ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 3/8 ojú ìwé 17-18
  • Gbígbẹ̀mí Ara Ẹni—Ìṣòro Ńlá Tó Ń Yọ́ Kẹ́lẹ́ Ṣọṣẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbígbẹ̀mí Ara Ẹni—Ìṣòro Ńlá Tó Ń Yọ́ Kẹ́lẹ́ Ṣọṣẹ́
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Àkọsílẹ̀ Fi Hàn
  • Wọn Kì Í Bà Á Tì
  • Pípa Ara Ẹni—Ìṣòro Wíwọ́pọ̀ Láàárín Àwọn Ọ̀dọ́
    Jí!—1998
  • Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Jí!—2001
  • Ohun Tó Ń mú Káyé Sú Àwọn Èèyàn Kan
    Jí!—2001
  • Gbogbo Èèyàn Ló Ń Fẹ́ Láti Wà Láàyè
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 3/8 ojú ìwé 17-18

Gbígbẹ̀mí Ara Ẹni—Ìṣòro Ńlá Tó Ń Yọ́ Kẹ́lẹ́ Ṣọṣẹ́

JOHN ÀTI MARYa ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́ta ọdún, wọ́n sì ń gbé inú ilé mọ́ńbé kan ní ìgbèríko kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àìsàn ara wíwú àti àìṣiṣẹ́ déédéé ọkàn-àyà ti sọ John di òkú òòró. Mary kò mọ nǹkan táyé òun yóò dà láìsí John, ojú ẹ̀ ò sì gbà á bó ṣe ń rí i tí John túbọ̀ ń di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, tó ń mí hẹ̀rẹ̀huru. Mary alára ò gbádùn lọ títí, fún ọ̀pọ̀ ọdún báyìí ló ti ń sorí kọ́. Àmọ́ ńṣe làyà John pàápàá ń já lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí nítorí pé Mary ń sọ pé òun fẹ́ para òun. Ìsoríkọ́ yẹn àti gbogbo oògùn tó ń kó mì ni kò jẹ́ kó lè ronú dáadáa mọ́. Mary lóun ò rò pé òun á lè dá ayé yìí gbé.

Gbogbo ilé wọn ló kún fún oògùn—àwọn oògùn tí wọ́n fi ń wo àrùn ọkàn-àyà, èyí tí ń pẹ̀rọ̀ sí ìdààmú ọkàn, kódà wọ́n ní àwọn egbòogi amárarọni. Ní kùtù hàì àárọ̀ ọjọ́ kan, ṣe ni Mary gbọ̀nà ilé ìdáná lọ, tó bẹ̀rẹ̀ sí kóògùn mì. Ẹnu ẹ̀ ló wà tí John fi wá bá a níbẹ̀, tó sì gba gbogbo oògùn náà lọ́wọ́ ẹ̀. Nígbà tó rí i pé Mary dákú, kíá ló figbe ta, tó ní káwọn ará àdúgbò gba òun. Bẹ́ẹ̀ náà ló ń fọkàn gbàdúrà pé kí ó máà tíì bọ́ sórí.

Ohun Tí Àkọsílẹ̀ Fi Hàn

Àwọn èèyàn ti kọ̀wé rẹpẹtẹ lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó ń gbẹ̀mí ara wọn—ó sì yẹ fún àfiyèsí lóòótọ́, àbí kí ni ká ti gbọ́ pé ọ̀dọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ayé ẹ̀, tí kò síkú lójú ẹ̀, ṣàdédé dá ẹ̀mí ara rẹ̀ légbodò? Àmọ́, nǹkan kan wà táwọn àkọlé ìròyìn ń gbójú fò dá o, ìyẹn ni pé, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣe làwọn arúgbó náà ń gbẹ̀mí ara wọn lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ. Òótọ́ lọ̀rọ̀ táà ń sọ yìí o, yálà iye àwọn tí ń fọwọ́ ara wọn pa ara wọn lórílẹ̀-èdè kan pọ̀ àbí wọn ò pọ̀, ẹ̀yin náà ẹ wo àpótí tó wà ní ojú ìwé tó ṣaájú èyí. Ìṣirò tẹ́ẹ ń wò yẹn tún fi hàn pé kò síbi tí ìṣòro ńlá tó ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́ yìí ò sí láyé.

Lọ́dún 1996, Àwọn Ibùdó fún Ìkáwọ́ Àrùn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ròyìn pé látọdún 1980, ṣe ni iye àwọn ará Amẹ́ríkà tọ́jọ́ orí wọ́n bẹ̀rẹ̀ látọdún márùnlélọ́gọ́ta sókè, tí wọ́n ń gbẹ̀mí ara wọn fi ìpín mẹ́rìndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. Ara ohun tó fà á tó fi ròkè báyìí ni pé ńṣe làwọn arúgbó ń pọ̀ sí i ní Amẹ́ríkà—àmọ́ èyí nìkan kọ́ nìdí abájọ. Lọ́dún 1996, ńṣe ni iye àwọn tó ti lé lẹ́ni ọdún márùnlélọ́gọ́ta tó gbẹ̀mí ara wọn fi ìpín mẹ́sàn-án nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i, èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tó ga tó bẹ́ẹ̀ láàárín ogójì ọdún. Lára gbogbo àwọn tí jàǹbá pa, kìkì ṣíṣubú àti jàǹbá ọkọ̀ nìkan ló ń pa àwọn arúgbó ará Amẹ́ríkà ju èyí tí ìgbẹ̀mí ara ẹni ń pa. Ó tiẹ̀ jọ pé iye jaburata tí wọ́n ṣírò sílẹ̀ yìí ṣì kéré síye tó jẹ́ gan-an. Ìwé A Handbook for the Study of Suicide sọ pé: “Ó jọ pé iye àwọn èèyàn táa ṣírò pé wọ́n ń fọwọ́ ara wọn pa ara wọn kéré jọjọ sí iye tó jẹ́ gan-an.” Ìwé náà fi kún un pé àwọn kan fojú bù ú pé bí wọ́n bá ṣírò rẹ̀ dáadáa, yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì iye tí wọ́n pè é.

Kí ló wá yọrí sí? Báwọn àgbààgbà ṣe ń fọwọ́ ara wọn pa ara wọn láwọn orílẹ̀-èdè yòókù kárí ayé ni ìṣòro ńlá tí ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́ yìí ń jà ràn-ìn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà pẹ̀lú. Dókítà Herbert Hendin, tó jẹ́ ògbógi nípa ọ̀ràn yìí, sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn tó ń gbẹ̀mí ara wọn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ń fojoojúmọ́ ayé pọ̀ sí i, tó sì jẹ́ àwọn arúgbó ló ń gbẹ̀mí ara wọn jù, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí ohun burúkú yìí tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn àgbàlagbà.” Èrèdí rẹ̀? Ó ní lójú tòun, ara nǹkan tó fà á ni pé, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé iye àwọn arúgbó tó ń fọwọ́ ara wọn pa ara wọn ò fẹ̀ẹ̀kan lọọlẹ̀ rí, “àwọn èèyàn ò kà á sí nǹkan bàbàrà mọ́, ikú àfọwọ́fà tó ń lé kenkà láàárín àwọn ọ̀dọ́ nìkan ló ń ká wọn lára.”

Wọn Kì Í Bà Á Tì

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣirò wọ̀nyí ń dáyà jáni lóòótọ́, iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nìkan ló lè sọ. Ìṣirò ò lè sọ nǹkan kan nípa ìmí ẹ̀dùn dídá wà láìsí olólùfẹ́ ẹni, ìbànújẹ́ tó ń wá látinú àìlèdádúró, àròdùn tí àrùn tí ò lọ bọ̀rọ̀ ń fà, rádaràda tí akọ ìsoríkọ́ ń sọ ayé ẹni dà, àti béèyàn ṣe máa ń ro ara rẹ̀ pin nígbà tí wọ́n bá sọ fún un pé àìsàn rẹ̀ ò gbóògùn. Kókó kan tó ń bani nínú jẹ́ ni pé, nígbà tó jẹ́ pé ìṣòro tí kò tó nǹkan lè jẹ́ kí ọ̀dọ́ fẹ́ kù gìrì gbẹ̀mí ara ẹ̀, tàwọn àgbà yàtọ̀, tiwọn sábà máa ń jẹ́ nítorí àwọn ìṣòro kongbári tí kò níyanjú. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé láìdàbí àwọn ọ̀dọ́, àwọn àgbà á ti ro ara wọn pin kí wọ́n tó gbẹ̀mí ara wọn, wọn kì í sì í bà á tì.

Dókítà Hendin sọ nínú ìwé rẹ̀, Suicide in America, pé: “Òótọ́ ni pé gbígbẹ̀mí ara ẹni wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn àgbàlagbà, àmọ́ ó tún yẹ ká kíyè sí i pé iye àwọn tó ń gbẹ̀mí ara wọn ní ti gidi jìnnà síra fíìfíì láàárín àwọn àgbà àti ọ̀dọ́. Ohun táa ń sọ ni pé, ìfiwéra iye àwọn tó gbìdánwò láti fọwọ́ ara wọn pa ara wọn àtàwọn tó para wọn ní ti gidi yàtọ̀ gan-an láàárín àwọn àgbàlagbà. Bí a bá wò ó ní gbogbo gbòò, nínú iye èèyàn mẹ́wàá tó ń gbìdánwò láti pa ara wọn, èèyàn kan ṣoṣo ló ń ṣeé ṣe fún láti pa ara rẹ̀; a ṣírò rẹ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ (ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́rìnlélógún) pé, nínú ọgọ́rùn-ún wọ́n tó ń gbìdánwò láti pa ara wọn, ẹnì kan ṣoṣo ló ń ṣeé ṣe fún láti pa ara rẹ̀; àmọ́ láàárín àwọn tó ti lé lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́ta, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tó pète àtipara wọn ni wọ́n gbẹ̀mí ara wọn ní ti gidi.”

Ọ̀ràn ńlá rèé o! Ọ̀ràn ìbànújẹ́ gbáà mà ni kéèyàn darúgbó, kára di hégẹhẹ̀gẹ, kéèyàn sì wá ya olókùnrùn kalẹ̀! Abájọ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ń gbẹ̀mí ara wọn. Àmọ́, ìdí gúnmọ́ wà tó fi yẹ kéèyàn fojú pàtàkì wo ìwàláàyè—kódà nígbà tí nǹkan ò bá rọgbọ pàápàá. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mary táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ wọ̀nyí padà.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 17]

Iye Àwọn Tí Ń Gbẹ̀mí Ara Wọn Láàárín Ọ̀kẹ́ Márùn-ún [100,000] Èèyàn, A Gbé E Ka Ọjọ́ Orí àti Ẹ̀yà Takọtabo

Ẹni Ọdún 15 sí 24 Ẹni Ọdún 75 Sókè

Ọkùnrin/Obìnrin Orílẹ̀-Èdè Ọkùnrin/Obìnrin

8.0 / 2.5 Ajẹntínà 55.4 / 8.3

4.0 / 0.8 Gíríìsì 17.4 / 1.6

19.2 / 3.8 Hungary 168.9 /60.0

10.1 / 4.4 Japan 51.8 /37.0

7.6 / 2.0 Mexico 18.8 / 1.0

53.7 / 9.8 Rọ́ṣíà 93.9 /34.8

23.4 / 3.7 Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà 50.7 / 5.6

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́