Ojúlówó Aásìkí Ń Bọ̀ Nínú Ayé Tuntun ti Ọlọ́run
KRISTẸNI ni Adéwálé,a ó níyàwó ó sì tún bímọ. Nígbà tó ṣí lọ sílẹ̀ Amẹ́ríkà, èrò rẹ̀ ni pé kò sóhun tó dáa tó ohun tóun ṣe yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wù ú láti fìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀, síbẹ̀ ó gbà pé nǹkan á túbọ̀ ṣẹnuure sí i fún wọn bóun bá túbọ̀ lówó sí i. Ìdí nìyẹn tó fi gbà láti lọ sílùú New York nígbà táwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan tó wà níbẹ̀ sọ pé kó máa bọ̀, kò sì pẹ́ tó débẹ̀ tó fi ríṣẹ́.
Àmọ́ bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, èrò tí Adéwálé ní tẹ́lẹ̀ pé kò ní séwu kankan bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà. Kò fi bẹ́ẹ̀ ráyè mọ́ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ó tiẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ dẹni tí kò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run mọ́ lákòókò kan. Ìgbà tó wá lọ́wọ́ nínú ìwàkíwà kan ló tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ irú ipò tóun wà. Owó tó ń lé lójú méjèèjì ti mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàgbé gbogbo ohun tó kà sí pàtàkì tẹ́lẹ̀. Ó wá di dandan kó ṣàtúnṣe ìgbésí ayé rẹ̀.
Bíi ti Adéwálé, ọdọọdún ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣí kúrò lórílẹ̀-èdè wọn pẹ̀lú èrò láti túbọ̀ rí towó ṣe nítorí pé orílẹ̀-èdè wọn tòṣì. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, àdánù ńlá ló máa ń já sí fún wọn nípa tẹ̀mí. Ìbéèrè táwọn kan wá ń béèrè ni pé ‘Ṣé ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni lè máa lé ọrọ̀ tara kó sì tún ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run?’ Àwọn gbajúgbajà òǹkọ̀wé àtàwọn olórí ẹ̀sìn sọ pé ó ṣeé ṣe. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tójú David àtàwọn mìíràn ti rí, kò rọrùn láti ní méjèèjì pa pọ̀.—Lúùkù 18:24.
Owó Fúnra Rẹ̀ Kò Burú
Ẹ̀dá èèyàn ló ṣe owó. Kì í sì í ṣe ohun tó burú, báwọn nǹkan mìíràn tí ẹ̀dá èèyàn ṣe kò ṣe burú. Ohun téèyàn fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ohun mìíràn lásán ni. Nípa bẹ́ẹ̀, béèyàn bá lò ó lọ́nà yíyẹ, ó wúlò gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì gbà pé ‘owó wà fún ìdáàbòbò,’ àgàgà lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tí ìyà àti òṣì ń fà. (Oníwàásù 7:12) Àmọ́ ó jọ pé lójú àwọn kan, ‘owo ni idahùn ohun gbogbo.’—Oníwàásù 10:19, Bibeli Mimọ.
Ìwé Mímọ́ kò fara mọ́ kéèyàn jẹ́ ọ̀lẹ, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló rọ̀ wá pé ká jẹ́ ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára. A ní láti pèsè fún ìdílé wa, tá a bá sì jẹ ṣẹ́ kù díẹ̀, ìyẹn á tún jẹ́ ká ní “nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” (Éfésù 4:28; 1 Tímótì 5:8) Yàtọ̀ síyẹn, dípò kí Bíbélì sọ pé kéèyàn máa fìyà jẹ ara rẹ̀, ó fún wa níṣìírí láti gbádùn ohun tá a ní. Ó sọ fún wa pé ká “kó ìpín [wa] lọ” ká sì gbádùn èrè iṣẹ́ ọwọ́ wa. (Oníwàásù 5:18-20) Àní, ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì nípa àwọn ọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n sì lọ́rọ̀.
Àwọn Ọkùnrin Tí Wọ́n Jẹ́ Olóòótọ́ Tí Wọ́n sì Lọ́rọ̀
Ábúráhámù tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó sì jẹ́ olóòótọ́, ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran, bẹ́ẹ̀ ló tún ní fàdákà àti wúrà jaburata, ó tún ní ilé ńlá àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìránṣẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 12:5; 13:2, 6, 7) Jóòbù tóun náà jẹ́ olódodo èèyàn ní ọ̀rọ̀ gan-an. Ó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun ọ̀sìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìránṣẹ́, wúrà àti fàdákà. (Jóòbù 1:3; 42:11, 12) Bó bá tiẹ̀ jẹ́ ojú tòde òní la fẹ fi wò ó, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ́rọ̀ gan-an, àmọ́ wọ́n tún lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
“Baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́” ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Ábúráhámù. Ábúráhámù kò háwọ́ bẹ́ẹ̀ ni kò fẹ́ràn àwọn ohun ìní rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. (Róòmù 4:11; Jẹ́nẹ́sísì 13:9; 18:1-8) Bákan náà, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ pe Jóòbù ní “aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán.” (Jóòbù 1:8) Ó máa ń ran àwọn òtòṣì àtàwọn tó wà nínú ìpọ́njú lọ́wọ́. (Jóòbù 29:12-16) Ábúráhámù àti Jóòbù kò gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ wọn, Ọlọ́run ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé.—Jẹ́nẹ́sísì 14:22-24; Jóòbù 1:21, 22; Róòmù 4:9-12.
Àpẹẹrẹ mìíràn tún ni Sólómọ́nì Ọba. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìtẹ́ tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, kì í ṣe pé Ọlọ́run fi ọgbọ́n jíǹkí Sólómọ́nì nìkan ni, ó tún fún un ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ àti ògo. (1 Àwọn Ọba 3:4-14) Ó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run ní èyí tó pọ̀ jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀. Àmọ́, lọ́jọ́ alẹ́ rẹ̀, ‘ọkàn rẹ̀ kò pé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.’ (1 Àwọn Ọba 11:1-8) Ká sòótọ́, nǹkan ìbànújẹ́ tó ṣẹlẹ̀ sí Sólómọ́nì jẹ́ ká rí díẹ̀ lára àwọn ewu tó wà nínú kéèyàn lọ́rọ̀. Gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ewu wọ̀nyí.
Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Ọrọ̀
Ewu tó burú jù lọ ni kéèyàn di ẹni tó nífẹ̀ẹ́ owó àtohun tówó lè rà. Owó máa ń sọ àwọn kan dẹni tó ń fẹ́ láti máa ní nǹkan ṣáá, tí wọn kì í sì í nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Sólómọ́nì rí i níbẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ pé àwọn èèyàn ní ẹ̀mí yìí. Ó wá kọ̀wé pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá. Asán ni èyí pẹ̀lú.” (Oníwàásù 5:10) Nígbà tó yá, Jésù àti Pọ́ọ̀lù náà kìlọ̀ fáwọn Kristẹni láti ṣọ́ra fún ìfẹ́ owó tó ń tanni jẹ yìí.—Máàkù 4:18, 19; 2 Tímótì 3:2.
Tówó bá di ohun tá a fẹ́ràn gan-an dípò kó kàn jẹ́ ohun tá a fi ń bójú tó àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe, a ti fira wa sínú ewu híhu oríṣiríṣi ìwàkíwà nìyẹn, títí kan irọ́ pípa, olè jíjà, àti dídi aládàkàdekè èèyàn. Torí ọgbọ̀n ẹyọ owó fàdákà péré ni Júdásì Ísíkáríótù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Kristi fi da ọ̀gá rẹ̀. (Máàkù 14:11; Jòhánù 12:6) Níbi táwọn kan tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ owó dé, wọ́n ti fi rọ́pò Ọlọ́run nípa sísọ ọ́ di olórí ohun tí wọ́n ń jọ́sìn. (1 Tímótì 6:10) Nítorí náà, ó yẹ káwọn Kristẹni máa gbìyànjú nígbà gbogbo láti mọ ìdí táwọn fi fẹ́ ní owó sí i.—Hébérù 13:5.
Lílé ọrọ̀ tún ní àwọn ewu mìíràn nínú téèyàn lè má tètè fura sí. Àkọ́kọ́, téèyàn bá lọ́rọ̀ gan-an, ó máa ń jẹ́ kéèyàn dẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé ara rẹ̀. Jésù mẹ́nu kan kókó yìí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “agbára ìtannijẹ ọrọ̀.” (Mátíù 13:22) Jákọ́bù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì pàápàá kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe gbàgbé Ọlọ́run kódà nígbà tí wọ́n bá ń wéwèé nípa iṣẹ́ wọn. (Jákọ́bù 4:13-16) Níwọ̀n bó ti jọ pé owó máa ń jẹ́ ká ní èrò pé a lè dá dúró fúnra wa, gbogbo ìgbà làwọn tó lówó wà nínú ewu dídi ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé owó wọn dípò Ọlọ́run.—Òwe 30:7-9; Ìṣe 8:18-24.
Èkejì, gẹ́gẹ́ bí Adéwálé tá a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan ṣe wá rí i, lílé ọrọ̀ sábà máa ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò àti okun èèyàn, débi pé kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, kò ní jẹ́ kí onítọ̀hún ráyè fáwọn nǹkan ti Ọlọ́run mọ́. (Lúùkù 12:13-21) Ní táwọn tó lówó, ìgbà gbogbo ni wọ́n wà nínú ìdẹwò lílo ohun tí wọ́n ní fún kìkì ìgbádùn tara wọn tàbí fún àwọn ohun tí wọ́n ń lépa.
Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé dé ìwọ̀n àyè kan, ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ tí Sólómọ́nì ń gbé ni kò jẹ́ kó mọ ohun tó ń ṣe mọ́, tí èyí sì ba àjọṣe àárín òun àti Ọlọ́run jẹ́? (Lúùkù 21:34) Ó mọ̀ pé Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ òkèèrè dá àna. Síbẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn obìnrin tó fẹ́ ń lọ sí bí ẹgbẹ̀rún. (Diutarónómì 7:3) Wíwá tó ń wá bóun ṣe máa tẹ́ àwọn aya àjèjì tó fẹ́ lọ́rùn mú kó ṣe àwọn ètò tó jẹ́ kó lọ́wọ́ nínú sísin àwọn ọlọ́run mìíràn fún àǹfààní àwọn aya náà. Bá a ṣe sọ níṣàájú, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ọkàn Sólómọ́nì ṣí kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà.
Ní kedere, àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí fi hàn pé òótọ́ ni ìmọ̀ràn Jésù tó sọ pé: “Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” (Mátíù 6:24) Kí wá lẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni lè ṣe nípa ìṣòro owó tó ń dojú kọ ọ̀pọ̀ èèyàn lákòókò yìí? Ìbéèrè mìíràn tó tún ṣe pàtàkì ni pé, ǹjẹ́ ìrètí tiẹ̀ wà pé ìgbésí ayé tó dára ju ti ìsinsìnyí lọ máa wà lọ́jọ́ iwájú?
Ojúlówó Aásìkí Ń Bọ̀ Lọ́nà
Ipò àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù yàtọ̀ sí tàwọn baba ńlá ayé ọjọ́un bíi Ábúráhámù àti Jóòbù, àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ohun tó sì mú kó yàtọ̀ ni pé Jésù pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Kí wọ́n sì tó lè ṣe iṣẹ́ yìí, wọn ní láti lo àkókò àti okun wọn fún un dípò kí wọ́n máa fi àkókò wọn lé nǹkan tayé kiri. Nítorí náà, bá a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí, ohun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ ká máa ṣe lohun tí Jésù sọ fún wa, pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba [Ọlọ́run] àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:33.
Lẹ́yìn tí Adéwálé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pàdánù ìdílé rẹ̀, tó tún fẹ́rẹ̀ẹ́ pàdánù ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà, ó wá tún ìgbésí ayé rẹ̀ tó. Nígbà tí David tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbájú mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó ń gbàdúrà tó sì ń wàásù déédéé, gbogbo nǹkan tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣèlérí. Díẹ̀díẹ̀, àárín òun àti ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gún padà. Ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ tó ti ní tẹ́lẹ̀ tún padà wá. Ó ṣì ń ṣiṣẹ́ kárakára o, kì í sì í ṣe pé ó ti wá di ọlọ́rọ̀. Síbẹ̀, ó kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye látinú ohun tojú rẹ̀ rí.
Ohun tí Adéwálé wá sọ ni pé ká lóun mọ̀ ni òun ò ní lọ sí Amẹ́ríkà, ó sì ti pinnu pé òun ò tún ní jẹ́ kówó darí ìpinnu òun mọ́ láé. Báyìí, ó ti wá mọ̀ pé owó kò lè ra àwọn ohun tó ṣeyebíye jù lọ nígbèésí ayé ẹni, ìyẹn àwọn nǹkan bíi ìdílé táwọn tó wà níbẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn, ọ̀rẹ́ rere, àti kéèyàn ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. (Òwe 17:17; 24:27; Aísáyà 55:1, 2) Ká sòótọ́, kéèyàn rọ̀ mọ́ ìwà títọ́ ṣeyebíye gan-an ju ọrọ̀ lọ. (Òwe 19:1; 22:1) Pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìdílé rẹ̀, Adéwálé ti pinnu pé àwọn ohun tó yẹ kó wà nípò àkọ́kọ́ lòun yóò máa fi sípò àkọ́kọ́.—Fílípì 1:10.
Ìsapá àwọn èèyàn láti mú kí ayé jẹ́ ibi táwọn èèyàn á ti ní ọrọ̀ tí wọ́n á sì tún níwà rere ti kùnà láìmọye ìgbà. Àmọ́, Ọlọ́run ti ṣèlérí pé Ìjọba òun yóò pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nǹkan tara àti tẹ̀mí tó máa jẹ́ ká gbádùn ayé wa gan-an. (Sáàmù 72:16; Aísáyà 65:21-23) Jésù kọ́ wa pé ká tó lè ní ojúlówó ayọ̀, nǹkan tẹ̀mí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ wá lọ́kàn. (Mátíù 5:3) Nítorí náà, yálà ọlọ́rọ̀ ni wá tàbí akúṣẹ̀ẹ́, gbígbájúmọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí lákòókò yìí ni ọ̀nà tó dára jù lọ tí ẹnikẹ́ni nínú wa lè gbà máa múra sílẹ̀ de ayé tuntun Ọlọ́run tó sún mọ́lé. (1 Tímótì 6:17-19) Nínú ayé yẹn, àwọn èèyàn yóò ní ojúlówó aásìkí wọn yóò sì tún ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ọlọ́run ni Jóòbù gbẹ́kẹ̀ lé, kì í ṣe ọrọ̀ rẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Owó kò lè ra àwọn ohun tó ṣeyebíye jù lọ nígbèésí ayé ẹni