ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 6/1 ojú ìwé 19-22
  • Ki Ni Ó Beere fun Lati Mú Ọ Layọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ki Ni Ó Beere fun Lati Mú Ọ Layọ?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Alainitẹẹlọrun Olufẹẹ Fadaka
  • A Le Ri Ayọ Ṣugbọn Bawo?
  • Dídá Awọn Aini Tẹmi Mọ̀
  • Gbigbẹkẹle Jehofa
  • Titẹwọgba Ibawi Atọrunwa
  • Jíjẹ́ Ẹni ti Ó Mọ́ ati Olufẹ Alaafia
  • Fifi Ifarada Hàn
  • Riri Ayọ Nisinsinyi ati Titilae
  • Ayọ Tootọ Ninu Ṣiṣiṣẹsin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Bí A Ṣe Lè Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Aláyọ̀ Ni Àwọn Tó Ń Sin “Ọlọ́run Aláyọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ọrọ̀ Ha Lè Mú Ọ Láyọ̀ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 6/1 ojú ìwé 19-22

Ki Ni Ó Beere fun Lati Mú Ọ Layọ?

AWỌN oṣelu ti awọn eniyan dìbò yànsípò a maa sọ ọ́ di ẹrù-isẹ́ ète wọn lati gbiyanju lati mú iru awọn eniyan bẹẹ láyọ̀. O ṣetan, iṣẹ wọn sinmi lé e. Ṣugbọn iwe-irohin àtìgbàdégbà kan sọ nipa “awọn afìbò yannisípò ti wọn kò láyọ̀ ti a sì sọdajeji” ni Poland. Akọrohin kan ṣalaye pe United States jẹ́ ẹgbẹ-awujọ kan “ti o kun fun ainigbẹkẹle nipa oṣelu ti a gbekari ilana títọ́.” Onkọwe miiran sọ fun wa nipa “aibikita oṣelu ti ń gasoke ni ilẹ̀ Faranse.” Iru aibikita ati aisi itẹlọrun ti o ti tankalẹ bẹẹ—ti kò mọ si awọn orilẹ-ede mẹta wọnyi—damọran pe awọn oṣelu ń kùnà ninu isapa wọn lati mú awọn eniyan láyọ̀.

Awọn olori isin pẹlu ṣeleri ayọ̀, bi kìí bá ṣe ninu igbesi-aye yii, nigba naa o kere tan ninu ti ọjọ iwaju kan. Wọn gbé eyi karí ìpìlẹ̀ èrò naa pe eniyan ni ọkàn alaileeku tabi eyi ti ń ṣí kiri, ero kan ti ọpọ awọn eniyan kọ silẹ fun oniruuru idi ti Bibeli sì jáníkoro. Awọn ṣọọṣi ti o ṣofo ati awọn akọsilẹ mẹmba ti ń kere sii fihan pe ẹgbẹẹgbẹrun ọkẹ awọn eniyan kò ka isin si ohun ti o ṣepataki fun ayọ̀ mọ́.—Fiwe Genesisi 2:7, 17; Esekieli 18:4, 20.

Awọn Alainitẹẹlọrun Olufẹẹ Fadaka

Bi kìí bá ṣe ninu oṣelu tabi ninu isin, nibo ni a ti le ri ayọ̀? Boya ni ayika ìṣòwò? Oun pẹlu ń sọ pe ohun lè pese ayọ̀. Ó ń gbe ọ̀ràn tirẹ kalẹ nipasẹ awọn ọ̀nà ipolowo-ọja, ti o sì ń sọ kedere pe: Ayọ ń wá lati inu gbogbo ohun-ìní ati iṣẹ́ ipese ti owó lè rà.

Iye awọn eniyan ti ń wá ayọ̀ ni ọ̀nà yii dabi eyi ti ń pọ̀ sii. A rohin rẹ̀ ni ọpọ ọdun sẹhin pe ni gbogbo iṣẹ́jú ààyá agbo-ile kọọkan ni Germany wà ninu gbèsè ti o wuwo. Kò yanilẹnu, nigba naa, pe iwe-irohin gbígbayì ti ilẹ Germany naa Die Zeit sọtẹlẹ pe “pupọ [ninu iwọnyi] kò ni bọ́ kuro ninu oko gbèsè lae.” O ṣalaye pe: “O rọrun gan-an lati gbà rekọja iwọn iye ti banki ń funni lati ìgbà dé ìgbà—ó sì nira gan-an lati bọ́ kuro ninu idẹkun gbese.”

Ipo-ọran naa ní awọn orilẹ-ede onile iṣẹ́ -ẹ̀rọ pupọ gidigidi rí bakan naa. Ni awọn ọdun diẹ ṣehin, David Caplovitz, onimọ nipa ẹgbẹ-oun-ọgba ati iwa ẹ̀dá ni City University ti New York, foju diwọn pe ni United States, laaarin aadọta-ọkẹ lọna 20 ati aadọta-ọkẹ lọna 25 agbo-ile ni wọn wà ninu gbèsè ti o ga. “Awọn eniyan ni gbèsè ti bò mọlẹ,” ni ó sọ, “o si ń run igbesi-aye wọn.”

Iyẹn kò dún bi ayọ̀! Ṣugbọn awa ha gbọdọ reti pe ki ayé iṣowo lè ṣe ohun ti awọn meji yooku (oṣelu ati isin) kò lè ṣe bi o ti hàn gbangba bi? Ọba Solomoni Ọlọ́rọ̀ nigba kan kọwe pe: “Ẹni ti o bá fẹ́ fadaka, fadaka kì yoo tẹ́ ẹ lọrun; bẹẹ ni ẹni ti o fẹ́ ọrọ̀, kì yoo tẹ́ ẹ lọrun; asán ni eyi pẹlu.”—Oniwasu 5:10.

Wíwá ayọ̀ ninu awọn ohun-ìní ti ara dabii kíkọ́ ile nla soju ofuurufu. O lè jẹ ohun ti ń wunilori lati kọ́ ọ, ṣugbọn iwọ yoo ni iṣoro ti o bá gbiyanju lati gbé ninu rẹ̀.

A Le Ri Ayọ Ṣugbọn Bawo?

Aposteli Paulu pe Jehofa ni “Ọlọrun aláyọ̀.” (1 Timoteu 1:11, NW) Nipa dídá awọn eniyan ni aworan araarẹ̀, Ọlọrun aláyọ̀ naa fun awọn pẹlu ni agbara lati jẹ́ aláyọ̀. (Genesisi 1:26) Ṣugbọn ayọ̀ wọn ni o nilati sinmi lori ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun, gẹgẹ bi olorin naa ti fihan: “Alayọ ni awọn eniyan ti Ọlọrun wọn jẹ Jehofa.” (Orin Dafidi 144:15b, NW) Ohun ti iṣẹ-isin wa si Ọlọrun ni ninu ati bi ṣiṣiṣẹsin in wa ṣe ń sinni lọ sinu ayọ tootọ ni a le loye daradara bi a ba ṣagbeyẹwo diẹ lara awọn ibi 110 ti awọn ọ̀rọ̀ naa “ayọ” ati “idunnu” ti wáyé ninu New World Translation.

Dídá Awọn Aini Tẹmi Mọ̀

Jesu Kristi, Ọmọkunrin Ọlọrun, sọ ninu Iwaasu rẹ̀ olókìkí lori Oke: “[Alayọ] ni awọn otoṣi ni ẹmi: nitori tiwọn ni ijọba ọrun.” (Matteu 5:3) Ayé iṣowo ń gbiyanju lati ṣì wa lọna sinu rironu pe rira awọn nǹkan amáyédẹrùn ti tó fun ayọ̀. O sọ fun wa pe ayọ jẹ níní ẹrọ kọmputa inu ile kan, kamẹra fidio, tẹlifoonu, ọkọ̀ ayọkẹlẹ, ohun iṣere idaraya ti o tobi julọ, aṣọ alarabara. Ohun ti kò sọ fun wa ni pe ẹgbẹẹgbẹrun aimọye awọn eniyan ní agbaye ṣalaini awọn nǹkan wọnyi sibẹ wọn kò fi dandan jẹ́ aláìláyọ̀. Nigba ti ó lè ṣeeṣe ki wọn mú igbesi-aye jẹ́ eyi ti o tubọ dẹrùn ti o sì dẹra, awọn nǹkan wọnyi kò ṣekoko fun ayọ̀.

Bi Paulu ti ṣe, awọn ẹni ti aini wọn nipa tẹmi jẹ lọkan sọ pe: “Bi a bá sì ni ounjẹ ati aṣọ iwọnyi yoo tẹ́ wa lọrun.” (1 Timoteu 6:8) Eeṣe? Nitori pe títẹ́ awọn aini tẹmi lọrun ni ohun ti ń sinni lọ si ìyè ayeraye.—Johannu 17:3.

Ohun kan ha wa ti o buru ninu gbigbadun awọn ohun didara bi a bá ni owó lati rà wọn bi? O ṣeeṣe ki o má ri bẹẹ. Sibẹ, o fun ipo tẹmi wa lokun lati kẹkọọ lati maṣe kowọnu gbogbo ero alainilaari tabi lati ra ohun kan kiki nitori pe a lagbara lati rà á. A tipa bayii kẹkọọ itẹlọrun a sì di ayọ mú, gẹgẹ bi Jesu ti ṣe, bi o tilẹ jẹ pe ipo iṣunna-owo rẹ̀ kìí ṣe eyi ti o dara julọ ni ibamu pẹlu awọn ọpa-idiwọn ti ayé. (Matteu 8:20) Kìí sìí ṣe pe Paulu ń fi àìnídùnnú hàn ni nigba ti o sọ pe: “Nitori pe ipokipo ti mo bá wà, mo ti kọ́ lati ni itẹlọrun ninu rẹ̀. Mo mọ̀ bi àá ti ṣeé di rírẹ̀-sílẹ̀, mo si mọ bi àá ti ṣeé di pipọ: ni ohunkohun ati ni ohun gbogbo mo ti kọ́ aṣiri ati maa jẹ ajẹyo ati lati wà ni aijẹ, lati maa ni àníjù ati lati ṣe alaini.”—Filippi 4:11, 12.

Gbigbẹkẹle Jehofa

Iwalojufo sí aini ẹni nipa tẹmi fi imuratan lati gbẹkẹle Ọlọrun hàn. Eyi ń mu idunnu wá, gẹgẹ bi Ọba Solomoni ti ṣalaye: “Ẹni ti o sì gbẹkẹle Oluwa, ibukun ni fun un.”—Owe 16:20.

Kìí ha ṣe otitọ, bi o ti wu ki o ri, pe ọpọ eniyan gbé igbẹkẹle ti o ga ju lé owó ati awọn ohun-ìní ju bi wọn ti ṣe ninu Ọlọrun lọ bi? Bi a bá wò ó lati inu oju-iwoye yii, ẹkukáká ni ibi bibaamu julọ kan fi lè wà lati ṣaṣehan ọ̀rọ̀ atọnisọna naa “Ọlọrun Ni Awa Gbẹkẹle” ju lori owó lọ, bi o tilẹ jẹ pe ọ̀rọ̀ yẹn farahan lori owó ilẹ U.S.

Ọba Solomoni, ẹni ti kò ṣalaini eyikeyii ninu gbogbo awọn ohun rere ti owó le rà, rii pe nini igbẹkẹle ninu awọn ohun-ìní ti ara kìí jalẹ si ayọ̀ pipẹtiti. (Oniwasu 5:12-15) Owó ni banki ni a lè padanu nipasẹ ìkùnà banki tabi ifosoke owó ọja. Ilé tabi ilẹ̀ ni awọn ìjì lilekoko lè parun. Awọn iwe akọsilẹ owó ìbánigbófò, bi o ti jẹ́ eyi ti ń rọ́pò awọn àdánù lọna ranpẹ, kò lè ṣàsanpadà fun awọn àdánù ti ero-imọlara. Awọn iwe ẹ̀tọ́ lori owó ìdókòwò ati ìwé ẹ̀tọ́ lori owó ti a fi yáni lè di alainiyelori ni ọ̀sán-kan-òru-kan ninu iwolulẹ ọjà iṣowo lojiji. Àní iṣẹ ti ń mówó jaburata wọle paapaa—fun ọpọlọpọ idi—lè wà nihin-in lonii ki o si jẹ́ fun ìgbà kukuru.

Fun awọn idi wọnyii ẹni ti o bá ń gbẹkẹle Jehofa ń ri ọgbọn ti fifetisilẹ si ikilọ Jesu pe: “Ẹ maṣe to iṣura jọ fun araayin ni ayé, nibi ti kokoro ati ìpáàrà íbà á jẹ́, ati nibi ti awọn ole írúnlẹ̀ ti wọn si i jale: Ṣugbọn ẹ to iṣura jọ fun araayin ni ọrun, nibi ti kokoro ati ìpáàrà kò lè bà á jẹ́, ati nibi awọn ole kò lè rúnlẹ̀ ki wọn sì jale.”—Matteu 6:19, 20.

Iru imọlara aabo ati imọlara ayọ nla wo ni o lè wà ju lati mọ pe ẹnikan ti fi igbẹkẹle ẹni sinu Ọlọrun Olodumare, ẹni ti o ń pese nigba gbogbo?—Orin Dafidi 94:14; Heberu 13:5, 6.

Titẹwọgba Ibawi Atọrunwa

Itọni, àní ibawi paapaa, ni a ń tẹwọgbà nigba ti a bá funni pẹlu ẹmi ifẹ lati ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ tootọ kan. Ẹnikan ti o jẹwọ jíjẹ́ ọ̀rẹ́ iranṣẹ Ọlọrun naa Jobu fi ẹmi mo-jẹ́-olódodo sọ fun un pe: “[Alayọ] ni ẹni ti Ọlọrun bawi.” Bi o tilẹ jẹ pe gbolohun-ọrọ naa jẹ otitọ, ohun tí Elifasi ni lọkan nipa awọn ọ̀rọ̀ wọnyi—pe Jobu jẹbi ẹ̀ṣẹ̀ wiwuwo—kìí ṣe otitọ. Oun ti jẹ́ ‘ayọnilẹnu olutunininu eniyan’ tó! Bi o ti wu ki o ri, nigba ti Jehofa wá bá Jobu wi ni ọ̀nà onifẹẹ, Jobu fi irẹlẹ gba ibawi naa o si fi araarẹ̀ si oju ọ̀nà ayọ̀ titobi ju.—Jobu 5:17; 16:2; 42:6, 10-17.

Lonii, Ọlọrun kìí bá awọn iranṣẹ rẹ̀ sọrọ ni taarata bi oun ti ṣe si Jobu. Kaka bẹẹ, oun ń bá wọn wi nipasẹ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati eto-ajọ rẹ̀ ti a ń fi ẹmi dari. Awọn Kristian ti wọn ń lepa èrè ọlọrọ alumọni, bi o ti wu ki o ri, kìí sábà ni akoko, okun-inu, tabi isunniṣe lati kẹkọọ Bibeli deedee ki wọn sì pesẹ si gbogbo awọn ipade ti eto-ajọ Jehofa pese.

Ọkunrin naa ti Ọlọrun ń bawi, ni ibamu pẹlu Owe 3:11-18, mọ ọgbọn titẹwọgba iru ibawi bẹẹ: “[Ayọ] ni fun ọkunrin naa ti o wá ọgbọ́n ri, ati ọkunrin naa ti o gba òye. Nitori ti owó rẹ̀ ju owó fadaka lọ, èrè rẹ̀ sì ju ti wura daradara lọ. O ṣe iyebiye ju iyùn lọ: ati ohun gbogbo ti iwọ lè fẹ́, kò si eyi ti a lè fi wé e. Ọjọ gigun ń bẹ ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ati ni ọwọ́ òsì rẹ̀, ọrọ̀ ati ọlá. Ọ̀nà rẹ̀, ọ̀nà didun ni, ati gbogbo ipa-ọna rẹ̀, alaafia. Igi iye ni i ṣe fun gbogbo awọn ti o di i mú: [ayọ] sì ni fun ẹni ti o di i mu ṣinṣin.”

Jíjẹ́ Ẹni ti Ó Mọ́ ati Olufẹ Alaafia

Jesu ṣapejuwe awọn aláyọ̀ gẹgẹ bi ẹni ti o jẹ́ “ọlọ́kàn-àyà mímọ́” ati “ẹni ti ń wá alaafia.” (Matteu 5:8, 9, NW) Ṣugbọn ninu ayé kan ti o fun ọ̀nà igbesi-aye kíkó ọrọ̀ alumọni jọ niṣiiri, ẹ wo bi o ti rọrun tó fun ọkan-ifẹ onimọtara-ẹni-nikan, ati boya aláìmọ́, lati ta gbòǹgbò ninu ọkan-aya wa! Bi a kò bá ṣamọna wa nipasẹ ọgbọ́n atọrunwa, ẹ wo bi o ti lè rọrun tó fun wa àní lati di ẹni ti a ṣilọna lọ sinu wíwá ire-áásìkí niti iṣunna owó nipasẹ awọn ọ̀nà ti kò tọna ti o lè bá awọn ibaṣepọ alalaafia pẹlu awọn ẹlomiran jẹ́! Kii ṣe lainidii, ni Bibeli fi kilọ pe: “Nitori ifẹ owó ni gbongbo ohun buburu gbogbo: eyi ti awọn miiran ń lepa ti a sì mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ, wọn sì fi ibinujẹ pupọ gún araawọn ni ọ̀kọ̀.”—1 Timoteu 6:10.

Ifẹ owó ń gbe oju-iwoye onigbeeraga larugẹ eyi ti ń ṣikẹ ainitẹẹlọrun, aimoore, ati ìwọra. Lati yẹra fun iru ẹmi òdì bẹẹ lati gberu, awọn Kristian kan, ṣaaju ki wọn tó ṣe awọn ipinnu iṣunna owó ti o ṣe gunmọ kan ń bi araawọn ní irú awọn ibeere bii: Mo ha nilo rẹ̀ niti gidi bi? Mo ha nilo ọjà olówó gọbọi yii tabi iṣẹ amówó gọbọi wọle, ti o ń gba akoko yii ju awọn araadọta-ọkẹ eniyan miiran ti wọn nilati gbé laisi i bi? O ha sì lè jẹ́ ohun ti o sàn jù fun mi lati lo owó mi tabi akoko mi fun mimu ipa mi gbooro sii ninu ijọsin tootọ, ni kikọwọti iṣẹ iwaasu kari-aye naa, tabi ni riran awọn eniyan ti wọn kò ni anfaani tó mi lọwọ bi?

Fifi Ifarada Hàn

Ọ̀kan ninu awọn idanwo ti a fipá mu Jobu lati farada ni ìfìṣúnná owó duni. (Jobu 1:14-17) Gẹgẹ bi apẹẹrẹ rẹ̀ ti fihan, ifarada ni a beere fun ninu gbogbo apá igbesi-aye. Awọn Kristian kan gbọdọ farada inunibini; awọn miiran, adanwo; sibẹ awọn miiran, awọn ipo iṣunna owó ti kò báradé. Ṣugbọn ifarada oniruuru ni Jehofa yoo san èrè fun, gẹgẹ bi Kristian ọmọlẹhin naa Jakọbu ti kọwe ni itọkasi Jobu: “Awa a maa ka awọn ti o farada ìyà si ẹni ibukun.”—Jakọbu 5:11.

Didagunla si awọn ire tẹmi ki a baa le mu ipo iṣunna owó wa sunwọn lè mú itura onigba kukuru wá niti iṣunna owó, ṣugbọn yoo ṣeranwọ lati mú òye iriran wa nipa itura wíwà titilọ niti iṣunna owó labẹ Ijọba Ọlọrun mọlẹ kedere bi? Ewu ti o yẹ lati koribọ ha ni bi?—2 Korinti 4:18.

Riri Ayọ Nisinsinyi ati Titilae

O hàn kedere pe awọn eniyan kan tako oju-iwoye Jehofa nipa ohun ti ó gba lati mú ki eniyan láyọ̀. Ni gbigbojufo awọn anfaani pipẹtiti tí ó ṣe pataki julọ dá, wọn kò ri anfaani oju-ẹsẹ ti o jẹ́ ti ara-ẹni ninu ṣiṣe ohun ti Ọlọrun gbaninimọran. Wọn kuna lati mọ̀ pe gbigbẹkẹle awọn ohun-ìní ti ara jẹ́ asán ó sì ń sini lọ sinu ijakulẹ. Onkọwe Bibeli naa beere lọna titọna pe: “Nigba ti ẹrù ba ń pọ si i, awọn ti o sì ń jẹ ẹ a maa pọ̀ si i: oore ki tilẹ ni fun ẹni ti o ni i bikoṣe pe ki wọn ki o maa fi oju wọn wò ó?” (Oniwasu 5:11; tun wo Oniwasu 2:4-11; 7:12.) Ẹ wo bi ìfẹ́-ọkàn ti ń yára fò lọ ti awọn nǹkan ti a si lero pe a wulẹ nilati ní sì ń di eyi ti a gbe ju sori pẹpẹ ìkẹ́rùsí ti yoo sì bu tátá fun eruku!

Kristian tootọ kan kì yoo jẹ́ ki a fa oun sabẹ ikimọlẹ lati “tẹ́gbẹ́-tọ́gbà” niti awọn ohun-ìní ti ara. Ó mọ̀ pe itoyeyẹ tootọ ni a ń diyele, kìí ṣe ninu ohun ti ẹnikan ni, ṣugbọn ninu ohun ti ẹnikan jẹ́. Kò si iyemeji ninu ọkàn rẹ̀ nipa ohun ti ó beere fun lati mú ki ẹnikan layọ—kí o layọ̀ nitootọ: gbigbadun ibaṣepọ rere pẹlu Jehofa ati jijẹ ki ọwọ́ di ninu iṣẹ-isin Rẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Awọn ohun-ìní ti ara nikan kò le mu ayọ̀ pipẹtiti wa lae

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Bibeli wi pe: “[Alayọ] ni awọn òtòṣì ní ẹ̀mí”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́