ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 9/8 ojú ìwé 11
  • Àpọ̀jù Ìpolówó Ọjà Kò Jẹ́ Ká Lè Ṣèpinnu Tí Ó Tọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpọ̀jù Ìpolówó Ọjà Kò Jẹ́ Ká Lè Ṣèpinnu Tí Ó Tọ́
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọgbọ́n Ìyíniléròpadà
    Jí!—1998
  • Agbára Tí Ìpolówó Ọjà Ní
    Jí!—1998
  • Tẹlifíṣọ̀n “Olùkọ́ Tó Ń kọ́ Wa Láìmọ̀”
    Jí!—2006
  • Ọgọ́rùn-ún Ọdún Rèé Tá A Ti Ń Polongo Ìjọba Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Jí!—1998
g98 9/8 ojú ìwé 11

Àpọ̀jù Ìpolówó Ọjà Kò Jẹ́ Ká Lè Ṣèpinnu Tí Ó Tọ́

“BÀBÁ, kí ni ó yẹ kí òṣùpá polówó?” Ìbéèrè ṣíṣàjèjì yìí, tí ọmọdé kan béèrè, yọ nínú ewì kan tí Carl Sandburg kọ ní nǹkan bí 50 ọdún sẹ́yìn. Lọ́jọ́ iwájú, irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣàjèjì. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ṣe sọ, àwọn ọ̀gá méjì nínú iṣẹ́ ìpolówó ọjà ní London ń ṣiṣẹ́ lórí ètò lílo ìtànṣán oòrùn láti gbé àwọn ìpolówó ọjà yọ lójú òṣùpá.

Ro fífi òṣùpá ṣe pátákó ìpolówó ọjà wò! Ronú nípa pípolówó ọjà fún gbogbo àgbáyé, ìsọfúnni tí àwọn tí ń wò ó kò lè sé pa, tí wọn kò lè dá dúró, tí wọn kò lè jù sínú apẹ̀rẹ̀ ìdàdọ̀tísí, tàbí kí wọ́n fi èlò ìdarí ẹ̀rọ mú ohùn rẹ̀. Èrò náà lè ṣàìdùn mọ́ ọ nínú, àmọ́ yóò jẹ́ àlá tó wá ṣẹ fún àwọn kan.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpolówó ọjà kò tí ì dé ojú òṣùpá, ó ti bo gbogbo ayé mọ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìwé ìròyìn ilẹ̀ Amẹ́ríkà ń fi ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn àyè ojú ìwé ìròyìn wọn sílẹ̀ fún ìpolówó ọjà. Ìwé ìròyìn The New York Times ti ọjọ́ Sunday nìkan lè ní tó 350 ojú ìwé ìpolówó ọjà. Àwọn ilé iṣẹ́ rédíò kan ń ya 40 ìṣẹ́jú sọ́tọ̀ láàárín wákàtí kọ̀ọ̀kan fún ìpolówó ọjà.

Tẹlifísọ̀n tún wà níbẹ̀. Bí ìdíyelé kan ṣe fi hàn, àwọn èwe ilẹ̀ Amẹ́ríkà máa ń fi wákàtí mẹ́ta wo ìpolówó ọjà lórí tẹlifíṣọ̀n lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá fi máa kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, wọn óò ti wo 360,000 ìpolówó ọjà orí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn tẹlifísọ̀n máa ń polówó ọjà ní àwọn pápákọ̀ òfuurufú, iyàrá ìjókòó-de-dókítà, àti ilé ẹ̀kọ́.

Àwọn àkókò eré ìdíje pàtàkì ti wá di pàtàkì nínú ìpolówó ọjà. Wọ́n ń fi ara àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí a fi ń sáré ìje ṣe pátákó ìpolówó ọjà. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú owó tí àwọn eléré ìje kan ń rí ń wá láti ọ̀dọ̀ àwọn olùpolówó ọjà. Akíkanjú agbábọ́ọ̀lù orí kọnkéré kan ń gba 3.9 mílíọ̀nù dọ́là nídìí eré tí ó ń ṣe náà. Àwọn olùpolówó ọjà san ìlọ́po mẹ́sàn-án iye náà fún un kí ó lè bá wọn gbé ọjà wọn lárugẹ.

A kò lè sá fún ìpolówó ọjà. A ń rí àwọn ìpolówó ọjà lára ògiri, ọkọ̀ èrò, àti ọkọ̀ akẹ́rù. Wọ́n wà nínú àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ akérò àti àwọn ọkọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀—kódà lára àwọn ilẹ̀kùn ilé ìyàgbẹ́ gbogbo gbòò. A ń gbọ́ ìpolówó ọjà lórí ẹ̀rọ gbohùngbohùn ní àwọn ilé ìtajà ńláńlá, ṣọ́ọ̀bù ìtajà, ẹ̀rọ agbéniròkè—nígbà tí a bá gbé tẹlifóònù sétí, tí a ń retí àtibá ẹnì kan sọ̀rọ̀. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ìpolówó ọjà tí ń dé sínú àpótí ìfìwéráńṣẹ́ pọ̀ gan-an débi tí ọ̀pọ̀ àwọn tí ń rí wọn nínú àpótí ìfìwéráńṣẹ́ wọn yóò tibẹ̀ lọ sídìí apẹ̀rẹ̀ ìdàdọ̀tísí tí ó sún mọ́ ìtòsí láti dà wọ́n nù.

Bí ìwé Insider’s Report, tí McCann-Erickson, ilé iṣẹ́ ìpolówó ọjà kárí ayé kan, ṣe sọ, iye owó tí a fojú díwọ̀n pé a ná lórí ìpolówó ọjà jákèjádò ayé ní 1990 jẹ́ 275.5 bílíọ̀nù dọ́là. Láti ìgbà yẹn wá, iye náà ti lọ sókè sí 411.6 bílíọ̀nù dọ́là ní 1997, a sì fojú díwọ̀n pé yóò tó 434.4 bílíọ̀nù dọ́là ní 1998. Kì í ṣe owó kékeré!

Ipa wo ni gbogbo èyí ń ní? Alálàyé kan sọ báyìí pé: “Ìpolówó ọjà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ipá tí ó lágbára jù lọ, tí ń múni bá àwùjọ mu. . . . Ìpolówó ọjà máa ń tà ju ọjà fúnra rẹ̀ lọ. Wọ́n ń súnni gbà gbọ́ nínú èròǹgbà, ìdíyelé, góńgó, èrò nípa ẹni tí a jẹ́ àti irú ẹni tí ó yẹ kí a jẹ́ . . . Wọ́n ń darí ìrònú wa, ìrònú wa ló sì ń darí bí a ṣe ń hùwà.”

Níwọ̀n bí a kò ti lè sá fún ìpolówó ọjà, o kò ṣe wádìí bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ àti bí ó ṣe lè ní ipa lórí rẹ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́