Ọrọ̀ Ha Lè Mú Ọ Láyọ̀ Bí?
Sólómọ́nì Ọba mọ ìjẹ́pàtàkì owó. Ó kọ̀wé pé: “Oúnjẹ wà fún ẹ̀rín àwọn òṣìṣẹ́, wáìnì sì ń mú kí ìgbésí ayé kún fún ayọ̀ yíyọ̀; ṣùgbọ́n owó ní ń mú ìdáhùn wá nínú ohun gbogbo.” (Oníwàásù 10:19) Bíbá àwọn ọ̀rẹ́ jẹun pọ̀ lè gbádùn mọ́ni gidi gan-an, ṣùgbọ́n láti lè ra oúnjẹ tàbí wáìnì, o nílò owó. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé owó ni a fi ń ra àwọn nǹkan ti ara, òun ni ó máa “ń mú ìdáhùn wá nínú ohun gbogbo.”
BÍ Ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì ní ọrọ̀ tabua, ó mọ̀ pé agbára ọrọ̀ ní ààlà. Ó mọ̀ pé ìgbésí ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì kì í yọrí sí ayọ̀. Ó kọ̀wé pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.”—Oníwàásù 5:10.
Kí a tilẹ̀ sọ pé ọlọ́rọ̀ kan ní ọrọ̀ púpọ̀ sí i. Sólómọ́nì wí pé: “Nígbà tí àwọn ohun rere bá di púpọ̀, dájúdájú àwọn tí ń jẹ wọ́n a di púpọ̀.” (Oníwàásù 5:11) Bí “àwọn ohun rere,” tàbí ohun ìní ẹnì kan ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni a óò nílò ènìyàn púpọ̀ sí i láti bójú tó wọn. Àwọn atún-nǹkan-ṣe, àwọn tí ń bójú tó nǹkan ìní, àwọn ìránṣẹ́, àwọn ẹ̀ṣọ́, àti àwọn mìíràn—gbogbo wọn ni a gbọ́dọ̀ máa sanwó iṣẹ́ fún. Ẹ̀wẹ̀, èyí ń béèrè fún owó púpọ̀-púpọ̀ sí i.
Irúfẹ́ ipò bẹ́ẹ̀ ń ṣàkóbá fún ayọ̀ ẹni. Òpìtàn náà, Xenophon, tí í ṣe Gíríìkì, ẹni tí ó gbé ní ọ̀rúndún kẹrin ṣááju Sànmánì Tiwa, ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ọkùnrin òtòṣì kan tí ó di ọlọ́rọ̀, pé:
“Họ́wù, ṣé o lérò ní ti gidi pé . . . bí mo ṣe ń ní ohun púpọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni n óò ṣe máa gbé ìgbésí ayé aláyọ̀ sí i?” Ó ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé, “o kò mọ̀ pé ìgbádùn tí mo ń rí nínú jíjẹ àti mímu àti sísùn nísinsìnyí kò lé rárá sí èyí tí mo ń rí nígbà tí mo jẹ́ òtòṣì. Èrè kan ṣoṣo tí mo ń jẹ láti inú níní ohun tí ó pọ̀ tó yìí ni pé ó di dandan fún mi láti máa bójú tó ohun púpọ̀ sí i, láti máa pín ohun púpọ̀ sí i fún àwọn ẹlòmíràn, àti wàhálà bíbójútó ohun tí ó pọ̀ ju ohun tí mo ní tẹ́lẹ̀. Nítorí pé nísinsìnyí, ọwọ́ mi ni ọ̀pọ̀ àwọn ará ilé ń wò fún oúnjẹ, ọ̀pọ̀ fún mímu, àti ọ̀pọ̀ fún aṣọ, nígbà tí àwọn mìíràn nílò dókítà; ọ̀kan a sì wá ṣàlàyé fún mi nípa bí àwọn ìkookò ṣe kọlu àwọn àgùntàn, tàbí nípa àwọn màlúù tí ó kú nípa jíjá sínú ọ̀gbun, tàbí láti wá sọ pé àrùn kan ti bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ohun ọ̀sìn. Nítorí náà lójú tèmi, ó jọ pé . . . wàhálà tí mo ní nísinsìnyí tí mo ní ohun púpọ̀, pọ̀ ju wàhálà tí mo ní nígbà tí mo ní ohun díẹ̀.”
Ìdí mìíràn tí àwọn ènìyàn fi ń lépa ọrọ̀ ṣáá ni pé ohun tí Jésù Kristi pè ní “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” ti tàn wọ́n jẹ. (Mátíù 13:22) A ń tàn wọ́n jẹ nítorí pé wọn kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ tí wọ́n ń retí láti ní nínú ọrọ̀ tí wọ́n ń wá lójú méjèèjì. Wọ́n ń ronú pé ohun tí ọrọ̀ tí ó mọ níwọ̀n kò lè ṣe, ọrọ̀ púpọ̀ yóò ṣe é. Nítorí náà, wọ́n ń làkàkà ṣáá fún púpọ̀ sí i.
Ìfẹ́ Owó Kì Í Yọrí sí Ayọ̀
Àníyàn tí ọlọ́rọ̀ ń ṣe nípa àwọn nǹkan ìní rẹ̀ lè máà jẹ́ kí ó gbádùn oorun alẹ́ ní àlàáfíà. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Dídùn ni oorun ẹni tí ń ṣiṣẹ́ sìn, ì báà jẹ́ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀ ni ó jẹ; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.”—Oníwàásù 5:12.
Nígbà tí ìdààmú bá pọ̀ lápọ̀jù nípa ṣíṣeéṣe tí ó ṣeé ṣe kí èèyàn pàdánù ọrọ̀ rẹ̀, àbájáde rẹ̀ lè ré kọjá àìrí oorun sùn. Nígbà tí Sólómọ́nì ń ṣàpèjúwe ahun ènìyàn, ó kọ̀wé pé: “Inú òkùnkùn ni ó ti ń jẹun ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀, pẹ̀lú pákáǹleke púpọ̀ gan-an, tòun ti àìsàn àti ìdí fún ìkannú.” (Oníwàásù 5:17) Dípò níní ayọ̀ nínú ọrọ̀, ó ń jẹun ‘nínú pákáǹleke,’ àfi bí ẹni pé owó tí ó ń ná sórí oúnjẹ pàápàá ń bí i nínú. Irú ojú ìwòye tí kò sunwọ̀n bẹ́ẹ̀ lè dákún àìlera. Ẹ̀wẹ̀, àìlera ń fi kún àníyàn ahun ènìyàn, níwọ̀n bí èyí ti ń ṣèdíwọ́ fún kíkó ọrọ̀ púpọ̀ sí i jọ.
Bóyá èyí rán ọ létí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé rẹ̀ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí . . . àwọn kan . . . ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tímótì 6:9, 10) Nígbà tí àwọn ènìyàn bá ń lépa owó, wọn a máa rẹ́ni jẹ, wọn a máa purọ́, wọn a máa jalè, wọn a máa ṣe aṣẹ́wó, wọn a tilẹ̀ máa pànìyàn. Ó máa ń yọrí sí ẹni tí ìrora dábírà sí lára ní ti èrò ìmọ̀lára, ní ti ara ìyára, àti nípa tẹ̀mí nítorí pé ó ń gbìyànjú láti nawọ́ gán ọrọ̀, kí ó sì dì í mú ṣinṣin. Èyí ha dún bí ọ̀nà tí ń sinni lọ sí ayọ̀ bí? Ó tì o!
Níní Ìtẹ́lọ́rùn Pẹ̀lú Ohun Tí A Ní
Sólómọ́nì ní púpọ̀ sí i láti sọ nípa ojú ìwòye tí ó wà déédéé nípa ọrọ̀. Ó kọ̀wé pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe jáde wá láti inú ikùn ìyá rẹ̀, ìhòòhò ni ènìyàn yóò tún lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe wá; ènìyàn kò sì lè kó nǹkan kan lọ rárá nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ̀, èyí tí ó lè mú dání lọ ní ọwọ́ rẹ̀. Wò ó! Ohun tí ó dára jù lọ tí èmi alára ti rí, èyí tí ó ṣe rèterète, ni pé kí ènìyàn máa jẹ kí ó sì máa mu kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀, èyí tí ó fi ń ṣiṣẹ́ kárakára lábẹ́ oòrùn ní iye ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ fi fún un, nítorí ìyẹn ni ìpín rẹ̀.”—Oníwàásù 5:15, 18.
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi hàn pé ayọ̀ kò sinmi lé lílàkàkà láti to ọrọ̀ jọ pelemọ fún ọjọ́ iwájú tí a lè má fi ojú wa rí. Ó kúkú sàn kí a ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìyọrísí iṣẹ́ àṣekára wa, kí a sì máa yọ̀ nínú rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ èrò kan náà jáde nínú lẹ́tà rẹ̀ onímìísí, èyí tí ó kọ sí Tímótì, ó wí pé: “A kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tímótì 6:7, 8; fi wé Lúùkù 12:16-21.
Àṣírí Ayọ̀
Sólómọ́nì ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọrọ̀ àti ọgbọ́n tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Ṣùgbọ́n ó fi hàn pé ọgbọ́n ni ayọ̀ bá tan, kì í ṣe owó. Ó wí pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó ti wá ọgbọ́n rí, àti ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀, nítorí níní in gẹ́gẹ́ bí èrè sàn ju níní fàdákà gẹ́gẹ́ bí èrè, níní in gẹ́gẹ́ bí èso sì sàn ju níní wúrà pàápàá. Ó ṣe iyebíye ju iyùn, a kò sì lè mú gbogbo àwọn nǹkan mìíràn tí í ṣe inú dídùn rẹ bá a dọ́gba. Ọjọ́ gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ọrọ̀ àti ògo sì ń bẹ ní ọwọ́ òsì rẹ̀. Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀nà adùn, gbogbo òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ àlàáfíà. Ó jẹ́ igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin ni a ó pè ní aláyọ̀.”—Òwe 3:13-18.
Èé ṣe tí ọgbọ́n fi lékè àwọn nǹkan ìní ti ara? Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò; ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.” (Oníwàásù 7:12) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé owó ń pèsè ìdáàbòbò díẹ̀, tí ó ń mú kí ó ṣeé ṣe fún ẹni tí ó ni ín láti ra ohun tí ó nílò, ọgbọ́n lè dáàbò boni lọ́wọ́ àwọn ìgbésẹ̀ tí ó lè fi ẹ̀mí ẹni wewu. Kì í ṣe kìkì pé ọgbọ́n tòótọ́ lè gbani lọ́wọ́ ikú àìtọ́jọ́ nìkan ni ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí a ti gbé e ka ìbẹ̀rù títọ́ fún Ọlọ́run, yóò yọrí sí jíjèrè ìyè àìnípẹ̀kun.
Èé ṣe tí ọgbọ́n tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá fi ń yọrí sí ayọ̀? Nítorí pé ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni ayọ̀ tòótọ́ ti ń wá. Ìrírí fi hàn pé a lè jèrè ojúlówó ayọ̀ kìkì nípasẹ̀ ṣíṣe ìgbọràn sí Ẹni Gíga Jù Lọ. Ayọ̀ pípẹ́ títí sinmi lé mímú ìdúró tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. (Mátíù 5:3-10) Nípa fífi ohun tí a ń kọ́ láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílò, a óò mú “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” dàgbà. (Jákọ́bù 3:17) Yóò fún wa ní ayọ̀ tí ọrọ̀ kò lè mú wá láé.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Sólómọ́nì Ọba mọ ohun tí ń múni láyọ̀. Ǹjẹ́ o mọ̀ ọ́n?