bẹ̀bẹ̀ fún nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká mọ òtítọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro; òótọ́ náà sì ni pé ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn lè sorí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kodò nígbà míì.—Sáàmù 34:19.

Ìbànújẹ́ ti sorí àwọn ọ̀dọ́ kan kodò débi pé wọn ò rídìí tó fi yẹ káwọn wà láàyè. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí lára ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún kan tó ń jẹ́ Laurab ló ṣe rí lára tiwọn náà, ó ní: “Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sígbà tí ìbànújẹ́ kì í sorí mi kodò. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì máa ń ronú pé ikú yá jẹ̀sín.” Tó o bá mọ ẹnì kan tó ti máa ń sọ pé òun fẹ́ para òun, tó bá sì jẹ́ pé ìwọ alára máa ń ronú pé ohun tó máa dáa jù ni pé kó o gbẹ̀mí ara ẹ, kí lo lè ṣe? Jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ohun tó máa ń fa irú èròkérò bẹ́ẹ̀.

Ohun Tó Ń Fà Á

Kí ló lè fà á tẹ́nì kan á fi fẹ́ para ẹ̀? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè fà á. Àkọ́kọ́ ni pé, “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé, àwọn ọ̀dọ́ sì ń mọ̀ ọ́n lára lọ́nà tó kàmàmà. (2 Tímótì 3:1) Yàtọ̀ síyẹn, àìpé ẹ̀dá lè jẹ́ káwọn kan ro ara wọn pin, kí wọ́n sì máa ronú pé nǹkan ò lè dáa fáwọn mọ́ láé. (Róòmù 7:22-24) Ó lè jẹ́ nítorí pé ẹnì kan fọwọ́ ọlá gbá wọn lójú tàbí kẹ́nì kan fi bí nǹkan ṣe rí fún wọn sọ̀rọ̀ gbá wọn lórí. Nígbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe wọ́n ló jẹ́ kí wọ́n máa ronú pé ikú ló kàn. Lórílẹ̀-èdè kan ẹ̀rí fi hàn gbangba pé mẹ́sàn-án lára àwọn mẹ́wàá tó ń para wọn ló ní irú àrùn ọpọlọ kan tàbí òmíràn.c

Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tí ìṣòro ò lè dé bá. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé “gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀.” (Róòmù 8:22) Ìyẹn ò sì yọ àwọn ọ̀dọ́ sílẹ̀. Kódà, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wà tó lè mú kí ìbànújẹ́ sorí àwọn ọ̀dọ́ kodò, irú bíi:

◼ Kí èèyàn wọn tàbí ọ̀rẹ́ wọn ṣaláìsí

◼ Èdèkòyédè láàárín ìdílé

◼ Kí wọ́n fìdí rẹmi níléèwé

◼ Kí olólùfẹ́ wọn já wọn kulẹ̀

◼ Kí wọ́n hùwà tí ò dáa sí wọn (bíi kí wọ́n fìyà jẹ wọ́n tàbí kí wọ́n fipá bá wọn lò pọ̀)

Òótọ́ ni pé, bópẹ́ bóyá á fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọ̀dọ́ ni ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ohun tá a tò sókè yìí máa ṣẹlẹ̀ sí. Kí nìdí táwọn kan fi máa ń tètè gbójú fo àwọn ìṣòro wọ̀nyí dá ju àwọn míì lọ? Àwọn ọ̀mọ̀ràn sọ pé àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń parí èrò sí pé kò sẹ́ni tó lè ran àwọn lọ́wọ́ àti pé ìṣòro àwọn ò lójúùtú. Lọ́rọ̀ kan ṣá, irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń gbà pé nǹkan ò lè dáa fáwọn mọ́, wọn kì í sì í rí àpẹẹrẹ pé nǹkan máa dáa lóòótọ́. Ọ̀mọ̀wé Kathleen McCoy sọ fún akọ̀ròyìn Jí! pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà kì í kúkú ṣe pé àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyẹn fẹ́ kú, àmọ́ ńṣe ni wọ́n kàn fẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn náà dópin.”

Kí Lọ̀nà Àbáyọ?

O lè mọ ẹnì kan tó ‘fẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn náà dópin’ débi pé ó ti pinnu láti para ẹ̀. Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, kí lọ̀nà àbáyọ?

Tó o bá ní ọ̀rẹ́ tí ìbànújẹ́ ti sorí ẹ̀ kodò débi pé ó ti ń ronú pé ikú lẹ̀rọ̀ ẹ̀, wá ọ̀nà láti jẹ́ kó mọ̀ pé ó nílò ìmọ̀ràn. Lẹ́yìn náà, ó gbà tàbí kò gbà, o ní láti fọ̀rọ̀ náà tó àgbàlagbà kan létí. Ìwọ gbàgbé ti pé àárín yín lè dà rú. Nítorí ìgbà tó o bá sọ fún àgbalagbà yẹn lo ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ara rẹ̀ hàn bí “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ . . . tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Ó lè jẹ́ bó o ṣe máa gba ẹ̀mí ẹ̀ là nìyẹn!

Tó bá jẹ́ pé ìwọ alára ti máa ń ronú pé ikú lẹ̀rọ̀ ńkọ́? Ìmọ̀ràn ọ̀mọ̀wé McCoy ni pé: “Wá ìrànlọ́wọ́ lọ. Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fẹ́nì kan, bóyá àwọn òbí ẹ, mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́, olùkọ́, tàbí òjíṣẹ́ Ọlọ́run kan tó fẹ́re fún ẹ, tá á fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan tó ń ṣe ẹ́, tá a tẹ́tí sí ẹ, tá á sì ran àwọn èèyàn míì tẹ́ ẹ jọ mọwọ́ ara yín lọ́wọ́ láti fetí sí ẹ.”

O ò lè pàdánù ohunkóhun, àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lo máa jèrè tó o bá fi ìṣòro lọ àwọn ẹlòmíì. Àpẹẹrẹ kan rèé nínú Bíbélì. Ìgbà kan wà tí Jóòbù tó jẹ́ ọkùnrin olóòótọ́ sọ pé: “Dájúdájú, ọkàn mi kórìíra ìgbésí ayé mi tẹ̀gbintẹ̀gbin.” Àmọ́ kíá ló fi kún un pé: “Èmi yóò tú ìdàníyàn nípa ara mi jáde. Èmi yóò sọ̀rọ̀ nínú ìkorò ọkàn mi!” (Jóòbù 10:1) Ìbànújẹ́ dorí Jóòbù kodò, ó sì ní láti sọ ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ fẹ́nì kan. O lè rí ìtura gbà tó o bá fọ̀rọ̀ lọ ọ̀rẹ́ kan tí òye ẹ̀ jinlẹ̀ dáadáa.

Ibòmíì tún wà táwọn Kristẹni tí ìbànújẹ́ ti sorí wọn kodò lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ, ìyẹn ni ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ. (Jákọ́bù 5:14, 15) Òótọ́ ni pé sísọ tó o máa sọ ìṣòro tó o ní fẹ́lòmíì ò ní kí ìṣòro náà pòórá. Àmọ́ ó lè jẹ́ kó o rí i pé kò yẹ kó o torí ẹ̀ ro ikú ro ara rẹ, ó sì lè jẹ́ pé ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ ẹnì kan tó o lè fọ̀ràn lọ̀ lo nílò láti yanjú ìṣòro ọ̀hún.

Nǹkan Máa Ń Yí Padà

Nígbàkigbà tó o bá ní ẹ̀dùn ọkàn, máa rántí pé: Kò sí bí ìṣòro náà ṣe lè dà bíi pó le tó, nǹkan máa yí padà bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́. Ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ ò ṣàjèjì sí Dáfídì tó kọ lára ìwé sáàmù, ó tiẹ̀ gbàdúrà nígbà kan pé: “Agara ìmí ẹ̀dùn mi ti dá mi; láti òru mọ́jú ni mo ń mú kí àga ìrọ̀gbọ̀kú mi rin gbingbin; omijé mi ni mo fi ń mú kí àga ìnàyìn mi kún àkúnwọ́sílẹ̀.” (Sáàmù 6:6) Àmọ́, nínú sáàmù míì, ó kọ̀wé pé: “Ìwọ ti sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó fún mi.”—Sáàmù 30:11.

Dáfídì ti nírìírí pé ńṣe nìṣòro máa ń wá tó sì máa ń lọ. Òótọ́ ni pé àwọn ìṣòro kan lè muni lómi. Àmọ́, mọ́kàn le. Lọ́pọ̀ ìgbà, nǹkan máa ń yí padà sí rere. Nígbà míì, ìṣòro wa máa yanjú lọ́nà tá ò rò tẹ́lẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ọ̀nà kan tó ò ronú kàn tẹ́lẹ̀ lo máa gbà kojú ìṣòro náà. Lọ́rọ̀ kan ṣá, àwọn ìṣòro tó ń sorí èèyàn kodò ò ní máa wà bẹ́ẹ̀ títí ayé.—2 Kọ́ríńtì 4:17.

Àdúrà Ṣe Pàtàkì

Ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù tá a lè gbà sọ ohun tó ń ṣe wá ni pé ká fi tó Ọlọrun létí nínú àdúrà. Ìwọ náà lè ṣe bíi ti Dáfídì tó gbàdúrà pé: “Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi. Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè, kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi, kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 139:23, 24.

Àdúrà kọjá ohun téèyàn kàn ń lò láti yanjú ìṣòro. Ọ̀nà tá a gbà ń bá Bàbá wa ọ̀run sọ̀rọ̀ ni, òun alára sì fẹ́ kó o “tú ọkàn-àyà [rẹ] jáde” fún òun. (Sáàmù 62:8) Gbé àwọn òkodoro òtítọ́ nípa Ọlọ́run tá a tò sísàlẹ̀ yìí yẹ̀ wò:

◼ Ó mọ ohun tó fà á tó o fi ń banú jẹ́.—Sáàmù 103:14.

◼ Ó mọ̀ ẹ́ ju bó o ṣe mọ ara ẹ lọ.—1 Jòhánù 3:20.

◼ ‘Ó bìkítà nípa ẹ.’—1 Pétérù 5:7.

◼ Nínú ayé tuntun, Ọlọ́run máa “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [rẹ].”—Ìṣípayá 21:4.

Tó Bá Jẹ́ Ọ̀ràn Nípa Ìlera

Bá a ṣe sọ lókè, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àìsàn ló máa ń fà á téèyàn fi máa ń ronú pé kí òun pa ara òun. Tó bá jẹ́ pé nǹkan tó ń ṣe ẹ́ nìyẹn, máà jẹ́ kójú tì ẹ́ láti wá ẹni ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jésù gbà pé àwọn tó ń ṣàìsàn nílò oníṣègùn. (Mátíù 9:12) Ibi tọ́ràn náà dáa sí ni pé púpọ̀ lára àwọn àìsàn tó ń ṣèèyàn ló máa ń lọ téèyàn bá gba ìtọ́jú tó péye. Ìtọ́jú yẹn sì lè mú kára yá!

Bíbélì ṣèlérí pé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Ní báyìí ná, ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti fara da àwọn ìṣòro tó wà nínú ayé yìí. Ohun tí Heidi tó ń gbé nílùú Jámánì ṣe nìyẹn. Ó ní: “Nígbà míì, ìbànújẹ́ máa ń mu mí lómi débi pé ó máa ṣe mí bíi kí n kú, àmọ́ ní báyìí ara mi ti yá, ọpẹ́lọpẹ́ àdúrà tí mò ń gbà láìdabọ̀ àti ìtọ́jú tí mo gbà.” Ọ̀rọ̀ tìẹ náà lè rí bẹ́ẹ̀!d

Àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” míì wà nínú ìwé ìròyìn yìí tó ṣàlàyé bá a ṣe lè fara dà á tí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni bá gbẹ̀mí ara ẹ̀

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Rèbékà, Mósè, Èlíjà àti Jóòbù náà sọ irú ọ̀rọ̀ tó ń fi ẹ̀dùn ọkàn hàn tí Jónà sọ yìí.—Jẹ́nẹ́sísì 25:22; 27:46; Númérì 11:15; 1 Àwọn Ọba 19:4; Jóòbù 3:21; 14:13.

b A ti yí àwọn orúkọ tá a lò nínú àpilẹ̀kọ yìí padà.

c Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀dọ́ tó lárùn ọpọlọ kọ́ ló máa ń para wọn.

d Fún àlàyé síwájú sí i lórí béèyàn ṣe lè fara da ẹ̀dùn ọkàn, wo ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Ìrànwọ́ fún Àwọn Èwe Tó Sorí Kọ́” nínú Jí! September 8, 2001 àti “Lílóye Àwọn Tí Ìṣesí Wọn Ṣàdédé Ń Yí Padà,” nínú Jí! January 8, 2004.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Àwọn ọ̀mọ̀ràn ti sọ pé bó o tiẹ̀ para ẹ, ìyẹn ò yanjú ìṣòro tó o ní; o wulẹ̀ tì í sọ́dọ̀ ẹlòmíì ni. Ṣóòótọ́ ni?

◼ Ta lo lè fọ̀rọ̀ lọ̀ tí ìbànújẹ́ bá sorí ẹ kodò?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ

Láwọn apá ibì kan lágbàáyé, kì í ṣe nǹkan tuntun mọ́ pé àwọn ọ̀dọ́ ń para wọn, ìyẹn sì ń kọ àwọn èèyàn lóminú. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nígbà tí wọ́n to àwọn nǹkan tó ń fa ikú àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, wọ́n rí i pé ipò kẹta ni pípa táwọn ọ̀dọ́ ń pa ara wọn wà. Láti nǹkan bí ogún ọdún sígbà tá a wà yìí, iye àwọn ọ̀dọ́ tó ń para wọn nígbà tí wọ́n wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá sí mẹ́rìnlá ti pọ̀ sí i ní ìlọ́po méjì. Àwọn tó sábà máa ń dáṣà yìí làwọn ọ̀dọ́ tó lárùn ọpọlọ, àwọn ọ̀dọ́ tí mọ̀lẹ́bí wọn kan ti para rẹ̀ rí, àtàwọn tó ti gbìyànjú nígbà kan rí láti gbẹ̀mí ara wọn. Àwọn nǹkan tẹ́ ẹ lè rí rèé tẹ́ ẹ fi lè mọ̀ bóyá ọ̀dọ́ kan ti ń ronú láti para rẹ̀:

◼ Á bẹ̀rẹ̀ sí í yara ẹ̀ láṣo

◼ Oúnjẹ á máa tètè sú u, á máa ṣèrànrán lójú oorun, ó sì lè máà rí oorun sùn dáadáa

◼ Àwọn nǹkan tó fẹ́ràn láti máa ṣe tẹ́lẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí rùn sí i

◼ Ìṣesí ẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí yàtọ̀ sí tàtẹ̀yìnwá

◼ Ó lè bẹ̀rẹ̀ sí lòògùn nílòkulò, kó sì máa mutí lámujù

◼ Á bẹ̀rẹ̀ sí fàwọn nǹkan tó jojú ní gbèsè tọrẹ

◼ Ọ̀rọ̀ nípa ikú ò ní máa wọ́n lẹ́nu ẹ̀ tàbí kó máa sọ nǹkan tó jọ mọ́ ọn

Ọ̀mọ̀wé Kathleen McCoy sọ fún akọ̀ròyìn Jí! pé àṣìṣe gbáà ló máa jẹ́ táwọn òbí ò bá lọ ka àwọn àmì wọ̀nyí sí. Ó sọ pé: “Kò sẹ́ni tó fẹ́ kí nǹkan kan ṣe ọmọ òun, torí náà ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń parí èrò sí pé kò sóhun tó ń ṣe ọmọ àwọn. Wọ́n sábà máa ń sọ pé ‘ìgbà ni, ó máa tó yí i dá’ tàbí kí wọ́n sọ pé ‘ó kàn fẹ́ jọ mí lójú ni.’ Ó léwu láti máa ronú báyìí o. Gbogbo àmì tẹ́ ẹ bá ń rí ló yẹ kẹ́ ẹ fọwọ́ pàtàkì mú.”

Ẹ̀yin òbí, ẹ máà jẹ́ kójú tì yín láti gbà ìtọ́jú fún ọmọ yín tó bá ní ìdààmú ọkàn tàbí tó lárùn ọpọlọ. Tẹ́ ẹ bá sì fura pé ọmọ yín ń ronú láti para ẹ̀, ẹ tètè bi í. Irọ́ gbuu lèrò táwọn èèyàn ní pé táwọn bá sọ̀rọ̀ nípa gbígba ẹ̀mí ara ẹni, ó lè jẹ́ káwọn ọmọ pa ara wọn. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lara wọn máa ń wálẹ̀ wọ̀ọ̀ táwọn òbí bá báwọn sọ̀rọ̀ nípa pípa tí wọ́n fẹ́ para wọn. Tí ọmọ yín ò bá jiyàn pé òun fẹ́ para òun, ẹ tètè béèrè bóyá ó ti ní bó ṣe fẹ́ ṣe é, tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ fara balẹ̀ gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa rẹ̀. Bí kúlẹ̀kúlẹ̀ tẹ́ ẹ gbọ́ bá ṣe le tó lẹ ṣe gbọ́dọ̀ káràmáásìkí ọ̀rọ̀ náà tó.e

Ẹ má kàn rò pé ìbànújẹ́ tó sorí onítọ̀hún kodò máa pòórá tó bá yá. Tó bá tiẹ̀ wá dà bíi pó rí bẹ́ẹ̀, ẹ má lọ rò pé ìṣòro ti tán nìyẹn o. Àwọn ògbóǹkangí sọ pé ríronú lọ́nà yẹn ló burú jù. Kí nìdí? Ọ̀mọ̀wé McCoy sọ pé: “Ọ̀dọ́ tí ìbànújẹ́ bá mu lómi kì í rójú ráyè tó bẹ́ẹ̀ láti ṣekú para ẹ̀, àmọ́ tí ìṣòro tó ní bá fúyẹ́ díẹ̀ ló máa lókùn tó pọ̀ tó láti gbẹ̀mí ara ẹ̀.”

Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ tó níṣòro máa ń ronú pé ikú ya jẹ̀sín, ni wọ́n ṣe máa ń para wọn. Àmọ́, tí ẹ̀yin òbí àtàwọn àgbàlagbà míì tó bìkítà nípa onítọ̀hún bá pàfiyèsí sáwọn àmì wọ̀nyẹn tẹ́ ẹ sì gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ, ẹ ó lè “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́,” ẹ ó sì wá di ibi ààbò fáwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyẹn.—1 Tẹsalóníkà 5:14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

e Àwọn ògbóǹkangí nínú ṣíṣèwáàdí lórí ọ̀rọ̀ gbígbẹ̀mí ara ẹni tún kìlọ̀ pé ó léwu láti máa fàwọn oògùn tó lè ṣekú pani tàbí àwọn nǹkan èlò bí ọ̀bẹ, àdá, ìbọn àtàwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ nínú ilé. Lórí ìkìlọ̀ táwọn ògbóǹkangí ṣe yìí, àjọ tó ń rí sí bí wọ́n ṣe lè dẹ́kun àṣà ṣíṣekú para ẹni lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn American Foundation for Suicide Prevention, ṣàkíyèsí pé: “Òótọ́ ni pé púpọ̀ lára àwọn tó níbọn nílé ló láwọn fi ń ‘dáàbò bò ara àwọn ni’ tàbí pé àwọn fi ń ‘gbèjà ara àwọn,’ síbẹ̀ ẹ̀rí ti fi hàn pé ó lé ní mẹ́jọ nínú mẹ́wàá lára àwọn tó ń para wọn tó jẹ́ pé ìbọn àwọn ará ilé wọn ni wọ́n yìn lu ara wọn.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù tá a lè gbà sọ ohun tó ń ṣe wá ni pé ká fi tó Ọlọrun létí nínú àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́