ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 9/8 ojú ìwé 8-10
  • Nígbà Tí Ìrètí Àti Ìfẹ́ Bá Tún Wà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà Tí Ìrètí Àti Ìfẹ́ Bá Tún Wà
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ àti Àwọn Àgbàlagbà Mìíràn Lè Ṣèrànwọ́
  • Ìdásílẹ̀ Kúrò Nípò Pípa Ara Ẹni
  • Kò Ní Sí Ikú Èwe Mọ́
  • Ṣé N Kúkú Para Mi?
    Jí!—2008
  • Ohun Tó Ń mú Káyé Sú Àwọn Èèyàn Kan
    Jí!—2001
  • Pípa Ara Ẹni—Ìṣòro Wíwọ́pọ̀ Láàárín Àwọn Ọ̀dọ́
    Jí!—1998
  • Gbogbo Èèyàn Ló Ń Fẹ́ Láti Wà Láàyè
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 9/8 ojú ìwé 8-10

Nígbà Tí Ìrètí Àti Ìfẹ́ Bá Tún Wà

ÀWỌN òbí, olùkọ́, àti àwọn mìíràn tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ àwọn èwe mọ̀ pé àwọn, tàbí àwọn èwe, tàbí ènìyàn mìíràn kan, kò lè yí ayé padà. Àwọn ipá tó dà bí ìgbì òkun tí ẹnikẹ́ni kò lè dá dúró wà lẹ́nu iṣẹ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ohun tí gbogbo wa lè ṣe láti mú kí àwọn èwe túbọ̀ láyọ̀, kí wọ́n túbọ̀ lera, kí wọ́n sì túbọ̀ mú ara bá ipò mu, ló wà.

Níwọ̀n bí ó ti dára kí a dènà ipò búburú ju pé kí a máa ṣàtúnṣe rẹ̀, ó yẹ kí àwọn òbí ronú jinlẹ̀ lórí bí ìgbésí ayé wọn àti àwọn ohun àkọ́múṣe wọn ṣe lè nípa lórí ìṣe àti ìwà àwọn ọmọ wọn. Jíjẹ́kí ilé jẹ́ àyíká onífẹ̀ẹ́ àti ti àbójútó ń fúnni ní ìdánilójú tí ó lè dènà ìwà ìpara-ẹni-run lọ́nà dídára jù lọ. Ọ̀kan nínú àwọn ohun tí àwọn ọ̀dọ́ nílò jù lọ ni, níní ẹnì kan tí yóò tẹ́tí sí wọn. Bí àwọn òbí kò bá ń tẹ́tí sí wọn, ó ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn tí kò tóótun tó bẹ́ẹ̀ máa tẹ́tí sí wọn.

Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí fún àwọn òbí lónìí? Wá àyè gbọ́ ti àwọn ọmọ rẹ nígbà tí wọ́n nílò rẹ̀—nígbà tí wọ́n ṣì kéré. Èyí kò rọrùn fún ọ̀pọ̀ ìdílé. Wọ́n ń tiraka láti gbọ́ bùkátà, àwọn òbí méjèèjì sì gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́. Èrè tí àwọn tí wọ́n múra tán láti pa àwọn ohun kan tì, kí wọ́n lè ní àkókò púpọ̀ sí i láti fi gbọ́ ti àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, sábà máa ń jẹ ni pé, wọ́n ń rí àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí wọ́n ń ṣàṣeyọrí gan-an nínú ìgbésí ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a ti sọ ṣáájú, nígbà mìíràn, láìka gbogbo ìsapá rere tí àwọn òbí ṣe sí, àwọn ìṣòro eléwu lè ṣẹlẹ̀ nípa àwọn ọmọ wọn.

Àwọn Ọ̀rẹ́ àti Àwọn Àgbàlagbà Mìíràn Lè Ṣèrànwọ́

Àwọn ogun, ìfipábáni-lòpọ̀, àti ìfìyàjẹni tí ń kan àwọn èwe gba ìsapá àrà ọ̀tọ̀ níhà àwọn àgbàlagbà tó ń bìkítà fún wọn ní tòótọ́, láti kápá ewu náà. Àwọn èwe tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ búburú bẹ́ẹ̀ kó ìyọnu bá lè má fi bẹ́ẹ̀ dáhùn lọ́nà rere sí àwọn ìsapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́ pàápàá. Ó lè gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá. Ó dájú pé kò bọ́gbọ́n mu, kò sì fi ìfẹ́ hàn, láti fojú kéré wọn tàbí láti pa wọ́n tì. Ǹjẹ́ a lè túbọ̀ fàyè gbà wọ́n nínú ìmọ̀lára tiwa, kí a sì sapá láti fún àwọn tó wà nínú ewu náà ní inúure àti ìfẹ́ tí wọ́n nílò?

Yàtọ̀ sí àwọn òbí, ó yẹ kí àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn alájọbí ní pàtàkì wà lójúfò láti ṣàkíyèsí àwọn ìwà tí ó lè jẹ́ àmì ipò ẹlẹgẹ́ tàbí ti àìwàdéédéé nínú ìmọ̀lára àwọn ọ̀dọ́. (Wo àpótí “Ìrànwọ́ Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ Pọndandan,” ojú ìwé 8.) Bí o bá rí àwọn àmì, múra tán ní kíá láti fọkàn sí i. Bí ó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti gbọ́ tinú àwọn èwe tó ní ìdààmú nípa fífi inúure béèrè ọ̀rọ̀, kí o sì mú kí ó dá wọn lójú pé ojúlówó ọ̀rẹ́ lo ń bá wọn ṣe. Àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí tí a fọkàn tán lè kún àwọn òbí lọ́wọ́ ní bíbójútó àwọn ipò lílekoko; ṣùgbọ́n bó ti wù kí ó rí, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, kí wọ́n má gba ipò àwọn òbí. Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ìtẹ̀sí tí àwọn ọ̀dọ́ ń ní láti pa ara wọn ń jẹ́ ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ tó dé góńgó láti gba àfiyèsí—àfiyèsí láti ọ̀dọ̀ òbí.

Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn dídára jù lọ tí a lè fún àwọn èwe ni ìrètí fífìdímúlẹ̀ gbọn-in fún ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀, ìsúnniṣe kan láti wà láàyè. Ọ̀pọ̀ èwe ti wá mọ bí ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa ètò ayé tuntun kan tí yóò dé láìpẹ́ ti jẹ́ òtítọ́ tó.

Ìdásílẹ̀ Kúrò Nípò Pípa Ara Ẹni

Obìnrin kan tí ó sábà máa ń ronú lórí pípa ara rẹ̀ ní Japan sọ pé: “Mo ti gbìyànjú láìmọye ìgbà láti pa ara mi. Ìgbà tí mo jẹ́ ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ ni ẹnì kan tí mo fọkàn tán bá mi ṣèṣekúṣe. . . . Tẹ́lẹ̀ rí, mo ti kọ ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ tí n kò lè mọye wọn pé, ‘mo fẹ́ kú.’ Mo ti wá di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì ń ṣiṣẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún ní báyìí, àmọ́, mo ṣì ń ní ìsúnniṣe yìí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. . . . Ṣùgbọ́n Jèhófà ti yọ̀ǹda pé kí n máa wà láàyè nìṣó, ó sì jọ pé ó ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ fún mi pé, ‘Máa wà láàyè nìṣó.’”

Ọmọbìnrin ọlọ́dún 15 kan ní Rọ́ṣíà sọ pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí rò pé ẹnikẹ́ni kò nílò mi. Àwọn òbí mi kò ní àkókò láti bá mi sọ̀rọ̀, mo sì ń gbìyànjú láti dá yanjú àwọn ìṣòro mi. N kì í bẹ́gbẹ́ ṣe. Mo máa ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí mi ṣaáwọ̀ léraléra. Èrò pé kí n pa ara mi wá wá sí mi lọ́kàn. Mo láyọ̀ gidigidi láti bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé!”

Láti Ọsirélíà, Cathy, tó lé díẹ̀ ní ọmọ 30 ọdún báyìí, sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí wọ̀nyí, tó fi hàn pé àìnírètí lè yí padà di ìrètí ní gidi, pé: “Mo lálàá léraléra nípa onírúurú ọ̀nà tí mo lè gbà gbẹ̀mí ara mi, mo sì gbìyànjú láti pa ara mi níkẹyìn. Mo fẹ́ fi ayé tó kún fún ìpalára, ìbínú, àti asán yìí sílẹ̀. Ìsoríkọ́ mú kí ó ṣòro fún mi láti bọ́ nínú ‘okùn aláǹtakùn’ tí mo nímọ̀lára pé mo kó sí yìí. Nítorí náà, ó jọ pé pípa ara mi ni ojútùú tó wà nígbà náà.

“Nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ayé di párádísè kan, tí ẹni gbogbo yóò sì ní ìgbésí ayé alálàáfíà àti aláyọ̀, ó wù mí gan-an ni. Ṣùgbọ́n, àlá tí kò lè ṣẹ ló jọ lójú mi. Bí ó ti wù kí ó rí, mo bẹ̀rẹ̀ sí lóye ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwàláàyè àti bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ṣe ṣeyebíye tó lójú rẹ̀, díẹ̀díẹ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ìdánilójú pé ìrètí ọjọ́ iwájú wà. Níkẹyìn, mo rí ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ‘okùn aláǹtakùn’ yẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, kò rọrùn láti jáde nínú rẹ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń soríkọ́, ọkàn mi sì máa ń dààmú gidigidi. Síbẹ̀, pípa ọkàn mi pọ̀ sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run mú kí n lè sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, kí n sì nímọ̀lára ààbò. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún mi.”

Kò Ní Sí Ikú Èwe Mọ́

Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èwe kan lè wá mọ̀ pé ohun kan tó sàn jù wà níwájú—ohun tí Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “ìyè tòótọ́.” Ó gba ọ̀dọ́kùnrin náà, Tímótì, nímọ̀ràn pé: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ . . . ní àṣẹ ìtọ́ni láti . . . má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa; láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, . . . kí wọ́n máa fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tímótì 6:17-19.

Ní àbárèbábọ̀, ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ máa bá àwọn ẹlòmíràn ṣe, kí a máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìrètí fífìdímúlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. “Ìyè tòótọ́” ni Jèhófà ti ṣèlérí pé yóò wà nínú ayé tuntun ti “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” rẹ̀.—2 Pétérù 3:13.

Ọ̀pọ̀ èwe tó ti wà nínú ewu tẹ́lẹ̀ ti wá mọ̀ pé ọ̀nà gígùn tó lọ́ kọ́lọkọ̀lọ, tó jálẹ̀ sí ikú, ni ìjoògùnyó àti ọ̀nà ìgbésí ayé oníṣekúṣe, pípa ara ẹni wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà àbùjá kan ni. Wọ́n ti wá mọ̀ pé ayé yìí, àti àwọn ogun, ìkórìíra, ìwà ìfìyàjẹni, àti àwọn ọ̀nà àìnífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò lọ sópin láìpẹ́. Wọ́n ti mọ̀ pé ètò ayé yìí ti bàjẹ́ kọjá àtúnṣe. Wọ́n gbà gbọ́ dájú ṣáká pé Ìjọba Ọlọ́run ni ìrètí tòótọ́ kan ṣoṣo tó wà, nítorí pé yóò mú ayé tuntun kan wá, níbi tí gbogbo aráyé onígbọràn, títí kan àwọn èwe, kì yóò ní láti kú—èèwọ̀, kódà, wọn kò ní fẹ́ kú mọ́.—Ìṣípayá 21:1-4.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

Ìrànwọ́ Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ Pọndandan

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The American Medical Association Encyclopedia of Medicine sọ pé, “àrùn ọpọlọ ló ń fa èyí tó lé ní ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-⁠ún ìpara-ẹni.” Ó mẹ́nu ba àwọn àrùn ọpọlọ bí ìsoríkọ́ bíburújáì (nǹkan bí ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-⁠ún), ìsínwín (nǹkan bí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-⁠ún), fífi ọtí mímu pàrònú (nǹkan bí ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-⁠ún), ànímọ́ ìhùwà àìbẹ́gbẹ́mu (nǹkan bí ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-⁠ún), àti oríṣi àìṣiṣẹ́ déédéé ọpọlọ kan (ó dín díẹ̀ ní ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-⁠ún). Ó gbani nímọ̀ràn pé: “A gbọ́dọ̀ fọwọ́ dan-⁠indan-⁠in mú gbogbo ìgbìyànjú láti para ẹni. Ìpín 20 sí 30 lára àwọn ènìyàn tí ń gbìyànjú láti pa ara wọn ló tún ń gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ láàárín ọdún kan.” Dókítà Jan Fawcett kọ̀wé pé: “Lára àwọn ènìyàn tí ń pa ara wọn [ní United States], àwọn tí kò dé ọ̀dọ̀ òṣìṣẹ́ ìlera ọpọlọ rí ní ń kó ìpín tó lé ní 50 nínú ọgọ́rùn-⁠ún.” Ìwé mìíràn sọ pé: “Apá tó ṣe pàtàkì jù nínú ìtọ́jú ni pé, kí ẹni náà lọ rí oníṣègùn ọpọlọ kan bí ó bá ti lè yá tó láti ràn án lọ́wọ́, láti borí ìsoríkọ́ tí ń fà á.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́