Gbogbo Èèyàn Ló Ń Fẹ́ Láti Wà Láàyè
YÀTỌ̀ sáwọn àìlera míì tó ń yọ Mary lẹ́nu, ìbànújẹ́ tún dorí ẹ̀ kodò. Àmọ́, ó máa ń túra ká sí gbogbo ẹbí, kì í mutí yó, kì í sì í lo oògùn nílòkulò. Ọ̀ràn Mary fi hàn gbangba pé kò dìgbà tí gbogbo nǹkan tí wọ́n sọ pé ó ń fa gbígbẹ̀mí ara ẹni bá ṣẹlẹ̀ kí ẹnì kan tó gbìdánwò láti pa ara rẹ̀.
Nígbà díẹ̀ sí i, ó jọ pé Mary yóò pẹ̀lú iye àwọn arúgbó tí ń pa ara wọn láìkì í bà á tì. Ó tó ọjọ́ mélòó kan tó fi dákú lọ gbári, láìmira, bó ti wà ní wọ́ọ̀dù ìtọ́jú àkànṣe nínú ilé ìwòsàn tó wà ládùúgbò, ó sì jọ pé ẹ̀mí rẹ̀ ò ní pẹ́ bọ́. John, ọkọ rẹ̀ tí ìpayà ti bá, kì í kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àwọn dókítà fi tó John àtàwọn ẹbí rẹ̀ létí pé Mary lè má yè é, wọ́n sì ní bó bá tiẹ̀ yè é, ó ṣeé ṣe kí ọpọlọ rẹ̀ dà rú pátápátá.
Ojoojúmọ́ ni aládùúgbò kan, tó ń jẹ́ Sally, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ń bẹ Mary wò. Sally sọ pé: “Mo gba ìdílé náà níyànjú láti má jọ̀gọ̀ nù. Bí ìyá mi, tó ní àrùn àtọ̀gbẹ, náà ṣe dákú lọ gbári fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn nìyẹn. Àwọn dókítà sọ fún ìdílé wa pé màmá mi ò lè yè é, àmọ́, ó yè é. Mo máa ń di Mary lọ́wọ́ mú bí mo ti ń bá a sọ̀rọ̀, bí mo ti ṣe fún màámi, ó sì jọ pé ara rẹ̀ ń padà bọ̀ sípò díẹ̀díẹ̀.” Nígbà tó di ọjọ́ kẹta, ara rẹ̀ ti túbọ̀ ń padà bọ̀ sípò dáadáa, ó tiẹ̀ jọ pé Mary ń dá àwọn èèyàn mọ̀, kò kàn lè sọ̀rọ̀ ni.
‘Ṣé Mi Ò Lè Dènà Rẹ̀ Ni?’
Sally sọ pé: “Ńṣe ni John kàn ń di ẹ̀bi ru ara rẹ̀. Gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ni pé ẹ̀bi òun ni gbogbo rẹ̀ pátá.” Báwọn aráalé àwọn tó gbìdánwò láti para wọn tàbí tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ní ti gidi ṣe máa ń ronú nìyẹn. “Mo rán an létí pé Mary ń gbàtọ́jú lọ́wọ́lọ́wọ́ nítorí ìsoríkọ́. Ara Mary tí kò yá ló fa ìsoríkọ́, bí òun John kò ti lè dènà kí àìsàn má ṣe òun náà.”
Ìbéèrè náà, Kí ni ǹ bá ti ṣe láti dènà rẹ̀? sábà máa ń dààmú àwọn tí èèyàn wọn gbẹ̀mí ara ẹ̀. Wíwà lójúfò sí onírúurú àmì àtàwọn ipò míì tó lè mú kéèyàn gbẹ̀mí ara ẹ̀ lè jẹ́ kó ṣeé ṣe láti yẹra fún gbígbìdánwò àtigbẹ̀mí ara ẹni. Àmọ́ bí o ò tiẹ̀ rí àmì wọ̀nyí, rántí pé ìwọ kọ́ lo sọ pé kí ẹnì kan lọ gbẹ̀mí ara rẹ̀. (Gálátíà 6:5) Ó ṣe pàtàkì kéèyàn rántí èyí, àgàgà tí mẹ́ńbà ìdílé tó ń pète àtipara ẹ̀ bá dìídì fẹ́ di ẹ̀bi ru ẹlòmíì. Dókítà Hendin, táa fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú, sọ pé: “Ó yẹ ká rántí pé àwọn tó ń gbìdánwò láti gbẹ̀mí ara wọn máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ káwọn ẹlòmíì lè mọ̀ ọ́n lára, tàbí láti lè gbún ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì ní kẹ́sẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ní sí láyé mọ́ láti rí i bóyá ète àwọn kẹ́sẹ járí tàbí kò kẹ́sẹ járí.”
Dókítà Hendin ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ní tàwọn àgbàlagbà tó ń pète àtigbẹ̀mí ara wọn, àwọn ọmọ wọn tó ti tójúúbọ́, àwọn ọmọ ìyá wọn, ọkọ tàbí aya wọn ni wọ́n fẹ́ kó mọ̀ ọ́n lára, tàbí ni wọ́n fẹ́ láti darí, tàbí ni wọ́n fẹ́ sọ ọ́ di túláàsí fún láti túbọ̀ máa tọ́jú àwọn. Kò sí béèyàn ṣe lè tẹ́ irú èèyàn bẹ́ẹ̀ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ rèé téèyàn ò bá tẹ́ wọn lọ́rùn, ọ̀ràn ni, nítorí wọn ò ní gbà, nígbà tí wọ́n bá sì kọ́kọ́ ń fi dánra wò díẹ̀díẹ̀, eré làwọn èèyàn máa pè é, àmọ́ nígbà tó bá yá, á wá kúrò lọ́ràn eré.”
Àwọn mẹ́ńbà ìdílé tó bá bá ara wọn nínú ipò wọ̀nyí lè fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́hùn, kí wọ́n sì máa rò pé ọ̀ràn náà le ju ẹ̀mí àwọn lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, má gbàgbé pé Jèhófà Ọlọ́run yóò jí òkú dìde, àti pé àwọn èèyàn wa tó tìtorí ìsoríkọ́ tàbí àrùn ọpọlọ tàbí àìnírètí gbẹ̀mí ara wọn lè wà lára àwọn tí yóò rí àjíǹde.—Wo “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ipara Ẹni—Ajinde Nkọ?” nínú Jí!, March 8, 1991, ojú ìwé 22 àti 23.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àwíjàre fún pípa ara ẹni, ó tuni nínú láti rántí pé ọjọ́ ọ̀la àwọn èèyàn wa ńbẹ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ọba arínúróde tó mọ̀ pé àìlera àti àìpé ẹ̀dá lè sún èèyàn gbẹ̀mí ara ẹ̀ . Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ ga lọ́lá sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí yíyọ oòrùn ti jìnnà réré sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ìrélànàkọjá wa jìnnà réré sí wa. Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.”—Sáàmù 103:11-14.
Àtúbọ̀tán Rere
Ọjọ́ méjì gbáko ni Mary fi wà ní ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan sàréè, àmọ́ ó rù ú là. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ojú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wálẹ̀, John sì gbé e lọ sílé, ṣùgbọ́n kó tó gbé e lọ, ó ti fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo oògùn mọ́nú kọ́bọ́ọ̀dù. Mary ń gbàtọ́jú déédéé báyìí lọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ afẹ́dàáfẹ́re tó ń tọ́jú àwọn alárùn ọpọlọ, ó sì lóun ò lè ṣàlàyé, kódà ó lóun ò rántí ìròkúrò tó sún òun ṣe ohun tó kù ṣín-ń-ṣín kó gbẹ̀mí òun.
Nísinsìnyí, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni Sally, tí í ṣe aládùúgbò John àti Mary, ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ látinú Bíbélì pé láìpẹ́ láìjìnnà, Ọlọ́run yóò yanjú àwọn ìṣòro títakókó wọ̀nyí, tó dà bíi pé kò lè níyanjú láé, pàápàá lójú àwọn arúgbó. Sally ṣàlàyé pé: “Àmọ́ ṣá o, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan kò lè tán gbogbo ìṣòro o. O gbọ́dọ̀ mú un dá ara rẹ lójú látinú Ìwé Mímọ́ pé òótọ́ ni ìlérí wọ̀nyí, o sì gbọ́dọ̀ fi ohun tóo ń kọ́ sílò. Ṣùgbọ́n mo lè sọ wàyí pé John àti Mary ti ní ìrètí tòótọ́ fún ọjọ́ ọ̀la.”
Bí ọjọ́ ọ̀la rẹ bá pòkúdu, tóo sì fẹ́ ní ìrètí tòótọ́, èé ṣe tí o ò kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Jẹ́ kí wọ́n mú un dá ẹ lójú, bí wọ́n ti mú un dá John àti Mary lójú, pé kò sí ìṣòro tí Ọlọ́run ò lè yanjú, yóò sì yanjú gbogbo ẹ̀ láìpẹ́ sígbà táa wà yìí. Bó ti wù kí nǹkan burú tó lójú wa nísinsìnyí, ojútùú ń bẹ. Dákun, jẹ́ ká jọ ṣàgbéyẹ̀wò ìrètí dídájú fún ọjọ́ ọ̀la, èyí tó ti fún ọ̀pọ̀ èèyàn ní àkọ̀tun ìfẹ́ láti wà láàyè.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn Ipò Tó Lè Fà Á, Àtàwọn Àmì Àfiyèsí
“Àwọn ipò tó lè mú káwọn àgbàlagbà gbẹ̀mí ara wọn yàtọ̀ sáwọn ipò tó lè fà á láàárín àwọn ọ̀dọ́,” ohun tí ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association wí nìyẹn. Àwọn ipò tó lè fà á wé mọ́ “mímutí lámujù àti ìsoríkọ́, gbígbìyànjú àwọn ọ̀nà tó burú jù láti fi gbẹ̀mí ara ẹni, àti fífẹ́ láti nìkan wà. Ní àfikún, àwọn àgbàlagbà . . . ni àìsàn máa ń ṣe jù, àwọn ló sì máa ń ronú jù.” Ìwé náà Suicide, látọwọ́ Stephen Flanders, ló to àwọn ipò tó wà nísàlẹ̀ yìí tó lè fa gbígbẹ̀mí ara ẹni, gbogbo rẹ̀ ló ń béèrè àfiyèsí.
Akọ ìsoríkọ́:
“Àwọn olùwádìí ròyìn pé ìdajì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn tó ń pa ara wọn ni akọ ìsoríkọ́ ti ń bá fínra látọjọ́ pípẹ́.”
Àìnírètí:
Nínú àwọn ìwádìí kan, àwọn tí kò dà bíi pé wọ́n sorí kọ́ pàápàá lè máa pète àtipa ara wọn bí wọn kò bá ní ìrètí kankan fún ọjọ́ ọ̀la.
Ìmutípara àti ìjoògùnyó:
“Wọ́n ṣírò rẹ̀ pé nǹkan bí ìpín méje sí mọ́kànlélógún nínú ọgọ́rùn-ún [lára àwọn ọ̀mùtípara] ló ń para wọn, ní ìfiwéra pẹ̀lú iye tó dín sí ìpín kan àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò.”
Tó bá ṣẹlẹ̀ sí aráalé ẹni:
“Àwọn ìwádìí ti fi hàn pé bí ẹnì kan bá para rẹ̀ nínú ìdílé kan, ewu ńlá ń bẹ pé àwọn míì nínú ìdílé yẹn lè para wọn.”
Àìsàn:
“Ẹ̀rù dídi hẹ́gẹhẹ̀gẹ, tí yóò mú kí wọ́n gbé olúwarẹ̀ lọ sílé ìtọ́jú àwọn arúgbó, tó láti mú káwọn arúgbó kan bẹ̀rẹ̀ sí ronú àtipa ara wọn.”
Àdánù:
“Àdánù náà lè pọ̀, ó lè jẹ́ ọkọ tàbí aya ẹni tàbí ọ̀rẹ́ ló kú, ó sì lè jẹ́ iṣẹ́ ló bọ́ lọ́wọ́ ẹni, tàbí kó jẹ́ pé ara ò ṣe ṣámúṣámú mọ́. Ó sì lè jẹ́ àdánù tí kò ṣeé fojú rí. Àpẹẹrẹ irú rẹ̀ ni kéèyàn pàdánù iyì ẹni, ipò, tàbí ìfọ̀kànbalẹ̀.”
Ní àfikún sáwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwé Flander to àwọn àmì àfiyèsí tó tẹ̀ lé e yìí tá ò gbọ́dọ̀ fojú kékeré wò.
Ìgbìyànjú látẹ̀yìnwá láti para ẹni:
“Èyí ni olórí àmì pé ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan gbẹ̀mí ara ẹ̀.”
Sísọ̀rọ̀ nípa gbígbẹ̀mí ara ẹni:
“Àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘Wọ́n á tiẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ wàhálà mi’ tàbí ‘Tí mo bá kú, wọ́n á tiẹ̀ lálàáfíà’ fi hàn pé kì í ṣe ọ̀ràn eré rárá.”
Àwọn ètò àṣekágbá:
“Irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ kan ṣíṣe ìwé ìhágún, fífi àwọn ohun ìní tó ṣeyebíye tọrẹ, àti ṣíṣètò ibi táwọn ẹran ọ̀sìn yóò wà.”
yípadà nínú ìhùwàsí tàbí ìṣesí:
Nígbà tí èyí bá “jẹ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé òun ò kúkú wúlò mọ́ tàbí pé kò sóhun tóun tún ń ṣe mọ́ láyé,” ó lè jẹ́ “àmì akọ ìsoríkọ́ tó lè yọrí sí ṣíṣekú pa ara ẹni.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn tí ọkọ tàbí aya wọ́n gbẹ̀mí ara ẹ̀ máa ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti lè forí tì í