Agbára Tí Ìpolówó Ọjà Ní
LÁYÉ ìgbà kan, tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìpolówó ọjà lórí tẹlifíṣọ̀n, wọ́n máa ń sọ pé, “Wàyí o, ẹ jẹ́ kí a gbọ́ ọ̀rọ̀ díẹ̀ láti ẹnu àwọn onígbọ̀wọ́ wa.” Àwọn onígbọ̀wọ́ ni àwọn ilé iṣẹ́ tí ń sanwó kí a bàa lè polówó ọjà wọn. Níwọ̀n bí “ọ̀rọ̀ díẹ̀ láti ẹnu àwọn onígbọ̀wọ́ wa” ti wá di ọ̀rọ̀ púpọ̀ jaburata, àwọn onígbọ̀wọ́ ṣì ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn àti ìnàjú—tẹlifíṣọ̀n, onírúurú ìwé ìròyìn, àti rédíò. Nítorí èyí, àwọn onígbọ̀wọ́ ń gbìyànjú láti lo agbára lórí ohun tí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ń gbé jáde àti èyí tí wọn kò gbé jáde.
Láti ṣàkàwé rẹ̀: Ní 1993, ilé iṣẹ́ kan tí ń ṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ìgbafẹ́ ní Germany kọ̀wé sí 30 ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn, ó sì pàṣẹ fún wọn pé, wọ́n gbọ́dọ̀ gbé ìpolówó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àwọn jáde “kìkì ní ibi tí ó tọ́ nínú ìwé ìròyìn wọn.” Lẹ́tà náà ṣàlàyé pé, àwọn ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn náà tí ó bá ní ìpolówó ọjà àwọn nínú kò gbọ́dọ̀ gbé ìròyìn kankan tí ó bá ṣe ọ̀fíntótó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àwọn, àwọn ohun tí a ṣe ní Germany, tàbí ilẹ̀ Germany fúnra rẹ̀. Lóòótọ́, kò yani lẹ́nu pé ilé iṣẹ́ yìí, tí ó ná mílíọ̀nù 15 dọ́là sórí ìpolówó ọjà nínú ìwé ìròyìn, yóò retí “ibi tí ó tọ́ nínú ìwé ìròyìn.”
Ko yani lẹ́nu bákan náà nígbà tí àwọn ìwé ìròyìn tí ń polówó àwọn aṣọ ìyàwó tuntun kò gbà láti polówó àwọn aṣọ ìyàwó tí a ti lò rí tàbí tí àwọn ìwé ìròyìn tí wọ́n to orúkọ àwọn alágbàtà dúkìá ilé àti ilẹ̀ kò fi sọ bí o ṣe lè ra ilé láìrí ọ̀kan. Bákan náà, kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu nígbà tí ilé iṣẹ́ ìròyìn tí ń polówó sìgá tàbí tẹ́tẹ́ oríire kò sọ ohunkóhun tí ó lòdì nípa sìgá mímu tàbí tẹ́tẹ́ títa.
Ohun Tí Àwọn Aláràlò Gbà Gbọ́
Nítorí náà, agbára tí ìpolówó ọjà ní kò mọ sórí ọjà títà. Ó ń gbé ọ̀nà ìgbésí ayé aláràlò kan lárugẹ, èrò àwọn ènìyàn tí ó dá lórí ọrọ̀ àlùmọ́nì kárí ayé.
Ṣe nǹkan kan wà tí kò dára nínú ìyẹn ni? Ó sinmi lórí ẹni tí o bá bi léèrè. Àwọn olùpolówó ọjà ń ronú pé àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí ríra nǹkan, kí wọ́n sì ní nǹkan; ìpolówó ọjà ń ṣiṣẹ́ fún ire wọn. Ní àfikún sí i, wọ́n sọ pé, ìpolówó ọjà ń mú kí iṣẹ́ wà, ó ń ṣonígbọ̀wọ́ eré ìdíje àti iṣẹ́ ọnà, ó ń ṣèrànwọ́ láti mú kí wọ́n báni gbé ìròyìn tí apá ẹni ká jáde, ó ń fún ìdíje níṣìírí, ó ń mú kí ọjà tí a ń ṣe jáde sunwọ̀n sí i, kì í jẹ́ kí ọjà gbówó lórí, ó sì ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn lè ṣàṣàyàn èyí tí wọn yóò rà nínú àwọn ọjà tí wọ́n ti gbọ́ nípa rẹ̀.
Àwọn mìíràn sọ pé ìpolówó ọjà kì í jẹ́ kí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀, kì í sì í jẹ́ kí ohun tí wọ́n ní tẹ́ wọn lọ́rùn. Ó ń mú wọn ronú nípa àwọn ìfẹ́-ọkàn wọn láìdábọ̀. Olùwádìí náà, Alan Durning, kọ̀wé pé: “Bí ti sànmánì wa, àwọn ìpolówó ọjà máa ń yára yí padà, wọ́n kún fún ìgbésí ayé aláfẹ́, wọ́n kún fún àwọn àwòfiṣàpẹẹrẹ, wọ́n ń tẹ̀ lé àṣà ìṣoge tó lòde; wọ́n ń fògo fún ènìyàn, wọ́n ń sọ níní nǹkan di ọ̀nà sí àṣeyọrí ẹni, wọ́n sì ń fìdí ìlọsíwájú ìmọ̀ ẹ̀rọ múlẹ̀ bí ipá tí ń pinnu àṣeyọrí.”
Agbára Tí Ó Ní Lórí Rẹ
Ǹjẹ́ ìpolówó ọjà ń pinnu irú ẹni tí a jẹ́ àti àwọn ohun tí a fẹ́? Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, bóyá ìdarí yẹn pọ̀ tàbí ó kéré sinmi lórí àwọn ìdarí mìíràn.
Bí a bá fi àwọn ìlànà àti ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé Bíbélì ṣe atọ́nà wa, a óò mọ̀ pé kò sí ohun tí ó burú nínú níní àwọn ohun àlùmọ́nì. Ó ṣe tán, Ọlọ́run fi ọrọ̀ jíǹkí Ábúráhámù, Jóòbù, Sólómọ́nì, àti àwọn mìíràn.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí a bá ń fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò, a óò yẹra fún àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn tí àwọn tí ń wá àṣeyọrí àti ayọ̀ nínú wíwá ohun àlùmọ́nì kiri láìdábọ̀ ń ní. Bíbélì kò ní kí a “Fi ọjà rírà pa ara wa.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wí fún wa pé:
Gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.”—1 Tímótì 6:17.
Ní ìtẹ́lọ́rùn. “A kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tímótì 6:7, 8.
Jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà. “Mo ní ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, èyíinì ni, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere.”—1 Tímótì 2:9, 10.
Mọ̀ pé ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju ọrọ̀ lọ. “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó ti wá ọgbọ́n rí, àti ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀, nítorí níní in gẹ́gẹ́ bí èrè sàn ju níní fàdákà gẹ́gẹ́ bí èrè, níní in gẹ́gẹ́ bí èso sì sàn ju níní wúrà pàápàá. Ó ṣe iyebíye ju iyùn, a kò sì lè mú gbogbo àwọn nǹkan mìíràn tí í ṣe inú dídùn rẹ bá a dọ́gba. Ọjọ́ gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ọrọ̀ àti ògo sì ń bẹ ní ọwọ́ òsì rẹ̀. Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀nà adùn, gbogbo òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ àlàáfíà. Ó jẹ́ igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin ni a ó pè ní aláyọ̀.”—Òwe 3:13-18.
Fi fífúnni ṣèwàhù. “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Ẹnì kan lè sọ pé, ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí pàápàá jẹ́ oríṣi ìpolówó ọjà kan, èyí tí “ń gbé” èrò pé a kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ìjẹ́pàtàkì ti ọrọ̀ àlùmọ́nì rọ́ àwọn ìjẹ́pàtàkì tẹ̀mí sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Kò síyè méjì pé ìwọ yóò gbà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yẹn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
Kíkéde Ìjọba Ọlọ́run
Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà tí ó dára jù lọ tí a lè gbà mú ìsọfúnni tí ń yíni lérò padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn? Ìwé náà, Advertising: Principles and Practice, sọ pé: “Lábẹ́ ipò yíyẹ, olúkúlùkù àwọn tí ń ṣe nǹkan jáde yóò lè bá olúkúlùkù aláràlò sọ̀rọ̀ lójúkojú nípa ohun tí wọ́n ń ṣe jáde tàbí iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ tí wọ́n ń gba owó lé lórí.” Àwọn Kristẹni tòótọ́ ti ń yọ̀ǹda ara wọn láti polongo Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà yìí fún ohun tí ó ti tó 2,000 ọdún. (Mátíù 24:14; Ìṣe 20:20) Kí ló dé tí àwọn oníṣòwò púpọ̀ sí i kì í lo ọ̀nà tí a ń gbà bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ yìí? Ìwé náà ṣàlàyé pé: “Ó wọ́n gan-an. Owó tí àwọn ọlọ́jà ń san lórí ìbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ń ṣe lè ju 150 dọ́là lọ.” Síbẹ̀, àwọn Kristẹni ń yọ̀ǹda ara wọn láti “kéde” Ìjọba Ọlọ́run. Ó jẹ́ apá kan ìjọsìn wọn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Bíbélì kò ní kí a “Fi ọjà rírà pa ara wa”