Owó àti Ìwà Rere Ohun Tí Ìtàn Kọ́ Wa Nípa Wọn
LỌ́JỌ́ keje oṣù kẹrin ọdún 1630, nǹkan bí irinwó [400] èèyàn wọ ọkọ̀ òkun mẹ́rin, wọ́n sì gbéra láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n forí lé ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ọ̀mọ̀wé gidi ni ọ̀pọ̀ lára wọn. Àwọn kan sì jẹ́ oníṣòwò tó rí towó ṣe. Kódà, ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin làwọn kan lára wọn. Ètò ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lákòókò náà, Ogun Ọgbọ̀n Ọdún tó ń jà lọ́wọ́ nílẹ̀ Yúróòpù (ọdún 1618 sí 1648) nígbà yẹn sì mú kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ burú sí i. Nítorí náà, wọ́n fi ilé wọn, iṣẹ́ wọn, àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn sílẹ̀ láìronú nípa ibi tí ìrìn-àjò náà lè já sí, wọ́n sì gbéra láti lọ wá bí nǹkan ṣe máa túbọ̀ dára sí i fún wọn.
Àwùjọ tó nígbàgbọ́ pé nǹkan á ṣẹnuure fáwọn yìí kì í ṣe àwọn oníṣòwò tó ń wá owó lójú méjèèjì o. Aláfọ̀mọ́ Ẹ̀sìn ni wọ́n, wọ́n sì nítara gan-an. Inúnibíni táwọn èèyàn ń ṣe sí wọn nítorí ẹ̀sìn wọn ló jẹ́ kí wọ́n máa sá lọ.a Olórí ohun tó wà lọ́kàn wọn ni pé káwọn dá àwùjọ kan tí yóò bẹ̀rù Ọlọ́run sílẹ̀, tí àwọn àti ìrandíran wọn yóò sì ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ láìsí pé àwọn tẹ ìlànà Bíbélì lójú. Kété lẹ́yìn tí wọ́n gúnlẹ̀ sí ìlú Salem ní ìpínlẹ̀ Massachusetts, wọ́n rí ilẹ̀ kékeré kan tí kò jìnnà sí etíkun, wọ́n sì tẹ ibẹ̀ dó. Boston lorúkọ tí wọ́n pe ibi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀dó yìí.
Kò Rọrùn Láti Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Kéèyàn sì Tún Jẹ́ Oníwà Rere
Ní ibùdó tuntun náà, ọ̀gbẹ́ni John Winthrop tó jẹ́ olórí wọn àti gómìnà wọn rọ̀ wọ́n gan-an pé kí kálukú ní ọrọ̀ kó sì fi ọrọ̀ rẹ̀ ṣe àwùjọ náà láǹfààní. Ó fẹ́ káwọn èèyàn náà lówó kí wọ́n sì tún níwà rere. Àmọ́ owó àti ìwà rere kì í sábà rìn pọ̀. Bó ti ń ronú pé ó ṣeé ṣe kí ìṣòro yọjú, ó bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ gan-an nípa ipa tí ọrọ̀ ń kó láwùjọ àwọn tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run.
Bíi tàwọn olórí yòókù láàárín àwọn Aláfọ̀mọ́ Ẹ̀sìn, ọ̀gbẹ́ni Winthrop gbà gbọ́ pé kò sóhun tó burú nínú lílé ọrọ̀. Ó ní olórí ohun tí ọrọ̀ wà fún ni láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, béèyàn bá ṣe lọ́rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni oore tó máa ṣe àwọn èèyàn yóò ṣe pọ̀ tó. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Patricia O’Toole sọ pé: “Bóyá la fi rí kókó ọ̀rọ̀ mìíràn tó máa ń kó ìdààmú ọkàn bá àwọn Aláfọ̀mọ́ Ẹ̀sìn yìí bí ọ̀rọ̀ níní aásìkí. Àmì ìbùkún Ọlọ́run ni wọ́n kà á sí, àmọ́ wọ́n tún kà á sóhun tó lè tètè sọni di onígbèéraga èèyàn . . . tó sì tún lè múni dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn.”
Káwọn èèyàn náà lè yẹra fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí owó àti ọrọ̀ rẹpẹtẹ lè fà, Winthrop rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì èèyàn àtẹni tó ń kóra rẹ̀ níjàánu. Àmọ́ kò pẹ́ rárá tí ẹ̀mí mo-fẹ́-dogún mo-fẹ́-dọgbọ̀n táwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní fi bẹ̀rẹ̀ sí í dí ìsapá rẹ̀ lọ́wọ́ láti mú wọn jẹ́ ẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run tó sì tún nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Àwọn kan tí kò fara mọ́ èrò Winthrop bẹ̀rẹ̀ sí í ta ko ohun tó ń sọ, wọ́n kà á sí pé ó ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé wọn, àti pé ó ń mára ni wọ́n. Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé kí wọ́n jẹ́ káwọn dìbò yan ìgbìmọ̀ kan tí yóò máa rí sí àwọn ìpinnu tí wọ́n bá fẹ́ ṣe. Àwọn kan ò tiẹ̀ dìbò, ńṣe ni wọ́n bá ẹsẹ̀ wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n forí lé ìlú kan tó ń jẹ́ Connecticut tí kò jìnnà sí wọn, kí wọ́n bàa lè ráyè ṣe ohun tí ọkàn wọn fẹ́.
Òpìtàn O’Toole sọ pé: “Àwọn ohun kan wà tó nípa gan-an lórí ìgbésí ayé àwọn Aláfọ̀mọ́ Ẹ̀sìn tó wà ní ìpínlẹ̀ Massachusetts yìí. Àwọn ohun náà ni yíyára lo àǹfààní tó bá yọjú, ọrọ̀, àti ìjọba tiwa-n-tiwa. Ó sì jọ pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ló túbọ̀ sọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn dẹni tó nífẹ̀ẹ́ ipò ọlá láìka èròǹgbà Winthrop sí pé kí wọ́n fi ọrọ̀ wọn ṣe àwọn èèyàn láǹfààní.” Nígbà tí Winthrop kú lọ́dún 1649 lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ní kọ́bọ̀ lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibùdó wọn tó ti fẹ́ túká náà wá fẹsẹ̀ múlẹ̀ nígbà tó yá láìka ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro sí, síbẹ̀ ohun tí Winthrop ní lọ́kàn kò ṣẹ títí tó fi kú.
Àwọn Èèyàn Ṣì Ń Wá Ìgbésí Ayé Tó Dára Gan-an
Ọ̀gbẹ́ni John Winthrop nìkan kọ́ ló nígbàgbọ́ pé ayé lè dára jù bó ṣe wà yìí lọ. Ọdọọdún ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn láti ilẹ̀ Áfíríkà, Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn Éṣíà, Ìlà Oòrùn Yúróòpù àti Latin Amẹ́ríkà ń ṣí lọ sáwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹ̀lú ìrètí pé ayé àwọn á dára sí i níbẹ̀. Ohun tó ń sún àwọn kan lára wọn ṣe bẹ́ẹ̀ ni ohun tí wọ́n ń rí nínú ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìwé tuntun tó ń jáde lọ́dọọdún, àwọn àpérò, àtàwọn ohun tó ń jáde lórí íńtánẹ́ẹ̀tì tó ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé wọ́n á rí towó ṣe. Ó hàn kedere pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ṣì ń sapá láti ní owó tí wọ́n sì retí pé àwọn ò ní sọ ìwà rere nù.
Àmọ́ ká sòótọ́, àwọn àbájáde tí à ń rí kò dùn mọ́ni nínú. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó ń lé ọrọ̀ kì í pẹ́ pa ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé tì, kódà wọ́n tiẹ̀ máa ń pa ìgbàgbọ́ wọn tì nígbà míì nítorí owó. Nítorí náà, o lè béèrè pé: “Ǹjẹ́ èèyàn lè jẹ́ Kristẹni tòótọ́ kó sì tún jẹ́ ọlọ́rọ̀? Ǹjẹ́ ayé kan tiẹ̀ máa wà táwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run ti máa ní ọrọ̀, tí wọ́n á sì tún níwà rere?” Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, a óò sì rí àwọn ìdáhùn náà nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ tí wọ́n sọ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì inú Ìjọ Áńgílíkà ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ni Aláfọ̀mọ́ Ẹ̀sìn, èyí tó túmọ̀ sí àwọn tó fẹ́ fọ gbogbo ẹ̀kọ́ Kátólíìkì mọ́ pátápátá kúrò nínú ẹ̀sìn wọn.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn ọkọ̀ òkun: The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck; Winthrop: Brown Brothers